2 Awọn Ọba 20:1-18; 2 Kronika 32:26, 31-33

Lesson 345 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọlọrun, wadi mi, ki o si mọ aiya mi: dán mi wò, ki o si mọ iro-inu mi: Ki o si wò bi ipa-ọna buburu kan ba wà ninu mi, ki o si fi ẹsẹ mi le ọna ainipẹkun” (Orin Dafidi 139:23, 24).
Cross References

I Aisàn Hẹsekiah ni Akoko Idaamu Juda

1 Ẹgbẹ ogun Sennakeribu daya fo Jerusalẹmu, 2 Awọn Ọba 20:6; 18:17

2 Isaiah sọ fun Hẹsekiah pe yoo kú ninu aisàn rè̩, 2 Awọn Ọba 20:1; Isaiah 38:1

3 Hẹsekiah sọkun niwaju Oluwa, 2 Awọn Ọba 20:2, 3

II Ọlọrun Oniṣẹ-Iyanu

1 Ọlọrun rán Isaiah padà ni idahun si adura, 2 Awọn Ọba 20:4-6

2 A wo Hẹsekiah sàn, 2 Awọn Ọba 20:7;Jakọbu 5:14, 15; Ẹksodu 15:26

3 Ọlọrun rán àmì kan, 2 Awọn Ọba 20:8-11; Marku 16:17, 18

III Iyiriwo Hẹsekiah

1 Hẹsekiah gba alejo lati Babiloni wá, 2 Awọn Ọba 20:12, 13; 2 Kronika 32:31

2 Ọkàn Hẹsekiah gbega, 2 Kronika 32:25, 26; Orin Dafidi 101:5; Owe 6:17

3 Isaiah bá Hẹsekiah wi, o si sọ nipa akoko igbekun ni ilẹ Babiloni, 2 Awọn Ọba 20:14-18

4 Hẹsekiah kú, 2 Kronika 32:32, 33

Notes
ALAYE

Agbara ninu Ailera

A fi ẹgún kan sara Paulu nitori ki o ma baa gberaga. O bẹ Oluwa ni ẹrinmẹta ọtọọtọ ki a mu un kuro, ṣugbọn ohun ti o gbọ ni eyi: “Ore-ọfẹ mi to fun ọ: nitoripe a sọ agbara mi di pipé ninu ailera” (2 Kọrinti 12:9). O daju pe ni akoko idanwo ati aisàn – nigba ti a ba wà ninu ailera -- igbẹkẹle wa ninu Ọlọrun maa n pọ jọjọ, agbára Ọlọrun yoo si fara hàn.

Iná Atunniṣe

Hẹsekiah ọba jé̩ẹni iwa-bi-Ọlọrun, ẹni ti o fi gbogbo ọkàn rè̩ sin Ọlọrun; ṣibẹọpọlọpọ idanwo ni o doju kọọ lati yiri rè̩ wò ati lati rè̩é̩ silẹ. Sennakeribu dide si i pẹlu gbogbo ogun Assiria; iparun si rọ dẹdẹ lori ijọba Juda. Ki Hẹsekiah baa le doju kọ idanwo yii o mu ara rè̩ le ninu Oluwa. Lati mu ki ọran naa tubọ le sii, akoko ti a dó ti Hẹsekiah ni o ṣaisan titi de oju ikú. O dabi ẹni pe, lati fi kun idaamu rè̩, a tun rán Wolii Isaiah lati sọ fun ọba ẹni ọdun mọkandinlogoji yii pe ki o pa ilẹ ile rè̩ mọ nitori ti oun yoo kú.

Wo bi ọjọ naa yoo ti jẹọjọ ibanujẹ to fun ọba yii nigba ti Isaiah jiṣẹ ikú fun un, ti o si fi i silẹ bẹẹ! Yoo dabi ẹni pe gbogbo ogun ọrun apaadi ni o dide si i, ọrun pẹlu si dabi idẹ loke ori rè̩. Hẹsekiah yi oju rè̩ si ogiri, ninu ibanujẹọkàn rè̩, o sọkun kikorò. Wo bi idahun ti o lagbara ti de kánkan lati ọdọỌlọrun nigba ti Ọlọrun ri i pe iná ipọnju fẹrẹ bori iranṣẹ Rè̩. O fara jọ igba ti Abrahamu gbéọbẹ soke lati fi ọmọ rè̩ kan ṣoṣo ọrubọ, ti angẹli Oluwa si kọ si i lati Ọrun wa ti o si ṣi i lọwọ. Ki Ọlọrun ma ṣai jẹ ki o di mimọ fun gbogbo awọn ọmọỌlọrun pe Ẹni ti n tun Lefi ṣe mọ wura Rè̩, Oun ki yoo si jẹ ki iná ki o gbona ju bi o ti yẹ lati tún awọn ọmọ Rè̩ṣe!

Iṣẹ-ami ati Iṣẹ-iyanu

Iṣẹ Oluwa ti jẹ iyanu to! Iranwọ Rè̩ si ti tobi to nigba ti O ba na ọwọ Rè̩ jade! Pẹlu ami ati iṣẹ-iyanu, O sọ ara Rè̩ di mimọ fun Hẹsekiah. Angẹli ikú réọba Juda kọja, o si pa awọn ọmọ-ogun Assiria, o fi Sennakeribu silẹ lati pada si Ninefe pẹlu ifajuro ati itiju, bi awọn wundia Sioni ti n mi ori wọn, ti wọn si n fi rẹrin ẹlẹya.

Ki i ṣe awọn wọnyi nikan ni ohun iyanu ti o ṣelẹ ni ọjọ ma-ni-gbagbe yii nitori pe Ọlọrun rán Isaiah pada lati sọ fun Hẹsekiah pe Oun yoo wòó sàn, Oun yoo si fi ọdún mẹẹdogun kun ọjọ aye rè̩. Lati fi idi rè̩ mulẹ pe iṣẹ naa ti ọdọỌlọrun wá, Isaiah ké pe Oluwa, Ọlọrun si mu ki oorun pada sẹyin ni ogoji iṣẹju, yoo si dabi ẹni pe ni ṣe ni agogo oòrun Ahasi n ṣiṣẹ segesege nigba ti ojiji pada sẹyin ni iṣisẹ mẹwaa. Wo iru idagiri ti yoo dá silẹ laaarin awọn eniyan ti o wà ninu ayé lati ri i pe oorun pada sẹyin ni oju ọrun! Bi awọn alaigbagbọ ba fẹ wọn le maa fi ohun ti o ṣẹlẹ yii ṣẹfẹ: ṣugbọn Ọlọrun Hẹsekiah ni Ọlọrun ti O dá oorun, ayé ati ofurufu; Oun ni O n mu ki ohun gbogbo ti o wà ninu agbaye ki o maa ṣiṣẹ letoleto: bi O ba si fẹ O le yi eto yii pada si idaamú awọn ti kò gbagbọ.

Iyin

Wo bi ayọ naa yoo ti pọ to ati bi ile Oluwa yoo ti maa ho fun orin ayọ ni ọjọ kẹta nigba ti Hẹsekiah wá lati fi ọpẹ fun Ọlọrun fun idasilẹ ati ọdun mẹẹdogun ti a fi kún ọjọ ayé rẹ! “Iboji kò le yin ọ, iku kò le fiyin fun ọ: awọn ti o sọkalẹ lọ sinu ihò kò le ni irèti otitọ rẹ. Alāye, alāye, on ni yio yin ọ, bi mo ti nṣe loni yi.” Ọrọ wọnyi ni o ti ẹnu ọba jade. O gba gbogbo ọdè̩dè̩ kan, gbohungbohun si gbe e jakejado agbala tẹmpili.

Iwosan

Lati gbadura si Oluwa fun iwosan gẹgẹ bi Hẹsekiah ti ṣe ki i ṣe ohun ajeji si awọn ọmọỌlọrun. Oluwa ti ṣe ileri pe, “Emi li OLUWA ti o mu ọ lara dá” (Ẹksodu 15:26). Ninu Ọrọ Rè̩, a gba awọn ti a n pọn loju niyanju lati gbadura, a si ke si awọn alaisan lati pe “awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rè̩, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa: Adura igbagbọ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide” (Jakọbu 5:14, 15). Agbara Rè̩ lati wosàn kò pamọ titi di oni-oloni fun awọn wọnni ti o ba gbẹkẹ wọn le E.

A fi awọn ti o gbẹkẹ le apáẹran-ara ti ọkàn wọn si ṣi kuro lọdọỌlọrun gegun. Inu Ọlọrun kò dun si Asa ẹni ti “kò wá OLUWA, bikòṣe awọn oniṣegun” (2 Kronika 16:12). Asa kò ri iwosan, o si kú; ṣugbọn Hẹsekiah gbadura o si yè. Awọn ẹlomiran le maa tọka pe eso ọpọtọ ti Isaiah sọ fun Hẹsekiah lati fi ṣan oowo naa jé̩ apẹẹrẹ lilo egbogi. Kòṣe e ṣe fun eso ọpọtọ lati wo oowo naa sàn gẹgẹ bi kò ti ṣe e ṣe fun omi Jọrdani lati wo arun è̩tẹ sàn. Amọ ti Jesu lò lati fi pa oju ọkunrin afọju nì ki i ṣe oogun fun oju fifọ gẹgẹ bi ororo ti awọn alàgba ijọ n ta sori awọn alaisan ki i ṣe oogun iwosan. Igbọran si aṣẹỌlọrun ati igbagbọ ninu Ọlọrun ni o n jẹ ki awọn alaisan ri iwosan gbà; aajo tabi iranlọwọẹran-ara kò ni nnkankan ṣe lati mu ipinnu Rè̩ṣẹ. Jẹ ki awọn ti n sin Ọlọrun ki o fi tọkàntọkàn gbe ẹkẹ wọn le “Ẹniti o si tán gbogbo àrun rẹ” (Orin Dafidi 103:3).

Igberaga

“S̩ugbọn Hẹsekiah kò si tun pada san gẹgẹ bi ore ti a ṣe fun u: nitoriti ọkàn rè̩ gbega” (2 Kronika 32:25). Ara ti le, ihalẹ awọn Assiria ti di asán, ọrọ ati ọlá si de fun un, o yẹ ki Hẹsekiah ki o rìn ni irẹlẹ niwaju Ẹlẹda rẹ ti o ti ṣe ohun iyanu fun un. S̩ugbọn nigba ti awọn ikọ múọrẹ ti Babiloni wá fun un, eyi jé̩ idẹkùn fun un. Pẹlu igberaga ọkàn o fi gbogbo iṣura rè̩ hàn fun wọn. Lẹkan si i Ọlọrun rán Wolii Isaiah si Hẹsekiah, ṣugbọn nisisiyii, lati ba a wi fun iwa aṣiwere rè̩.

“Igberaga ni iṣaju iparun, agidi ọkàn ni iṣaju iṣubu” (Owe 16:18). Ohun gbogbo ti Hẹsekiah ati Juda n fi hàn pẹlu igberaga ni a o gba lọ kuro lọwọ wọn. Gbogbo awọn iṣura ti wọn fi n ṣe féfé ni yoo bọ si ọwọ awọn ara Babeli niwaju ẹni ti wọn ti n fè̩ soke. Ki Ọlọrun ki o ran gbogbo wa lọwọ lati mọ pe igberaga jẹ ohun irira niwaju Ọlọrun. “Okú eṣinṣin o mu ororo-ikunra alapolu bajẹ ki o ma run õrùn buburu: bḝni wère diẹ wuwo jùọgbọn ati ọlá lọ” (Oniwasu 10:1).

Irẹlẹ

Hẹsekiah gba ibawi yii lati ọdọ Oluwa, gẹgẹ bi ẹni nla, o rẹ ara rè̩ silẹ; Ọlọrun si sun ọjọ ikolọ Juda siwaju ti kò fi ṣẹlẹ ni ọjọ Hẹsekiah. NitootọỌlọrun juba awọn onirẹlẹ o si “gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là” (Orin Dafidi 34:18). Ọlọrun boju wo ẹni bi Ahabu apaniyan, nigba ti o rẹ ara rè̩ silẹ nipa ibawi Elijah; O si gbọ adura Manasse ti o fi ẹjẹ alaiṣẹ kún Jerusalẹmu nitori ti o rẹ ara rè̩ silẹ gidigidi. Ọlọrun maa n na ọwọ aanu Rè̩ si awọn ti o ba rẹ ara wọn silẹ ti o si mọ ara wọn ni ẹlẹbi niwaju Rè̩. “Ẹ rẹ ara nyin silẹ niwaju Oluwa, on yio si gbé nyin ga” (Jakọbu 4:10). Tabi iwọ ti tobi ju loju ara rẹ lati rẹ ara rẹ silẹ?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ka itàn igbesi-ayé Hẹsekiah lẹsẹẹsẹ ki o si sọ bi o ṣe mọ pé aisàn dé ba a ni akoko ti Sennakeribu gbogun ti ilẹ Juda.

  2. 2 Sọ diẹ ninu awọn ohun ti Hẹsekiah ṣe lakoko ijọba rẹ ki o to ṣaisàn.

  3. 3 Ẹni ọdun meloo ni Hesekiah nigba ti aisan kọ lu u?

  4. 4 Bawo ni o ti pẹ to ki Ọlọrun to gbọ adura rẹ fun iwosan?

  5. 5 Tọka si diẹ ninu awọn ẹsẹỌrọỌlọrun ti o mu ki a gbẹkẹ le Ọlọrun fun iwosàn.

  6. 6 Bawo ni a ṣe mọ pé ogoji iṣẹju ni iṣisẹ mẹwaa ninu agogo-oorun Ahasi bọ si?

  7. 7 Iṣẹ wo ni eso ọpọtọṣe ninu iwosan Hẹsekiah?

  8. 8 Tọka si awọn asọtẹlẹ miiran nipa ikolẹru lọ si ilẹ Babiloni.

  9. 9 Ki ni kò jẹ ki ibinu Ọlọrun wa sori Jerusalẹmu ni akoko ijọba Hẹsekiah?