Isaiah 2:1-22; Orin Dafidi 2:1-12

Lesson 342 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọpọlọpọ enia ni yio si lọ, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si òke OLUWA, si ile Ọlọrun Jakọbu; On o si kọ wa li ọna rè̩, awa o si ma rin ni ipa rè̩; nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọrọ OLUWA lati Jerusalẹmu” (Isaiah 2:3).
Cross References

I Igbega Kristi

1 Wolii naa sọ nipa ti ipo giga ti Kristi ati ti Ijọba Rè̩ ti n bọ, Isaiah 2:1, 2; Orin Dafidi 2:6, 7; Mika 4:1; Ifihan 19:11-16

2 Gbogbo orilẹ-ède ni yoo wá si abẹ akoso Kristi lakoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún, Isaiah 2:2, 3; Orin Dafidi 2:8-12; Mika 4:2; Ifihan 11:15

3 Ogun yoo dẹkun ni akoko Ijọba ti Kristi, Isaiah 2:4; Mika 4:3, 4

II Ijọba Ododo

1 Awọn ti o kọ lati wá si abẹ akoso Kristi ni a o dá lẹjọ, Isaiah 2:5-9; Orin Dafidi 2:1-3; Sekariah 14:17-19; Ifihan 19:19-21

2 Ẹṣè̩ ati igberaga ni a o rè̩ silẹ ni Ọjọ Oluwa, Isaiah 2:10-18

3 A o mu ibọriṣa kuro, awọn eniyan yoo si maa wa ibi ti wọn yoo fara pamọ si nigba ti Oluwa ba de lati mi aye tìtì, Isaiah 2:19-22; Orin Dafidi 2:4, 5; Ifihan 6:12-17

4 A o gbé Oluwa ga, yoo si jọba ni ododo ati alaafia, Isaiah 2:17; 25:6-9; 35:1-10; Sekariah 14:16, 20, 21; Ifihan 20:4-6

Notes
ALAYE

Ni ijimiji, Ọlọrun Mẹtalọkan boju wo iṣẹọwọ Rè̩, “si kiyesi i, daradara ni.” Ọlọrun ti ṣe ipese ti o tó fun anfaani ati alaafia gbogbo ẹda. Eredi rè̩ ti ohun gbogbo fi wà ni pe ki wọn wà pẹlu iṣọkan pẹlu Ọlọrun ki wọn si maa fi iyin fun Un.

S̩ugbọn irẹpọ didun ati igbesi-ayé pipé yii bajẹ lai pẹ jọjọ, nitori ọmọ-eniyan feti si arekereke imọran è̩ṣẹ Satani, eyi ti o gbà ti ẹnu ejo sọ. Lẹsẹkẹsẹ, ẹmi iye ti ki i kú ti a fun eniyan, yapa kuro lọdọỌlọrun – o kú ninu aiṣedeedee ati è̩ṣẹ. Ẹkunrẹrẹ iwa pipé ti a fi fun eniyan parun, ẹdáè̩ṣẹ si gbilẹ o si n jọba ninu ọkàn ati igbesi-ayéẹni ti a kò tunbi, titi di oni-oloni. Satani gbiyanju lati gba agbára Ọlọrun ati awọn ẹda Rè̩, o si dabi ẹni pe o fẹrẹ bori; ṣugbọn ipa ati aṣẹ wà lọwọỌlọrun, ni ọjọ kan Oun yoo gba ayé kuro lọwọ igbèkùn buburu ti egun è̩ṣẹ ti mu wá sori rè̩. Ọlọrun yoo rán Jesu pada si ayé lati gbé ijọba Rè̩ kalẹ, yoo si ṣe akoso ayé ni ododo fun ẹgbẹrun ọdún.

Igba Ikẹyin

Ohun ti Isaiah fi bẹrẹ asọtẹlẹ rẹ nipa Ijọba Kristi ti n bọ wá ni eyi pe, “Yio si ṣe ni ọjọ ikẹhin.” Nigba ti è̩ṣẹ ba ti ṣe iṣẹọwọ rẹ ti o si dabi ẹni pe Eṣu ṣe tán lati pa ayé ati awọn eniyan run, Jesu yoo fara hàn yoo si já ayé gbà kuro lọwọ agbára ati ipá Satani. “Mo si ri ọrun ṣi silẹ, si wo o, ẹṣin funfun kan; ẹniti o si joko lori rè̩ ni a npe ni Olododo ati Olõtọ, ninu ododo li o si nṣe idajọ, ti o si njagun … Awọn ogun ti mbẹ li ọrun ti a wọ li aṣọọgbọ wiwẹ, funfun ati mimọ, si ntọọ lẹhin lori ẹṣin funfun. Ati lati ẹnu rè̩ ni idà mimu ti njade lọ, ki o le mā fi iṣá awọn orilẹ-ède: on o si mā fi ọpá irin ṣe akoso wọn” (Ifihan 19:11, 14, 15). Ijọba Kristi yoo kari gbogbo ayé. Gẹgẹ bi itàn akọsilẹ, ohun ti awọn akọni jagunjagun fẹ ni, ti wọn si fi ẹmi wọn ṣofo lati ni, ni a o fi fun Jesu ỌmọỌlọrun.

Ogun kikoro yoo wa fun akoko kukuru ni imurasilẹ fun ijọba ododo Kristi yii. Ogunlọgọ eniyan yoo gbogun ti Oluwa ni ọjọ naa, ṣugbọṅ idà mimu ẹnu Kristi ni a o fi pa wọn run. A o si mú Satani dè sinu ọgbun fun ẹgbẹrun ọdun, a o si sọ awọn balogun rè̩ sinu adagun iná laaye. Awọn eniyan ti o ba bọ ni akoko idajọ ati ipọnju yii yoo ni ipin ninu alaafia ẹgbẹrun ọdún ti a kò gbọ irú rè̩ rí.

Ọna si Ijọba Naa

Ọna ti o daju ti o si dara wà lati wọ inu Ijọba rere Kristi ti n bọ wá. Johannu Baptisti ni ohun elo ti Ọlọrun lò lati kede fun araye nipa ohun ti yoo gbà wọn ki wọn to wọle: “Ẹ ronu piwada; nitori ijọba ọrun kù si dè̩dè̩” (Matteu 3:2). Jesu kede ohun kan naa, O si tun ṣe alaye kikun lori rè̩, O fi ye ni wi pe akoko ijọba naa kò i ti de ni kikun nigba naa. “Nigbati awọn Farisi bi i pe, nigbawo ni ijọba Ọlọrun yio de, o da wọn li ohùn pe, Ijọba Ọlọrun ki iwá pẹlu àmi; Bḝ ni nwọn ki yio wipe, Kiyesi i nihin! tabi kiyesi i lọhun! sawõ, ijọba Ọlọrun mbẹ ninu nyin” (Luku 17:20, 21).

Gbogbo ẹni ti o ba gba Jesu Kristi tọkàntọkàn, ti wọn si gbọran si aṣẹ Rè̩ yoo di ọmọ ijọba Rè̩. Awọn wọnyii ṣẹgun agbára Satani nipa ẸjẹỌdọ-agutan ati nipa ọrọè̩ri wọn. Awọn aṣẹgun wọnyii ti le kú nipa ti ara, sibẹ a o ji wọn dide, a o pa wọn lara dà pẹlu awọn eniyan mimọ aṣẹgun ti o wà laaye, wọn o si lọ si Ọrun lati wà pẹlu Kristi nibi Ase-alẹ Igbeyawo Ọdọ-Agutan. Nigba ti Kristi ba fara hàn ninu ayé bi Ọba, awọn eniyan mimọ wọnyii yoo bá A pada bọ wá si ayé lati jé̩ alufaa Ọlọrun ati ti Kristi, wọn yoo si jọba pẹlu Rè̩ ni ẹgbẹrun ọdun (Ka Ifihan ori 19 ati 20).

Si iparun ara wọn, ogunlọgọ eniyan ni o n lọra lati ṣe ipinnu lati sin Kristi. Pupọ eniyan ni kò mọ wahala nla ti yoo dé ba wọn nipa ṣiṣe ainaani ohun ti o yẹ fun wọn lati ṣe lati jé̩ alabapin ninu Ijọba Kristi, ṣugbọn kò si ohun ti o gbọdọ leke lọkàn eniyan tayọ adura agbayọri si igbala. Oluwa ti fi akoko ati anfaani fun awọn ọmọ-eniyan lati pese ọkàn wọn silẹ fun ayeraye. “Nitorina gẹgẹ bi Ẹmi Mimọ ti wi, Loni bi è̩nyin bá gbọ ohùn rè̩, Ẹ máṣe séọkàn nyin le, bi igba imunibinu” (Heberu 3:7, 8). Gbogbo awọn ti o kọ tabi ti o kuna lati gbọran ati lati gbẹkẹle Kristi ninu ayé yii yoo ni ipin ninu ikú keji. Diẹ ninu awọn ẹlẹṣẹ ti kò ronu piwada yoo ni anfaani lati wà ninu ayé ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun, ṣugbọn wọn yoo duro niwaju Ọlọrun nibi Itẹ Idajọ Nla Funfun. Lati ibẹ ni a o ti dari wọn sinu adagun iná: “Eyi ni ikú keji” (Ifihan 20:14).

Ijọba Ayinlogo

Ninu itan igbagbọ kò ti i si akoko kan ti gbogbo ayé tẹwọ gba isin Kristi, sibẹ akoko naa n bọ nigba ti gbogbo eniyan ti o wà lori ilẹ ayé yoo mọ Jesu Kristi ni Oluwa. Ọpọlọpọọdun ni awọn ọmọlẹyin Kristi ti fi ṣe laalaa lati mu awọn eniyan wá sinu Ijọba Kristi, ṣugbọn gbogbo laalaa wọn, igbokegbodo ati ijolootọ wọn, kò le fi idi Ijọba Kristi mulẹ lori aye ni kikun ati ni pipé. O di igba ti Ọba tikalara Rè̩ ba dé lati Ọrun.

Awọn olugbe ayé ki yoo korira Jesu mọ, bẹẹ ni won ki yoo tun wi pe “Awa kò fẹ ki ọkunrin yi jọba lori wa” (Luku 19:14); ṣugbọn gbogbo orilẹ-ède ni yoo lọ si ile Oluwa ni Sioni. “Ọpọlọpọ enia ni yio si lọ, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹki a lọ si òke OLUWA, si ile Ọlọrun Jakọbu; On o si kọ wa li ọna rè̩, awa o si ma rin ni ipa rè̩” (Isaiah 2:3). Oluwa nikan ni a o gbega ni ọjọ naa. A o rẹ iwo giga awọn eniyan silẹ, a o si tẹri igberaga ọkàn awọn eniyan ba. Gbogbo oriṣa ni yoo run womuwomu. Ki i ṣe gbogbo eniyan ni o n sin oriṣa wura tabi ti fadaka lọjọ oni, ṣugbọn ohunkohun ti a ba gbé kalè̩ lẹyin Ọlọrun, tabi ti a ba ni ifẹ ati itara si ju Ọlọrun lọ, oriṣa ni, gbogbo rè̩ ni a o si parun patapata ni ọjọ Oluwa awọn ọmọ-ogun.

Igba Alaafia

Ki eṣu ati è̩ṣẹ to wọ inu Ọgba Edẹni, alaafia ati itura ni o wà ninu Ọgba naa. Awọn eniyan, ẹranko ati awọn ẹyẹ ni o n gbé pọ lai si ibẹru ati ifura. Oluwa ti ṣeto pe awọn koriko igbẹ ni yoo jé̩ ounjẹ fun awọn ẹranko ati awọn ẹyẹ oju-ọrun, lai si aniani ègún è̩ṣẹ ni o mu ki ẹranko kan maa pa ekeji jẹ. Nigba ti Kristi bá pada bọ lati ọrun lori ẹṣin funfun ti O si ṣẹgun eṣu ati gbogbo agbara iwa buburu, iṣesi ati ijẹun awọn ẹyẹ ati ẹranko yoo pada si bi o ti ri ni Ọgba Edẹni. “Ikõkò pẹlu yio ma ba ọdọ-agutan gbe pọ, kiniun yio si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ati ọmọ mal ati ọmọ kiniun ati ẹgbọrọẹran abọpa yio ma gbe pọ; ọmọ kekere yio si ma dà wọn. Mal ati beari yio si ma jẹ pọ; ọmọ wọn yio dubulẹ pọ; kiniun yio si jẹ koriko bi mal. Ọmọẹnu-ọmu yio si ṣire ni ihò pamọlẹ, ati ọmọ ti a já lẹnu-ọmu yio si fi ọwọ rè̩ si ihò gunte. Nwọn ki yio panilara, bḝni nwọn ki yio panirun ni gbogbo òke mimọ mi; nitori aiye yio kún fun imọ OLUWA gẹgẹ bi omi ti bo okun” (Isaiah 11:6-9).

Oluwa yoo ṣe idajọ laaarin awọn orilẹ-ède, yoo si báọpọlọpọ eniyan wi. Pẹlu Kristi, Ọba aṣẹgun gẹgẹ bi alakoso ijọba, Ẹni ti a ni lati ma a bọ ki a si maa sin, pẹlu Satani ti a ti gbe dè sinu ọgbun ainisalẹ, tí owú ati igberaga ki yoo le ta wúyẹ ninu ọkàn awọn ẹlẹṣẹ, yoo rọrun fun awọn eniyan lati ma a gbe pọ ni alaafia pẹlu ara wọn. Awọn ohun ija ogun, idà ati ọkọ ni wọn o fi rọọbẹ-plau ati doje. “Orilẹ-ède ki yio gbe idà soke si orilẹ-ède; bḝni nwọn ki yio kọ ogun jijà mọ.” Wahala pupọ ni awọn orilẹ-ède ti ṣe lati le mu ki alaafia ki o wà ninu ayéṣugbọn pẹlu gbogbo aniyan ati laalaa wọn, alaafia tubọ n jina si ayé. Ni ọjọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, alaafia yoo wà ni ibi gbogbo – ninu ile, ati ni igboro, ni abule ati laaarin ilu. Ki yoo si ile-ẹjọ fun ikọsilẹ tọkọ-taya nitori igbépọ tọkọ-taya yoo rọgbọ gẹgẹ bi Ọlọrun ti lana rè̩ silẹ.

Awọn Ju

Nigba ti Jesu ba pada wá si aye lati fara hàn awọn Ju ati gbogbo araye, ni a o mu ifọjú ti o de bá Israẹli ni apakan kuro. Nigba naa ni asọtẹlẹ Isaiah yoo ṣẹ: “Ara ile Jakọbu, ẹ wá, ẹ jé̩ ka rìn ninu imọlẹ OLUWA” (Isaiah 2:5). Diẹ ninu awọn Ju ti o tú kaakiri ti gba Jesu gbọ gẹgẹ bi Messia wọn lati igbaani titi di isisiyii, ṣugbọn ni apapọ awọn Ju kò gba Jesu gẹgẹ bi Messia wọn. Wahala ti kòṣe fẹnu sọ ti ba orilẹ-ède naa paapaa ju lọ lati ọjọ ti awọn alaṣẹ wọn ti paṣẹ pe ki a kan Jesu mọ agbelebu, ti wọn si wi pe, “Ki ẹjẹ rè̩ wà li ori wa, ati li ori awọn ọmọ wa” (Matteu 27:25). Gudugbẹ nla n bọ wá já lu wọn, nikẹyin awọn Ju ti o kù yoo ri Ọba wọn lori ẹṣin funfun ti wọn yoo si tẹwọ gba A gẹgẹ bi ỌmọỌlọrun ati Olugbala wọn. “Yio si ṣe, ni gbogbo ilẹ, li OLUWA wi, a o ké apá meji ninu rè̩ kuro, yio si kú; ṣugbọn apá kẹta yio kù ninu rè̩. Emi o si mu apá kẹta na làārin iná, emi o si yọ wọn bi a ti yọ fadaka, emi o si dán wọn wò, bi a ti idán wura wò: nwọn o si pe orukọ mi, emi o si gbọ wọn: emi o wipe, Awọn enia mi ni: awọn o si wi pe, OLUWA li Ọlọrun mi” (Sekariah 13:8, 9).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Nigba wo ni Ijọba Kristi yoo fara hàn lori ilẹ ayé?

  2. 2 Nibo ni olu-ilu ijọba naa yoo wa?

  3. 3 Awọn ta ni ninu awọn olugbe ayé ni yoo foribalẹ fun Ọba ni ọjọ naa?

  4. 4 Ọna wo ni Ijọba Kristi yoo fi yatọ si awọn ijọba ayé ode-oni?

  5. 5 Ki ni ṣe rẹ ti Oluwa fi kọ ile Jakọbu silẹ?

  6. 6 Ki ni Oluwa yoo ṣe si igberaga ati irera ni Ọjọ Oluwa?

  7. 7 Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn oriṣa ati awọṅ abọriṣa nigba ti Oluwa ba fara hàn?

  8. 8 Bawo ni Ijọba Kristi yoo ti pẹ tó lori ilẹ ayé?

  9. 9 Bawo ni a ṣe le ni idaniloju pe awa yoo ni ipin pẹlu Kristi ninu Ijọba Rè̩?