Iṣe Awọn Apọsteli 20:1-38

Lesson 347 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi kò kàẹmi mi si nkan rara bi ohun ti o ṣọwọn fun mi, ki emi ki o ba le fi ayọ pari ire-ije mi, ati iṣẹ-iranṣẹ ti mo ti gbà lọdọ Jesu Oluwa, lati mā ròhin ihinrere ore-ọfẹỌlọrun” (Iṣe Awọn Apọsteli 20:24).
Cross References

I Irin-ajo Paulu lati Efesu si Kọrinti ati Ipadabọ si Troasi

1 Paulu gba ilu Troasi lọ si Makedonia lẹyin irukerudo ti o ṣẹlẹ ni Efesu, Iṣe Awọn Apọsteli 20:1; 2 Kọrinti 2:12, 13

2 O wá si Kọrinti ni ilẹ awọn Hellene, Iṣe Awọn Apọsteli 20:2

3 O pada bọ si Troasi, Iṣe Awọn Apọsteli 20:3-6

II Irin-ajo Paulu lati Troasi si Miletu

1 Eutiku ṣubu lati oju ferese òke-kẹta ni akoko iwaasu Paulu, Iṣe Awọn Apọsteli 20:7-9

2 A dáẹmi rè̩ pada, Iṣe Awọn Apọsteli 20:10-12

3 Paulu rin irin ajo lọ si Miletu, Iṣe Awọn Apọsteli 20:13-17

III Ọrọ-iyanju Paulu si awọn Alagba ni Efesu

1 O rán awọn alagba leti nipa iwaasu ati ẹkọ irẹlẹ ti o ti fi kọ wọn, Iṣe Awọn Apọsteli 20:18-21;Titu 2:7, 8

2 Oun kò kábamọ lilọ kuro nibẹ, Iṣe Awọn Apọsteli 20:22-27; 2 Timoteu 4:7

3 A gba awọn alagba niyanju lati bọ agbo Kristi, a si kilọ fun wọn nipa awọn eniyan buburu, Iṣe Awọn Apọsteli 20:28-32; 2 Timoteu 3:1-5; 2 Peteru 2:1-3

4 Aini ojukokoro Paulu jé̩ apẹẹrẹ fun gbogbo eniyan, Iṣe Awọn Apọsteli 20:33-35; 1 Samuẹli 12:3

5 O fi adura pari iwaasu rè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 20:36-38

Notes
ALAYE

Ẹmi Itankalẹ Ihinrere Paulu

“Nipa agbara iṣẹ-àmi ati iṣẹ iyanu, nipa agbara Ẹmi Ọlọrun; tobḝ lati Jerusalẹmu ati yiká kiri ani titi fi de Illirikoni, mo ti wasu ihinrere Kristi ni kikun” (Romu 15:19). Bayii ni Paulu kọ iwe si Romu nigba ti o n rin irin-ajo kẹta ti itankalẹ Ihinrere yii. Illirikoni ti o ju bi ẹgbẹrun ibusọ ni ọgbọn-ọn ran lati Jerusalẹmu wà ni idabu okun lati Itali wá. Nigba ti o ti bẹ gbogbo ilu ti o wà ni agbegbe Jerusalẹmu ati Itali wò, ifẹọkan Paulu ni lati kọja lati Romu lọ si Spania ati awọn ilu ti o jinna siwaju. “S̩ugbọn nisisiyi bi emi kò ti li àye mọ li ẹkùn wọnyi, bi emi si ti fẹ gidigidi lati ọdún melo wọnyi lati tọ nyin wá, nigbakugba ti mo ba nlọ si Spania, ng ó tọ nyin wá” (Romu 15:23, 24).

Ninu awọn ọrọ diẹ wọnyii a ri ogunlọgọ ilẹ ti Apọsteli naa ti gba, sibẹọkan rè̩ n poungbẹ lati gba awọn ilẹ titun miiran fun Ihinrere. Ẹmi itankalẹ-ihinrere tootọ ni eyi ti kò mọ idaduro. Wahala oju ọna kò jẹnnkan bi oun ba sa ti le waasu Kristi ki o si funrugbin Ihinrere si ilẹ titun ọlọra.

Irin-ajo lati Efesu

Lẹyin irukerudo nla ti Demetriu dá silẹ, Paulu fi Efesu silẹ o si mu ọna ajo rè̩ pọn lati Makedonia lọ si Kọrinti ni Griki; bi ẹni pe o n pada sẹyin, o bẹrẹ si pada si Jerusalẹmu nibi ti o ti lero lati wọọkọ lọ si Romu. Nigba ti o kuro ni Efesu, ọkan ninu awọn ilu ti o gbé duro ni Troasi. O wi bayii pe: “Nigbati mo de Troasi lati wāsu ihinrere Kristi, ti ilẹkun si ṣi silẹ fun mi lati ọdọ Oluwa wá, Emi kò ni alafia li ọkàn mi, nitoriti emi ko ri Titu arakọnrin mi: ṣugbọn nigbati mo ti dagbere fun wọn, mo rekọja lọ si Makedonia” (2 Kọrinti 2:12, 13). A gbagbọ pe ibi keji ti o tun ti duro ni Filippi nibi ti o ti kọ iwe keji yii si awọn ara Kọrinti ninu eyi ti o wi bayii pe: “Nigbati awa tilẹ de Makedonia, ara wa kò balẹ, ṣugbọn a nwahalà wa niha gbogbo; ija mbẹ lode, ẹru mbẹ ninu. S̩ugbọn ẹniti ntù awon onirẹlẹ ninu, ani Ọlọrun, o tù wa ninu nipa didé Titu” (2 Kọrinti 7:5, 6).

Iṣoro

Luku, ẹni ti o kọ Iwe Iṣe Awọn Apọsteli, kò mẹnu ba pupọ ninu awọn ohun ti o ṣẹlẹ, ṣugbọn ni ibẹrẹ iṣẹ-iranṣẹ Paulu, Ọlọrun ti wi pe, “Emi o fi gbogbo iya ti kò le ṣaijẹ nitori orukọ mi han a” (Iṣe Awọn Apọsteli 9:16). Igbesi-ayé Paulu Apọsteli ki i ṣe ọrọ gbẹfẹ gẹgẹ bi o ti n fi ẹsẹ rin tabi wọọkọ oju-omi lati ibikan de ekeji. Iwe ti o kọ si awọn ara Korinti fi diẹ ninu awọn iṣoro ti o ba pade han ni. “Ará, awa kò sá fẹ ki ẹyin ki o wà li aimọ nipa wahalà wa, ti o dé bá wa ni Asia, niti pe a pọn wa loju gidigidi rekọja agbara wa, tobẹẹ ti ireti kò tilẹ si fun ẹmi wa mọ: S̩ugbọn awa ni idahùn ikú ninu ara wa, ki awa ki o máṣe gbẹkẹ le ara wa, bikoṣe Ọlọrun ti n ji okú dide: Ẹni ti o ti gbà wa kuro ninu ikú ti o tobi tobẹẹ, ti o si n gbà wa” (2 Kọrinti 1:8-10). Bi o tilẹ jẹ pe ikú doju kọ Paulu sibẹ o le wi pe, “Ipọnju wa ti o fẹrẹ, ti iṣe fun ìṣé̩ju kan, o nṣiṣẹ ogo ainipẹkun ti o pọ rekọja fun wa” (2 Kọrinti 4:17). “A npọn wa loju niha gbogbo, ṣugbọn ara kò ni wa; a ndāmu wa, ṣugbọn a kò sọ ireti nù. A nṣe inunibini si wa, ṣugbọn a kò kọ wa silẹ, a nrè̩ wa silẹ, ṣugbọn a kò si pa wa run; Nigbagbogbo awa nru ikú Jesu Oluwa kiri li ara wa, ki a le fi iye Jesu hàn pẹlu li ara wa” (2 Kọrinti 4:8-10). Yoo ràn wá lọwọ lati gbagbe awọn idanwo ati aroye wa bi a ba mọ pe awọn iyọnu wa wọnyii kò to nnkan bi a ba fi wọn wé eyi ti o dé bá aṣiwaju wa ninu Ihinrere yii.

Ronu awọn nnkan wọnni ti o ti la kọja, bi o ti n fi iṣẹ rẹṣe akawe pẹlu ti awọn eke apọsteli: “Niti lālā lọpọlọpọ, niti paṣan mo rekọja, niti tubu nigbakugba, niti ikú nigbapupọ. Nigba marun ni mo gba paṣan ogoji din kan lọwọ awọn Ju. Nigba mẹta ni a fi ọgọ lù mi, ẹkanṣoṣo li a sọ mi li okuta, ḝmẹta li ọkọ rì mi, ọsán kan ati oru kan ni mo wa ninu ìbú. Ni irin àjò nigbakugba, ninu ewu omi, ninu ewu awọn ọlọṣa, ninu ewu awọn ara ilu mi, ninu ewu awọn keferi, ninu ewu ni ilu, ninu ewu li aginjù, ninu ewu loju okun, ninu ewu larin awọn eke arakunrin; Ninu lālā ati irora, ninu iṣọra nigbakugba, ninu ebi ati orùngbẹ, ninu àwẹ nigbakugba, ninu otutù ati ihoho” (2 Kọrinti 11:23-27). Dajudaju ki i ṣe ohun miiran bi ko ṣe imisi Ọlọrun ni o le mu ki eniyan tè̩ siwaju ninu igbesi-ayé ti o kún fún ewu ati wahala bẹẹ.

Kọrinti

Lẹyin “ọrọ iyanju pupọ” ni gbogbo ẹkùn Makedonia, Paulu wá si Griki, nibi ti o gbe ni oṣu mẹta pẹlu awọn ara Kọrinti ti o ti kọwe si. Bi o tilẹ jẹ pe Paulu ti jiya ohun gbogbo wọnni fun Kristi, sibẹ oun kò dakẹ lati maa waasu Ihinrere nigba ti o tilẹ jẹ pe o ti n sunmọẹni ọgọta ọdun, nitori nihin ni o kọ iwe rè̩ si awọn ara Romu ti o sọ pẹlu igbona ọkan pe: “Tobḝ bi o ti wà ni ipá mi, mo mura tan lati wasu ihinrere fun ẹnyin ara Romu pẹlu” (Romu 1:15).

Ọjọ Ikinni Ọsẹ

Dipo ki Paulu wọọkọ lati Kọrinti gẹgẹ bi eto ti o ṣe tẹlẹ ri, o rán awọn ọrẹ rẹ lọ si Troasi pẹlu ọkọ nigba ti oun tikara rẹ fi ẹsẹ rin ibi ti o tó irinwo mile tabi ju bẹẹ lọ si Filippi, nibẹ ni o ti wọọkọ lọ si Troasi. Nihin, ni Ọjọ Oluwa, ti i ṣe ọjọ ikinni ọsẹ, awọn ọmọ-ẹyin pejọ. Ọjọ yii jé̩ọjọ ti awọn ọmọ-ẹyin maa n pamọ lẹyin ti Oluwa ti jinde, nitori Paulu paṣẹ fun awọn ara Kọrinti pe ki wọn mu ọrẹ wọn wá si ile Ọlọrun ni ọjọ naa. Jesu pẹlu, lẹyin ti O ti jinde ni owurọỌjọ Oluwa, O fi ara han awọn Apọsteli Rè̩ ni ọjọ yii ati ni Ọjọ Oluwa ti o tẹle e; nipa bayii Oluwa tikara Rè̩ fi aṣẹ si pipa ọjọ ikinni ọsẹ mọ dipo Ọjọ Isinmi awọn Ju. Awọn ọmọ-ẹyin ni Troasi pẹlu pa ilana Ase Ounjẹ Alẹ Oluwa mọ gẹgẹ bi Oluwa wa ti pa a laṣẹ.

Awọn ti Ebi n Pa

Agbara nla Ọlọrun fi ara hàn ni Troasi nipa jiji okú dide. Lai si aniani ebi ỌrọỌlọrun ni lati maa pa awọn eniyan wọnyii, nitori pe Paulu waasu titi di ọganjọ, kò si da ẹnu duro ninu iwaasu rè̩ titi di afẹmọjumọ bi ko ṣe igba ti o mu ẹmi ọdọmọkunrin ni pada bọ. Lai fi aye silẹ fun isinmi, Paulu fi ẹsè̩ rin ogun mile lọ si Assosi. Boya Paulu ni itura gẹgẹ bi Jesu ti ni in nidi kanga Jakọbu nibi ti O ti bá obinrin ara Samaria ti ebi otitọ n pa pade.

Ọrọ-iyanju Ikẹyin Paulu si awọn Alagba ni Efesu

Iduro Paulu ni Efesu kò pẹ to bẹẹ, nitori ifẹọkan rè̩ ni lati wà ni Jerusalẹmu ni akoko ase Pẹntikọsti, ṣugbọn o ranṣẹ si awọn alagba, o si sọọrọ iyanju ikẹyin rè̩ fun wọn pe wọn ki yoo ri oju oun mọ. Ni fifi ara rè̩ṣe apẹẹrẹ, Paulu gbà wọn niyanju lati jé̩ onirẹlẹ ati oloootọ. O rán wọn leti péẸmi Mimọ ni o fi wọn ṣe alabojutó, wọn si ni lati bọ ijọỌlọrun nipa sisọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun wọn. Ẹkọ Kristi ṣe pataki pupọ fun Apọsteli awọn Keferi yii, nitori o mọ pe akoko yoo dé nigba ti awọn eniyan ki yoo le gba ẹkọ ti o ye kooro mọ.

Paulu kò fẹ ki awọn ara Efesu yii fi ironupiwada silẹ. Boya oun ro ewu ti yoo dé bá awọn eniyan wọnyi nigba ti a ba n waasu pe ki awọn eniyan gba Kristi lai ni irobinujẹẹni iwa-bi-Ọlọrun fun è̩ṣẹ wọn ati ironupiwada tootọ ki wọn si ni iyipada ọkàn. Oun kò fẹ ki awọn eniyan wọnyi ni ẹsin ti kò ni gbongbo lai ni Ẹjẹ Etutu ninu gẹgẹ bi o ti ri fun ọpọ eniyan lode oni; nitori o rán wọn leti pe Ẹjẹ Jesu ni a fi ra IjọỌlọrun. O tun wi pe ỌrọỌlọrun le gbé wọn duro ki o si fun wọn ni ini laaarin gbogbo awọn ti a sọ di mimọ.

O ni lati di mimọ fun Paulu pe awọn ikookò buburu yoo sọẹsìn di ọja tita, nitori naa o kilọ fun awọn alagba naa nipa ojukokoro. Jẹ ki ọwọ Paulu ti o ṣiṣẹ fun aini rẹ jẹ ibawi fun awọn wọnni ti n bẹbẹ fun fadaka ati wura ti wọn si n waasu Ihinrere fun ere ijẹkujẹ.

Lọsan ati loru fun ọdun mẹta, ikilọ ati omije Paulu ti fi ifẹ ati itara rẹ hàn fun awọn ara Efesu. Ifi tọkantọkan waasu Ọrọ naa han gbangba ninu ọrọ rẹ ti o wi bayii pe: “Emi kò ti fà sẹhin lati sọ ohunkohun ti o ṣanfani fun nyin.” Ẹmi Mimọ fi hàn péọna ti o wa niwaju Paulu yoo mu ide ati ipọnju wa, ṣugbọn ọkàn rè̩ ti o duro ṣinṣin le dahun pe “Emi kò kàẹmi mi si nkan rara bi ohun ti o ṣọwọn fun mi, ki emi ki o ba le fi ayọ pari ire-ije mi, ati iṣẹ-iranṣẹ ti mo ti gbà lọdọ Jesu Oluwa, lati maa rohin ihinrere ore-ọfẹỌlọrun.” Njẹ eyi ni ipinnu rẹ -- lati fori ti i titi de opin?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Gbiyanju lati ṣe awaari nipa awọn ọkunrin ti a darukọ wọn ninu Iṣe Awọn Apọsteli 20:4.

  2. 2 Sọ bi Paulu ṣe rin lati ilu dé ilu ninu ẹkọ wa oni.

  3. 3 Fi hàn lati inu Bibeli ifẹọkàn Paulu ati agbara rè̩.

  4. 4 Ibi meloo ni a ti ri i kà pe a ji okú dide ninu Bibeli?

  5. 5 Sọ pupọ ninu idi rè̩ ti a fi n jọsin ni Ọjọ Ikinni ọsẹ dipo Ọjọ Isinmi awọn Ju.

  6. 6 Ta ni yan awọn alàgbà Efesu ni alakoso?

  7. 7 Bawo ni Paulu ṣe duro pé̩ tó ni Efesu?

  8. 8 Ọna wo ni Paulu gbà fi hàn pe oun kò ni ojukokoro?

  9. 9 Awọn koko ẹkọỌrọỌlọrun meloo ni a fi ẹnu ba ninu ori ẹkọ yii?

  10. 10 Sọ diẹ ninu awọn iya ti Paulu jẹ nitori Ihinrere.