Filippi 4:8

Lesson 341 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “(Nitori ohun ija wa ki iṣe ti ara, ṣugbọn o li agbara ninu Ọlọrun lati wó ibi giga palẹ;) Awa nsọ gbogbo ero kalẹ, ati gbogbo ohun giga ti ngbé ara rè̩ ga si imọỌlọrun, awa si ndi gbogbo ero ni igbekun wá si itẹriba fun Kristi” (2 Kọrinti 10:4, 5).
Cross References

I Awọn ohun ti o ṣe danindanin ninu Igbesi-ayé Onigbagbọ

1 Paulu kàá lẹsẹẹsẹ fun awọn eniyan mimọ ti o wa ni Filippi awọn ohun ti o yẹ lati ni fun igbesi-ayé iṣẹgun Onigbagbọ, Filippi 4:8

2 Ọrọ iyanju Paulu si gbogbo eniyan mimọ ni pe, ẹ maa wá ohun ti i ṣe otitọ ti o wàninu Jesu Kristi, Filippi 4:8; Matteu 22:16; Johannu 7:18; 14:6; 1:14, 17; 1 Johannu 5:6, 20

3 Jijẹ oloootọ ninu ohun gbogbo jé̩ ohun amuyẹ pataki fun Onigbagbọ, Filippi 4:8; Iṣe Awọn Apọsteli 6:3; Romu 12:17; 13:13; 2 Kọrinti 8:21; 13:7; 1 Tẹssalonika 4:12

4 A ni lati fun ododo ati idajọ ni ifiyesi ti o tọ ni igbesi-ayé eniyan gbogbo, Filippi 4:8; Gẹnẹsisi 18:19; Deuteronomi 16:19, 20; 2 Samuẹli 23:3; Orin Dafidi 83:3; Owe 11:1; Matteu 23:23

5 Awọn Onigbagbọ ni lati ka ohun wọnni ti i ṣe mimọ si ohun ti o ṣe iyebiye, Filippi 4:8; 1 Timoteu 4:12; Jakọbu 1:27; 3:17; 2 Peteru 3:1; 1 Johannu 3:3

6 Wọn ni lati maa gba ohunkohun ti i ṣe fifẹ rò, Filippi 4:8; 2 Samuẹli 1:23;Orin Solomọni 5:16; Marku 10:21; Johannu 11:36

7 Onigbagbọ ni lati fé̩, ki o si maa ṣe afẹri pe ki a ni iroyin rere nipa oun, Filippi 4:8; Iṣe Awọn Apọsteli 6:3; 10:22; 22:12; 1 Timoteu 3:7; 5:10; Heberu 11:2

8 Iwa rere jé̩ ohun ti o ṣe iyebiye lọpọlọpọ nibikibi ti a ba le ri i, Filippi 4:8; Rutu 3:11; Owe 12:4; 31:10; 2 Peteru 1:3, 4

9 Ijọsin wa si Ọlọrun kò le jé̩ pipe lai si iyin fun Ọlọrun, Filippi 4:8; 1:10, 11; Orin Dafidi 33:1; 50:23; Matteu 21:16; Efesu 1:6; Heberu 13:15

Notes
ALAYE

Gba Nnkan Wọnyii Rò

Ẹkọ wa yii ké si awọn Onigbagbọ lati “ronu” ati lati gba awọn ohun mẹjọọtọọtọ wọnyii rò; õtọ, ọwọ, iwa titọ, iwa mimọ, ohun rere, irohin rere, iwa rere ati iyin. Ọkàn ni ibode si ẹmi. Awọn ọtá eniyan mẹtẹẹta wọnni – aye, ara ati èṣu -- mọ daju pe bi ọkàn eniyan ba le gba ero ẹṣẹ laye, ẹmi oluwarẹ yoo ṣubu sinu idanwo. Eyi fara hàn ninu igbekalẹ awọn Ẹgbẹ Alohun-gbogbo pọ-ṣọkan ti o fi danindanin le e lati gbin ẹkọ aiwa-bi-Ọlọrun ati ilana rè̩ ti o sé̩Ọlọrun sinu awọn eniyan.

Apẹẹrẹ miiran ni ọna ipolowo ọja lode oni nipa eyi ti awọn oniṣowo n lo gbogbo ọna nigba gbogbo ati leralera lati mu ki ọkàn awọn eniyan ki o fà si ọja wọn. Awọn oniṣowo ọti ati taba n ná owó gọbọi ni ọdọọdun lati polowo awọn nnkan wọnyii ati lati kọ awọn eniyan bi a ti n lò wọn. Awọn oniṣowo taba tà ni ọdun kan ju bi wọn ti n ta tẹlẹri nipa nina owo gọbọi lati fi yé awọn obinrin pe ki i ṣe ohun ti o buru fun awọn obinrin lati maa mu taba.

Gbogbo atẹ itawe asiko ni o kun fun iwe ti kò fẹsẹ iwa rere mulẹ. Ni ọnakọna ni awọn oniṣowo ti kò nilaari wọnyii gba n fi idẹkun si ọna awọn ọdọmọde lati mu ki ifẹ wọn fà si ọja wọn lai bikita ipalara ati iwa ibajẹ ti o le ti ibẹ jade. Ibá ti dara tó bi awọn obi Onigbagbọ ba le maa ṣe abojuto iru iwe ti awọn ọmọ wọn n kà, ki wọn si maa fi ỌrọỌlọrun ti o le sọ wọn di alagbara bọọkàn wọn lojoojumọ!

Onigbagbọ kò gbọdọ lero wi pe Bibeli oun ti di ogbologbo ti kò wulo mọ, ti kò si le fun ni ni itọni nipa ohun ti n lọ lode oni. Ọlọrun ni Olotu Bibeli, O si lagbara lori ohun gbogbo. Ẹgbẹrun ọdun bi ọjọ kan ni o ri fun Un. Ọtun ni ỌrọỌlọrun, o tọnà, o si dara fun igbesi-ayé Onigbagbọ ni akoko ti wa yii gẹgẹ bi o ti ri lati igbaani. Imọran Paulu si awọn eniyan mimọ ti o wà ni Filippi lati “gbà nkan wọnyi rò” niye lori fun awọn ti o wà lode oni pẹlu gẹgẹ bi o ti ri fun awọn ti igbaani.

Igba ayé Paulu kun fun aṣeju ati è̩ṣẹ. Dajudaju ohun pupọ ni o wà ti o le fa ọkàn awọn Onigbagbọ ti igba ayé Paulu lati dẹṣẹ, bakan naa ni o ri lati igba nì titi di oni oloni. Bi o tilẹ jẹ pe ni akọbẹrẹ igbagbọ kò si awọn è̩rọ amereya gẹgẹ bi awa ti ni lode oni bi ẹrọ tẹlifiṣọn, redio ati sinima -- sibẹ anfaani wa fun wọn nigbaanì lati dẹṣẹ. Gbogbo akẹkọọ itàn igba laelae ni o mọ bi iwa buburu ati iwa ika ti gbilẹ tó ni igba ayé awọn Apọsteli. Imọran wo ni a gba awọn Onigbagbọ igba naa lati fi doju kọ awọn nnkan wọnni? Maa ṣe aṣaro nipa awọn ohun ti i ṣe ti Ọlọrun – ati awọn nnkan wọnni ti i ṣe mimọ, ti o si dara!

Kò si Onigbagbọ ti o le maa ro ero ti o lodi si Ẹmi Ọlọrun ati ohun ti i ṣe ti Ọlọrun ti o le ni ẹmi isin tootọ ninu ọkàn rẹ. “Nitoripe bi o ti nṣiro li ọkàn rè̩, bḝ li o ri” (Owe 23:7). Ẹnikan sọ bayii pe “bi iwe ti eniyan n kà ti ri bẹẹ ni iwa rè̩ yoo ri.” Iwe kan ni o ṣe pataki jù fún awọn Onigbagbọ, Iwe naa ni Bibeli. Bi eniyan ba le maa ka Iwe Mimọ ki o si maa ṣe aṣaro lori rè̩ tọkan-tọkan lojoojumọ, a o fa ọkan rè̩ soke, a o si mu u sanra. Bibeli ni iwe ti o gbamuṣe ju lọ ninu iwe ti ọmọ eniyan n kà. O wà fun ayeraye, o si jé̩ orisun iwa rere gbogbo. Oun ni Olufihan Ọlọrun ati ododo Rè̩, oun nikan ni o le sọrọ taṣẹtaṣẹ nipa ọna ti o dara fun eniyan lati maa gbé ati rin. Ni ode-oni, ti ẹgbẹgbaarun onfa n fa awọn eniyan lati dẹṣẹ, Bibeli ta gbogbo wọn yọ, o n kede lóhun rara pe ọna Ọlọrun ni o tọ. Gẹgẹ bi a ti pa a laṣẹ ninu ẹkọ wa, Onigbagbọ ni lati fi tọkàntọkàn ṣe aṣaro lori awọn ohun ti n ṣe ti Ọlọrun.

Rere ati Buburu

Imọ iwa buburu ti ẹlẹṣẹ ti ni nigba ti o n dẹṣẹ jé̩ orisun èrò ti o le di abinuku ọtá fun un nigba ti o ba yi pada tán lati di ọmọỌlọrun. Ẹbun Ọlọrun ni igbala, oore-ọfẹỌlọrun ni o si n fa eniyan jade kuro ninu è̩ṣẹ rè̩ gbogbo ti o si n wẹẹ nipa Ẹjẹ Kristi. S̩ugbọn ki eniyan ma ba sọ igbala rè̩ nù mọ lẹyin ti Ọlọrun ti gba a là, o ni lati lakaka. Onigbagbọ kò gbọdọ tu ara silẹ dẹngbẹrẹ fun igbi ayé lati maa gba a kiri lai lakaka lati ni Ẹmi Ọlọrun ninu ọkàn rè̩. Eniyan Ọlọrun kan ni ọdun pipẹ diẹ sẹyin sọ bayii nipa ṣiṣe iṣẹ igbala wa pẹlu iwariri: “Ero rere tabi aṣayan akoko lati ṣafẹri ọrun ati idapọ mimọ kò le dipo ifarada ati iṣẹ aṣekara ti n mu ki a ṣe aṣeyọri ninu ohun miiran, kò le ṣai ri bẹ niwọn-igbati o jé̩ pe ọna kanṣoṣo yii ni ọna aṣeyọri, ani lọna ti ẹmi pẹlu.”

Gbigba ti Efa gba imọran eṣu lati ṣe ibi ni o fa iṣubu ẹda. Iṣisẹ kan ni o wa laaarin fifi eti si imọran eṣu ati dida ẹṣẹ naa gan an. “Jù gbogbo ohun ipamọ, pa àiya rẹ mọ; nitoripe lati inu rẹ wá ni orisun iye,” jé̩ ikilọ ti a ni lati fi ọwọ danindanin mú. Wolii ni wi pe, “Iwọ o paa mọ li alafia pipé, ọkàn ẹniti o simi le ọ” (Isaiah 26:3). A ni lati ranti pe gbigba ero buburu laaye ninu ọkàn wa yoo sọ wa di ẹlẹbi niwaju Ọlọrun bi ẹni ti o ti dẹṣẹ naa gan. Ohun ti o fa idalẹbi awọn eniyan ti o wa ṣiwaju igba ìkún omi ni eyi pe “ỌLỌRUN si ri pe iwabuburu enia di pipọ li aiye, ati pe gbogbo iro ọkàn rè̩ kiki ibi ni lojojumọ” (Gẹnẹsisi 6:5). (Ka Deuteronomi 29:19, 20; Matteu 15:19). Ọlọrun sọ fun Israẹli pe Oun yoo mu ibi wá si ori wọn, ani eso ọkàn wọn nitori ti Israẹli kọ ofin Ọlọrun silẹ (Jeremiah 6:19). Pẹlupẹlu Oluwa fi Israẹli sun nitori ti wọn n rin gẹgẹ bi iro inu ọkàn ara wọn (Jeremiah 9:14). Ọlọrun si mú Esekiẹli lọ ninu ẹmi, O si fi iwa buburu Israẹli hàn án gẹgẹ bi o ti n gba è̩ṣẹ láye ninu yara oriṣa wọn (Esekiẹli 8:12). Otitọ ni ọrọ yii pe ọkàn ni ibode si ẹmi.

Aṣàrò nipa Ọlọrun

Ọlọrun mọ ero ọkàn awọn eniyan buburu ati ti awọn olododo pẹlu. Ọlọrun ṣeleri ibukun nla fun awọn ti n ṣe aṣaro nipa orukọ Rè̩. A ka bayii pe: “Nigbana li awọn ti o bè̩ru OLUWA mba ara wọn sọrọ nigbakugba; OLUWA si tẹti si i; o si gbọ, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rè̩, fun awọn ti o bè̩ru OLUWA, ti nwọn si nṣe aṣarò orukọ rè̩” (Malaki 3:16).

Ni ayé ode-oni igbesi-ayé awọn eniyan fi hàn wi pe ọwọ yẹpẹrẹ ni wọn fi mu otitọ inu, iṣotitọ, ododo, iwa mimọ ati iwa rere. Kò si ohun ti o le báè̩ṣẹ wi bi igbesi-aye mimọ ati alailabuku, ti Onigbagbọ. Ninu “Awọn Akọsilẹ John Wesley” a ri akọsilẹ yii: Nigba ti iwa buburu ba rọ wọle bi ikun omi ti o si da bi ẹni pe ẹmi ati ina igbagbọ fẹrẹ kú, ọna ti o dara jù lati doju kọ awọn iru idanwo bẹẹ ni fun alufaa (ani gbogbo Onigbagbọ) lati fi ara wọn ṣe apẹẹrẹ nipa gbigbe igbesi-ayé iwa rere ti yoo tako gbogbo iwa buburu wọnni, pẹlu gbogbo igbona ọkàn ati itara -- wọn ni lati mu ki isẹra-ẹni ati iwa-bi-Ọlọrun wọn di mimọ ni gbangba ati nigba gbogbo lati bá gbogbo iwa asán wi.

Erò wa ni abayọrisi ifẹ ati ohun ti o wà ninu ọkàn wa. A o sọ ero yii jade ni ọjọ kan ṣá, ero wa yoo maa jẹ jade ni igbesi-ayé wa, ohun ti a rò ni a o si ma hù ni iwa (Owe 23:7). Nipa ṣiṣe aṣaro lori nnkan wọnyii, ti o le fun wa ni iroyin rere, wọn yoo di ara fun wa. Nigba ti a ba n ṣe aṣaro pupọ lori wọn, wọn yoo di apa kan ẹmi wa. Otitọ ati aiṣegbe yoo di ara oun è̩jẹ fun wa. A o ni ifẹ fun awọn iwa rere wọnni ti o n gbé wa ró ti o n fun wa ni imisi fun igbala ẹmi wa. Ilu ibilẹ wa n bẹ ni ọrun, a o si ni idapọ pẹlu awọn wọnni ti ero wa dọgba lori nnkan wọnyii. Awa yoo ni idapọ pẹlu Oluwa, nitori pe “Ẹni meji lè rin pọ, bikòṣepe wọn ré̩?” (Amosi 3:3).

“Li akotan, ará, ohunkohun ti iṣe õtọ, ohunkohun ti iṣe ọwọ, ohunkohun ti iṣe titọ, ohunkohun ti iṣe mimọ, ohunkohun ti iṣe fifẹ, ohunkohun ti o ni irohin rere; bi iwa titọ kan ba wà, bi iyìn kan ba si wà, ẹ mā gbà nkan wọnyi rò” (Filippi 4:8).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Darukọ ohun mẹjọ ti a paṣẹ fun Onigbagbọ lati maa ṣe aṣaro le lori.

  2. 2 Ki ni ṣe rẹ ti o fi ṣe danindanin lati gba nnkan wọnyii ro?

  3. 3 Ki ni ṣe rẹ ti awọn apolowo-ọja ode-oni fi mu un ni ọranyan lati gbin ifẹ ohun ti wọn n polowo si ọkàn eniyan?

  4. 4 Ki ni ibode si Ẹmí?

  5. 5 Ohun ti o wà ninu ọkàn wa ha le yatọ si ohun ti o wà ninu ero wa?

  6. 6 Ọna wo ni eṣu n gba gbé idanwo lọ si inu ọkàn ọmọ-eniyan?

  7. 7 Awa ha ti dẹṣẹ bi a ba gba ero buburu láyè ninu ọkàn wa?

  8. 8 Iru iwe wo ni Onigbagbọ ni lati tẹra mọ lati kà?

  9. 9 Bibeli ha n fun ni ni imọran rere sibẹ nipa ọna ti Onigbagbọ le gbà gbé igbesi-ayé rere ni igba ode-oni? S̩e alaye idahun rẹ.

  10. 10 Ki ni iwọ mọ nipa iwa rere? Sọ ohun ti iwa mimọ ati ododo jasi.