Orin Dafidi 5:1-12

Lesson 343 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ohùn mi ni iwọ o gbọ li owurọ, OLUWA; li owurọ li emi o gba adura mi si ọ, emi o si ma wòke” (Orin Dafidi 5:3).
Cross References

I Adura Dafidi

1 O bẹ Oluwa pe ki o gbọ igbe oun, Orin Dafidi 5:1, 2; 3:4; 65:2; Jakọbu 5:16

2 O gbadura ni kutukutu owurọ, o si fi igbagbọ wòke fun idahun, Orin Dafidi 5:3; 88:13; Mika 7:7; Habakkuku 2:1

3 Oluwa korira awọn oniṣẹè̩ṣẹ, Orin Dafidi 5:4-6;55:23; Ifihan 21:8

4 Nipasẹ aanu ati ninu ibẹru ni Dafidi yoo sin Oluwa, Orin Dafidi 5:7

5 O gbadura ki a tọ oun ni ọna taara, Orin Dafidi 5:8; Owe 15:19; Matteu 7:13, 14

6 O sọ ti ipò awọn eniyan buburu, o si sọ tẹlẹ pe wọn yoo ṣubu nipa imọ ara wọn, Orin Dafidi 5:9, 10; Luku 11:44; Romu 3:13;

7 O sọ ti ayọ awọn ti o gbẹkẹle Oluwa ati awọn ibukun ti n tẹle e, Orin Dafidi 5:11, 12; Isaiah 65:13, 14; Habakkuku 3:17-19

Notes
ALAYE

Isin Owurọ

Ninu Psalmu kẹrin, Dafidi wi pe oun dubulẹ, oun si sun ni alaafia nitori Oluwa ni o mú oun joko ni ailewu. Nigba ti o ji, o gbadura si Ọlọrun ti o pa a mọ ni gbogbo oru. Nigba ti eniyan ba lọ sun pẹlu iyin ni ẹnu rẹ, nigba pupọ ni oun maa n ji pẹlu adura ni ookan-aya rè̩. Wo bi o ti dara to lati bẹrẹ iṣẹ oojọ --pẹlu adura ati è̩bẹ si Ọlọrun ti i ṣe alaabo lori ohun gbogbo!

Anfaani Awiyannu

Dafidi jé̩ẹni ti n gbadura awiyannu niwaju Itẹ Aanu. O n bẹbẹ pe ki Oluwa feti si aroye oun; nigba ti ọrọ ba kuna, o n bẹbẹ pe ki aṣaro, oungbẹ ati ifẹọkàn oun ki o jé̩ itẹwọgba lọdọỌba ati olododo oludani lare – ani Ọlọrun rè̩, Ẹni ti o mọ ni Oluwa rè̩, Ẹlẹda ti o fẹran ti o si n sin. Ati nigba ti ẹdùn ọkàn rẹ ba kọja oye rè̩, ti ifẹỌlọrun lori ohun kan ba si pamọ fun un, oun a bẹbẹ bayii pe, “Fi eti si ohùn ẹkún mi,” “irora ti a kò le fi ẹnu sọ” (Romu 8:26, 27).

Dafidi mọ pe awọn ọtá oun pọ ati pé abé̩ iyẹ apa Olodumare nikan ṣoṣo ni aabò oun wà. Awọn ọtá kan naa ni o wà fun ọmọỌlọrun lọjọ oni. Ọta-i-yọta kan ni o ti wà fun gbogbo awọn Onigbagbọ -- oun naa ni èṣu. Ogun ti awa n báọtá jà lonii kò yatọ si ti Dafidi. Awọn Goliati wà lọjọ oni lati bá jà, igbagbọ si jé̩ọkan ninu awọn ohun ijà wa gẹgẹ bi Dafidi ti ni igbagbé pe Oluwa yoo dari okuta kekere ti o jade lati inu ohun ijà kan ṣoṣo ani kannakanna kekere kan ti o ni, si ọgangan ibi ti yoo bi ọta wó. Awọn ohun ijà wa ki i ṣe ti ara, ṣugbọn o ni agbara ninu Ọlọrun lati wo ibi giga palẹ. “Awa n sọ gbogbo ero kalẹ, ati gbogbo ohun giga ti ngbé ara rè̩ ga si imọỌlọrun, awa si ndi gbogbo ero ni igbekun wá si itẹriba fun Kristi” (2 Kọrinti 10:4, 5). (Wo Efesu 6:10-18).

Wiwo Oke

“Ohùn mi ni iwọ o gbọ li owurọ, OLUWA.” Dafidi pinnu pe adura ati aṣaro lori ỌrọỌlọrun ni oun yoo fi ṣe ohun kin-in-ni ni kutukutu owurọ ti i ṣe akoko ti o ṣọwọn ju lọ ni igbesi ayé rè̩, ati pe oun yoo ṣi ọkàn oun paya fun Un, yoo si fi àya rè̩ fun Un ki oye ifẹ ati ilana Ọlọrun ki o le ye e.

“Ọdọ rẹ li emi o ma gbadura si” – emi yoo si to adura mi li ẹsẹẹsẹ niwaju Rẹ. Emi yoo fi iyin ati ọpẹ fun ọ; emi yoo gbe ohun ẹbẹ mi, aroye mi ati adura mi soke si ọ. Ohun kan ti n dena adura ni pe ki a jẹ ki ọkàn wa maa ṣáko kiri nigba ti a ba n wá oju Ọlọrun. Gbogbo agbara ati oye wa -- ọkàn wa, ero ati gbogbo ohun ti o wa ninu wa ni o gbọdọ rọ mọ Oluwa. Bawo ni a ṣe rò pe adura ète lasan yoo ti ri niwaju Ọlọrun nigba ti ọkàn wa n bẹ lori iṣẹ oojọ wa, ẹbí, aniyan ayé, tabi ohunkohun miiran? O yẹ ki a gbadura si Oluwa lati mu irú iwa bẹẹ kuro ki a ba le ni anfaani lati gbadura gidigidi pẹlu igbona ọkàn. Ọrun yoo ṣi silẹ; Ọlọrun yoo si bè̩rè̩ si ṣiṣẹ nipa tiwa. “Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ” (Jakọbu 5:16).

Dafidi wi pe oun yoo maa “wòke” fun idahun – wòke ni igbagbọ si Ọlọrun ati si ileri Rè̩. Ọlọrun wi pe, “Bère, a o si fifun nyin; wá kiri, ẹnyin o si ri; kànkun, a o si ṣi i silẹ fun nyin.” “Bi awa ba bère ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rè̩, O ngbọ ti wa: bi awa ba si mọ pe O ngbọ ti wa, ohunkohun ti awa ba bère, awa mọ pe awa ri ibere ti awa ti bère lọdọ rè̩ gbà” (1 Johannu 5:14, 15).

Ajanbaku adura ti di ara fun ẹlomiran; wọn n gbadura, ṣugbọn wọn kò ni ireti pe wọn yoo ri idahun si adura wọn. Wọn lero pe bi adura wọn kò bá gbà lonii, yoo gbà lọla. Adura gbigba ti di ara fun wọn ṣugbọn kò mu eso kan jade rara. Ẹnikẹni ti o ba ti bọ sinu àṣa yii ni lati ke pe Ọlọrun lati kó oun yọ ki O si ṣe ohun kan fun Un lati Ọrun ti yoo mu eso jade. “Ẹnyin o si ṣafẹri mi, ẹ o si ri mi, nitori ẹ o fi gbogbo ọkàn nyin wá mi” (Jeremiah 29:13).

Iwa Mimọ tabi Ọrun Apaadi

Mimọ ni Ọlọrun. O fẹ iwa mimọ, O si korira ibi. Ibi kò lè bá Olodumare gbé. Eredi rẹ ni yii ti àye kò si fun è̩ṣẹ ni Ọrun. Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun korira è̩ṣẹ, sibẹ O fé̩ọkàn ẹlẹṣẹ. “Ọlọrun fẹ araiye tobḝ gẹ, ti o fi Ọmọ bibi rè̩ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ má bàṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun” (Johannu 3:16). Ọlọrun ti ṣe ilana silẹ nipasẹ eyi ti ọkàn ti è̩ṣẹ ti sọ di ibàjẹ fi le ronupiwada è̩ṣẹ rè̩, ki o bẹbẹ fun aanu, pẹlu igbagbọ ninu Ẹjẹ etutu Jesu Kristi, ki a gba a kuro ninu è̩ṣẹ, ki a si fọ aṣọ rè̩ mọ ninu ẸjẹỌdọ-agutan. Nigba naa oun yoo ni anfaani lati fi ayọ iṣẹgun wọẸnu Ọna Pearli lati wà lae ni Ọrun mimọ pẹlu Ọlọrun mimọ.

Dafidi mọ pe awọn aṣiwere ki yoo le duro niwaju Ọlọrun. Eniyan le maa ro pe oun le fi iṣẹ rere oun ṣe ara oun yẹ fun Ọrun, ṣugbọn lai pẹ jọjọ oun yoo ri i pe iṣẹ-ọwọ oun kò tó. Ile igbesi-ayé rè̩ ti kò kọ pari ti o si n ya lulẹ diẹdiẹ yoo fi iwa were rè̩ hàn ni ti pe o taku sinu èrò ati ọna ti ara rè̩ kaka ki o gbẹkele Ọlọrun fun itọni ojoojumọ gẹgẹ bi Dafidi ti ṣe (Wo Luku 14:28-33).

S̩ugbọn bi ọkàn ba jingiri sinu è̩ṣẹ, ti o si kọ aanu Ọlọrun, a o ta iru ọkan bẹẹ nù patapata kuro niwaju Ọlọrun mimọ, ki yoo si ni anfaani ati gbé ninu Ọrun mimọ pẹlu awọn eniyan mimọ. Awọn ẹsẹ miiran ninu Iwe Mimọ fi idi rè̩ mulẹ pe gbogbo awọn ti n ṣiṣẹè̩ṣẹ ati awọn ti n sọ eke jade, ẹni-è̩jẹ ati ẹlẹtan yoo ni ipa ti wọn ninu adagun iná ti n fi iná ati sulfuru jó (Ifihan 21:8 ati Orin Dafidi 101:7). S̩ugbọn awọn ti o ba tọ ipasẹ Jesu “Ẹniti kò dẹṣè̩, bẹni a kò si ri arekereke li ẹnu rè̩” (1 Peteru 2:22) yoo duro “lai si abuku niwaju itẹỌlọrun” (Ifihan 14:5). Ẹni kan ti pari ọrọ naa pe “Iwa mimọ tabi ọrun apaadi.”

Ipinnu Dafidi

“Bi o ṣe ti emi, emi o wá sinu ile rẹ li ọpọlọpọānu rẹ: ninu è̩ru rẹ li emi o tẹriba si iha tẹmpili mimọ rẹ.” Dafidi mọ pe oun ti jé̩ wère ati eniyan buburu lẹẹkan ri, ati pe aanu Ọlọrun ni a fi gba oun là. Paulu Apọsteli sọ bayii ninu Episteli rẹ si Titu:

“Awa pẹlu ti jẹ were nigbakan ri, alaigbọran, aṣako, ẹniti nsin onirru ifẹkufẹ ati adùn aiye, a wà ninu arankàn ati ilara, a jẹẹni irira, a si nkorira awọn ọmọnikeji wa.

S̩ugbọn nigbati iṣeun Ọlọrun Olugbala wa ati ifẹ rè̩ si eniyan farahan,

“Ki iṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo ṣugbọn gẹgẹ bi ānu rè̩ li o gbà wa là, nipa iwẹnu atúnbi, ati isọdi titun Ẹmi Mimọ’

“Ti o dà si wa lori lọpọlọpọ nipasẹ Jesu Kristi Olugbala wa;

“Ki a le dá wa lare nipa ore-ọfẹ rè̩, ki a si le sọ wa di ajogún gẹgẹ bi ireti iye ainipẹkun” (Titu 3:3-7).

Aṣiwere ni ẹni ti o kọỌlọrun silẹ. Ọlọgbọn eniyan ni ẹni ti o yan igbala ati iye ainipẹkun. Iwọ ha ti yan ipa ti o dara? Bi iwọ kò bá ti i ṣe eyi, ṣe bẹẹ lonii. Kò si ẹnikẹni ti o ni è̩tọ si aanúỌlọrun ṣugbọn Ọlọrun nipa ifẹ nla Rè̩ si ẹlẹṣẹ, na ọwọ aanú Rè̩ si wa. Bawo ni a o ṣe kọọ?

Ibẹru Ẹni Iwa-bi-Ọlọrun

Pelu ibẹru ẹni iwa-bi-Ọlọrun ni Dafidi fi n sin Oluwa -- ibẹru ki oun ma baa ṣẹ si Ọlọrun ti o ni ipá, ti O jẹ mimọ, ti O si lagbara to bẹẹ ti O fi ọrọẹnu Rè̩ dá ayé -- ibẹrù ki oun ma ba ṣubu, tabi ki oun ma baa di ẹni itanu kuro ninu aanu ati oore-ọfẹỌlọrun. “Nitorina ẹniti o ba rò pe on duro, ki o kiyesara, ki o má ba ṣubu” (1 Kọrinti 10:12). Ibẹru ti o lọwọ tọ si Ọlọrun. Dafidi mọ eyi, o si wi pe, “ninu è̩ru rẹ li emi o tẹriba si iha tẹmpili mimọ rẹ.” Ọkunrin ọlọgbọn nì wi pe: “Bè̩ru Ọlọrun ki o si pa ofin rè̩ mọ: nitori eyi ni fun gbogbo enia.”

Adura fun Itọni

Dafidi gbadura pe ki Oluwa ki o tọ oun ni ipa ọna tooro ati hiha nì ti i ṣe ọna ododo. O mọ pe ọna àbùjá pupọ ni o wà ti n mu ni ṣina. Ogunlọgọẹsin ode-oni ni o kún fún è̩tan: ẹgbẹ imulẹ ati ẹsin èké gbilẹ kan. Johannu wi pe “Ẹlẹtàn pupọ ti jade wá sinu aiye” (2 Johannu 7). Gbogbo ayé kún fún ẹlẹtàn. Awọn ojiṣẹỌlọrun meloo ni o n kede lati ori aga-iwaasu wi pe ọrun apaadi wa, ti wọn si n tẹnu mọọrọ Jesu wi pe, “Bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bḝ gẹgẹ” (Luku 13:3). Wọn ha tun n kede kikan wi pe è̩ṣẹẹgbẹjọda nì, ti i ṣe è̩ṣẹ panṣaga, ti o gbilẹ lọjọ oni kò dára? Ile isin kun fọfọ fun awọn ọkunrin ti o ti n gbé pẹlu iyawo ẹlomiran ati awọn obinrin ti o n gbé pẹlu ọkọọlọkọ. OjiṣẹỌlọrun meloo ni o n kede lati ori aga-iwaasu pe “a gbodọ tun nyin bi”? ati pe a ni lati ṣe atunṣe nigba ti a ba di atunbi? Wọn ha tun n sọ fun ni wi pe a ni lati sọ wa di mimọ, ki a ni ọkàn mimọ ati àya funfun ninu eyi ti a ti pa è̩ṣẹ abinibi run? Awọn kóko è̩kọ pataki ba wọnyii ni a ki i waasu mọ ninu ile isin pupọ. Sibẹ otitọ wọnyii wà ninu ỌrọỌlọrun, Iwe Mimọ sọ fun ni pe bi ẹnikẹni bá fi kún ỌrọỌlọrun tabi ki o yọ kuro ninu Rè̩, Oun ki yoo ni ipin lọdọỌlọrun. “Iwọ máṣe fi kún ọrọ rè̩, ki on má ba ba ọ wi, a si mu ọ li eke” (Owe 30:6). (Wo Deuteronomi 4:2; 12:32; Jọṣua 1:7; Ifihan 22:18, 19 pẹlu).

Dafidi mọ pe awọn eniyan ayé n ṣọ iṣisẹ oun. O n fẹ ki gbogbo ohun ti oun ba sọ tabi ohun ti oun ba ṣe ki o le fi iyìn fun ẹbi Ọlọrun, ki o si lè gbé ogo orukọ nla Baba rẹỌrun ga. “Hihá ti ni ẹnu-ọna na, ati toro li oju-ọna na, ti o lọ si ibi ìye, diẹ li awọn ẹniti o nri i” (Matteu 7:14).

Ikorira è̩ṣẹ

Psalmu yìí n sọ fun wa pe Oluwa korira “gbogbo awọn oniṣẹè̩ṣẹ.” Bi ọkàn kan bá taku si iṣọtẹ si ipe aanu Ọlọrun si ironupiwada, ti o si fẹ maa dẹṣẹ, kò din iwa mimọỌlọrun kù. “Oju rẹ mọ jùẹniti iwò ibi lọ, iwọ kò si lè wò iwa-ika” (Habakkuku 1:13).

Ọlọrun rọòjo iná ati sulfuru lé Sodomu ati Gomorra lori nitori iwa buburu wọn dídò. Iwa awọn eniyan buburu burú jai ni ọjọ Noa to bẹẹ ti Oluwa fi kaanu nitori ti O dá eniyan si ayé, O si dun Un de ọkàn. Inu Ọlọrun kò dun lọjọ oni si awọn oniṣẹè̩ṣẹ, Oun yoo si rán idajọ ododo Rè̩ si ori ayé lẹẹkan si i.

Ibukun awọn Olododo

“Gbogbo awọn ti ngbẹkẹle ọ yio yọ; lai wọn o ma ho fun ayọ, nitoriti iwọ dabobo wọn: ati awọn ti o fẹ orukọ rẹ pẹlu yio ma yọ ninu rẹ.” Ileri ti o wà fun awọn olododo pọ to bẹẹ gẹẹ ti o yẹ fun wọn lati maa yọ lọsan ati loru. Idande kuro ninu è̩ṣẹ a maa fi alaafia kún ọkàn. Ileri iye ainipẹkun yoo fun ẹni naa ni ayọ. Ireti Ọrun a maa mú ki eniyan hóìhó ayọ si Ọlọrun. Peteru sọ bayii pe igbala yii n mú wa yọ “ayọ ti a kò le fi ẹnu sọ, ti o si kun fun ogo.”

Eṣu jé̩ọtá awọn ọmọỌlọrun, awọn ẹlẹṣẹ a si maa fi oju è̩gan wò wọn. S̩ugbọn ayanfẹ Baba ni wọn i ṣe, Jesu n ṣọè̩ṣọ lori wọn, Ẹmi Mimọ si n tù wọn ninu. Ireti ologo wà fun ọmọỌlọrun pé ni ọjọ kan oun yoo ri Jesu, oun yoo si ma ba A gbe titi lae ni ilu didan nì ti Johannu ri ti n sọkalẹ lati ọdọỌlọrun wá.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Nigba wo ni Dafidi gbadura rè̩ si Oluwa?

  2. 2 Ki ni Jesu sọ nipa adura awiyannu?

  3. 3 Ki ni ṣe ti Dafidi fi n gbadura fun itọni Ọlọrun?

  4. 4 Iru ìbè̩rù wo ni o wà ni ọkàn Dafidi nígbà ti o lọ si iha Tẹmpili lati jọsin?

  5. 5 Ìhà wo ni Ọlọrun kọ si awọn oluṣe buburu?

  6. 6 Nipa ìmọ ta ni awọn eniyan buburu yoo ṣègbé?

  7. 7 S̩e afiwe iyatọ to wà laaarin eniyan buburu ati olododo.

  8. 8 Darukọ díè̩ ninu awọn ohun to n mu inú olododo dùn.