Iṣe Awọn Apọsteli 19:21-41; Matteu 10:16-28; Luku 21:12-19

Lesson 346 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati wọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn ba nfi eke sọrọ buburu gbogbo si nyin nitori emi. Ẹ mā yọ, ki ẹnyin ki o si fò fun ayọ: nitori ère nyin pọ li ọrun; bḝni wọn sáṣe inunibini si awọn woli ti o ti mbẹṣaju nyin” (Matteu 5:11, 12).
Cross References

I Iranṣẹ ati Oluwa Rè̩

1 Jesu kilọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ nipa inunibini ti n bọ wá, Matteu 10:16-18, 21-23; 24:9-14; Luku 21:12, 16, 17; Mika 7:5, 6; Marku 13:9, 12, 13

2 Jesu ti fún awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni imọran pe Ọlọrun yoo kọ wọn ni ọrọ ti wọn yoo sọ nigba ti a ba ṣe inunibini si wọn, Matteu 10:19, 20; Luku 21:13-15; Ẹksodu 4:10-12; Jeremiah 1:6-9; Daniẹli 3:16-18; Johannu 7:46; Marku 12:34

3 Jesu ṣe alaye ẹkọ nla naa fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe, ọmọ-ọdọ kò tobi ju oluwa rè̩ lọ, Matteu 10:24, 25;Luku 6:40; Johannu 13:13-16; 15:20

4 A sọ fun awọn ọmọ-ẹyin pe ki wọn ki o máṣe bẹru awọn ti o le pa ara, ṣugbọn ki wọn kuku bẹru Ẹni ti o le pa ẹmi run ni ọrun apaadi, Matteu 10:26-28; Luku 21:18, 19; Jakọbu 4:12; Orin Dafidi 119:120; Oniwasu 5:7; Jeremiah 5:22; Amosi 5:6

II Wahala ni Efesu

1 Lati ọwọ Demetriu, alagbẹdẹ fadaka, ni inunibini si iwaasu Ihinrere Jesu Kristi ti dide, Iṣe Awọn Apọsteli 19:21-28;2 Timoteu 4:14; 3:11, 12

2 Awọn oni-jagidi-jagan eniyan mu awọn alabaṣiṣẹ Paulu, wọn si fi wọn sinu tubu, Iṣe Awọn Apọsteli 19:29

3 Awọn ọrẹ Paulu dá a-lé̩kun ati wọ ibi-iṣire lọ pẹlu awọn oni rukerudo eniyan, ki o ma baa fi ẹmi rè̩ wewu, Iṣe Awọn Apọsteli 19:30, 31; 21:12; Johannu 11:8

4 Akọwe ilu pa awọn eniyan lẹnu mọ, o si tú wọn ká, nipa bayii o gba awọn ọmọ-ẹyin lọwọ ipalara, Iṣe Awọn Apọsteli 19:32-41

Notes
ALAYE

Ewu jijẹỌmọ-ẹyin

A sọ fun ni pe, “Ipọnju ni tuna-aṣiri iwa ti o wà lodo ọkàn ọmọ-eniyan.” On ni o n fi irú igbala ti awọn ọmọ-lẹyin Kristi ni hàn. Awọn ẹlomiran ti ni igbala tootọṣugbọn wọn ṣe aarẹ labẹ inunibini, wọn si pada kuro lẹyin Kristi.

Jesu kò fi ọkàn ẹnikẹni balẹ sinu ireti asán wi pe ọna Ọlọrun jé̩ọna gbẹfẹ, tabi ọna ti ki i ṣe dandan pe ki a ni ipinnu ti o fẹsẹ mulẹ gidigidi tabi eyi ti ki yoo fun ni ni awọn ojuṣe ti o ṣe pataki. Owe Jesu nipa ọkunrin ti o bẹrẹ si kọ ile iṣọ giga ṣugbọn ti kò le pari rè̩ nitori ti kò mura silẹ, ni lati jé̩ ikilọ fun awọn wọnni ti wọn fi iwara-papa bẹrẹ lati maa ṣe ọmọlẹyin Rè̩. (S̩e ayẹwo Ẹkọ 149, Iwe Kejila, apa Kẹta “Ohun ti yoo gba wa”).

Nipa riru itara wiriwiri kan soke, awọn eniyan ayé a maa ko ọmọ-ẹyin jọ fun ara wọn lai jẹ ki wọn mọ awọn ewu ti wọn yoo ba pade ninu ipe wọn. Ọlọrun ki i sọàabọ-ootọ fun ni, bẹẹ ni ki i pe awọn eniyan si ilana Rè̩ lai sọ iṣoro ti o le doju kọ wọn ni ọjọ iwaju. Ọlọrun a maa sọ okodoro otitọ, ni bi o ti ri gan an, lai fi nnkan to dùn bo otitọ ti o korò lara, lati mu ki Ihinrere tè̩ siwaju. Ọlọrun mọ pe kiki awọn ti o pinnu lati sin Oun lai kọ ohun ti o le dé ni yoo fara da iṣoro titi wọn yoo fi gba ade iye, ti wọn o si fi ara wọn hàn gẹgẹ bi ọmọ-ẹyin tootọ fun Oluwa.

Jesu sọ pato lai si ilọra, fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe wọn yoo fi ara da inunibini nla nitori orukọ Oun. Niwọn bi Ọlọrun ti kilọ fun wa tẹlẹ pe awọn iṣoro wà niwaju, kò yẹ ki o ba wa ni itulẹ, a ni lati le sọ gẹgẹ bi ti Paulu wi pe, “A gbe mi dide fun idahun-ẹjọ ihinrere” (Filippi 1:17). Bi kòṣe bẹẹ, Satani, ọta Ọlọrun ati awọn eniyan Rè̩, le mu ki awọn ọmọỌlọrun gbagbọ pe Ọlọrun ti fi wọn silẹ nigba ti idojukọ ba dide si wọn.

Ọpọè̩ri ni o wà ninu itan IjọỌlọrun ti o fi imuṣẹ ikilọ Jesu nipa inunibini mulè̩. Itan atọwọdọwọ sọ fun ni pe Johannu Ayanfẹ nikan ni ẹni ti kò kú ikú ajẹrikú ninu gbogbo awọn Apọsteli mejila. Ọkẹ aimoye eniyan ni o ti tun fi ẹmi wọn le lẹ nitori Ihinrere, kàkà ki wọn sé̩ igbagbọ wọn ninu Ọlọrun.

Kristi ati Beelsebubu

Ki ni ṣe ti a fi n ṣe inunibini si awọn Onigbagbọ? Idahun ibeere yii wa ninu ỌrọỌlọrun. Jesu wi pe: “Bi aiye ba korira nyin, ẹ mọ pe, o ti korira mi ṣaju nyin” (Ka Johannu 15:18-25).

Nitori ti Ọlọrun dáè̩ṣẹ lẹbi, o jẹ ikorira ninu ọkàn awọn eniyan, eyi si n mu ki wọn ki o maa dide pẹlu irunu èṣu lati tako Kristi ati Ẹmi Ọlọrun ati gbogbo awọn ti Ẹmi Ọlọrun ba n gbé inu wọn. Satani ni ẹni kin-in-ni ti o kọ dẹṣẹ si Ọlọrun; nigba ti Adamu ati Efa ṣaigbọràn si Ọlọrun, è̩ṣẹ ati iwa buburu wọ inu ọkàn è̩dá. Lati igba yii ni agbára Satani ati ogunlọgọ ninu eto ayé ti lodi si Ọlọrun ati Kristi ati ti awọn eniyan Rè̩. (Ka Orin Dafidi 2:1-4). Niwọn igba ti è̩ṣẹ ba wà ninu ọkàn ọmọ-ẹniyan; niwọn igba ti ejo nla nì, eṣu, wa ni itusilẹ ninu ayé; niwọn igba ti awọn alaiwa-bi-Ọlọrun bá kuna lati ṣe ojuṣe wọn si Kristi; bẹẹ ni inunibini si Ọlọrun, Ọmọ Rè̩, awọn eniyan Rè̩, ilana Rè̩ ati Ijọba Rè̩ yoo maa pọ si i. Otitọ ni: “Bi aiye ba korira nyin, --- o ti korira mi ṣaju nyin.”

Olukọ ati Oluwa

Ibeere ti o maa n saba jade nigba ti inunibini nla ba dide si awọn eniyan Ọlọrun ni pe, “Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi n jẹ ki awọn eniyan Rè̩ fi ara da ipalara nla, nigba ti o wà ni ipá Rè̩ lati da a duro bi O ba fé̩?” Alaye Bibeli lori ibeere yii kò já gaara. Pupọ ninu idi rè̩ ti Ọlọrun ṣe n fi àye silẹ fun inunibini yoo jẹ adiitu titi di ọjọ nla nì nigba ti Ọlọrun yoo fi aṣiiri ohun gbogbo hàn fun awọn eniyan Rè̩. Jesu wi pe: “O to funọmọ-ẹhin ki o dabi olukọ rè̩ ti ọmọ-ọdọ ki o dabi oluwa rè̩.” O yẹ ki a ni itẹlọrun pẹlu ọrọ yii. Ọlọrun kò mu ijiya ati inunibini nla ti o dide si Jesu kuro. Anfaani ti a ri gbà nipa iya ti Jesu jẹ lati ọwọ awọn eniyan buburu pọ ju eyi ti a ba ri gbà ti o ba ṣe pe kò fi àye silẹ fun iru inunibini bẹẹ. Bakan naa ni o ri nipa Onigbagbọ kọọkan niwọn iba tirẹ. Ọlọrun le mu inunibini kuro, lọnakọna ti o le gbà wa sọdọ awọn eniyan Rè̩ bi ẹnikan tabi lapapọ, ṣugbọn ni ọpọlọpọ igba Oun n fi àye silẹ fun inunibini lati wá. O le jẹ ohun ti o ṣoro fun ọmọ eniyan elero kukuru lati mọ ire ti o le ti inunibini wá nigba ti ipalara ba dé si ara ijọ Kristi, ati nigba ti idena ba dé si iwaasu Ihinrere, tabi ti ọtá ba tilẹ da duro. Ohunkohun ti o tilẹ le de, otitọ ni ỌrọỌlọrun, a le gbẹkẹle e ni isisiyii ati titi ayeraye, a si le fi ayé wa jì lai si ibẹru fun otitọ rè̩. “Ranti,” Jesu wi pe “ọrọ ti mo ti sọ fun nyin pe, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù Oluwa rè̩ lọ. Bi wọn ba ti ṣe inunibini si mi, wọn óṣe inunibini si nyin pẹlu.”

Kò yẹ ki igbagbọ wa ninu Ọlọrun ki o yè̩, nigba naa bi inunibini, ani titi de ikú ba tilẹ de si wa. “Bi wọn ba pe bāle ile ni Beelsebubu, melomelo ni awọn ara ile rè̩?” Bẹẹ ni a kò gbọdọ ka a si ohun ajeji pe nigba ti a n ṣe rere ki a maa fi wa sun bi ẹni ti n ṣe ibi. (Ka Matteu 12:24-48; Isaiah 5:20).

ỌrọẸri Wa

Bibeli wi pe ọrọẹri wa si awọn ti o fẹṣe inunibini si wa jẹ pataki lọpọlọpọ. Jesu gba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni imọran pe ki wọn ki o máṣe ronu ṣaaju ohun ti wọn o fi dahun nigba ti a ba fi wọn sùn ẹsun lai nidii. Ọlọrun yoo fi fun wọn, ohun ti wọn o wi, ki yoo ṣe awọn ni yoo sọrọ, ṣugbọn Ẹmi Ọlọrun ti o wà ninu wọn ni yoo maa sọọgbọn Ọlọrun jade. O wi bayii pe: “Nitoriti emi ó fun nyin li ẹnu ati ọgbọn, ti gbogbo awọn ọtá nyin ki yio si le sọrọ-òdi si, ti nwọn kì yio si le kò loju” (Luku 21:15).

Jesu sọ fun wọn pe, “Yio si pada di ẹrí fun nyin” (Luku 21:13). Paulu sọ nipa Jesu bayii pe, “ẹni, niwaju Pọntiu Pilatu, ti o jẹri ijẹwọ rere” (1 Timoteu 6:13). Lakotan, ninu Ifihan a ka bayii: “Nwọn si ṣẹgun rè̩ nitori è̩jẹỌdọ-Agutan na, ati nitori ọrọẹrí wọn, nwọn kò si fẹran ẹmi wọn ani titi de ikú” (Ifihan 12:11). O le ṣai ye wa ni kikun eredi rè̩ ti a ni lati fi ọrọẹri oore-ọfẹ igbala wa ninu Jesu Kristi hàn fun awọn eniyan buburu, sibẹ lai ṣe iyemeji o ṣe iyebiye, o si ṣe pataki lọpọlọpọ lati ṣe e, ki a si ṣe e gẹgẹ bi Jesu ti wi, pẹlu Ẹmi Ọlọrun ti n sọỌrọỌlọrun jade lati ẹnu wa wá.

A mọ pe Ọlọrun ki i ṣe ibi ki ire baa le ti inu rè̩ jade. Ki i ṣe pe ki wọn kan le jẹri fun awọn eniyan buburu ni Ọlọrun ṣe n fi àye silẹ fun inunibini lati dé si awọn eniyan Rè̩. Ohun ti o wà ninu rè̩ ju eyi lọ; ṣugbọn a kò le jiyan rẹ pe ẹrí Onigbagbọ ni akoko iṣoro bayii ṣe iyebiye lọpọlọpọ.

Bẹru Ọlọrun

Ki ni Onigbagbọ ni lati ṣe nigba ti a ba fi ikú dẹruba a nitori ijẹwọ igbagbọ rè̩ si Kristi? “Ẹ má fòiya awọn ẹniti ipa ara, ṣugbọn ti wọn ko le pa ọkàn: ṣugbọn ẹ kuku fòiya ẹniti o le pa ara ati ọkàn run li ọrun apadi.” Wọnyi i ba jẹọrọ omugọ boya bi o ba ṣe pe ẹlomiran yatọ si Jesu Kristi ni o sọ wọn, ṣugbọn wọn jẹọrọ idalare ati àṣẹ nigba ti O sọ wọn. Ọlọrun mọ rirì ohun gbogbo. Oun kò si fi ọwọ yẹpẹrẹ mu igbesi-ayéè̩dá, nitori Ọlọrun ni O paṣẹ pe, “Iwọ kò gbọdọ pania.” Sibẹ awọn eniyan ni lati ni ifẹ lati fi igbesi-ayé wọn jì fun otitọỌlọrun ati fun igbala ti Kristi rà dipò ki wọn gbọjè̩gé̩ nitori è̩ṣẹ ati eké.

Lati kú lọwọ awọn eniyan buburu le dabi ohun ti o buru jù lọ ti o le ṣẹlẹ si wa ni ilẹ alaaye, sibẹỌlọrun sọ fun wa pe ki a ma ṣe bè̩ru ikú ara tabi ohun ti eniyan le ṣe si wa. Ẹru nla ti o gbọdọ wà ninu ọkàn eniyan ní lati jé̩ si Ọlọrun ti O le, ti yoo si sọ ara ati ọkàn awọn ẹlẹṣẹ si ọrun apaadi. Ohun ti o buru jù ti eniyan le ṣe ni lati pani lara ati lati fi ni sinu ijiya fun igba diẹ. Ọlọrun le rán eniyan lọ sinu ijiya ayeraye, nibi ti irora ati ijiya kò lopin. S̩ugbọn bi Onigbagbọ ti mọ pe ohunkohun ti oun yoo fara dà fun Kristi yoo jẹ fun igba diẹ, o le gbaradi lati jà fun Ihinrere, ani titi de ikú. “Iyebiye ni ikú awọn ayanfẹ rè̩ li oju OLUWA;” nitori naa bi a ba jiya nihin nitori orukọ Jesu, Ọlọrun yoo wo ọgbé̩ ati ipalara wa sàn, ayeraye yoo si fi ibukun rè̩ fun gbogbo awọn ti i ṣe oloootọ titi de opin.

Arakunrin si Arakunrin

Ni oju wa ni ọjọ oni ỌrọỌlọrun n ṣẹ gẹgẹ bi Jesu ti sọọ: “Arakunrin yio si fi arakunrin rè̩ fun pipa, ati baba yio si fi ọmọ rè̩ fun pipa: awọn ọmọ yio si dide si awọn obi wọn, wọn o si mu ki a pa wọn.” Ni ilu China ati Korea, ati awọn ilu ti o wa labẹ akoso Russia, ohun ti n ṣẹlẹ ni ojoojumọ ni pe ki awọn eniyan idile kan maa dide si ara wọn nitori ti awọn kan ni igbagbọ ninu otitọ Kristi tabi ọrọ wọn lodi si ilana ẹkọ pe kò si Ọlọrun.

Ni ilu China ati Korea, ọpọlọpọ idile ni a ti pa bi ẹni pa ẹran nitori ti wọn jé̩ọré̩ pẹlu awọn Onigbagbọ, tabi nitori ti wọn ni Bibeli tabi iwe orin mimọ. Ogun ti Onigbagbọ n ba è̩ṣẹ, ayé, ẹran-ara, ati eṣu jà kò i ti pari. Awọn ikilọ ati imọran Jesu bá igba mu lonii, gẹgẹ bi wọn ti ri nigba ti O kọ sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩. “O to fun ọmọ-ẹhin ki o dabi olukọ rè̩ ati ọmọ-ọdọ ki o dabi oluwa rè̩.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ṣe ti inunibini fi n dide si awọn Onigbagbọ?

  2. 2 Ki ni ṣe ti wọn fi ṣe inunibini si Jesu?

  3. 3 Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi fi àye silẹ fun awọn eniyan buburu lati ṣe inunibini si Jesu?

  4. 4 NjẹỌlọrun le dí awọn eniyan lọwọ lati ṣe inunibini si awọn eniyan Rè̩?

  5. 5 Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi n fi àye silẹ pe ki a ṣe inunibini si awọn eniyan Rè̩?

  6. 6 Ki ni yẹ ki awọn Onigbagbọ wi nigba ti a ba n ṣe wọn ni ibi?

  7. 7 Ki ni yẹ ki Onigbagbọṣe nigba ti o ba wà ninu ipò lati fi ẹmi rè̩ tán an?

  8. 8 Ta ni o yẹ ki a bẹru jù lọ?

  9. 9 Ki ni ohun ti o buru jù lọ ti eniyan le ṣe si wa?

  10. 10 Ki ni Ọlọrun le ṣe si eniyan ti awọn eniyan kò lèṣe?

  11. 11 Ki ni o rò pe ó wà lọkan Jesu nigba ti O wi pe, “O to fun ọmọ-ẹhin ki o dabi olukọ rè̩”?