Filippi 4:8

Lesson 341 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ka iṣẹ rẹ le OLUWA lọwọ, a o si fi idi iro-inu rẹ kalẹ” (Owe 16:3).
Notes

Episteli

Paulu ti bẹ ilu ti a n pe ni Filippi ni Makedonia wò ninu irin-ajo rè̩ ikeji ati ikẹta fun itankalè̩ Ihinrere. Ninu adura rè̩, o dupẹ lọwọỌlọrun fun iranti ti o mayọ kún ọkàn rè̩ nipa awọn ọmọ-ẹyin ti o wà nibè̩, ati fun idapọ mimọ wọn (Filippi 1:3-5). Awọn ọmọ-ẹyin ti o wa ni Filippi pẹlu ṣe iranti Paulu. Wọn fi ọrẹ ranṣẹ si i lati fi ṣe iranlọwọ fun un ninu iṣẹ itankalẹ Ihinrere ti o n ṣe. Ni akoko kan wọn fi ọrẹ wọn rán ẹni kan ti a n pe ni Epafroditu. Nigba ti Paulu kọ iwe idúpé̩ si awọn ara Filippi o wi bayii pe: “Mo si kún nigbati mo ti gbà nkan wọnni ti a ti rán lati ọdọ nyin wá lọwọ Epafroditu, ọrẹ olõrùn didùn, ẹbọ itẹwọgbà, ti iṣe inu didùn gidigidi si Ọlọrun” (Filippi 4:18).

Iwe ti a n pe ni Filippi ni Episteli Paulu si ijọ ti o wà ni Filippi. Ọlọrun mi si Paulu lati kọọ, awọn ọmọ-è̩yin Jesu si ti ri itọni ati iwuri gbà ninu rè̩ lati igba nì titi di oni-oloni.

Èrò

Iwe Paulu sọ nipa igbesi-ayé Onigbagbọ ati nipa diẹ ninu ojuṣe rè̩. Paulu ṣe akọsilẹ ohun wọnni ti o dara ti o si ṣanfaani fun awọn ti a gbàlà lati maa ṣe aṣaro nipa rè̩. Erò Onigbagbọ yatọ si eyi ti o ti wà lọkàn rè̩ ki a to gbàọkàn rè̩ là. Bi Isaiah ti n pé awọn eniyan si ironupiwadà, o wi pe: “Jẹ ki enia buburu kọọna rè̩ silẹ, ki è̩lẹṣẹ si kọ ironu rè̩ silẹ; si jẹ ki o yipada si OLUWA, on o si ṣanu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi ji lọpọlọpọ” (Isaiah 55:7). Ọlọrun sọ ní ti awọn eniyan Rè̩ pe: “Emi ó fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ wọn si ọkàn wọn” (Heberu 8:10).

Erò rere nikan kò le sọ eniyan di Onigbagbọ, ṣugbọn èrò buburu le sún eniyan dè̩ṣẹ. Lẹyin ti eniyan ba ti ri aanu ati idariji è̩ṣẹ rè̩ gbà, yoo fẹ ki alaafia yii ki o wà ninu ọkàn oun titi. Wolii Isaiah wi pe: “Iwọ o pa a mọ li alafia pipé, ọkàn ẹniti o simi le ọ, nitoriti o gbẹkẹle ọ” (Isaiah 26:3).

Dafidi pẹlu, mọ bi o ti ṣe ohun pataki tó fun Onigbagbọ lati ṣọèròọkàn rè̩. O gbadura pe ki aṣaro tabi èròọkàn rè̩ ati ọrọ oun pẹlu le jẹ itẹwọgbà fun Ọlọrun (Orin Dafidi 19:14). Dafidi bẹỌlọrun pe ki o yẹọkàn oun wò lati mọ bi ọna buburu kan ba wà ninu oun (Orin Dafidi 139:23, 24).

Ọlọrun mọèrò wa, O si ni akọsilẹ kan fun awọn ti o n ṣe aṣaro nipa Rè̩. Wolii Malaki wi pe: “Awọn ti o bè̩ru OLUWA mba ara wọn sọrọ nigbakugba; OLUWA si tẹti si i, o si gbọ, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rè̩, fun awọn ti o bè̩ru OLUWA, ti wọn si nṣe aṣaro orukọ rè̩” (Malaki 3:16).

Ohun ti i ṣe Otitọ

Gẹgẹ bi a ti ri i pe èrò wa ṣe ohun pataki, ki ni ohun ti o yẹ ki a maa ṣe aṣaro le lori? Paulu wi pe, “Ohunkohun ti iṣe õtọ … ẹ mā gba nkan wọnyi rò.” Ohun pupọ lode oni ni o jẹèké. Bawo ni a ṣe le mọ eyi ti i ṣe otitọ? Nigba kan nigba ti Jesu n gbadura ti O si n ba Ọlọrun sọrọ, O wi pe, “Otitọ li ọrọ rẹ” (Johannu 17:17). ỌrọỌlọrun ni Bibeli, otitọsi ni Bibeli. O n kọ ni pe awọn ileri Ọlọrun jé̩ otitọ. A ka a pe “idajọ OLUWA li otitọ, ododo ni gbogbo wọn” (Orin Dafidi 19:9). Awọn ileri Ọlọrun, nipa ibukun ati idajọ kun fun aṣaro rere lọpọlọpọ. S̩iṣe aṣaro lori awọn nnkan wọnyi ti o jẹ otitọ, yoo mu ki eniyan pinnu lọkan ara rè̩ lati fi ayé rè̩ fun Oluwa. Nigba naa yoo ni anfaani lati pe gbogbo awọn ibukun iyanu wọnni ti a ti ṣeleri ni ti rè̩.

Eke

Satani ni baba èké, kò si si otitọ ninu rè̩ (Johannu 8:44). Oun ni ọta ti ẹmi wa, oun yoo maa wáọna lati mu wa gba èké gbọ ati lati maa ṣe aṣaro nipa ohun ti ki i ṣe otitọ. Nigba ti iwọ ba n ṣaisan, o le maa mu ki o ni ero wi pe, Ọlọrun ki yoo wòọ san; ṣugbọn Oluwa wi pe, “Emi li OLUWA ti o mu ọ lara dá” (Ẹksodu 15:26).

Ẹ jẹ ki a wo apẹẹrẹẹni kan ti o n ṣe aṣaro nipa ohun ti ki i ṣe otitọ. Satani kó sinu ejò, o si tan Efa jẹ ninu ọgba Edẹni. O wi fun un pe, “Ẹnyin ki yoo kú ikú kikú kan” (Gẹnẹsisi 3:4). Ọlọrun ti wi pe: “Ninu igi imọ rere ati buburu nì, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rè̩: nitoripe li ọjọ ti iwọ ba jẹ ninu rè̩ kikú ni iwọ o kú” (Gẹnẹsisi 2:17). Nitori ti Efa gba è̩tan ti Satani gbé le e lọwọ rò, a dá an wò, o si dè̩ṣẹ. A yà a nipa kuro lọdọỌlọrun, bẹẹ ni o kú ikúẹmi. Ki i ṣe bẹẹ nikan, ṣugbọn è̩ṣẹ ti mú ki gbogbo eniyan di okú nipa ti ẹmi. Ọna kan ṣoṣo ti ẹnikẹni le fi di alaaye ni pe ki a gba ọkàn rè̩ là nipa Ẹjẹ Jesu.

Ẹ jẹ ki a maa ṣe aṣaro nipa ohun ti i ṣe otitọ. A sọ nipa Jesu pe, Oun ni “àjara tootọ” (Johannu 15:1), “onjẹ otitọ” (Johannu 6:32), ati “Imọlẹ otitọ” (Johannu 1:9).

Òtítọ

Otitọ jẹ ohun miiran ti o ni lati wà ninu èrò wa. Lati jé̩ oloootọ ni pe ki a jẹẹni ti o n huwa ti kò ni èrú ati ẹni ti o ṣe e fọkàn tan. A le fi ọkàn tan ẹni ti o n ṣe olotitọ lati huwa ẹtọ. Awọn eniyan ki i fi ọkàn tán alaiṣootọ. Siwaju sii awọn eniyan ki i fẹran awọn to n ṣèrú ti wọn kò si ṣe fọkàn tán. O ṣe pataki fun wa lati jé̩ oloootọ, ki a si maa ṣe aṣaro nipa iwa otitọ. O ṣe e ṣe nigba kan, ki ẹni kan maa ji iṣẹẹnikeji rè̩ kọ silẹ ni ile-iwe. Satani yoo fẹ lati mu ki awọn ọmọde miiran maa ronu nipa iwa aiṣootọ yii. Oun yoo sọ fun wọn pe o rọrùn yoo si gbà wọn niyanju lati ṣe bẹẹ pẹlu. Nigba ti wọn ba ròó, ti wọn si pinnu rè̩ tán, ohun ti yoo tẹle e ni pe wọn o ṣe e. Abajọ ti Paulu fi gbà wa niyanju lati maa ronu nipa ohun ti i ṣe otitọ.

Ẹtàn

Ninu Bibeli, a ri apẹẹrẹ awọn ti o ronu nipa ohun ti ki i ṣe otitọ. Awọn kan ninu awọn ọmọ-è̩yin n ta ohun ini wọn, wọn si n kó owó naa fun awọn Apọsteli. Anania ati iyawo rè̩, Safira, rò nipa ọna kan ti awọn le gbà fi ara han bi ẹni ti o n ṣe ohun kan naa. Wọn ta ohun ini wọn. Wọn gbèro wọn si fi imọṣọkan nipa ohun ti wọn o ṣe. Anania mu apa kan ninu owo naa tọ awọn Apọsteli wá. O si ṣe bi ẹni pe gbogbo owo naa ni. O huwa è̩tan ati aiṣootọ. Ikú ni ijiyà Anania ati Safira. Eké jẹ ohun ti kò dara, i baa ṣe pe a sọọ lẹnu tabi a hú u niwà. A ni lati jé̩ olotitọ, ki a si maa ronu nipa ohun ti i ṣe otitọ.

Titọ ati Mimọ

Lati jé̩ olotitọ, gẹge bi ofin Ọlọrun, ni lati jé̩ olododo ati ẹni diduro-ṣinṣin, ki igbesi-ayé wa si ṣe deedee pẹlu ilana ti a fi lelẹ ninu Iwe Mimọ. Lati jé̩ẹni mimọ ni lati wà lai ni è̩bi, alailè̩ṣẹ, ati alaileeri. Ronu nipa nnkan wọnyi. Iru iwe oriṣiriṣi ti eniyan n kà, aworan ati iran ti o n wò, ati iru orin ati itàn ti o n gbọ, a maa lagbara lori èro ọkàn rè̩. Agbára yii kò pin sori èro wa nikan, ṣugbọn o kan iwa wa ati iṣe wa pẹlu. Ọpọlọpọ awọn ọmọde ati ọdọ paapaa ni o hàn gbangba pé wọn ti huwa buburu ati iwa-ọdaran kan naa ti wọn ti ri ninu aworan sinima, tẹlifiṣọn, ati eyi ti wọn ti gbọ lori ẹrọ redio. Wọn rò nipa wọn, wọn ṣe àṣàrò lori wọn, wọn si dán wọn wò. Fun awọn miiran, irú nnkan bayii ti ṣe okunfa ikú wọn, tabi ikú fun awọn ẹlomiran ati ijiya fun awọn paapaa.

Máṣe rò pe eniyan le maa fi oju-kọrọ wo è̩ṣẹ ki ẹni naa si rò pe ohun ti oun ti ri kò ni i ṣe ohunkohun lọkàn oun. Eyi a maa fun Satani ni anfaani pupọ si i lati mu awọn ero aimọ ati aitọ wá sinu ọkàn eniyan ati lati dán oluwa rè̩ wò lati ṣe ibi. Ki ni ṣe ti eniyan ni lati fi ohun buburu ba ara rè̩ jẹ nigba ti ohun ti o mọ ti o si wu ni wà fun igbadun wa? Ki ni ṣe ti iwọ kò fi maa ka iwe ti o dara? Ki ni ṣe ti iwọ kò fi maa tẹti-lelẹ lati maa gbọ orin ti o dara? Ki ni ṣe ti iwọ kò le maa wo ohun wọnni ti Ọlọrun dá? Awọn wọnyi ki i dán ni wò lati dè̩ṣẹ. Awọn ohun ti è̩dáọwọỌlọrun – itanna inu ọgbà, oorùn ti nwọ ti o si rè̩ dodo, odo ti n ṣàn lẹgbẹ oke – gbogbo wọn ni o n yin Ọlọrun ni ọna ti wọn, wọn si n rán wa leti pe ki awa ki o ṣe bẹẹ gẹgẹ.

Awọn Ohun ti i ṣe Fifẹ

Ronu nipa awọn ohun ti i ṣe fifẹ! Ki ni i ṣe fifẹ? Awọn ohun ti o maa n rúọkàn wa soke lati fẹran ati lati sọrọ rere. Orin nipa aanu Ọlọrun, ọrọ arofọ nipa iké̩ Rè̩, aworan nipa igbesi-ayé Jesu -- awọn wọnyii kò ha n rúọkàn wa soke lati fẹran Rè̩ si i? Wo bi Jesu Kristi ti fẹran wa, to bẹẹ ti O fi ẹmi Rè̩ lelè̩ ki awa ba le ri igbala. Njẹ eyi kò ha mu ki o fẹran Rè̩? A fẹran Rè̩ nitori Oun ni o kọ fẹ wa.

Njẹ iwọ ha n rò nipa iwa rere ti o wà ninu awọn ẹlẹgbẹ rẹ ni ile-ẹkọ, awọn ọrẹ rẹ, ati awọn eniyan Ọlọrun? Satani ni olufisun awọn ará. O fẹ ki a maa rò nipa aṣiṣe ti ẹni kan ṣe, tabi ọrọ ailọgbọn ti ẹni kan sọ, tabi iwà ailọgbọn ti ẹni kan hù, tabi ohun ti o fara jọ ibi. Bi a ba gba iru èro bẹẹ láyè ninu ọkàn wa, wọn a maa mu ki a ni èrò ti kò tọ si ẹlomiran. “Bi ìwa-titọ kan ba wà, bi iyin kan ba si wà, ẹ mā gbà nkan wọnyi rò.” Diẹ ni awọn eniyan ti o wà ni ayé ti a kò le ri ohun kan ninu wọn eyi ti o dara ti a le fi yin wọn. Eniyan ni lati maa rò nipa iwà rere ati iwà ti o ni iyin ti o wà lara awọn Onigbagbọẹlẹgbẹ rè̩, ki o si gbadura tọkàntọkàn pe ki Ọlọrun ran olukuluku wọn lọwọ lati jé̩ Onigbagbọ tootọ, ẹni ti a fi idi rè̩ mulẹ ninu “ọrọ rere ati iṣẹ rere gbogbo.” Ẹ jẹ ki a maa rò nipa ohun wọnni ti yoo rú ifẹ wa soke si Ọlọrun ati awọn eniyan Rè̩.

Ti o ni Ihin Rere

Awọn Onigbagbọ a maa rò nipa ohun wọnni ti o ni ihin rere, dipo ki wọn maa rò nipa ohun wọnni ti o le mú wọn rè̩wè̩sì, ti o si le mu iyemeji kún inu wọn. Onigbagbọ kò gbọdọ feti si òfófó, ki a ma ṣẹṣẹ wá sọ wi pe ki o tilẹ ròó wò. Bibeli fun wa ni apẹẹrẹ awọn kan ti wọn gba ihin buburu rò. A rán awọn amí mejila lati lọ wò Ilẹ Kenaani. Nigba ti wọn pada bọ awọn amí mẹwaa fi iroyin buburu fun awọn eniyan, wọn sọ nipa awọn ilu-olodi ati awọn òmiran. Ọkan ninu awọn amí ti o mu ihin rere wá wi pe, “Ẹ jẹ ki a gòke lọ lḝkan ki a si gbà a; nitoripe awa le ṣé̩ẹ” (Numeri 13:30). Awọn eniyan naa kò rò nipa ileri Ọlọrun. Wọn gba ihin buburu rò, wọn gbá a gbọ, wọn si n rin kiri ninu aginju fun ogoji ọdún.

“Bi ìwa titọ kan ba wà, bi iyin kan ba si wà, ẹ mā gba nkan wọnyi rò.” Awọn ọrọ wọnyii kó gbogbo imọran miiran nipa èrò wa pọ. A lé mọèro rere tabi buburu lọna bayii: iwa titọ, iwa rere, tabi iwa ọmọ-luwabi ha wà ninu rè̩ bi? Iyin ha wà ninu rè̩, o ha ṣe e fara mọ, o ha ni ọlá bi?

Wiwọ inu Ọkàn

Eniyan le ṣalai-lagbara lati paṣẹ fun èro pe ki o máṣe wọ inu ọkàn oun, ṣugbọn oun le kọ lati gbà a làye lati duro nibẹ. Le èrò buburu wọnni jade ti Satani n fẹ lati fi sibẹ, ki wọn má ba wọ inu ọkàn rẹ lọ, wọn a si di è̩ṣẹ. A fi imọran yii ṣe apẹẹrẹ fun wa: Eniyan kò le sọ pe ki ẹyẹ máṣe fo kọja lori oun, ṣugbọn o le kọ fun ẹyẹ lati kọle si oun lori. È̩wè̩ o le ṣoro fun eniyan lati dáèro buburu duro pe ki o ma ṣe wọ inu ọkàn oun, ṣugbọn o le kọ lati gba wọn làye nipa ṣiṣe aṣaro lori ỌrọỌlọrun ati Ọlọrun. Nipa sisọọrọ inu Bibeli, Jesu mu ki eṣu fi Oun silẹ. A le mu awọn akọsori ti a ti kọ wá si iranti wa tabi awọn ẹsẹỌrọỌlọrun ti a n kà ninu Bibeli kika wa ojoojumọ; bi a si ti n fi iwọnyi kún inu ọkàn wa, eṣu yoo fi wa silẹ pẹlu.

Paulu wi pe: “Ẹ maa yọ ninu Oluwa nigbagbogbo: … Ẹ máṣe aniyàn ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupé̩, ẹ mā fi ibere nyin hàn fun Ọlọrun. Ati alafia Ọlọrun, ti o ju ìmọran gbogbo lọ, yio ṣọọkàn ati ero nyin ninu Kristi Jesu” (Filippi 4:4-7).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni kọ iwe yìí si awọn ara Filippi?

  2. 2 Nigba wo ni o bẹ Filippi wò?

  3. 3 Ki ni ohun ti a ranti nipa Lidia ati nipa onitubu ilu Filippi?

  4. 4 Ọna wo ni awọn ará Filippi gbà fi ranti Paulu?

  5. 5 Bawo ni Paulu tin ṣe iranti wọn?

  6. 6 Ki ni ohun ti èrò maa n ṣe ninu ọkàn?

  7. 7 Bawo ni èro wa ṣe le lagbara lori iwà wa?

  8. 8 Bawo ni a ṣe le mọèro rere ati buburu?

  9. 9 Darukọ awọn è̩dáọwọỌlọrun ti wọn n yin Ọlọrun, ti o si n fi hàn fun wa pe o yẹ fun wa lati maa ṣe bẹẹ pẹlu.

  10. 10 Darukọ awọn nnkan miiran ti o lagbara lori èrò wa.