2 Kronika 32:1-23; 2 Awọn Ọba 19:14-37

Lesson 344 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA ni imọlẹ mi ati igbala mi; tali emi o bè̩ru? OLUWA li agbara ẹmi mi; aiya tali yio fò mi?” (Orin Dafidi 27:1).
Cross References

I Igbogun Sennakeribu ati IgbagbọHẹsekiah

1 Sennakeribu dó ti awọn ilu olodi Juda, 2 Kronika 32:1; 2 Awọn Ọba 18:13-16; Isaiah 36:1

2 Hẹsekiah sa gbogbo ipa rè̩ lati daabo bo Jerusalẹmu kuro lọwọọtá, 2 Kronika 32:2-5

3 Igbagbọ rè̩ ninu Ọlọrun ràn án lọwọ lati sọọrọ ikiyà, 2 Kronika 32:6-8

II ỌrọÒdì Sennakeribu ati Adura Hẹsekiah

1 A sọrọẹgan si Hẹsekiah ati si Oluwa, 2 Kronika 32:9-19; Isaiah36:2-22; 2 Awọn Ọba 18:17-37

2 Sennakeribu kọ iwe ọrọ-òdi ranṣẹ si Hẹsekiah, 2 Kronika 32:17; 2 Awọn Ọba 19:8-13; Isaiah 37:14

3 “Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ,” Jakọbu 5:16; 2 Awọn Ọba 19:14-19; 2 Kronika 32:20; Isaiah 37:15-20; Orin Dafidi 46:1

III Idahun Oluwa ati Iparun Sennakeribu

1 A sọ ti idajọ Sennakeribu lati ẹnu Isaiah, 2 Awọn Ọba 19:20-34; Isaiah 37:21-35

2 Ibẹwo angẹli ti a rán mu ikú wa sori ẹgbé̩ ogun Assiria, 2 Awọn Ọba 19:35-37; 2 Kronika 32:21-23; Isaiah 37:36

Notes
ALAYE

Iṣọkan

“Nibiti igbimọ kò si, awọn enia a ṣubu” (Owe 11:14). Lẹsẹkẹsẹ ti Hẹsekiah mọ pe Sennakeribu, ọba Assiria, n bọ lati wa ba oun jà, ó bá awọn ijoye rẹ, ati awọn ọkunrin alagbara rè̩ gbimọ. Wọn jumọṣiṣẹ lati mú odi wọn le, wọn si mura silẹ lati ba Sennakeribu jà. Iṣọkan ti o wà laaarin wọn ni akoko iṣoro yii jé̩ abayọri imupada isin ti è̩mí ni akoko ijọba Hẹsekiah. Hẹsekiah ṣe ohun ti o le ṣe nigba naa, o si “sọrọ iyanju” fun awọn eniyan rẹ.

Imulọkanle

“Ẹ mu ara le, ki ẹ si ṣe onigboiya, ẹ má bè̩ru, bḝni ki aiya ki o máṣe fò nyin” (2 Kronika 32:7). Igba meloo ni iru ọrọ iṣiri bayii ti rúọkàn awọn ọmọ-ogun Kristi soke lati tè̩ siwaju ninu ija igbagbọ. O le jé̩ ipin awọn ọmọ-ogun Rè̩ lati la afonifoji ojiji ikú kọja, ṣugbọn ọmọỌlọrun kò gbọdọ bè̩ru, nitori ti o le gbé oju rè̩ soke Ọrun pẹlu igbagbọ pe Ọlọrun yoo “pa a mọ li alafia pipé, ọkàn ẹniti o simi le ọ” (Isaiah 26:3).

Ogun Ọlọrun

“Awọn ti o pẹlu wa jù awọn ti o pẹlu rè̩ lọ” (2 Kronika 32:7). Ọba Assiria ni ọmọ-ogun ti o lọṣua; o tilẹ gboju-gboya lati fi ẹgbaa ẹṣin lọ Hẹsekiah ki ẹgbẹ ogun tọtún tosì ba le fẹrẹ dọgba, sibẹ Hesekiah le wi pe “Awọn ti o pẹlu wa jù awọn ti o pẹlu rè̩ lọ.” Bi o tilẹ jẹ pe oju rè̩ kò ri awọn ẹlẹṣin ati awọn kẹkẹ iná ti o yi i ká gẹgẹ bi o ti ri fun iranṣẹ Eliṣa, sibẹ gẹgẹ bi Eliṣa o mọ pé wọn wà nibẹ.

Nigba pupọ ni a ma n gbọ riru omi okun, ti a si n gbọn pè̩pẹ, lai ranti Ẹni ti o wi pe “Nihin yi ni iwọ o dé, ki o má si rekọja, nihin yi si ni igberaga riru omi rẹ yio gbe duro mọ” (Jobu 38:11). O yẹ ki o da wa loju pe, “Nigbati ọta yio de bi kikún omi, Ẹmi Oluwa yio gbe ọpágun soke si i” (Isaiah 59:19). Bi ikun omi tilẹ wó ogiri alagbara, ti o si wó adamọdi ile ti a fi ipilẹ rè̩ sọlẹ sori iyanrin, sibẹọpagun Oluwa yoo duro gbọnin ninu iji lile, bẹẹ ni igbi omi ti o rọlu u ki yoo le bi i wó.

Bi apa ẹran ara tilẹ lagbara, ta ni o tobi ju, ẹdá ni, tabi Ẹlẹda ti o da a? Bi Ẹlẹda ba le fi ọrọẹnu Rẹ da a, kò ha le fi ọrọẹnu rẹ kan naa gba ẹmi rè̩. Njẹ o yẹ ki awa ẹdáọwọ Rè̩ ki o maa bẹru lati jọwọ ara wa yii lọwọ fun Ọlọrun nigba idanwo ati ipọnju, ni ero pe apa ẹran-ara lagbara ju Ọrọ agbára Rè̩? Njẹ o yẹ ki a maa gbọn jinnijinni nigba ti èṣu ba n bu ramuramu nigba ti a mọ pe oun kò le ṣe ju bi Oluwa ti gba a laye lọ? Ọlọrun wi pe, “Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọọ silẹ” (Heberu 13:5).

Ifisùn

“Awọn enia na si gbẹkẹ wọn le ọrọ Hẹsekiah, ọba Juda.” Wo bi ọtá ti n sọrọèebú! Wo bi o ti n sọrọẹgàn nigba ti o ri bi awọn eniyan naa ti gbẹkẹ le Ọlọrun! Iwọ ha gbọ bi o ti n wi pe “Iwọ n fi iku ṣire bi o kò ba ro nnkan ṣe! Ebi ni yoo pa ọ kú! Oungbẹ ni yoo gbẹọ pa! Ọlọrun ti kọ Hẹsekiah silẹ wayii, Ọlọrun ti binu si i! Wo gbogbo ile oriṣa ti Hẹsekiah ti wó lulẹ ati awọn pẹpẹ ti o ti parun!” Nigba pupọọtá a maa tọka si agabagebe bi ẹni pe Onigbagbọ tootọ ni oun i ṣe. LotitọHesekiah wó ibi giga lulẹ, ṣugbọn o ṣe e gẹgẹ bi ilana Ọlọrun. Leke gbogbo irunu rè̩, Sennakeribu sọrọ odi ni ti pe o sọ wi pe Oluwa wà ni iha oun ati pe Oluwa ti wi fun oun pe, “Gòke lọ si ilẹ yi, ki o si pa a run” (2 Awọn Ọba 18:25).

Idakẹ Jẹẹ

“S̩ugbọn awọn enia pa ẹnu wọn mọ, nwọn kò si da a li ohun ọrọ kan: nitori aṣẹọba ni, pe, Ẹ máṣe da a li ohùn” (2 Awọn Ọba 18:36). Kòṣe anfaani lati maa bá eṣu jiyan. Kòṣanfaani lati da a lohùn. Ninu gbogbo ẹsun ti a fi sun Un, Jesu kò dá a ni “gbolohun kan” (Matteu 27:14); Mikaẹli, olori angẹli, dá Satani lohùn pe, “Oluwa ni yio ba ọ wi” (Juda 9). Lati maa ba awọn ti o lodi si ijẹwọ igbagbọ rẹ jiyan kò le mú ohun rere kan wá. Ta kete si ijiyan ati gbolohun asọ, ṣugbọn, “Ki ẹ si mura tan nigbagbogbo lati dá olukuluku lohùn ti mbere ireti ti o mbẹ ninu yin, ṣugbọn pẹlu ọkàn tutù ati ibẹru” (1 Peteru 3:15).

Adura Hesekiah

Nigba iṣoro, Hẹsekiah rẹ ara rè̩ silẹ, o fa aṣọ rè̩ ya, o fi aṣọọfọ bora, o si lọ si ile Oluwa. O ranṣẹ si Isaiah, wolii alagbara ninu Ọlọrun nì, lati so ọwọ pọ pẹlu rè̩ ninu adura. O ba awọn eniyan mimọ wọnyii ninu jé̩ lati gbọ bi awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ti n sọrọ odi si Ọlọrun Israẹli, ti wọn si ka A si bi ọkan ninu awọn ọlọrun keferi ti i ṣe iṣẹọwọ awọn ẹlẹṣẹ. Bi Hẹsekiah ti té̩ iwe è̩gan ti Sennakeribu kọ si i siwaju rè̩, o bẹỌlọrun lati daabo bo Jerusalẹmu “ki gbogbo ilẹọba aiye le mọ pe iwọ OLUWA, iwọ li Ọlọrun nikanṣoṣo” (2 Awọn Ọba 19:19).

Idahun

Ọlọrun ranṣẹ pada si Hẹsekiah pe Oun ti gbọ adura rè̩, O si jẹ ki o mọ eredi rè̩ ti Sennakeribu fi le ṣẹgun awọn orilẹ-ède wọnni. Agbara rè̩ kò jọ ni loju mọ nigba ti Oluwa fi hàn pe awọn orilẹ-ède ti o parun dabi “ọkà ti o rè̩ danù ki o to dàgba soke” (2 Awọn Ọba 19:26). Oluwa ti fi hàn niye igba pe Oun ni alakoso ni ijọba awọn eniyan. Farao ọlọkàn lile kọju ija si Ọlọrun titi Ọlọrun fi pa Egipti run. Nebukadnessari gbé ara rè̩ ga titi Ọlọrun fi lé e jade kuro ni ijọba rè̩, ti o si pa iye rè̩ dà. Bẹlṣassari n mookùn ninu è̩ṣẹ titi ọwọỌlọrun fi kọ iparun rè̩ sara ogiri. Jẹ ki Sennakeribu ati gbogbo awọn ti n jọba ni ilẹ ayé mọ pe “Kò si aṣẹ kan, bikoṣe lati ọdọỌlọrun wá: awọn alaṣẹ ti o si wà, lati ọdọỌlọrun li a ti làna rè̩ wá” (Romu 13:1). Eṣu kò le lọ tayọ ibi ti Ọlọrun ba gba a laye dé. Ké̩kẹ pa mọ Sennakeribu lẹnu o si pada si ilu rè̩ pẹlu itiju.

Angẹli Apanirun

Akewi Ọlọla Bryon kọọrọ arofọ ti o gbadun nipa bi Ọlọrun ṣe rán angẹli Rè̩ ti o pa ọkẹ mẹsan-an le ẹgbẹẹdọgbọn eniyan ati gbogbo awọn alagbara ogun, ati awọn aṣaaju ati awọn balogun ninu awọn ogun Siria.

IPARUN SENNAKERIBU

Awọn Assiria sọkalẹ bi ikookò ti i bé̩ sinu agbo,

Awọn ọmọ-ogun rè̩ n kọ mọnà ninu aṣọ elese aluko ati wura;

Ọkọ wọn si n kọ mọnà bi itanṣan irawọ lori okun,

Nigba ti igbi omi okun ba n fé̩ lẹlẹ ni àṣaalé̩ lori okun Galili.

Gẹgẹ bi ewe igi igbẹ ti i tutu yọyọ ni igba òjò,

Bẹẹ ni a ri awọn ọmọ-ogun wọn ni àṣaalé̩ pẹlu ọpagun wọn;

Gẹgẹ bi ewe igi igbẹ ti i rè̩ danu lakoko ẹẹrun,

Bẹẹ ni a ri awọn ọmọ-ogun wọn lọjọ keji ti wọn ti ṣubu lulẹ lọ bẹẹrẹ bẹ.

Nitori pe Angẹli Apanirun ti fò kọja,

O si mi eemi rè̩ si oju awọn ọtá bi o ti n kọja lọ;

Oju awọn oloorun wọnyi si di tutu bi yinyin,

Wọn mí kanlẹ lẹẹkan, akukọ si kọ lẹyin ọkunrin!

Awọn ẹṣin ṣubu yakata, imú wọn si fè̩ gan an

Wọn kò le fi imu wọn mi eemí igberaga mọ:

Ifoofoo ẹnu wọn funfun lọ saa lori ilẹ,

O si tutu bi imú ajá.

Ẹlẹṣin ṣubu lulẹ gbalaja, àgbọn isalẹ ti yè̩,

Iri sẹ si i lori, ẹwu irin si dipẹta;

Gbogbo agọ parọrọ, oluṣọ kò si fun ọpagun,

A kò r’ẹni gbe’dà, ohun ipè dẹkun.

Awọn opó Aṣuri pohunrere ẹkun kikan,

A si fọ gbogbo oriṣa ninu tẹmpili Baali;

Agbara keferi, ti a kò gbọwọ ida soke si,

Ti yọ bi yinyin niwaju Oluwa!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni Hẹsekiah ṣe lati daabo bo Jerusalẹmu?

  2. 2 Ki ni ṣe ti Hẹsekiah fi le wi pe “awọn ti o pẹlu wa jù awọn ti o pẹlu rè̩ lọ”?

  3. 3 Iru iha wo ni awọn eniyan naa kọ si ọrọ Hẹsekiah?

  4. 4 Sọ oriṣiriṣi ọna ti Sennakeribu fi ṣe aṣiṣe nigba ti o fi ẹsun sun Hẹsekiah ati Ọlọrun.

  5. 5 Ki ni ṣe ti ọba Assiria fi le ṣẹgun ọpọlọpọ orilẹ-ède?

  6. 6 Ta ni Hẹsekiah ke si lati ba a gbadura?

  7. 7 Nitori ta ni Ọlọrun fi wi pe Oun yoo daabo bo Jerusalẹmu?

  8. 8 Awọn meloo ni angẹli Oluwa pa?

  9. 9 Iru ipo wo ni awọn ti a pa naa wà laaarin ogun?

  10. 10 Ki ni ṣẹlẹ si Sennakeribu?