Isaiah 40:1-31; 52:7-10; Matteu 3:1-3; 11:2-15

Lesson 352 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “A o si wasu Ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de” (Matteu 24:14).
Cross References

I Iṣẹ-iranṣẹ Aṣaaju Kristi

1 A rán iṣẹ itunu, eyi ti a sọ ninu asọtẹlẹ, si Israẹli, Isaiah 40:1, 2

2 Johannu Baptisti ni ẹni ti yoo wáṣaaju Oluwa lati kede bibọ Rè̩, Isaiah 40:3; Malaki 3:1; Matteu 3:1-3; Marku 3:1-3; Luku 1:13-17; Johannu 1:19-30

3 Wiwá Johannu ni lati sọ nipa ti ìgbà titun ti i ṣe ti Ihinrere, Isaiah 40:4-8; Matteu 3:5-12; 11:2-15; Marku 1:4-8; Luku 1:57-80; 3:7-18; Johannu 1:30-37

II Àkókò Ihinrere ati Abayọrisi Rè̩

1 Nitori bi o ti jẹ pe fun igba diẹ ni igbesi ayé eniyan yii yoo wà, o jé̩ọran dandan gbọn lati tan Ihinrere kalẹ, Isaiah 40:6-8; 1 Peteru 1:24, 25

2 Ohun-elo Ọlọrun fun itankalẹ Ihinrere – ni Ijọ Rè̩ -- o si ni lati kún fun iṣẹ naa pẹlu itara ati igbona ọkàn, Isaiah 40:9-11; 52:7-10; Johannu 4:35; Iṣe Awọn Apọsteli 1:8; 1 Kọrinti 9:19-22; Jakọbu 5:20; Juda 23

3 A fi pipé agbara Ọlọrun ati aijamọ nnkankan eniyan hàn, Isaiah 40:12-17; 43:13; Ifihan 19:6; 1 Kronika 29:12; Jobu 26:12; Orin Dafidi 115:3; Matteu 19:26

4 A sọìwà ibọriṣa ati igberaga eniyan di asán, Isaiah 40:18-24; Daniẹli 4:37; 1 Samuẹli 5:1-12

5 A sọ ti ogo Ọlọrun ati ireti Onigbagbọ, Isaiah 40:25-31; Orin Dafidi 19:1-14; 89:6; 73:25

Notes
ALAYE

Ni igba miiran, awọn alaigbọran Ọmọ Israẹli ni a rán iwaasu Isaiah ti o lẹwa ti o si lagbara si, ati ni igba miiran, è̩wẹ, gbogbo ayé ni iṣẹ naa wà fún. Níwọn igba ti a ti mọ nipa aṣẹ imisi ỌrọỌlọrun pe ibẹrẹ iwe Isaiah ori ogoji jé̩ asọtẹlẹ nipa wiwá Johannu Baptisti, a le sọ pẹlu idaniloju pe iyoku ori iwe naa jé̩ọkan ninu awọn ọrọ iyebiye ti a waasu rè̩ si gbogbo orilẹ-ède ti o n kede Ihinrere ati bibọ Messia Ẹni ti a rán Johannu lati tun ọna Rè̩ṣe.

Ọrọ Itunu

A bẹrẹ iwe Isaiah ori ogoji pẹlu ọrọ itunu si Jerusalẹmu ati awọn Ju, lori ọrọ yii pe, bi wọn ba le gba Jesu Kristi ni Messia wọn; ṣugbọn gbogbo ayé mọ pe gbogbo Ju ni apapọ kọỌmọỌlọrun nigba ti O wá si ayé. Nitori ti awọn Ju kọọrọ itunu, ani Ihinrere naa silẹ, a mu un tọ awọn Keferi lọ, abayọrisi eyi ti o ti mu ọké̩ aimoye ọkàn bọ sinu ijọba Kristi, ti wọn si ti ri itunu idariji è̩ṣẹ gbà ati agbára lati gbé igbesi-ayé ailẹṣẹ ninu aye yii ati pẹlu ireti iye ainipẹkun pẹlu Ọlọrun lẹyin ti iku ba pa oju wa dé.

Akoko n bọ, lai pẹ jọjọ, nigba ti awọn Ju yoo ri ifara hàn Jesu Kristi nigba ti o ba n pada bọ si ayé lati gbé Itẹ Ijọba Rè̩ kalẹ ninu eyi ti yoo jọba ni ododo ati agbára fun ẹgbẹrun ọdun. Ni ọjọ naa, gbogbo awọn Ju ti o wà laaye yoo kawọ iṣọtẹ wọn silẹ wọn yoo si tẹwọ gba Jesu gẹgẹ bi Messia wọn. Ni ọjọ naa a le sọ lotitọ pe: “Ẹ sọọrọ itunu fun Jerusalẹmu, ki ẹ si ké si i pe, ogun jijà rẹ tán, pe, a dari aiṣedede rẹ ji: nitoripe o ti gbà nigba meji lati ọwọ Oluwa wá fun è̩ṣẹ rè̩ gbogbo” (Isaiah 40:2). Bi o ba ṣe pe awọn Ju ti gba Jesu Kristi ni Messia wọn, wọn ki ba ti ri ijiya, inilara ati inunibini ti wọn ti fara dà lati ọjọ yii wá, itunu Ọlọrun ni iba si jé̩ ipin wọn.

Otitọ yii kan naa ni o ba ọkàn olukuluku keferi wi lọjọ oni. ỌrọỌlọrun le jẹ ohun-elo si iye ainipẹkun tabi ohun-elo si iparun ọkàn. Ẹni ti o ba kọ lati sin Kristi ki o si gbọran si ỌrọỌlọrun n fa oriṣiriṣi wahala sori ara rè̩ ninu ayé, ti o ba si taku sinu iwa-ọtẹ rè̩ yii yoo jiya ayeraye ninu adagun iná; ṣugbọn ẹni ti o ba fi tọkàntọkàn sin Kristi, oun ni a fi ileri iye isisiyi fun ati ti ayé ti n bọ. Gbogbo ayé ni Ọlọrun ranṣẹọrọ itunu si, ṣugbọn yoo jé̩ fun kiki awọn ti o ba gbàá.

Ẹmi ati Agbára Elijah

“Wò o, emi o rán woli Elijah si nyin, ki ọjọ nla-nlà OLUWA, ati ọjọ ti o li è̩ru to de” (Malaki 4:5). Nigba ti Jesu n sọ nipa ireti awọn Ju, O wi bayii pe: “Mo wi fun nyin pe, Elijah ti de na, nwọn kò si mọọ, ṣugbọn nwọn ti ṣe ohunkohun ti o wù wọn si i. Gẹgẹ bḝ na pẹlu li Ọmọ-enia yio jiya pupọ lọdọ wọn. Nigbana ni o yé awọn ọmọ-ẹhin rè̩ pe, Johannu Baptisti ni ẹniti o nsọrọ rè̩ fun wọn” (Matteu 17:12, 13). Angẹli nì sọ asọtẹlẹ nipa Johannu pe: “Ẹmi ati agbara Elijah ni on o si fi ṣaju rè̩ lọ, lati pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ti awọn alaigbọran si ọgbọn awọn olõtọ; ki o le pèse enia ti a mura silẹ dè Oluwa” (Luku 1:17).

Eredi ẹmi ati agbára Elijah? Elijah jé̩ aṣoju awọn wolii Majẹmu Laelae, gẹgẹ bi Mose ti jé̩ aṣoju Ofin. Bi Johannu ti n bọ ni agbára ati ẹmi aṣoju awọn wolii, o di àye oyè kan, bi o ti jẹẹni ikẹyin ninu awọn wolii Majẹmu Laelae bẹẹ ni o si tun jẹ ipilẹ ti Majẹmu Titun. “Ofin ati awọn woli mbẹ titi di igba Johannu: lati igba na wá li a ti nwasu ijọba Ọlọrun, olukuluku si n fi ipá wọ inu rè̩” (Luku 16:16).

Iru Ẹmi kan naa ti Elijah ni li o n tọ, ti o si n dari Johannu Baptisti, iṣẹ-iranṣẹ wọn si fẹrẹ jé̩ bakan naa – lati yi ọkan awọn Ọmọ Israẹli pada si Ọlọrun wọn. Elijah gbadura bayii pe: “Gbọ ti emi, OLUWA, gbọ ti emi, ki awọn enia yii ki o le mọ pe, Iwọ OLUWA, li Ọlọrun, ati pe, Iwọ tún yi ọkàn wọn pada” (1 Awọn Ọba 18:37). Angẹli nì sọ nipa Johannu Baptisti pe “On o si pa pipọ dà ninu awọn ọmọ Israẹli si Oluwa Ọlọrun wọn” (Luku 1:16). Igbesi-ayé Elijah ati Johannu Baptisti ri bakan naa – adado ninu aginju, lai si ohun meremere ti igbesi-ayé irọrun ati lai wáọpọ ounjẹ ti o le gbé ara ró. Iwaasu awọn mejeeji muna pẹlu ỌrọỌlorun ti o gbona; awọn mejeeji ni o duro niwaju ọba ati awọn alaṣẹ lati tako è̩ṣẹ; awọn mejeeji ni a si ṣe inunibini si nitori ti wọn n fi itara sọrọ lai bẹru. Jesebeli halẹ, o si gbiyanju lati gba ẹmi Elijah kuro, bakanna ni Herọdia pete titi ọwọ rè̩ fi tẹ Johannu Baptisti ti o si pa a. Iwa ati iṣe Elijah ati Johannu Baptisti jọ ara wọn to bẹẹ gẹẹ ti awọn Ju fi rán awọn alufaa ati Lefi lọ lati beere lọwọ Johannu Baptisti bi oun ni Kristi tabi Eliasi (ti a n pe ni Elijah ni ede Griki). Johannu dahun pe oun ki i ṣe Kristi tabi Eliasi, ṣugbọn pe oun ni “Ohùn ẹniti nkigbe ni ijù, Ẹṣe ki ọna Oluwa tọ” (Johannu 1:23). Dajudaju Johannu Baptisti wá ni agbára ati ẹmi Elijah.

Kò si Ojusaju

Ọlọrun ki i ṣe ojusaju eniyan. Ẹnikẹni ti o ba le san ohun ti yoo gba a le ṣe iṣẹ ribiribi fun Ọlọrun ninu Ihinrere. Owo wa kò le ra agbára ati ojurere Ọlọrun, nitori igbesi-ayé ti a yà sọtọ ni Ọlọrun n fé̩ lati lò. Elijah ati Johannu Baptisti ta ara ati ifẹ wọn, wọn si fi ẹbun Ọlọrun ti i ṣe ododo, aanu ati agbára ṣe iṣura. Jesu sọ nipa Johannu Baptisti pe: “Kini ẹnyin jade lọ iwò ni ijù? Ifefe ti afẹfẹ nmi?” (Matteu 11:7). Bẹẹ kọ, Johannu ki i ṣe ifefe ti afẹfẹ n mi, nitori ti iwaasu Johannu ti o kun fun imisi Ẹmi Ọlọrun duro ṣinṣin lai mì-sihin-mì-sọhun. Iba ṣe pe Johannu jé̩ọlọrọ meji ni, awọn eniyan ki ba ti fi ile ati ọna wọn silẹ ki wọn si wá si aginju lati gbọọrọ iwaasu rè̩. Dajudaju awọn eniyan naa wá -- eyi fi idi rẹ mulẹ pe bi oniwaasu bá kún fún Ẹmi Ọlọrun, awọn eniyan yoo wá lati gbọ iwaasu rè̩.

Ibeere Jesu lọ siwaju si, “Ọkunrin ti a wọ ni aṣọ fẹlẹfẹlẹ?” Bẹẹ kọ, ni aafin ọba ni a gbe ti le ri awọn ti a wọ ni aṣọ fẹlẹfẹlẹ, ki i ṣe awọn ti n ṣiṣẹ ninu ọgba ajara Oluwa ikore. Ihinrere n fẹ pe ki awọn ti o ba gba a fi tifẹtifẹ fi ara wọn rubọ. “Bi ẹnikẹni ba fẹran aiyé, ifẹ ti Baba kò si ninu rè̩” (1 Johannu 2:15). Jesu pari ibeere Rẹ bayii pe, “Woli? Lõtọ ni mo wi fun nyin, o si jù wolĩ lọ .. Lõtọ ni mo wi fun nyin, .. kò si ẹniti o ti idide jù Johannu Baptisti lọ; ṣugbọn ẹniti o kere ju lọ ni ijọba ọrun o pọ ju u lọ” (Matteu 11:9, 11). Ẹni ti o kere ju lọ ni Ijọba Ọrun -- ẹnikẹni ti a tunbi tootọ nipa Ẹjẹ Jesu, ti igbesi-ayé rè̩ si jé̩ gẹgẹ bi ỌrọỌlọrun -- pọ ju Johannu Baptisti. Nipa bayii Jesu tọka si ipe giga ati ipo ifọkan tán ti a fi Onigbagbọ tootọ si ninu eto iyanu nla ti Ọlọrun. Njẹ awa gẹgẹ bi Onigbagbọ n ṣe oloootọ si ipè wa gẹgẹ bi Ọlọrun ti n fẹ lọwọ wa?

Kanju-kanju

Nigba ti Ẹmi Oluwa n sọrọ lati ẹnu wolii Isaiah, O fi aidaniloju ayé han ni ati bi iṣẹ Ihinrere ti fé̩ ikanju tó. A fi eniyan we koriko, ati ireti ayé rè̩ wé itanna eweko igbẹ. Bi a ba fi oju ayeraye wòó, ootọ patapata ni ọrọ yii. Lai si ifẹ ati aanu Ọlọrun lati dá si ati lati daabo bo awọn ọmọ-eniyan, kò si ẹni ti yoo le lo ọjọ ti a dá fun un pé. O ṣe danindanin pe a ni lati waasu Ihinrere pẹlu ileri iye ainipẹkun nipa etutu ti Jesu ṣe nipa irubọ ikú Rè̩ ati ajinde iṣẹgun Rè̩.

Ọlọrun ni ohun elo aayo -- awọn Ẹni Irapada Rè̩ -- ti yoo fi tan Ihinrere ká gbogbo ayé. Ihinrere ti igbala ti lu agogo ninu ọkàn awọn eniyan, a si ti kede rè̩ ni oriṣiriṣi ọna lati akoko ti Jesu ti goke re Ọrun. Awọn ẹgbé̩ Onigbagbọ kin-in-ni kere nitootọ, ṣugbọn akitiyan wọn, agbára ati okiki wọn tànka gbogbo orilẹ-ède. Lọjọ oni, ọna Kristi ni o ṣe pataki jù lọ, ki i ṣe fun Onigbagbọ kọọkan nikan bi ko ṣe fun gbogbo aimọye ọkẹ olugbe ayé. Olukuluku eniyan ni o ni ẹmi ti yoo wà titi lae yala ni Ọrun tabi ninu adagun iná. Lati ni idaniloju pe ibugbe oun ni ayeraye yoo wà pẹlu Ọlọrun ni Ọrun, oluwarẹ ni lati ni igbagbọ ninu Jesu Kristi ki o si pa gbogbo ofin Rè̩ mọ, “Kò si si igbala lọdọẹlomiran: nitori kò si orukọ miran labẹọrun ti a fi funni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là” (Iṣe Awọn Apọsteli 4:12). Nipa bayii, a le ri bi iṣẹ Ihinrere ti n fé̩ kanjukanju tó ati bi ajaga ati tan Ihinrere ti wà lọrun awọn ẹni ti o ti gba ifẹỌlọrun si ookan aya wọn.

Kò tó Nnkan, ṣugbọn Aikú ni

“Nigbati mo ròọrun rẹ, iṣẹ ika rẹ, oṣupa ati irawọ, ti iwọ ti ṣe ilana silẹ. Kili enia, ti iwọ fi nṣe iranti rè̩? ati ọmọ enia, ti iwọ fi mbè̩ẹ wò” (Orin Dafidi 8:3, 4). Wolii Isaiah pẹlu sọrọ lori iṣẹ iyanu Ọlọrun alagbara ati ainilaari ọmọ-eniyan, “Kiyesi i, awọn orilẹ-ède dabi iró kan ninu omi ladugbo, a si kà wọn bi ekúru kiun ninu iwọn: kiyesi i o nmu awọn erekùṣu bi ohun diẹ kiun” (Isaiah 40:15). A fi ootọ yii hàn pe eniyan jẹ ohun kekere laaarin awọn ẹda Ọlọrun; a fi bi Ọlọrun ti rẹ ara Rè̩ silẹ lati kiyesi eniyan, ki ba ti si ohun ti eniyan le ṣe lati ri ojurere Ẹlẹda. S̩ugbọn Ọlọrun ka awọn ọmọ-eniyan si – ikasi ti o kọja eyi ti eniyan paapaa ka ara rè̩ si lọ. Ọlọrun ni o mú ki eniyan wa laaye, O si mọ ero ati iṣe olukuluku eniyan. “Ọlọrun yoo mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ikọkọ, ibaa ṣe rere, ibaa ṣe buburu” (Oniwasu 12:14). “Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣi awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe iye: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe naa, gẹgẹ bi iṣẹ wọn” (Ifihan 20:12).

Imúlọkànle

Bi o ba ṣe pe nipa iṣẹ rere ẹni ni eniyan fi le ri igbala, tabi bi eniyan yoo bá gbẹkẹle iṣẹọwọ rè̩ lati lọ si Ọrun, ireti ki bá ti si; ṣugbọn Onigbagbọ tootọ fi igbẹkẹle ati ireti rè̩ sinu eto igbala Ọlọrun. “Kiyesi i, ọwọ OLUWA kò kuru lati gba ni, bḝni eti rè̩ kò wuwo ti ki yio fi gbọ” (Isaiah 59:1). “Emi kò sọrọ ni ikọkọ ibi okùnkun aiyé: Emi kò wi fun iru ọmọ Jakobu pe, Ẹ wá mi lasan: emi OLUWA li o nsọ ododo, mo fi nkan wọnni ti o tọ hàn” (Isaiah 45:19). “Iwọ kò ti imọ? iwọ kò ti igbọ pe, Ọlọrun aiyeraiye, OLUWA, Ẹlẹda gbogbo ipẹkun aiye, ki iṣārẹ, bḝ ni ārè̩ ki imu u? kò si awari oye rè̩. O nfi agbara fun alārè̩; o si fi agbara kún awọn ti kò ni ipá. Ani ārè̩ yio mu awọn ọdọmọde, yio si rè̩ wọn, ati awọn ọdọmọkunrin yio tilẹṣubu patapata: S̩ugbọn awọn ti o ba duro de OLUWA yio tun agbara wọn ṣe; nwọn o fi iyé̩ gùn oke bi idi; nwọn o sare, kì yio si rè̩ wọn: nwọn o rin, ārè̩ ki yio si mu wọn” (Isaiah 40:28-31). Ha! Ileri ologo, awọn ẹni ibukun ti n rin ninu imọlẹ, ati ifẹ Oluwa Ọlọrun! Bawo ni eniyan ṣe le kọ ipè Ihinrere Oluwa ti o kún fún iyanu bayii?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ọna wo ni wolii naa fi ṣeleri itunu fun awọn Ọmọ Israẹli ati Jerusalẹmu?

  2. 2 Tani “ohùn ẹniti nkigbe ni ijù”?

  3. 3 Bawo ni ohùn ti n kigbe ni iju ṣe bá eto Jesu ati ti Ihinrere dọgba?

  4. 4 Alaye wo ni a ṣe ninu ẹkọ yii nipa kikuru igbesi-ayéọmọ eniyan?

  5. 5 Ki ni ṣe ti wo ni o fi jé̩ pataki fun eniyan lati fi igbesi-ayé rè̩ sin Ọlọrun nigba ti o wà laaye?

  6. 6 Ki ni itumọọrọ yii “Olodumare” tabi “alagbara ailopin”?

  7. 7 Tọka si awọn ẹsẹ wọnni ninu ẹkọ yii ti o fi hàn pe Ọlọrun wa ni O ni gbogbo agbára.

  8. 8 Ki ni a fi awọn orilẹ-ède wé niwaju Ọlọrun?

  9. 9 Iwuri wo ni a fi fun awọn ti yoo gbẹkẹ wọn le Ọlọrun?