Isaiah 1:1-31

Lesson 348 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Jesu si wi fun u pe, Kò si ẹni, ti o fi ọwọ rè̩ le ohunelo itulẹ, ti o si wòẹhin, ti o yẹ fun ijọba Ọlọrun” (Luku 9:62).
Cross References

I Iran Isaiah

1 Isaiah ri iran kan nipa Juda ati Jerusalẹmu ni ọjọ Ussiah, Jotamu, Ahasi, ati Hẹsekiah, awọn ọba Juda, Isaiah 1:1

2 Ọlọrun fi itara bá Israẹli wi: bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹranko ti kò le fọhun mọ oluwa wọn, sibẹsibẹ Israẹli kò mọ Oluwa ati Ẹlẹda wọn, Isaiah 1:2-4;Jeremiah 8:7

3 A beere lọwọ Israẹli pé ki ni ṣe ti wọn fé̩ ki a lù wọn si i, nigba ti a ti lù wọn lati ori déẹsẹ, Isaiah 1:5-9;Jeremiah 2:30; 5:3

4 Ọlọrun kọ lati gba ọpọẹbọ Israẹli ati iṣẹ-isin wọn ti o mu abùkù bá isin Ọlọrun tootọ, Isaiah 1:10-15;Malaki 1:6-14; Matteu 15:7-9

5 Ọlọrun paṣẹ fun Israẹli lati dẹkun ati ṣe buburu ki wọn si kọ lati ṣe rere, Isaiah 1:16, 17;Hosea 6:6; Matteu 9;13; Jeremiah 4:14; Jakọbu 4:8-10

6 Ọlọrun fẹ bá Israẹli sọ asọyé nipa è̩ṣẹ wọn, Isaiah 1:18-20;1 Samuẹli 12:7; Mika 6:2, 3

7 Ọlọrun kẹdun lori Jerusalẹmu nitori iwa ibọriṣa wọn ati nitori iwa itijú niti yiyi pada kuro lẹyin Rè̩, Isaiah 1:21-23; Jeremiah 2:19-27; Esekiẹli 22:24-29

8 Ọlọrun ṣeleri lati rán iná iwẹnumọ si ori Israẹli titi a o fi ra Sioni pada pẹlu idajọ ati awọn ti o yi pada pẹlu ododo, Isaiah 1:24-31; Malaki 3:3-6; Sẹkariah 13:9; Romu 11:24-27; 9:26, 27

Notes
ALAYE

Awọn IranṣẹỌlọrun

Akoko ti Isaiah bẹrẹ si sọtẹlẹ jẹ akoko ti o dabi ẹni pe gbogbo orilẹ-éde Israẹli fẹ lọ kuro ninu ẹsin otitọ. Awọn olugbe Jerusalẹmu ati Juda ni iṣẹ ti a rán Isaiah doju kọ gan an. Awọn ẹya Israẹli mẹwaa iyoku ti lọ kuro ninu sisin Oluwa to bẹẹ gẹẹ ti idajọỌlọrun n rọ dè̩dè̩ lori wọn. Ọlọrun mú idajọ naa ṣẹ nipa rirán awọn Assiria, awọn ikà ati onroro eniyan lati pa ilẹ wọn run ati lati kó awọn olugbe rè̩ lọ ni igbekun. Juda ati Bẹnjamini ṣi n sin Ọlọrun ṣugbọn isin afaraṣe ni, nitori níọna isin ẹmi ati otitọ awọn paapaa ti bẹrẹ si di ẹni irira gẹgẹ bi awọn arakunrin wọn.

Bi o tilẹ jẹ pe Israẹli ti pẹyinda kuro lọdọỌlọrun, sibẹỌlọrun gbéọpọlọpọ wolii dide ti n sọ otitọỌlọrun fun awọn eniyan lai bẹru. Ninu awọn eniyan ti Ọlọrun gbé dide wọnyi ni Isaiah wà a si maa n saba pe e ni “ajihinrere karun un” nitori asọtẹlẹ ati ẹkọ rè̩ nipa Jesu Kristi ti ko ṣe fi ṣakawe ti ẹnikẹni. Isaiah waasu otitọỌlọrun lai si igbọjẹgẹ ni akoko ọba mẹrin tọtọ. Titako è̩ṣẹ ati iwa buburu lai bẹru mu ki o sọẹmi rè̩ nù ni akoko ijọba Manasse ọba buburu nì. Gẹgẹ bi itan atọwọdọwọ, a sọ fun ni pe Isaiah ni a n tọka si ninu ori kọkanla iwe Heberu bi ẹnikan ti a fi ayun rẹ si meji.

Iṣẹ ti Ọlọrun Rán

Iṣẹ ti Ọlọrun rán Isaiah si Israẹli, gẹgẹ bi a ti ka a ninu ori kin-in-ni iwe Isaiah, wá nipa iran eyi ti o fi irú ipò ti ọkàn awọn eniyan naa wà niwaju Ọlọrun hàn án. Iran yii kó ijọba ọba mẹrin tọtọ já. Iran naa jé̩ iṣẹ ti Isaiah ni lati waasu rè̩ ni akoko ijọba awọn ọba wọnyii, lati kede fun awọn eniyan bi ipòè̩ṣẹ wọn ti ri niwaju Ọlọrun.

Ọlọrun kò ni inudidun si ikúẹlẹṣẹ; sibẹ awọn eniyan fẹ taku sinu iwa è̩ṣẹ lai ka gbogbo ikilọ ti Ọlọrun rán si wọn si. Israẹli kòṣalai ni oye kikun pe ỌrọỌlọrun kò yi pada ati pe kò si ẹni ti o le re e kọja lai jiya ki wọn tó yà kuro ninu Isin Ọlọrun lati lọ maa bọriṣa. A le pe awọn wolii ti Ọlọrun rán si Israẹli ni ẹri ọkàn fun Israẹli, wọn si pohun réréè̩ṣẹ Israẹli niwaju awọn eniyan. Awọn wolii Ọlọrun sọ inu Ọlọrun. Ẹni ti o bá gbọ ti wọn, gbọ ti Ọlọrun; ẹni ti o ba si kọ wọn, kọỌlọrun.

Paulu sọ fun awọn eniyan mimọ ti o wa ni Tẹssalonika nipa ihin ti o mu wa: “Nitorina ẹnikẹni ti o bá kọ, ko kọ enia, bikoṣe Ọlọrun” (1 Tẹssalonika 4:8). Bakan naa pẹlu ni Jesu sọ fun awọn Apọsteli Rẹ: “Ẹniti o ba gbọ ti nyin, o gbọ ti emi: ẹniti o ba si kọ nyin, o kọ mi; ẹniti o ba si kọ mi, o kọẹniti o rán mi” (Luku 10:16). Bi o tilẹ jẹ pe awọn wolii naa wá pẹlu àṣẹ ati agbára Ẹmi Ọlọrun, sibẹ awọn eniyan ki i saba fi inu rere gbà wọn; ati nigba pupọ Israẹli ki i le fara daa lati maa ri wọn. Sibẹsibẹ wọn wá, a rán wọn wá lati ọdọỌlọrun, wọn si kilọ fun Israẹli nipa ijiya ti yoo tẹle è̩ṣẹ wọn lai pẹ.

OtitọỌlọrun

Apejuwe ti o tẹ Isaiah lọwọ nipa è̩ṣẹ Israẹli jé̩ọkan ninu aworan è̩ṣẹ kikun ti o si hàn gbangba ti Bibeli fi fun wa. Ọlọrun kò fi oju tinrin è̩ṣẹ; bẹẹni Oun paapaa kò lọra lati sọ fun awọn eniyan irú ipò ti ọkàn wọn wà niwaju Rè̩. Awọn eniyan ko le, wọn ki yoo si yi pada kuro ninu è̩ṣẹ wọn titi di igba ti wọn ba mọ bi è̩ṣẹ ti wuwo ti o si buru jai to. Nigba ti awọn eniyan ba mọè̩bi è̩ṣẹ wọn, nigba naa, ani nigba naa gan an ni ireti wà fun wọn lati yi pada si Ọlọrun fun ironupiwada.

Jesu wi pe, “Ẹó si mọ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira” (Johannu 8:32). Apakan otitọỌlọrun ni lati fi idalẹbi si ọkàn lori è̩ṣẹẹni kọọkan. Eredi rẹ ni eyi ti Ọlọrun fi ṣe iṣipaya è̩ṣẹ Israẹli. Niwọn bi Isaiah ti mọ lẹẹkan ipo ti ọkàn awọn eniyan wọnyii wà, yoo le tako è̩ṣẹ wọn lai dáẹnikẹni si, ki wọn ki o le mọ pe è̩ṣẹ wọn di mimọ fún Ọlọrun, ki wọn si lè ronu piwada.

Oju rere ati aanu Ọlọrun ni o n mu ki è̩ṣẹọkàn awọn eniyan di mimọ fun wọn ki wọn ki o ba le mọ aini wọn nipa igbala. Awọn eniyan kì i fẹ gbọ nipa ibinu Ọlọrun si è̩ṣẹ, ọrun apaadi, tabi Ọjọ Idajọ, nigba ti a o ṣe idajọ olukuluku ẹni ti kò ba ronu piwada iwa buburu ti o ti hù; tabi ki wọn gbọ pe ikú ni ère è̩ṣẹ, ṣugbọn bi kòṣe pe wọn ba mọ otitọ ki wọn si gba a gbọ wọn kò le ri idande kuro ninu è̩ṣẹ.

Ifẹ ti Ọlọrun ni si ọkàn eniyan kò fun eniyan ni anfaani lati maa mookun ninu è̩ṣẹ. Nida keji è̩wẹ, nitori pe Ọlọrun fẹran eniyan ni O ṣe pese igbala nipa Ẹjẹ Kristi lori agbelebu ki wọn ki o ba le bọ kuro ninu ijiya è̩ṣẹ ti wọn ti dá.

Ohun kan naa a ni o hàn gan an ninu iran Isaiah ati iwaasu rè̩. A sọ fun Israẹli gbangba ati ni kikun bi è̩ṣẹ rè̩ ti buru ati bi o ti pọ tó, Ọlọrun si n beere lọwọ wọn eredi rè̩ ti wọn fi fé̩ lati jingiri sinu è̩ṣẹ.

Yiyan Ikú

Ọlọrun n beere leralera lọwọ eniyan eredi rẹ ti yoo fi maa fara da irora è̩ṣẹ nigba ti kòṣanfaani lati ṣe bẹẹ. Isaiah ti ké si awọn eniyan pe, “Eeṣe ti a o fi lù yin si i mọ?” Ọlọrun fi Israẹli wéẹni ti a ti lù lọpọlọpọ, to bẹẹ ti atẹlẹsẹ rẹ titi de ori fi jẹ kiki ipalara, ọgbé̩ ati oóju. Itumọ eyi ni péè̩ṣẹ wọn ni o mú gbogbo wahala yii dé ba wọn, yoo jẹ iwa wère lati mu ki wahala yii pọ si i nipa didáè̩ṣẹ si Ọlọrun.

È̩ṣẹ a maa fani mọra fun saa kan, ṣugbọn kò si bi o ti le fani mọra tó ati bi adun rẹ ti le pọ to ti a ki yoo fi mọ irora ẹri ọkàn ti a ti ṣá ni ọgbé̩. Bẹẹ ni a kò le tilẹkun mọ ohùn Ọlọrun ti n ké mọẹṣẹ ninu ọkàn ọmọ eniyan. È̩ṣẹ a maa mú irora wá, ọna olurekọja ṣoro. Bayii ni Ọrọ Oluwa wi: “Awọn eniyan buburu dabi okun riru, nigbati kò le simi, eyiti omi rè̩ nsọẹrẹ ati ẽri soke. Alafia kò si fun awọn enia buburu, ni Ọlọrun mi wi” (Isaiah 57:20, 21). O jẹ ohun iyanu pe awọn eniyan le maa pafọ ninu è̩ṣẹ pẹlu gbogbo irora ti è̩ṣẹ n mu wá, to bẹẹ ti ijiya ti orikunkun wọn n mu bá wọn ya Ọlọrun lẹnu ti o fi beere pe, “Eeṣe ti a o fi lù yin si i mọ?”

Aanu, Ki i si i S̩e Ẹbọ

Ni igba kan Jesu wi pe: “Ẹ lọẹ si kọ bi ā ti mọ eyi si, Anu li emi nfẹ, ki iṣe ẹbọ” (Matteu 9:13; Hosea 6:6). Ọrọ yii kan naa ni Isaiah n bá Israẹli sọ. Gbogbo ilana eto isin wọn kò jamọ nnkan fun Ọlọrun bi o tilẹ jẹ pe Oun paapaa ni O fi ilana naa lelẹ, nitori pe wọn ti gbagbe, wọn si ti kọ otitọ wọnni silẹ ti awọn eto isin naa n ṣe apejuwe; itumọ eyi ni pe, Ọlọrun ki yoo fara da è̩ṣẹ, bi a o ba sin In a ni lati sin In ni ẹmi ati ni otitọ. Aiṣegbè ati ododo ki i ṣe ọgbọn ẹsin lasan, bi kòṣe eso ti o n ti inu ọkàn awọn ti o fẹ Oluwa jade. Ni ibi gbogbo ninu ỌrọỌlọrun – ninu Majẹmu Laelae ati Titun, ninu ẹkọ awọn wolii ati ti Jesu – a n tẹnu mọọn leralera pe kò le si isin Ọlọrun tootọ a fi bi a ba gba pe iwa aileeri ati mimọ kó ipa pataki ninu Ihinrere.

“Kọ lati ṣe rere; wá idajọ, ran awọn ẹniti anilara lọwọ, ṣe idajọ alainibaba, gbàẹjọ opó wi.” Iṣẹ ti Isaiah jé̩ fun Israẹli ni eyi, ọrọ yii kan naa ni a mú wá lati ipilẹṣẹ, bakan naa si ni lonii: “Dawọ duro lati ṣe buburu.” Ẹṣẹ Israẹli ki i ṣe pe wọn ṣáọrọẹsin ti, ṣugbọn gbogbo igboke gbodo wọn nipa isin jé̩ asán ati agabagebe niwaju Ọlọrun. Ilẹ wọn kún fun iwa buburu ati aiṣododo to bẹẹ ti a fi awọn eniyan ibẹ wé awọn olugbe Sodomu ati Gomorra, ori awọn ẹni ti Ọlọrun rọ ojo iná lé.

Sisọ Asọyé Pọ

A sọọrọ akiyesi nla kan ninu ori ẹkọ wa: “Oluwa wi pe, wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ: bi è̩ṣẹ nyin ba ri bi òdodó, nwọn o si fun bi òjo-didi; bi nwọn pọn bi àlāri, nwọn o dabi irun-aguntan.” Dajudaju ifihan iwa Ọlọrun ni pe Oun ni ifẹ lati bá eniyan sọ asọyé pọ lori iwa wère è̩ṣẹ rè̩. Bi eniyan yoo ba jẹ fi eti silẹ si Ọlọrun nigba ti O ba n ba a sọ asọyé pọ, lai pẹ iwa wère rè̩ yoo di mimọ fún un. Ọlọrun le fi è̩ṣẹ rè̩ ji i, bi wọn tilẹ ri bi òdodó, Ọlọrun yoo fọ wọn fún bi ojo didi. “Bi ẹnyin ba fé̩ ti ẹ si gbọran, ẹnyin o jẹ ire ilẹ na.”

Bi wọn ba ṣaigbọran n kọ? “Bi ẹnyin ba kọ, ti ẹ si ṣọtẹ, a o fi idà run nyin: nitori ẹnu Oluwa li o ti wi i.” Israẹli kọ lati feti si asọyéỌlọrun pẹlu wọn. Wọn tẹra mọè̩ṣẹ wọn titi ibinu Ọlọrun fi wá sori wọn ni kikun lẹyin ikú Kristi.

Awọn è̩sẹ ti o kẹyin ninu ẹkọ wa sọ fun wa pe nipa aanu Ọlọrun awọn eniyan diẹ yoo ṣẹku, ni gbogbo igba, titi a o fi mu ògo Sioni pada si bi ti iṣaaju, ati pe Jesu Kristi ti wọn ti kọ lẹẹkan, ti wọn si ti pa yoo jé̩ Oluwa ati Ọba wọn.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Bawo ni Isaiah ṣe gba iṣẹ rẹ pe oun ni yoo waasu fun Israẹli?

  2. 2 Ọdun meloo ni Isaiah fi ṣe iwaasu?

  3. 3 Bawo ni Isaiah ṣe kú ni ikẹyin?

  4. 4 Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi ipo Israẹli han yékeyéke lọna bayii?

  5. 5 Ki ni ṣe ti ẹlẹṣẹ fi ni lati mọ dajudaju pe ẹlẹṣẹ ni oun ki o to le ronu piwada è̩ṣẹ rè̩?

  6. 6 Bawo ni awọn ẹlẹṣẹṣe n ni idaniloju pe ẹlẹṣẹ ni wọn?

  7. 7 Ki ni ṣe ti inúỌlọrun kò fi dun si ijọsin Israẹli?

  8. 8 Bawo ni a ni lati ṣe sin Ọlọrun?

  9. 9 Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi fẹ bá Israẹli sọ asọyé pọ?