Isaiah 5:1-30

Lesson 349 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nwọn o si wọ inu ihò apata lọ, ati inu ihò ilẹ, nitori ibẹru OLUWA, ati nitori ogo ọlanla rè̩, nigba ti o ba dide lati mì ilẹ aiye kijikiji” (Isaiah 2:19).
Cross References

I Ọgba Ajara Oluwa

1 A gbin ọgba-ajara Oluwa si ori oke ẹlẹtù-loju, a si fi ifẹ ati ikẹ tọju rè̩, Isaiah 5:1, 2; Orin Dafidi 80:8, 9, 15

2 Oluwa wò pé ki o so eso, ṣugbọn eso kikan ni o so, Isaiah 5:3, 4; Jeremiah 2:21

3 Oluwa paṣẹ pe ki a fi ọgba naa ṣòfo, Isaiah 5:5, 6; Orin Dafidi 80:12, 13

4 Ọgba-ajara Oluwa yii ni ile Israẹli, Juda si ni igi-gbigbìn ti o wu ni, Isaiah 5:7

II Isọdahoro awọn Eniyan Buburu

1 A sọ pe ègbé ati òṣi yoo jẹ ti awọn olojukokoro, Isaiah 5:8-10; Ẹksodu 20:17; Habakkuku 2:9; Luku 12:15; Kolosse 3:5

2 Iwà imutipara wá si idajọ niwaju Ọlọrun, Isaiah 5:11-13, 22, 23; Lefitiku 10:9; Owe 20:1; 23:29-31; Luku 21:34; Romu 13:13

3 Ọrun-apaadi ti la ẹnu rè̩ lai ni iwọn lati gba awọn eniyan buburu, Isaiah 5:14

4 Awọn oniṣẹ buburu ati agberaga ni a mu wá sinu idajọ, Isaiah 5:15, 17-21; Owe 16:18;21:4; Luku 1:52; 1 Johannu 2:16; Malaki 4:1

III IdajọỌlọrun

1 Oluwa awọn ọmọ-ogun ni a o gbega ni idajọ, Isaiah 5:16; Ifihan 20:11-15

2 Ọlọrun ni ẹtọ gidigidi lati dá awọn Ọmọ Israẹli lẹjọ, Isaiah 5:24, 25

3 Ọlọrun lo awọn orilẹ-ede ti o wà lọna jijin réré gẹgẹ bi ohun-elo lati fi ṣe idajọ, Isaiah 5:26-30

Notes
ALAYE

“Emi pèọrun ati ilẹ jẹri ti nyin li oni pe, emi fi iye ati ikú, ibukún ati egún siwaju rẹ: nitorina yàn iyè, ki iwọ ki o le yè, iwọ ati irúọmọ rẹ” (Deuteronomi 30:19). Awọn Ọmọ Israẹli ni Oluwa rán iṣẹ yii si; ṣugbọn nitori pe Jesu jẹỌdọ-Agutan “ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye” wá, gbogbo eniyan ti o wà ninu ayé ni a rán iṣẹ naa si. Ọna si Ọrun ṣi silẹ fun gbogbo eniyan. Gẹgẹ bi o ti jẹ ohun aigbọdọ ma ṣe fun olukuluku Ọmọ Israẹli lati yàn lati sin Ọlọrun tabi lati má sin In, bakan naa ni olukuluku eniyan ni lati pinnu fun ara rè̩ lati yan ọna iye ainipẹkun tabi ikú ainipẹkun. Ẹnikẹni ti o ba fẹ lati gbé ni ayeraye pẹlu Ọlọrun ni Ọrun ni lati wá igbala Ọlọrun ki o si maa gbé gẹgẹ bi ỌrọỌlọrun nigba ti o wà ninu ayé. Nitori naa ipa ti ẹni kọọkan bá yàn ni yoo sọ ipin rè̩ ni ayeraye.

Ọgba Ajara Oluwa

“Nisisiyi, emi o kọ orin si olufẹọwọn mi, orin olùfẹ mi ọwọn niti ọgba àjara rè̩. Olufẹọwọn mi ni ọgba àjara lori okèẹlẹtù loju” (Isaiah 5:1). Ori okèẹlẹtù loju yii naa ki i ṣe ibomiran bi kòṣe Kenaani, Ilẹ Ileri ti a fi fun awọn ọmọ Israẹli ẹrú ti Ọlọrun da silẹ kuro ninu ajaga lile buburu ti awọn ara Egipti. Awọn okuta ilẹ naa, ti i ṣe awọn ẹya keferi abọriṣa ni ilẹ Kenaani ki awọn Ọmọ Israẹli to de, ni a lé kuro nipa agbára Ọlọrun nigba ti awọn Ọmọ Israẹli gba ini wọn. Bi keferi kan ba kù silẹ si ilẹ naa ti Ọlọrun fi fun Israẹli, o wà nibẹ nitori pe awọn Ọmọ Israẹli kuna lati ṣe ati lati pa gbogbo aṣẹỌlọrun mọ.

Oluwa fi Otitọ sagbara yi ọgba ajara Rè̩ ká lati lé awọn orilẹ-ède keferi sẹyin ki wọn ma ba ba awọn irugbin Rè̩ titun jé̩. “Yio si ṣe, bi iwọ ba farabalẹ gbọ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe aṣẹ rè̩ gbogbo ti mo pa fun ọ li oni, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbéọ ga jù gbogbo orilẹ-ède aiye lọ … OLUWA yio mu awọn ọtá rẹ ti o dide si ọ di ẹni ikọlù niwaju rẹ: nwọn o jade si ọ li ọna kan, nwọn o si sá niwaju rẹ li ọna meje” (Deuteronomi 28:1, 7).

A kọ ile ẹṣọ kan saarin ọgba ajara Oluwa. A kọ awọn ile-iṣọ igbaani fun ibi aabo ati isasi nigba ogun ati ewu. A kọ wọn ga to bẹẹ gẹ ti awọn oluṣọ ti o wa ni tente ori ile-iṣọ naa le maa ri bi ọta ba n bọ. Awọn ile-iṣọ naa lagbara o si nipọn to lati le ọtá sẹyin bi o ba fẹ gbiyanju lati báẹni ti o ni ọgba ajara naa jà. Ilu Jerusalẹmu ati Tẹmpili Oluwa di ibi aabo nla fun awọn Ọmọ Israẹli, pataki ni akoko igba ti wọn ba n sin Oluwa pẹlu gbogbo ọkàn, iye ati agbára wọn. (Ka Isaiah 37:14-23, 33-36).

Oluwa wi fun ile Israẹli pe awọn ni ọgba-ajara Oun – ati pe awọn ọkunrin Juda jé̩ aṣayan ọgbin Ọlọrun. Oluwa ni ẹtọ lati reti ọpọ ikore lati inu laalaa Rè̩; bi o ba si ṣe pe awọn Ọmọ Israẹli ti fi otitọọkàn sin Ọlọrun ni, ireti i ba wa fun iru ikore bẹẹ. “Awọn ẹniti a gbin ni ile OLUWA, yio gbà ni agbala Ọlọrun wa. Wọn o ma so eso sibẹ ninu ogbó wọn” (Orin Dafidi 92:13, 14). Kò si aleebu kankan lara ọgbin Ọlọrun. “Emi ti gbin ọ ni ajara ọlọla, irugbin rere patapata.”

Orin Idajọ

“Eeṣe ti iwọ fi yipada di ẹka ajara ajeji si mi?” (Jeremiah 2:21). Orin idajọ Isaiah fi hàn pé Oluwa ti ṣe ohun gbogbo ti o yẹ ni ṣiṣe lati mu ki ọgba ajara Rè̩ jé̩ eleso; ṣugbọn nigba ti O n reti ikore, eso kikan ni ọgba ajara Rè̩ n so. Gbogbo awọn Ọmọ Israẹli ni apapọ, kọ lati sin Ọlọrun. O dabi ẹni pe wọn yàn lati fi ara fun è̩ṣẹ ati ibọriṣa ki wọn si wa doju kọ ibinu ati idajọỌlọrun oloootọ. Awọn Ọmọ Israẹli mọ pe Ọrun n duro de awọn wọnni ti o fi ọkàn otitọ sin Ọlọrun ni ayé, wọn si mọ pẹlu péọrun apaadi ti kòṣe e yẹ silẹ ni opin igbesi-ayéè̩ṣẹ ati aiṣododo; sibẹ awọn ti o pọju ninu awọn Ọmọ Israẹli yàn lati wà ninu è̩ṣẹ si i. Njẹ a le rò wi pe yiyan were kan tun wà ti o ga ju eyi lọ?

Ki ni a ba ṣe si ọgba-ajara alaileso naa? Oluwa sọtẹlẹ pe Oun yoo mu ọgba aabo rè̩ kuro, a o si jẹọgba-ajara naa run – a o si wó ogiri rè̩ lulẹ, a o si tẹ ogba-ajara naa mọlè̩. A gba ibukun Oluwa ti o wà lori Israẹli kuro ati lai pẹ a tú wọn ká si origun mẹrẹẹrin ayé. Oluwa dáòjo duro lori ilẹ naa, lai pẹ ilẹ daradara naa di aṣálè̩ gbigbẹ. Aṣayan ọgbin Oluwa ti o wà lori okèẹlẹtù loju di igi gbigbẹ patapata; iba ma ṣe aanu ati majẹmu Oluwa, awọn Ọmọ Israẹli i ba ti parẹ lori ilẹ ayé. Lati ẹnu wolii yii, Ọlọrun sọ diẹ ninu awọn è̩ṣẹ ti awọn Ọmọ Israẹli jẹbi rè̩, awọn ọlọfintoto paapaa yoo gbà pe Ọlọrun ni idi lati rán idajọ gbigbona sori awọn alaiwa-bi-Ọlọrun yii.

Iyi Igbà Pada

Aworan ọrọ ti wolii Isaiah n fi han ni ni akoko yii nipa awọn Ọmọ Israẹli jé̩ eyi ti kò fani mọra ni kikà tabi ni gbigbọ. Adura wa ni pe ki Ọlọrun le jẹ ki idajọ kan ṣoṣo yii lori è̩ṣẹ tó lati kilọ fun gbogbo ẹlẹṣẹ lati sá kuro ninu ibinu Olodumare ki wọn si yi pada tọkantọkan lati sin Ọlọrun alaaye ati otitọ.

Fi awọn Keferi rọpo awọn Ọmọ Israẹli ninu aworan ọrọ yii, a o ri i pe bakan naa ni ohun ti n ṣẹlẹ lọjọ oni rí. Nigba ayé oore-ọfẹ, awọn Keferi gan an ni Ọlọrun rán Ẹmi Rè̩ si. Oluwa ti pese gbogbo anfaani fun igbala gbogbo eniyan, ṣugbọn Ọlọrun fun eniyan ni ominira lati le yan ohun ti o ba fẹ, i baa ṣe iye ainipẹkun tabi ikú ayeraye. Ọlọrun ti ṣe ohun gbogbo ti o wà ni ipa Rè̩ lati múọmọ-eniyan wá si ironupiwada; ṣugbọn ni apapọ wọn n kọ eti didi si ipe aanu Rè̩ sibẹ. Idajọ ti Oluwa sọ nipa ọlọtẹ Israẹli yoo wá sori awọn Keferi ti wọn kọ lati ronu piwada è̩ṣẹ wọn ati lati gba oore-ọfẹỌlọrun si ookan-aya wọn.

Imọ-ti-ara-ẹni-nikan

Oluwa fi awọn olojukòkoro Israẹli ré, sibẹ idajọè̩ṣẹ Israẹli kò múè̩ṣẹ naa kuro ninu ayé. Awọn eniyan ṣi jé̩ olojukokoro sibẹ, bi ibinu Ọlọrun ṣe muna nigba nì, bẹẹni o ṣi muna titi di oni nitori è̩ṣẹ yii. Jesu wi fun awọn olugbọ Rè̩ pe: “Kiyesara ki ẹ si māṣọra nitori ojukòkoro: nitori igbesi aiye enia ki iduro nipa ọpọ ohun ti o ni” (Luku 12:15). Ọpọ ohun ti eniyan ni tabi ohun ti o ṣe, ni ayé fi maa n diwọn aṣeyọri ti eniyan ni, ṣugbọn Ọlọrun n diwọn aṣeyọri eniyan nipa ọpọ ohun ti ẹmi ti o ni ati ibi ti o dé nipa ti ẹmi. Iyatọ pupọ ni o wa laaarin idiwọn mejeeji.

Ẹṣẹ imọ-ti-ara-ẹni-nikan miran ti Oluwa tun n dá-lẹbi lọjọ oni, gẹgẹ bi o ti ṣe ni akoko awọn Ọmọ Israẹli ni è̩ṣẹ imutipara. Iwe iṣiro fi han ni pe ọkẹ aimoye ẹgbẹgbẹrun naira ni awọn eniyan n ná lọdọọdun lori ohun oloro yii, awọn ẹni ti kò tilẹ yẹ, nipa aini, lati le fi ara wọn fun ayé ijẹkujẹ, ailere ati ibajẹ ti ohun oloro yii n mu wá. Ọpọ agbo ile ati awọn ọmọ wé̩wẹ ni a n dù ni ounjẹ oojọ ati anfaani fun igbesi ayé wọn nitori pe ọkan ninu awọn obi wọn tabi awọn mejeeji ti ná gbogbo owó tán lori ọti ati awon ohun ibajẹ miiran gbogbo. Ni ilu Amẹrika, eniyan bi aadọjọọkẹ ni ọti mimu ti di baraku fun, ti wọn kò tun le fi ọti silẹ mọ. Ọkẹ aimoye awọn miiran ni wọn n mu ọti gbajumọ, ti ọti mimu n ti si jamba ti n ṣe ikú pa ọpọlọpọ eniyan ni opopo ọna wa. ỌrọỌlọrun ti ki i tase, sọ ipin awọn ọmuti: “Ipania, imọtipara, iréde oru ati iru wọnni: awọn ohun ti mo nwi fun nyin tẹlẹ, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin tẹlẹ ri pe, awọn ti nṣe nkan bawọnnì ki yio jogún ijọba Ọlọrun” (Galatia 5:21).

Ọrun Apaadi di Gbigbooro

Iwa awọn eniyan buru jai, o si gbilẹ to bẹẹ gẹẹ ti Ọlọrun fi wi fun wolii naa pe, “Ipò-okú ti fun ara rè̩ li àye, o si làẹnu rè̩ li aini iwọn: ati ogo wọn, ati ọpọlọpọ wọn, ati ọṣọ wọn, ati awọn ẹniti nyọ, yio sọkalẹ lọ sinu rè̩” (Isaiah 5:14). Ki i ṣe eniyan ni a dáọrun apaadi fun tẹlẹtẹlẹ, ṣugbọn a pese rẹ silẹ fun “Eṣu ati fun awọn angẹli rè̩” (Matteu 25:41). A maa n fi ṣe ọrọ sọ pe ẹni ti o ba n gbé igbesi-ayéèṣu yoo fara mọ owo ọya èṣu. “Ikú li ère è̩ṣẹ” (Romu 6:23). “Awọn ojo, ati alaigbagbọ, ati ẹni irira, ati apania, ati àgbèrè, ati oṣó, ati abọriṣa, ati awọn eke gbogbo, ni yio ni ipa ti wọn ninu adagun ti nfi iná ati sulfuru jò; eyi ti iṣe ikú keji” (Ifihan 21:8).

Iwa ẹṣẹ kan naa ti awọn Ọmọ Israẹli n hù nigbaanì ni awọn eniyan ayé ode-oni n hù. Bi Ọlọrun ti dáè̩ṣẹ Israẹli lẹjọ, bẹẹ gẹgẹ ni yoo ṣe idajọè̩ṣẹ ni ọkàn ati igbesi-ayé olukuluku Keferi. “Bayi li emi o ṣe si ọ, iwọ Israẹli: ati nitoriti emi o ṣe eyi si ọ, mura lati pade Ọlọrun rẹ” (Amosi 4:12). Ọlọrun tun n sọ fun gbogbo eniyan pe: “Yàn iye, ki iwọ ki o le yè, iwọ ati irú-ọmọ rẹ” (Deuteronomi 30:19).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni Ọgba-ajara Oluwa?

  2. 2 Ọna wo ni Oluwa gbà daabo bo ọgba-ajara Rè̩?

  3. 3 Ki ni a le fi wé ile-iṣọ ti wolii naa ṣe apejuwe rè̩?

  4. 4 Ki ni Oluwa ri nigba ti O n reti eso ninu ọgba-ajara Rè̩?

  5. 5 Ki ni ṣẹlẹ si ọgba-ajara Oluwa? Ki ni ṣe?

  6. 6 Ọna wo ni a gba jẹ ojukokoro awọn Ọmọ Israẹli niya?

  7. 7 Ki ni Oluwa sọ nipa imutipara?

  8. 8 Ki ni ṣe ti ipò-okú fi fun ara rè̩ ni àyè?