Isaiah 24:1-23; 26:19-21; 34:1-8

Lesson 351 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Wá, enia mi, wọ inu iyè̩wu rẹ lọ, si se ilẹkun rẹ mọ ara rẹ: fi ara rẹ pamọ bi ẹnipe ni iṣé̩ju kan, titi ibinu na fi rekọja” (Isaiah 26:20).
Cross References

I IdajọỌlọrun lori Ilẹ

1 Oluwa yoo bẹ ayé wò ati awọn olugbe inu rẹ, Isaiah 24:1, 3, 4; 26:21; 34:1-3; 13:11; Matteu 24:21, 22; 2 Tẹssalonika 1:7-9

2 IdajọỌlọrun yoo wà lai ṣègbè, Isaiah 24:2; 34:2-5; Johannu 12:48; Romu 2:8, 9; Kolosse 3:25; 1 Peteru 1:17

3 A fi ilẹ gegun nitori è̩ṣẹ awọn eniyan, Isaiah 24:5-12; Gẹnẹsisi 3:17; Jeremiah 44:22

4 Awọn eniyan diẹ ni a o dá si, wọn o si yin Ọlọrun logo, ṣugbọn awọn eniyan buburu ki yoo le sáàsálà, Isaiah 24:16-18, 21, 22; 34:6-8; Owe 11:21; 19:5; Amosi 9:1-4; Matteu 23:33; Romu 2:3; Heberu 2:3

5 Ilẹ yoo ta gbọn-ọn gbọn-ọn gẹgẹ bi ọmuti eniyan, Isaiah 24:19, 20; 2:19; 13:13; Ifihan 11:19

II Aabo fun awọn Olododo

1 A o ji awọn okú mimọ dide, ati awọn olododo ti o wà laaye ni a o gbà si awọsanma ṣaaju igbà ipọnju naa, Isaiah 26:19, 20; 1Kọrinti 15:19-22, 51-54; 1 Tẹssalonika 4:13-17; Ifihan 20:4

2 Oluwa awọn ọmọ-ogun yoo jọba ni Jerusalẹmu ni opin ìgbà ipọnju naa, Isaiah 24:23; 2:1-3; Sẹkariah 14:9, 16, 17;Ifihan 11:15; 19:11-16

Notes
ALAYE

“A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de …nigbana ni ipọnju nla yio wà, irú eyi ti kò si lati igba ibẹrẹọjọ iwa di isisiyi, bḝkọ irú rè̩ ki yio si si” (Matteu 24:14, 21). A ti waasu Ihinrere Ijọba ni gbogbo orilẹ-ède ayé, ọpọlọpọ eniyan ni o ti kọọ; nitori naa Ipọnju Nla ni yoo si tẹle e. Bi a ba wo inu ayé loni, a o ri i gbangba bi imisi buburu ti è̩ṣẹ, ati ifara hàn iṣẹ Eṣu ti n bo gbogbo ẹda ayé mọlẹ. O dabi ẹni pe bi anfaani ẹkọ ati imọ ti n ga si i, bẹẹni ọkàn awọn eniyan n fà kuro ninu ododo ati iwa-bi-Ọlọrun tó. Bibeli wi bayii pe: “Awọn enia buburu, ati awọn ẹlẹtàn yio mā gbilẹ siwaju si i, nwọn o mā tàn-ni-jẹ, a o si mā tàn wọn jẹ” (2 Timoteu 3:13).

Awọn Idajọ ti n Bọ

Oluwa kilọ ninu Ọrọ Rè̩ pe ẹlẹṣẹ ati è̩ṣẹ ki yoo lọ lai jiya. Asọtẹlẹ Isaiah sọ fun ni bi ijiya yii yoo ti tànká tó li ọjọ ibinu Oluwa: “Kiyesi i, OLUWA sọ aiye di ofo, o si sọọ di ahoro, o si yi i po, o si tú awọn olugbé inu rè̩ ka” (Isaiah 24:1). Kò si ẹni ti o wà laaye ti yoo bọ kuro ninu idajọỌlọrun ni ọjọ naa. Gbogbo eniyan ni yoo jiya è̩ṣẹ ti wọn ti dá. Awọn eniyan naa yoo jiya, ati awọn wolii èké ti n kọ wọn, ti o si n fi ọkàn wọn balẹ sori asán; awọn oluwa ninu ayé ti wọn le fi owo wọn ra ohun rere ti ayé ati ayọ yoo jiya pẹlu awọn ọmọ-ọdọ ti n ṣe iranṣẹ fun wọn; iranṣẹ-binrin ati oluwa rè̩, olura ati oluta, atọrọ ati awinni – gbogbo wọn ni yoo bá ibinu ati idajọỌlọrun pade nitori ti wọn kọ eto igbala Ọlọrun ti i ṣe fun awọn olugbé ayé.

Didà Majẹmu

Laaarin awọn wolii nla ti igba Majẹmu Laelae, Isaiah tayọ gẹgẹ bi wolii alasọtẹlẹ nipa irapada; ṣugbọn o sọ ohun pupọ pẹlu nipa idajọ ti n bọ lori awọn aṣayan ilu ati lori ayé lapapọ. O dabi ẹni pe gbogbo ayé ni a dari ọrọ idajọ ti o wà ninu ori kẹrinlelogun Iwe Isaiah si, a si ka awọn idi ti idajọ fi n bọ: “wọn ti rú ofin, wọn pa ilàna dà, wọn dà majẹmu ayeraye.”

Gbogbo è̩ṣẹ ti eniyan n dá ni inu Ọlọrun kò dùn si, ṣugbọn eyi ti o dabi ẹni pe o buru ju ninu è̩ṣẹ ti eniyan n dá ni kikọ Kristi. Lati igba ti eniyan ti kọkọ dáè̩ṣẹ si Ọlọrun ni O ti ṣeleri pe Oun yoo rán Olurapada ti yoo ṣe etutu fun è̩ṣẹ eniyan. Gbogbo eniyan ni majẹmu ayeraye yii wà fun. Lati ayebaye ni Ọlọrun ti n sọ ileri yii di ọtun, ti otitọ naa si n sunmọ-tosi titi o fi di akoko igba ti Ọlọrun rán Ọmọ Rè̩ Jesu Kristi si ayé lati jiya ati lati kú ikú irubọ lori Agbelebu, pe nipa Ẹjẹ Jesu ki a le gba gbogbo eniyan là. “Ọlọrun ----nisisiyi o paṣẹ fun gbogbo enia nibi gbogbo lati ronupiwada: Niwọnbi o ti da ọjọ kan, ninu eyiti yio ṣe idajọ aiye li ododo, nipasẹọkunrin na ti o ti yàn; nigbati o ti fi ohun idaniloju fun gbogbo enia, niti o ji i dide kuro ninu okú” (Iṣe Awọn Apọsteli 17:30, 31).

Ohun idaniloju kan ṣoṣo ti o le yọ ni kuro ninu è̩ru ati ijiya Ipọnju Nla ni igbọran si gbogbo ilana majẹmu ayeraye – tabi ni kukuru, gba Jesu Kristi gbọ, jẹwọ gbogbo è̩ṣẹ ti o ti dá, ki o si gbọran si Ọlọrun, ki o si fẹẸ pẹlu gbogbo ọkàn, iye, inu, ati agbára rẹ. O ṣe ni laanu pe, gbogbo ayé lapapọ kò fé̩ tẹriba fun, bẹẹni wọn kò si fé̩ gba gbogbo ipese majẹmu naa. Nitori ti wọn kọ lati gba ifẹ otitọ ti a ba fi gbà wọn là, awọn ti o pọju ninu awọn eniyan ti o wà ninu ayé ni yoo parun.

Ipọnju Nla

È̩ṣẹ ti ṣiṣẹ ibi lọpọlọpọ ni igbesi-ayéọmọ-eniyan lati ọdunmọdun; ṣugbọn akoko Ipọnju Nla yoo jé̩ igba idajọ ti kò si irú rè̩ ri. Akoko iyọnu ti wàṣaaju ri, ṣugbọn kò si eyi ti yoo dabi igba ipọnju ti a sọrọ nipa rè̩ yii ninu ỌrọỌlọrun ni gbogbo itan agbaye. Ipọnju Nla naa yoo wà fun ọdun meje. Nigba ti ipọnju naa ba n lọ si opin ni a o rán idajọ gbigbona sori gbogbo orilẹ-ède ayé, Ju ati Keferi bakan naa, fun gbogbo aiwa-bi-Ọlọrun wọn ati kikọ Ihinrere ati iṣẹ ti Kristi rán si wọn. Yoo jẹ igba ibanujẹ kikoro, irora ati inira, lara ati lọkan fun gbogbo ẹda ti o wa laaye. Ẹṣẹ ati iwa buburu yoo dé ogogoro ninu idajọ gbigbona nla yii.

“Ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká,” ni ỌrọỌlọrun sọ fun wa, bi akoko ifunrugbin ti daju bẹẹ gẹgẹ ni akoko ikore yoo dé pẹlu.

ỌrọỌlọrun fi ye ni pe ki i ṣe ohun kekere ni lati yi pada kuro lẹyin Oluwa ati lati ká abayọri síè̩ṣẹ. Awọn ẹlomiran a maa fẹṣe awawi pe wọn jẹ ope si Ọlọrun ati Ofin Rẹ, ṣugbọn Ọlọrun wi pe “wọn mmọṣe aifḝmọ” (2 Peteru 3:5). Ko si awawi kan fun è̩ṣẹ ti yoo duro ni akoko idajọ yii, nitori ti Ọlọrun ti pese ohun gbogbo silẹ lati mu è̩ṣẹ kuro ninu ọkàn ọmọ eniyan. Idajọ ki i ṣe ohun ti o wuni-lori, ṣugbọn o jẹ apakan pataki ninu ỌrọỌlọrun paapaa nitori awọn nnkan wọnni ti o n daya fo ayé.

Aṣodi-si-Kristi

“Egbé ni fun aiye ati fun okun! nitori Èṣu sọkalẹ tọ nyin wá ni ibinu nla, nitori o mọ pe igba kukuru ṣá li on ni” (Ifihan 12:12). Eṣu ti jà ni Ọrun ṣugbọn kò le bori, nitori naa yoo sa gbogbo ipa rè̩ ninu ayé lati bi eto Ọlọrun wó. Ni gẹrẹ ti a ba ti gba IjọỌlọrun -- awọn Onigbagbọ aṣẹgun ni kikun – soke kuro ninu ayé, eṣu yoo gbá ogun jọ, yoo si gbé eto buburu rè̩ kalẹ lati jọba lori ilẹ ayé.

Jesu wá bi ỌrọỌlọrun ti o gbe ara wọ, ỌmọỌlọrun ti a fi hàn ninu ara; bakan naa ni Aṣodi-si-Kristi yoo wá gẹgẹ bi eṣu ti o gbé ara wọ, oun paapaa ni o duro fun eṣu. Gbogbo iwà ati iṣe Aṣodi-si-Kristi yii ni a tò fun ni lẹsẹẹsẹ ninu Bibeli. Alailofin ni, ẹni ti kò bẹru Ofin Ọlọrun tabi ti eniyan. Eyi hàn gbangba ni ode-oni nitori ayé ailofin ni a n gbé lọjọ oni. Ohun ti o ba irẹpọ ti o wà laaarin awọn orilẹ-ède jẹ ni awọn ọjọ wọnyi ni ṣiṣe ainaani ofin, tabi adehùn, tabi ọrọ ileri ti o wà laaarin wọn; gbogbo rè̩ ni wọn ti ṣá ti. Kikọ Ofin Ọlọrun silẹ patapata wà laaarin awọn orilẹ-ède miiran pẹlu. Awọn wọnyi jẹ diẹ ninu awọn ami ti n fi hàn pe Aṣodi-si-Kristi kò ni pẹ de mọ.

Yoo jẹ aninilara, iwa buburu ati ikà rẹ yoo ju ti ẹnikẹni lọ. Nipa ipọnni ni yoo fi de ipo giga rẹ; ṣugbọn gẹrẹ ti o ba ti de àye rè̩ tán, pẹlu ipa ni yoo fi mu gbogbo ayé lati tẹri ba fun un. Nigba ti Daniẹli n sọnipa rẹ, o wi bayii pe oun yoo “ma bu ọla fun ọlọrun awọn ilu olodi,” nida keji ẹwẹ yoo ṣe àpọnlé ogun jija.

Ni ọjọ oni nigba ti gbogbo ayé n fi gbogbo agbara wọn kó nnkan ogun jọ ti wọn si n sagbàrà yi ara wọn ká, eto ogun ti di ohun ikinni ninu èto ọpọlọpọ orilẹ-ède. Ọpọ orilẹ-ède ni o gbẹkẹle agbára ogun-jija lati mú ifẹ inu wọn ṣẹ; fifi ipa mú orilẹ-ède tẹri ba jé̩ ohun ti o wọpọ laaarin awọn orilẹ-ede ologun wọnyii. Wọn kò tun ni igbẹkẹle ninu ọgbọn-ẹwẹ ti iṣelu tabi ti ilaja mọ. Wọn kò tun gbiyanju ati pade ara wọn lapapọ ni ọna ti o tọ ki wọn si yanju gbogbo iṣoro wọn lọna ti o tọ: ṣugbọn wọn n pinnu lati bori nipa lilo ipá – iru iwa Aṣodi-si-Kristi gan an ni eyi.

Ami Ẹranko Naa

Igbesi-ayé Kristi ta gbogbo igbesi-ayéẹnikẹni yọ gẹgẹ bi aṣoju ododo Ọlọrun fun gbogbo ayé. Nida keji ẹwẹ, Aṣodi-si-Kristi yoo wá gẹgẹ bi aṣoju iwa buburu. Ẹranko buburu ẹlẹru nì. A fi i wéẹranko ninu ỌrọỌlọrun; gbogbo awọn eniyan ti o ba kù silẹ ninu ayé ni akoko ijọba Aṣodi-si-Kristi ni a o fi agbára mu lati gba àmìẹranko buburu naa si iwaju tabi ni ọwọ otun wọn tabi ki wọn sọẹmi wọn nù. Ofin Aṣodi-si-Kristi naa yoo le to bẹẹ gẹ ki “ẹnikẹni má le rà tabi ki o tà, bikoṣe ẹniti o bá ni ami orukọẹranko na, tabi iye orukọ rè̩” (Ifihan 13:17). A fi awọn ti o ba gba ami ẹranko naa gegun kikoro: “Bi ẹnikẹni ba nforibalẹ fun ẹranko nì, ati aworan rè̩, ti o si gbààmi si iwaju rẹ tabi si ọwọ-rè̩, On pẹlu yio mu ninu ọti-waini ibinu Ọlọrun, ti a tú jade li aini àbula sinu ago irunu rè̩; a o si fi iná ati sulfuru da a loró niwaju awọn angẹli mimọ, ati niwaju Ọdọ-agutan: fin oró wọn si nlọ soke titi lailai, nwọn kò si ni isimi li ọsán ati li oru, awọn ti nforibalẹ fun ẹranko na ati fun aworan rè̩, ati ẹnikẹni ti o ba si gbààmi orukọ rè̩” (Ifihan 14:9-11).

Ọna Abayọ

Bi a ti n kà nipa ijọba Aṣodi-si-Kristi ninu ỌrọỌlọrun, ati awọn ohun buburu wọnni ti yoo ṣẹlẹ lakoko Ipọnju Nla, a le dupẹ pe Ọlọrun ti lana kan silẹ ti a fi le sá asala ni akoko yii. Jesu Kristi n pada bọ si ayé lati wá mu awọn eniyan mimọ Rè̩ ti n duro de E --awọn ọmọ Rè̩ wọnni ti wọn ti mura silẹ lati pade Rè̩. “Oluwa tikararè̩ yio sọkalẹ lati ọrun wá ti On ti ariwo, pẹlu ohùn olori awọn angẹli, ati pẹlu ipèỌlọrun; awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ jinde: nigbana li a ó si gbà awa ti o wà lāye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun: bḝli awa ó si ma wà titi lai lọdọ Oluwa” (1 Tẹssalonika 4:16, 17).

Ọlọrun dá Noa si nigba ti a fi omi pa ayé rè̩, Ọlọrun dá Lọti si nigba ti a pa Sodomu ati Gomorra run. O da Israẹli si nigba ti angẹli apanirun la Egipti kọja. Bẹẹ gẹgẹ ni O ti pese ọna atila silẹ fun awọn eniyan Rè̩ kuro ninu Ipọnju naa. “Wá, enia mi, wọ inu iyè̩wu rẹ lọ, si se ilẹkun rẹ mọ ara rẹ: fi ara rẹ pamọ bi ẹni pe ni iṣé̩ju kan, titi ibinu na fi rekọja. Nitorina, kiye si i, Oluwa ti ipò rè̩ jade lati bè̩ aiṣedede ẹniti ngbe ori ilẹ wo lori ilẹ; ilẹ pẹlu yio fi è̩jẹ rè̩ hàn, ki yio si bò okú rè̩ mọ” (Isaiah 26:20, 21). O jé̩ọranyàn fun ọmọ-eniyan lati jé̩ ipe Ihinrere lonii nitori ọjọ-de-ọjọ ni n fi àmi ti o daju hàn pe dide Kristi sunmọ tosi.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi pinnu pe idajọ yoo wá sori ayé?

  2. 2 Awọn wo ninu olugbe ayé ni Ọlọrun yoo dá lẹjọ?

  3. 3 Ki ni “majẹmu aiyeraiye” jasi fun ayé lọjọ oni?

  4. 4 Bawo ni awọn eniyan ṣe da “majẹmu aiyeraiye” naa?

  5. 5 Nigba wo ni Ipọnju Nla naa yoo dé sori ilẹ ayé?

  6. 6 Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ti o gba ami ẹranko buburu nì lakoko Ipọnju Nla?

  7. 7 S̩e apejuwe diẹ ninu awọn ohun buburu ti yoo ṣẹlẹ lori ilẹ ayé lakoko Ipọnju Nla.

  8. 8 Ọna wo ni a fi le bọ kuro ninu Ipọnju Nla naa?