Isaiah 6:1-13

Lesson 350 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹnyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya nyin, gẹgẹbi Kristi si ti fẹran ijọ, ti o si fi ara rè̩ fun u; Ki On ki o le sọọ di mimọ lẹhin ti a ti fi ọrọ wẹẹ mọ ninu agbada omi. Ki On ki o le mu u wá sọdọ ara rè̩ bi ijọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni; ṣugbọn ki o le jẹ mimọ ati alaini àbuku” (Efesu 5:25-27).
Cross References

I Iran Ọlọrun Mẹtalọkan ti a fi han Isaiah

1 Isaiah ri iran naa lẹyin ti a ti pe e si iṣẹ wolii, o jẹẹni iwa-bi-Ọlọrun nitori a ti da a lare, Isaiah 6:1; 1:1

2 Iran naa jẹ ti Ẹni Mẹtalọkan mimọ, alagbara ailopin, Isaiah 6:1-3, 8; Johannu 12:41; Iṣe Awọn Apọsteli 28:25; Ifihan 4:1-11; 5:6; Esekiẹli 1:1-28; Orin Dafidi 72:19

3 Awọn ohun ti o ri ninu iran naa jẹ awọn ohun ijinlẹ, Isaiah 6:4; Ẹksodu 40:34, 35; 1 Awọn Ọba 8:10, 11

II Isaiah Ri Aipe Ara rẹ, lẹyin eyi Isọdimimọ Rẹ Tẹle e

1 Iran ẹwa iwa-mimọỌlọrun yii mu ki Isaiah ri idibajẹẹda ainilaari ti rè̩, Isaiah 6:5; Ẹksodu 33:20; Luku 5:8; Matteu 5:8; Heberu 12:14

2 A sọ Isaiah di mimọ nigba ti è̩ṣé̩ ina kan ète rè̩, Isaiah 6:5-7; Orin Dafidi 51:2, 7; Esekiẹli 36:26

III Ipe Isaiah ati Aṣẹ ti a fi rán an jade

1 Lẹyin isọdimimọ Isaiah, a pe e si iṣẹ kan ti o jẹ pataki ti o si nipọn, Isaiah 6:8; Gẹnẹsisi 17:1-22

2 Ifi ara-rubọ atọkanwa rè̩ṣíọna silẹ fun Ọlọrun lati fi iṣẹ kan pato, le e lọwọ, Isaiah 6:8-13; Ẹksodu 3:1-10; 1 Awọn Ọba 19:19-21; fi we 2 Awọn Ọba 3:11, 12; Iṣe Awọn Apọsteli 13:2

Notes
ALAYE

Iran ati Ẹkọ ti o Kọ Ni

Awọn ẹkọ ti a ri kọ ninu iran Isaiah pọ pupọ, ninu wọn ni iṣipaya ti Mẹtalọkan Mimọ ju lọ. Pe Ọlọrun jẹ Mẹtalọkan hàn gbangba nitori pe Isaiah ri Oluwa o si gbọ bi awọn ẹda Ọrun ti n fi iyin ilọpo mẹta fun Un. Iru iyin ilọpo mẹta yii ni awọn ẹni irapada ti o wa niwaju ItẹỌlọrun yoo maa fi yin In nigba ti Ipọnju Nla ba wà lori ilẹ ayé (Ifihan 4:8; 5:8-10). Ki i ṣe eeṣi ni o mu ki iyin wọn pin si ipa mẹta, apa kọọkan ninu iyin wọn wà fun Ẹni kọọkan ninu Mẹtalọkan, nitori kò si aṣiṣe lọdọỌlọrun. Awọn itọka miiran tun wà ninu iran Isaiah ti o fi han pe Mẹtalọkan ni Ọlọrun.

Ọlọrun Baba wà nibẹ, nitori Oun ni a n fi hàn bi Ẹni ti o joko lori Itẹ ni Ọrun. Nisisiyii Kristi joko lọwọọtun Itẹ nì, Ẹmi Mimọ Olubukun si wà ninu ayé O n fi òyé yé “araiye niti è̩ṣẹ, ati niti ododo, ati niti idajọ” (Johannu 16:8). S̩ugbọn Johannu Ayanfẹ wi pe nigba ti Isaiah ri Oluwa, o ri Jesu! (Wo Johannu 12:37-41). Ati ninu Iṣe Awọn Apọsteli a kà wi pe Ẹmi Mimọ sọrọ nigba naa! (Wo Iṣe Awọn Apọsteli 28:25-27). A fi iyin ilọpo mẹta naa fun Ọlọrun Mẹtalọkan -- Ọlọrun Baba, Jesu Kristi Ọlọrun Ọmọ ati Ẹmi Mimọ.

Ni afikun awọn ijẹri wọnyii, a ri i pe nigba ti Isaiah gbọ ohùn Oluwa, oun kò gbọ ohun ẹnikan ṣoṣo bi kòṣe ohùn ti o ju ti ẹnikan ṣoṣo lọ, ti o si duro gẹgẹ bi ohùn kan, nitori Oluwa wi pe: “Tali Emi o rán, ati ta ni o si lọ fun wa?” A fi iṣẹ rán Isaiah gẹgẹ bi iranṣẹ Mẹtalọkan, ṣugbọn iṣẹ ti a fi rán an ti ọdọỌlọrun ti O parapọṣọkan wá -- iṣọkan ti kò lè yéẹda (Wo Johannu 17:21-23; Heberu 2:11).

Ori iwe yii n kọ wa pẹlu pe Mẹtalọkan ti wà lati ayebaye ati titi ayeraye. “Mimọ, Mimọ, Mimọ, li OLUWA awọn ọmọ-ogun” li orin-iyin ti n tọka si i pe Kristi wà ninu iwa-Ọlọrun nigba naa. Gbogbo awọn wọnni ti n wi pe nigba ti a bi Kristi ni Bẹtlẹhẹmu ni O ṣẹṣẹ bẹrẹ igbesi-ayé Rè̩ n ṣe aṣiṣe nla. Ẹni ti “a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye” fun awọn ẹda ti n ṣegbe (Ifihan 13:8), “O mbẹ lāye titi lai lati mā bè̩bẹ fun wọn” (Heberu 7:25).

A kọ wa pẹlu pe iyin ati ọlanla yẹ fun Ọlọrun wa, a si gbọdọ fi tọkàntọkàn fi wọn fun Un. Awọn iranṣẹ ti o ga ju lọ nibi Itẹ bo oju ati ẹsẹ wọn ni ipo ibuyin fun, wọn si n fi gbogbo agbára wọn yin Ọlọrun logo. Bi awọn ẹda alai lẹṣẹ ti n duro niwaju Olodumare ba le ṣe eleyi, meloomeloo ni awa ti a ti rà pada nipa Ẹjẹ iyebiye nì ni lati ṣe bẹẹ pẹlu. A ni lati fi gbogbo iyin wa, ijọsin wa, ifọkànsin wa, iṣẹ-isin wa – ani gbogbo igbesi-ayé wa -- fun Un pẹlu irẹlẹ ti o jinlẹ jù lọ. Awọn ẹda mimọ wọnyii n yin In nigba gbogbo -- awọn ti kò mọè̩ṣẹ ri, ti wọn kò si mọ titobi oore-ọfẹ irapada ati ifẹỌlọrun si wọn ri. Iyin wa gbọdọ ju ti wọn lọ, nitori ti awa ti mọ ifẹ ati oore-ọfẹ Rè̩, ati aanu Rè̩ ti O n na ọwọ Rè̩ si wa lọjọọjọ ni igbesi-ayé wa.

Isọdimimọ Isaiah

Isaiah jé̩ eniyan Ọlọrun nigba ti a fi iran yii hàn án. Wolii Ọlọrun ni oun i ṣe nigba naa. Gbogbo awọn wolii Ọlọrun jé̩ eniyan mimọ, bi o tilẹ jẹ pe Isaiah kò i ti ri isọdimimọ patapata gbàṣiwaju akoko yii, sibẹ a ka a si ẹni mimọ gẹgẹ bi o ti n ṣẹlẹ ni igbesi-ayé awọn ti a ti dalare nitootọ. S̩ugbọn akoko kan de ninu iriri Isaiah bi o ti má n ṣẹlẹ ni iriri igbesi-ayé olukuluku Onigbagbọ ti a ti dalare bi o ti n rin ninu imọlẹ, nigba ti o ba ri isọdimimọ gbà, ninu iriri ẹsẹkẹsẹ ti o daju ninu iṣẹ isọdimimọ patapata ti a ṣe ninu ọkàn rè̩. Iwamimọ ti a kà si ni lọrun nipa oore-ọfẹỌlọrun jẹ ti oluwarẹ niwọn igba ti oun ko i ti ri imọlẹ nla tabi anfaani lati wá oore-ọfẹ iwamimọ nì ti a n fi fun ni nipa agbára ẹbun oore-ọfẹỌlọrun – Jesu Kristi, ati Ẹjẹ Rè̩ ti a ta silẹ -- ni akoko isọdimimọ patapata.

Nigba ti Isaiah ri i bi ipo rè̩ ti ri niwaju Ọlọrun, ti mimọỌlọrun si fara hàn niwaju rè̩, o kigbe ni ibanujẹọkàn pe: “Egbe ni fun mi, nitori mo gbé, nitoriti mo jé̩ẹni-alaimọ etè, …nitoriti oju mi ti ri Ọba, OLUWA awọn ọmọ-ogun.” Riri iwa-Ọlọrun ayeraye ninu pipe ẹwa iwa mimọ mu ki o ri ipo ti oun paapaa wà. Eyi mu ki o mọ pe iwa è̩ṣẹ-abinibi ṣi wà sibẹ ninu ọkàn rè̩ eyi ti a gbọdọ fà tu kuro. O ri i bi oun ti ṣe alaiyẹ tó. Riri ti o ri ara rè̩ ni iru ipo bayii mu ki o ṣeeṣe fun Ọlọrun lati ṣe iṣẹ iwẹnu ninu ọkàn rè̩ eyi ti a n pe ni isọdimimọ patapata.

O dara fun wa lati ri ara wa gẹgẹ bi Ọlọrun ti ri wa. Bi a ba ṣe bẹẹ, yoo mu ki a ke pe Ọlọrun fun iranwọ. Nigba naa Ọlọrun le ṣiṣẹ fun wa, ki o si ṣe ohun ti O ba fẹ fun wa. A fi ỌrọỌlọrun ṣe awojiji. A gbọdọ maa wo awojiji naa nigbakuugba pẹlu adura ninu ọkàn wa pe ki a le ri i bi awa ti ri gan an nibẹ. Olukuluku ẹni ti kò ti i ri isọdimimọ gbà ni lati mu ọkàn le, “nitori eyi ni ifẹỌlọrun, ani wiwà ni mimọ nyin” (1 Tẹssalonika 4:3). Awa ti a si ti ri iriri ologo nì si tun le yẹ ara wa wò ninu Ọrọ ti n wáni ri nì, nitori a gbọdọ wẹ ara wa mọ, gẹgẹ bi Oun ti mọ, ki a si maa ti “igbagbọ de igbagbọ,” ati lati inu ogo de inu ogo, titi awa o fi ri I gẹgẹ bi Oun ti ri, ki a si dabi Rè̩ nipa oore-ọfẹ iyanu Rè̩.

Ninu agọ ti o wà ni ayé, ọna iyanu ni iná n gbà de ori pẹpẹ idẹ, a si n mu è̩ṣé̩-iná lati ori pẹpẹ-idẹ si Ibi Mimọ a si n fi sori pẹpẹ-wura ti turari, èefín eyi ti n goke tọsantoru sọdọỌlọrun. Eyi jẹ apẹẹrẹ isọdimimọ patapata. Ọkan ninu awọn serafu múè̩ṣé̩-iná lati ori pẹpẹ o si fi kan ète Isaiah, a si kede rẹ pe, “a mu aiṣedede rẹ kuro, a si fọè̩ṣẹ rẹ nù.” Nitori naa a le sọ pẹlu idani loju pe a sọ Isaiah di mimọ.

Isọdimimọ Isaiah ki i ṣe ohun ti o ṣẹlẹ diẹdiẹ. Iriri ẹsẹkẹsẹ ni. Oun kò dagba lọ sinu iwa mimọ, tabi ki o ri i ki a maa mu è̩ṣẹ-abinibi rè̩ kuro diẹdiẹ. Ni iṣẹju kan Isaiah ri ara rè̩ bi eleeri, ṣugbọn ni iṣẹju ti o tẹle e o gbọ ohùn serafu nì ti o wi fun un pe o ti di mimọ laulau. Isọdimimọ jé̩ iṣẹ iwẹnumọọkàn ti igbagbọ n mu wá lẹyin igba ti ẹni ti n wá iriri yii ti ya ara, ẹmi, ọkàn ati ayé rè̩ sọtọ patapata.

A le ṣe akiyesi pe è̩ṣé̩-iná ti a mú lati ori pẹpẹ jẹ apẹẹrẹiná atunniṣe ti Ẹmi Mimọ, ki i si ṣe ti agbára ti a n ri gba nigba ti a ba fi Ẹmi Mimọ wọ ni. Idarudapọ ma n wà nigba ti awọn eniyan ba n ṣe alaye ti kò péye nipa ifi Ẹmi Mimọ wọ ni, eyi ti i ṣe iriri kẹta Onigbagbọ ti o dáju. A sọ Isaiah di mimọ-- a mu aiṣedeedee rè̩ kuro, a si wẹẹdáè̩ṣẹ rè̩ nù – nigba ti è̩ṣé̩-iná naa kan etè rè̩. A kò fi iru agbára ti Ẹmi Mimọ maa n fi fun awọn ti o ti gba Ileri Baba fun un nigba naa. Iriri Isaiah jé̩ iṣẹ iwẹnumọ ti Ẹmi Mimọ n ṣe. O jẹ ibuwọn Ẹjẹ iwẹnu -- è̩ṣé̩-iná atunniṣe – ti n pese wa silẹ fun ifiwọni Ẹmi Mimọ ni kikun agbàra Rè̩. A n fun wa ni agbara yii nigba ti a ba ri iriri kẹta ti Onigbagbọ -- fifi Ẹmi Mimọ wọ ni.

A sọ Isaiah di mimọ, ṣugbọn a kò fi Ẹmi Mimọ wọ eniyan ṣiwaju Ọjọ Pẹntikọsti. Olutunu naa kò dé titi di igba ti Jesu fi goke re Ọrun, nitori naa kò si ninu awọn eniyan mimọ igba Majẹmu Laelae ti a fi Ẹmi Mimọ wọ. S̩ugbọn aimoye ninu awọn eniyan mimọ ti Majẹmu Laelae ni a sọ di mimọ, wọn si jẹri si otitọ naa nipa isin wọn lori ilẹ aye yii ninu pipe iwa-mimọ yii eyi ti o jẹ kiki awọn ti a sọ di mimọ ni o le mọ.

Iṣẹ ti a fi Rán Isaiah

Olukuluku eniyan ni Ọlọrun pè. Diẹ ni o jé̩ ipè naa, Ọlọrun si yàn wọn, bi wọn si ti n foriti i lọna iwa-bi-Ọlọrun wọn jẹ oloootọ (Matteu 20:16; Ifihan 17:14). Awọn kan ninu awọn ti o jẹ ipe Ọlọrun si igbala ni a pè, ti a si yàn si awọn iṣẹ pataki ninu isin Rè̩ (1 Kọrinti 12:28; Efesu 4:11-13). A ti pe Isaiah ni wolii Ọlọrun paapaa ṣiwaju isọdimimọ rè̩, ṣugbọn nigba ti a wẹẹ mọ kuro ninu è̩ṣẹ-abinibi, ipè rè̩ wá yanju kedere, a si fun un ni iṣẹ pataki lati ṣe nipa orilẹ-ède Israẹli apẹyinda.

A fi iṣẹ pataki rán Isaiah si awọn eniyan, ki wọn ma ba tẹra mọọna iwa buburu wọn ti iyọrisi rẹ jé̩ okunkun ati ikolẹru. A yàn án fun iṣẹ pataki yii, a si pese rè̩ fun un. Gbogbo iwe asọtẹlẹ rè̩ jẹri si i pe oun jé̩ oloootọ si ipè rè̩ ati si awọn eniyan rè̩. Ohun nla ribiribi ti o yani lẹnu ni a fi hàn wá ninu ọrọ ti o mu wa fun wa lati ọdọỌlọrun nipa imisi Ẹmi Mimọ. Idajọ ti o bani lẹru ati èṣe ti o nira ti n tẹle è̩ṣẹ didá ati iṣọtẹ si Ọlọrun, ni a kọ sinu iwe Isaiah. A pèé, a yàn án, o si jẹ oloootọ ani titi de ikú.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Sọ awọn otitọ pataki nipa ti Ọlọrun ti a kọ wa ninu iran Isaiah.

  2. 2 Bawo ni a ṣe mọ ninu ibi ti a kà fun ẹkọ wa ati ibomiran ninu Iwe Mimọ pe Ẹni Mẹta ọtọọtọ ni o wà ninu Iwa-Ọlọrun?

  3. 3 Ki ni abayọrisi ifarahàn Ọlọrun lori Tẹmpili funra rè̩?

  4. 4 Ki ni abayọrisi ìran naa lori Isaiah?

  5. 5 Ki ni serafu naa ṣe ati ki ni o si sọ si ọrọ ti Isaiah sọ nipa ti ara rè̩?

  6. 6 Bawo ni a ṣe mọ pe a sọ Isaiah di mimọ ni akoko yii?

  7. 7 Bawo ni a ṣe mọ pe a kò fi Ẹmi Mimọ wọ Isaiah ni akoko yii?