Lesson 340 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ fi ogo fun OLUWA, ti o yẹ fun orukọ rè̩; ẹ ma sin OLUWA ninu ẹwà iwa-mimọ” (Orin Dafidi 29:2).Notes
Irannileti
Ni ọjọ nla ni ti awọn Ọmọ Israẹli fi Egipti silẹ patapata, Ọlọrun dá ajọ kan silẹ ti a n pè ni Ajọ Irekọja. Wọn ni lati maa ṣe ajọ yii ni ọdọọdun lati rán awọn Ọmọ Israẹli leti oore Ọlọrun si wọn ni mimu wọn jade kuro ni oko-ẹrú.
Ọpọlọpọọdun ti kọja lọ lẹyin ọjọ yii, awọn Ọmọ Israẹli kò si pa ajọ yii mọ. Ki i ṣe pe wọn gbagbe igbalà nla yii nikan, ṣugbọn wọn ti gbagbe Ọlọrun tikara Rè̩. Dipo ki wọn sin Ọlọrun, wọn n sin oriṣa; Ọlọrun si rán idajọ gbigbona si wọn nitori è̩ṣẹ wọn.
Awọn orilẹ-ède ajeji wá si ilẹ Kenaani wọn si kóọpọlọpọ ninu awọn Ọmọ Israẹli lẹrú. Mose ti sọ fun awọn baba nla wọn pe eyi ni ohun ti yoo ṣẹlè̩ si wọn bi wọn ba kọỌlọrun silẹ. Mose sọọpọlọpọ ibukun ti yoo jé̩ ti wọn bi wọn bá gbọran si Ọlọrun lẹnu; bakan naa ni o si tun sọègún ti yoo wá sori wọn bi wọn kò bá gbọran (Deuteronomi 28). Kò si ẹni ti o le ṣàigbọran si ofin Ọlọrun ti ki yoo jiya. Ijiya le ṣai de lẹsẹkẹsẹ, ṣugbọn mọ daju péè̩ṣẹ rẹ yoo wáọ ri.
Israẹli kọ eti didi si gbogbo ikilọ wọnni, wọn sin ọlọrun miiran, bẹẹ ni ègún ikólọ si igbekùn si ṣẹ si wọn lara. Ọlọrun ti kilọ pe: “OLUWA yio si mu ọ di ẹni ikọlù niwaju awọn ọtá rẹ: iwọ o jade tọ wọn lọ li ọna kan, iwọ o si sá niwaju wọn li ọna meje: a o si ṣi ọ kiri gbogbo ijọba aiyé” (Deuteronomi 28:25). Ọrọ wọnyii bẹrẹ si ṣẹ si wọn lara diẹdiẹ to bẹẹ ti o fi jẹ pe ni ọjọ oni, a le ri awọn ọmọ wọn ni gbogbo orilẹ-ède kaakiri ayé.
Aanu Ọlọrun
Aanu Ọlọrun n tọ awọn eniyan Rè̩ lẹyin ninu idaamu wọn. Nigba ti ògo Israẹli de gongo ni akoko ijọba Sọlomọni, Ọlọrun ṣeleri pe bi awọn eniyan tilẹ kọ Oun silẹ ti Oun si jẹ wọn niyà, sibẹ bi wọn bá rẹ ara wọn silẹ ti wọn si gbadura, bi wọn bá ronupiwada, Oun yoo dariji: “Bi awọn enia mi ti a npe orukọ mi mọ, ba rẹ ara wọn silẹ, ti nwọn ba si gbadura, ti nwọn ba si wá oju mi, ti nwọn ba si yipada kuro ninu ọna buburu wọn; nigbana ni emi o gbọ lati ọrun wá, emi o si dari è̩ṣẹ wọn ji, emi o si wò ilẹ wọn sàn” (2 Kronika 7:14).
Ma ṣe gbagbe pe O sọ wi pe wọn ni lati yipada kuro ninu ọnà buburu wọn bi wọn bá fé̩ ni ibukun Ọlọrun. Ọpọlọpọ eniyan ni òde-oni ni o lero pe wọn le jé̩ Onigbagbọ ki wọn si maa dẹṣẹ sibẹ. Jesu wi pe, “Mā lọ, má dẹṣè̩ mọ.” Bi ẹnikẹni ba fé̩ ni ibukun Ọlọrun, o ni lati ronupiwada ki o si yipada kuro ninu ẹṣẹ rè̩. Didun inu Ọlọrun ni lati gbọ ki eniyan gbadura wi pe, “S̩aanu fun mi, si dariji mi” bi awọn ọrọ wọnyii bá ti odo ọkàn jade wá.
Ododo Hesekiah
Awọn ọba buburu ti mú Israẹli ati Juda dé̩ṣè̩. Lati igba ti orilẹ-ède yii ti pin si meji, kò si ọba rere ni Israẹli. S̩ugbọn Juda ni anfaani lati wà labẹ awọn ọba rere diẹ. Nigba ti Hesekiah bẹrẹ si jọba ni Juda, “O si ṣe eyiti o tọ li oju OLUWA, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Dafidi, baba rè̩, ti ṣe” (2 Kronika 29:2). Wo iyipada ti eyi mu bá Juda! Wọn gbá Tẹmpili, wọn si tun pada si isin otitọỌlọrun lẹẹkan si i. Eyi mú ki inu awọn eniyan ki o dùn.
Hesekiah mọ nipa ofin Ajọ Irekọja ti a fi lelẹ niwọn ẹgbẹrin ọdun (800) sẹyin. Inu rè̩ bajẹ pe a kò pa àjọ yii mọ fun ọdún pupọ. O fẹṣe ohun ti Ọlọrun palaṣẹ, nitori naa o fi iwe ranṣẹ, ki i ṣe si kiki ẹya Juda ti o n jọba le lori nikan, ṣugbọn si gbogbo Israẹli pẹlu, o si pe wọn lati wá si Jerusalẹmu fun Ajọ Irekọja.
Hesekiah kò beere pe ki awọn eniyan Israẹli dara pọ mọ ijọba oun, ki wọn si ṣeleri lati fara mọ oun. Akoso ijọba kọ ni o ṣe pataki fun un bi iṣẹ-isin Ọlọrun. O fẹ ki a gba ọkàn awọn enyan naa là, ki wọn ba le lọ si Ọrun ki wọn si ni ìyè ainipẹkun. Akoko wa nihin kúrú pupọ, o si ṣe pataki fun wa lati lo akoko wa lati mura silẹ fun ayeraye.
Ọjọ Ajọ Naa
Ofin ti a fi fun Mose ni pe a ni lati bẹrẹ ajọ yii lati ọjọ kẹrinla oṣu kin-in-ni. Wọn ni lati ya ọdọ-agutan fun ẹbọ naa sọtọ tẹlẹ ki wọn ba le ni anfaani lati ri i bi abuku ba wà lara ẹran naa laaarin ọsè̩ meji wọnni.
Gbigbá Tẹmpili ati yiya awọn alufaa si mimọ jẹ ohun ti a ni lati mu ṣe laaarin akoko kukuru to bẹẹ ti kò fi si anfaani tó lati ṣe gbogbo imurasilẹ. Mose ti sọ tẹlẹ pe bi ko ba ṣe e ṣe lati pa ajọ naa mọ ni oṣu kin-in-ni, wọn le ṣe e ni oṣu keji. Hesekiah bá awọn ijoye ati diẹ ninu awọn ijọ eniyan gbimọ, wọn si pinnu lati pa ajọ yii mọ ni oṣu keji. Wọn fé̩ lati ni idaniloju pe nigba ti wọn ba wá siwaju Ọlọrun lati jọsin, wọn o wà ni ipò ti Ọlọrun yoo fi bukun fun wọn. Ki i ṣe kiki pe ki wọn gbá Tẹmpili nikan ni wọn ni lati ṣe, wọn ni lati ni iyipada ọkàn pẹlu.
Ohun nla ni eyi jé̩. Lẹyin ipe lati wá si ajọ, a tun gba awọn eniyan niyanju lati yipada kuro ninu è̩ṣẹ wọn ki wọn si yipada si Ọlọrun. Wọn kò ni ri ire ninu Ajọ Irekọja naa bi wọn ba wà ni ipòè̩ṣẹ. Eyi tayọ ipejọpọ nibi ti ọré̩ n pade ọré̩ lati jumọ ta okúọrọ sọ. Akoko yii ni lati jé̩ akoko isin ọwọ ninu eyi ti awọn eniyan yoo wá gbà ibukun Ọlọrun ati lati ni idapọ pẹlu Rè̩.
Nigba ti a ba pejọ fun Ajọ Agọ ti i ṣe ipade nla, a maa n ri ibukun gbà lọpọlọpọ bi a ba gbadura ṣaaju akoko yi, ti a si bẹỌlọrun lati ṣiṣẹ laaarin wa. Nigba ti a ba pese ọkàn wa silẹ fun àsè ti ẹmi nipa bibáỌlọrun sọrọ, a o jé̩ ibukun fun awọn ẹlomiran, awa paapaa yoo si pada pẹlu agbára ọtun.
Alabukun ninu S̩iṣe Nnkan Wọnyii
Nigba ti Jesu dá Ounjẹ Alẹ Oluwa silẹ, eyi ti a n ṣe dipo Ajọ Irekọja O wi pe, “Bi ẹnyin ba mọ nkan wọnyi, alabukun-fun ni nyin, bi ẹnyin ba nṣe wọn.” Ayọ a maa jé̩ ti wa nigba ti a ba pa aṣẹỌlọrun mọ ni ọna ti Rè̩. Paulu Apọsteli kilọ fun awọn eniyan ki wọn máṣe jẹ Ounjẹ Alẹ Oluwa bi wọn ba wà ni ipo è̩ṣẹ. Eyi yii yoo mú ijiya wá sori wọn. S̩ugbọn nigba ti ọmọỌlọrun kan ba wá sibi tabili Oluwa ti o si n ṣe aṣaro nipa alẹọjọ naa ti a fi Jesu hàn, oun yoo ri ọpọ ibukun gbà. Ki i ṣe kiki ẹbọ ti Kristi fi ara Rè̩ rú nikan ni a ni lati bojuwo è̩yin wò, ṣugbọn a n wọna fun ọjọ naa ti a o ba A jẹun ni Ijọba Rè̩.
Hesekiah rán awọn eniyan naa leti ileri ti Ọlọrun ti ṣe fun wọn bi wọn bá jé̩ ronupiwada. Ọpọlọpọ awọn Ọmọ Israẹli wà ni oko-ẹrú nigba yii. Bi awọn ti o kù yoo ba fi gbogbo ọkàn wọn wáỌlọrun, Oun yoo mú awọn eniyan wọn pada bọ.
Iwọ le ro pe gbogbo eniyan ni yoo ronupiwada ti wọn yoo si bẹrẹsi gbadura nigba ti wọn ri iwe yii gbà. Ireti tun sọji pe Ọlọrun yoo ràn wọn lọwọ. S̩ugbọn dipo eyi, wọn fi awọn eniyan ti o mu ihin yii wa ṣe ẹlé̩yà, “nwọn fi wọn rẹrin ẹlẹya.” Ohun kan naa ha kọ ni awọn ẹlẹṣẹ n ṣe ni ode-oni.
Ayé kò fi igba kan fé̩ gbọ ti Ihinrere. O dabi ẹni pe ọkàn ọmọ-eniyan kun fun kiki ibi nigba gbogbo; iwọn iba eniyan diẹ ni o n lakàkà lati ri igbala. Wò bi inu awa ti a ti fi ọkàn wa fun Ọlọrun ti a si mọ pe a n reti bibọ wa ni Ọrun ti dùn pọ tó! Ayọ awa pẹlu ti pọ tó lati ri i pe awọn ẹlomiran ri igbala!
A ko ṣai ri iwọn iba eniyan diẹ ti o n jẹ ipe Ihinrere ni gbogbo igba ati akoko. Diẹ ninu awọn ti wọn ri iwe yii gbà ni Israẹli ṣetan lati gbọran si aṣẹỌlọrun, wọn si wá si Jerusalẹmu lati pa Ajọ Irekọja mọ.
Awọn ẹya Juda tete tẹwọgba ipe naa ju awọn iyoku lọ. Ọpọlọpọ ninu wọn wá si Jerusalẹmu lati jumọ bá wọn kó iyoku pẹpẹ oriṣa jade ati lati pa wọn run.
Isin Atọkanwa
Ki i ṣe kiki pẹpẹ oriṣa ni a ni lati wó lulè̩ ki a si wẹ Tẹmpili mọ, awọn eniyan pẹlu ni lati wẹ ara wọn mọ fun Ajọ Irekọja. S̩ugbọn àye kò si tó fun awọn eniyan lati pa gbogbo ilana iwẹnùmọ ti ode-ara mọ ni kikun, o si ni lati jẹ pe ajakalẹ-arun kọlu awọn eniyan diẹ nitori ti wọn jẹ Irekọja lai ṣe iwẹnumọ ti o yẹ ki wọn ṣe. Hesekiah gbadura pe ki Ọlọrun dári aiṣe iwẹnumọ ode-ara wọnyii ji, ki O si wo awọn eniyan naa sàn. Ọlọrun gbọ adura rè̩ nitori ọkàn awọn eniyan naa yipada si Ọlọrun, eyi ni si ṣe pataki ju isin ode-ara lọ. Isin atọkanwa ni Ọlọrun n fé̩.
Igba kan wà ni igbesi-ayé awọn Ọmọ Israẹli ti wọn bojuto gbogbo ọjọ ase ati ilana isin, ṣugbọn ọkàn wọn jinna si Ọlọrun. Ọlọrun sọ nigba naa pe: “Ẹ má mu ọrẹ asan wá mọ: turari jasi ohun irira fun mi; oṣù titun ati ọjọ isimi, ipè ajọ, emi kò le rọju gbà” (Isaiah 1:13, 14). Awọn eniyan n fẹ lati sin Ọlọrun pẹlu è̩ṣẹ ninu ọkàn wọn. S̩ugbọn Ọlọrun fé̩ ki wọn jé̩ mimọ, “Ẹ wè̩, ki ẹ mọ; mu buburu iṣe nyin kuro niwaju oju mi: dawọ duro lati ṣe buburu; kọ lati ṣe rere” (Isaiah 1:16, 17).
Yiyọ ninu Oluwa
Ọlọrun gbọ adura Hesekiah, O ri i pe awọn eniyan jé̩ oloootọ, O si tú ibukun Rè̩ dà sori awọn ti o ti pese ọkàn wọn silẹ lati wá A. Ọjọ meje ni wọn fi n jẹwọè̩ṣẹ wọn, wọn si n ri ibukun Ọlorun gbà. Wọn pa ajọ aiwukara mọ pẹlu “ayọ nla; awọn ọmọ Lefi ati awọn alufa yin OLUWA lojojumọ, wọn nfi ohun-elo olohùn goro kọrin si OLUWA.” Awọn ọmọ Lefi si kọ awọn eniyan naa ni “imọ rere OLUWA.” “A! ijinlẹọrọ ati ọgbọn ati imọỌlọrun! Awamáridi idajọ rè̩ ti ri, ọna rè̩ si jù awari lọ!” (Romu 11:33).
Yatọ si igba ijọba Sọlomọni, awọn Ọmọ Israẹli kò layọ to bayii ri. Wọn ti yipada si Ọlọrun wọn si n sin In gẹgẹ bi aṣẹ rè̩. Eyi ni orisun alaafia tootọ. Lẹyin ọjọ meje, wọn tun pinnu lati duro ni ọjọ meje si i. Olukuluku eniyan ni o layọ ati awọn alejo ti wọn tilẹ wà ni Jerusalẹmu pẹlu.
Lakotan, asè nla naa pari, awọn eniyan si pada si ile wọn. Wo ire ti wọn ti ri gbà nitori pe wọn wá! Wọn tun fi oju kan ara wọn, wọn si sin Ọlọrun ninu iṣọkan igbagbọ. Wọn ni ipinnu ọtun lati fara mọ isin otitọ, nibikibi ti wọn ba si ti ri oriṣa ati pẹpẹ oriṣa, wọn a wo o lulẹ.
Wọn layọ nitori pe wọn mu ifẹỌlọrun ṣẹ. Ọlọrun a maa bukun wa nigba ti a ba jọwọ ohun gbogbo fun Un.
Isọji yii ṣilẹkun igba titun silẹ fun isin otitọ ni Jerusalẹmu. Hesekiah fi idi ijọ kalẹ ati eto isin awọn alufaa, iranlọwọ fun awọn alufaa nipa idamẹwaa, ati ohun gbogbo ti a ni lati ṣe lati sin Ọlorun ni ọna ti o ṣe itẹwọgbà. Gbogbo eyi ti Hesekiah ṣe ni o ṣe tọkàntọkàn, Ọlọrun si mu ki o ṣe rere ati awọn Ọmọ Israẹli pẹlu.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ajọ wo ni Hesekiah fẹṣe ni Jerusalẹmu?
2 Nigba wo ni a kọ dá ajọ yii silẹ?
3 O ti pé̩ tó ti wọn ti ṣe ajọ yii kẹyin?
4 Ki ni awọn Ọmọ Israẹli ṣe lati murasilẹ fun ajọ naa?
5 Bawo ni awọn eniyan ṣe gba ihin yii ni Israẹli ati Juda?
6 Ki ni ṣẹlẹ ni ibi ajọ naa?
7 Bawo ni ajọ yii ti pé̩ tó?
8 Iru isin wo ni o ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun?
9 Ki ni Hesekiah ṣe lẹyin ajọ naa?