Lesson 342 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA nikanṣoṣo li a o gbe ga li ọjọ na” (Isaiah 2:11).Notes
Ohun ti o S̩e Pataki Julọ
Bi akoko ti n kọja lọ ti ọjọ si n gori ọjọ, aniyan le wọ inu ọkàn rẹ fun ohun ti iwọ kò le ni. Boya iwọ n fé̩ lọjọ kan lati ni è̩kọ giga, tabi ifẹ lati rin irin-ajo lọ si ọna jijin lati ri ayé. O le ṣai ni anfaani lati ni awọn nnkan ti o fẹ ni, ṣugbọn awọn ohun kan wà ti iwọ ni lati ri i daju pe ó tè̩ọ lọwọ. Awọn ohun kan ṣe pataki to bẹẹ ti a kò gbọdọṣe alai ni wọn. Ẹ jẹ ki a farabalẹ lati ṣe àṣàrò nipa awọn ohun ti o ṣe pataki ju lọ láye.
A kọ ninu è̩kọ wa lai pẹ yii pe awọn Wolii Ọlọrun ti wọn kọ Bibeli ṣe bẹẹ nipa imisi Ẹmi Mimọ, ati pe gbogbo Ọrọ Iwe Mimọ ni a o muṣẹ. Isaiah, ọkan ninu awọn Wolii agba, kọ akọsilẹọpọlọpọ nnkan ti o n bọ wáṣẹ ni ọjọ iwaju. Ninu ori keji Iwe Wolii Isaiah, a kà awọn ọrọ diẹ ti Mika kọ silẹ, ẹni ti a kọè̩kọ nipa rè̩ ninu Ẹkọ 330. Wò bi iwọ ba le ri awọn ẹsẹỌrọ Bibeli miiran ti o lọ bakan naa. O ni lati jẹ pe o ṣe pataki ju lọ, bi bẹẹ kọỌlọrun kò ni sọ fun awọn Wolii Rè̩ meji, lati kọ awọn ọrọ kan naa silẹ. Gbogbo rè̩ ni otitọ, wọn o si ṣẹ; ṣugbọn akoko naa gan an ti yoo ṣẹlè̩ pamọ kuro loju wa (Matteu 24:36, 42).
Ipadabọ Lai Pé̩
Ki a má ba daamú nipa awọn ohun ti n bọ wa ṣẹlè̩ lọjọ iwaju ati ètò bi wọn yoo ti ṣe ṣẹlè̩ lẹsẹẹsẹ, ẹ jẹ ki a fi awọn nnkan wọnni ti o n bọ wa lai pé̩ sinu ọkàn wa. Ohun nla ti o n bọ wa mi ayé kijikiji – o le ṣẹlè̩ lonii – eyi ni bibọ Jesu lati wá mú Iyawo Rè̩ ti o n duro de E lọ. “Ijọ” Rè̩, awọn eniyan ti wọn ti mura silẹ ti wọn si n ṣọnà fun Oluwa (Matteu 24:27; 1 Tẹssalonika 4:16, 17).
Eyi yii ni a mọ si Ipalaradà awọn eniyan mimọ, o si jẹ iṣẹlè̩ kan ti a kò gbọdọ padanu rè̩! Jesu ki yoo sọkalẹ sori ilẹ ayé nigba Ipalaradà, ṣugbọn yoo ti Ọrun wá si awọsanma; gbogbo awọn ti wọn bá ti mura silẹ, yoo fi ayé silẹ lọgán, a o si pa wọn lára dà lati lọ pade Oluwa. Awọn òkú ninu Kristi yoo ji dide lati inu iboji wọn, wọn o si pade Rè̩ ninu awọsanma pẹlu, wọn yoo si gbé ara aikú wọ (1 Tẹssalonika 4:16, 17).
“A o mu ọkan, a o si fi èkeji silẹ” (Matteu 24:40, 41). A o mu ọkan lọ lati lọ wà pẹlu Oluwa, a o si fi èkeji silẹ lati wà layé ni akoko ipọnju (Matteu 24:21; Isaiah 26:20, 21; Ifihan 13:1-18). Igba ipọnju yii jẹọkan ninu awọn iṣè̩lè̩ ti a ni lati ni idaniloju pe a kò ni ipin ninu rè̩; bi a ba le pẹlu awọn ti a pa lara dà, a ki yoo ni ipin ninu ipọnju yii.
Ase-alẹ Igbeyawo
Awọn ti a gbà soke nigba Ipalarada yoo ni ipin ninu Ase-alẹ ti Igbeyawo Ọdọ-agutan (Ifihan 19:7-9). A kò mọ bi àse-alẹ igbeyawo yii yoo ti ri, ṣugbọn Kristi ni yoo maa ṣe iranṣẹ fun ni; nitori O wi pe: “Ibukun ni fun awọn ọmọ-ọdọ wọnni nigbati oluwa na ba de ti yoo ba ki nwọn ki o ma ṣọna: lõtọ ni mo wi fun nyin, yio di ara rè̩ li amure, yio si mu wọn joko lati jẹun, yio si jade wá lati ṣe iranṣẹ fun wọn” (Luku 12:37). Nisisiyii, ọkàn wa wà ni iṣọkan pẹlu Kristi, ṣugbọn nigba naa a o wà ni iṣọkan pẹlu Rè̩ titi lai. A! bi yoo ti dara to lati jé̩ aṣẹgun ati lati “pade Oluwa li oju ọrun” (1 Tẹssalonika 4:17).
Gẹgẹ bi Oluwa ti pa Noa ati ẹbi rẹ mọ ninu ọkọ, bẹẹ ni Oun yoo fi Iyawo Rè̩ pamọ sọdọ ara Rè̩ ni igba Ase-alẹ Igbeyawo Ọdọ-agutan. Gẹgẹ bi ọkọ nì ti fó sori ikun-omi, bẹẹ gẹgẹ ni a o ṣe gbà wá soke pẹlu Kristi ninu awọsanma. Ikún-omi naa kò de titi Noa ati ẹbi rè̩ fi wà lai lewu ninu ọkọ, bakan naa ni a gbagbọ pe ipọnju ti o lẹrù yii ki yoo tú jade titi Jesu yoo fi gba awọn ayanfẹ Rè̩ sọdọ ara Rè̩.
Ni akoko Ase-alẹ Igbeyawo Ọdọ-agutan ni a o pin erè fun iṣẹ ti a ti ṣe tọkàntọkàn. Awọn ti wọn ti lo talẹnti wọn fun ogo Ọlọrun yoo gbọ gbolohun yii pe: O ṣeun, ọmọ-ọdọ rere ati olotitọ, bọ sinu ayọ Oluwa rẹ. Gbogbo iṣẹ ti a ba ṣe bi fun Oluwa, fun ogo Rè̩ nikan, ni yoo gba èrè kikún, a o si fi iná sun gbogbo iṣẹ iyoku (1 Kọrinti 3:13, 14).
Ipọnju
Nigba ti Isaiah kiyesi awọn ẹlẹṣẹ layé, o fi ipin wọn hàn wa nigba ti o wi pe: “Nwọn o si wọ inu ihò apata lọ, ati inu ihò ilẹ, nitori ibè̩ru OLUWA, ati nitori ogo ọlanla rè̩, nigba ti o ba dide lati mi ilẹ aiye kijikiji” (Isaiah 2:19). S̩ugbọn bi wọn ti sare soke sare sodo tó, kò si ibi isapamọ kan kuro niwaju Ẹni naa ti oju Rè̩ “dabi ọwọ iná” (Ifihan 19:12). A! awọn ohun ini wọn i ba le ṣe iranwọ fun wọn nigba naa! ṣugbọn awọn agberaga, awọn ọlọkàn giga ati awọn ti wọn n fè̩ soke ni a o rè̩ silẹ ni ọjọ Oluwa. Ọjọ oni jé̩ ti eniyan; “ọjọ OLUWA” (Isaiah 2:12) n bọ wá. Ni ọjọ yii ọlọrọ ki yoo sàn ju alagbe lọ. Pẹlu ọpọlọpọọrọ ti a tò jọ “dèọjọ ikẹhin” (Jakọbu 5:3), ọlọrọ kò le ra ibi àbò ani fun wakati kan. Oun yoo ju fadaka ati wura rè̩ ti o ti n bọ bi oriṣa si awọn ekute ti n wà ilẹ, ati awọn àdán ti n fò ninu okùnkùn ninu ile ti o kún fun eeri ti a si ti kọ silẹ (Isaiah 2:20). Wọn ki yoo jamọ nnkan kan ni ọjọ naa.
Ifihan
Ni ipari ipọnju ọdun meje Jesu yoo tun pada wá si ayé lẹẹkan si i. Ni igba yii ki yoo wá “bi olè” (1 Tẹssalonika 5:2), ṣugbọn “kiyesi i, o mbọ ninu awọsanma; gbogbo oju ni yio si ri i” (Ifihan 1:7). Akoko yii ni a n pe ni Ifarahan Kristi. Awọn eniyan mimọ yoo gun ẹṣin funfun tẹle Kristi ni ipadabọ Rè̩ wá si ayé. Eyi yii jẹ iṣẹlẹ nla miiran ti a kò gbọdọ padanu rè̩, o si daju pe a o ni ipin ninu rè̩ bi a ba ti le ṣe alabapin ninu Ipalarada.
Kristi yoo sọkalẹ, gẹgẹ bi Johannu Ayanfẹ ti sọ fun wa, lori ẹṣin funfun, ati “lati ẹnu rè̩ ni idà mimu ti njade lọ, ki o le mā fi iṣá awọn orilẹ-ède: on o si mā fi ọpá irin ṣe akoso wọn” (Ifihan 19:15).
Amagẹddoni
Ẹgbẹ ogun nla yii ti o wà lori ẹṣin funfun, eyi ti Ọba awọn ọba, ati Oluwa awọn oluwa i ṣe balogun rè̩, yoo lọ ja ogun kan iru eyi ti kò i ti i ṣẹlẹ layé ri. Ogun yii ni a n pe ni ogun “Amagẹddoni.” “Aṣodi-si-Kristi” ni a o “sọ laayè sinu adagun iná ti n fi sulfuru jó” (Ifihan 19:20). Jesu Kristi yoo si kó “gbogbo ohun ti o mu-ni-kọsè̩ ni ijọba rè̩ kuro, ati awọn ti o ndẹṣẹ” (Matteu 13:41).
Ẹgbẹrun Ọdún ti Alaafia
Awọn alaṣẹ ayé, awọn ijọba nla, ati awọn ọba ti lo igbà ti wọn. S̩ugbọn ọpọlọpọ ninu wọn ni o ti ṣe akoso ni ọna ti o jẹ wi pe, Satani ni o jẹ olori. S̩ugbọn nigba ti Jesu ba pada si ayé bi Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa, a o de Satani ni è̩wọn fun ẹgbè̩rún ọdún (Ifihan 20:1-3).
Isaiah sọ nipa akoko yii ninu ori iwe yii, Esekiẹli pẹlu si tun sọ fun wa pe, “Nwọn o si ma gbe aginju ni ailewu, nwọn o si sùn ninu igbó” (Esekiẹli 34:25). A kọ ninu Ẹkọ 168 fun Ọdọ ati Agbà ninu Iwe Kẹtala, ati ninu Ẹkọ 121 ninu ti awọn Ọmọde, nipa igba kan ti awọn ọmọ kekere paapaa le sun ninu igbó ti wọn o si wà ni ailewu. Ni owurọ, bi wọn bá ji, bi wọn ba ri ikooko lẹgbẹọdọ wọn, wọn le gbe ọwọ le e ki wọn maa ba a ṣire ki wọn má si bè̩ru, nitori awọn ẹranko buburu gbogbo ki yoo huwa ẹhànnà mọ. Awọn igbin, kòkòrò, ati kòkòrò jewé-jewé ki yoo tún ba awọn itànná ati ewebẹ jé̩ ninu ọgbà gẹgẹ bi wọn ti maa n ṣe lode oni. Tè̩tè̩ẹlẹgun ki yoo ni è̩gún lara mọ, bẹẹ ni ki yoo si è̩gún, òṣùṣù ati è̩gún ọgàn ti o le pa ni lara tabi ki wọn fa ni laṣọ ya. Aṣálè̩ ti o gbẹ ti o si yán lonii yoo di àbàtà, iṣan-omi ati orisun-omi, bẹẹ ni awọn ilẹ gbigbẹ yoo “tanna bi lili” (Isaiah 35:1). A ki yoo tun ri awọn afọju ti o n ṣagbe lẹba ọna igboro ilu mọ, nitori oju gbogbo awọn afọju ni yoo là; ohun ti wọn n fi seti ki eniyan le gbọran daadaa ki yoo si mọ, nitori pe “eti awọn aditi yio si ṣi. Nigba naa ni awọn arọ yoo fò bi agbọnrin, ati ahọn odi yoo kọrin” (Isaiah 35:5, 6).
Ni opin Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún, a o tú Satani silẹ fun saa kan (Ifihan 20:3, 7); ṣugbọn lai pẹ a o sọọ sinu adagun iná ati sulfuru, nibi ti a o ti maa da a loro tọsan toru lae ati laelae (Ifihan 20:10).
Idajọ
Lẹyin eyi ni akoko Itẹ Idajọ Nla Funfun nigba ti Kristi yoo kó awọn alaaye ati òkú jọ lati ṣe idajọ wọn gẹgẹ bi iṣẹ wọn (Ifihan 20:11-13). Ọjọ Idajọ ni ki yoo jé̩ọjọè̩rù fun awọn ti o ti ni ipin ninu Ipalarada. Awọn ti wọn ti fi è̩ṣẹ wọn ranṣẹṣaaju si idajọ (1 Timoteu 5:24), awọn ti a ti pa lára dà lati wà pẹlu Oluwa titi lae ki yoo tun bè̩ru mọ. Ẹlẹṣè̩, alaiṣododo, ati awọn ti wọn ṣe alainaani ti wọn si kọ igbala nla Ọlọrun ni a o dá lẹjọ ni ọjọ naa. “Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi?” (Heberu 2:3). Kò si àbá ati là fun awọn ti o kọ lati wáỌlọrun.
Pataki Jù Lọ
O di ọwọ wa. Bi a ba ti mura silẹ fun iṣẹlẹ nla ti n bọ wá eyi ti i ṣe Ipalarada awọn eniyan mimọ, awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ lẹyin eyi ki yoo jé̩ ohun ijaya fun wa. Nitori naa a pari gbogbo rè̩ si eyi pe ohun ti o ṣe pataki jù lọ layé ni lati mura silẹ lati pade Jesu nigba ti O ba de. Jọwọọkàn rẹ silẹ fun igbalà kuro ninu è̩ṣẹ rẹ bi iwọ kò ba ti i ri igbalà; lẹyin eyi wá Isọdimimọ lọdọỌlọrun, ati fun Agbara Ẹmi Mimọ ati Iná. Lẹyin eyi tẹra mọ adura ki o si maa kà Bibeli, ki o si mura silẹ, “nitori Ọmọ-enia mbọ ni wakati ti ẹnyin kò daba” (Luku 12:40).
Eto Awọn Iṣẹlẹ Nla Wọnni Fun Oye Kikun, Wo
Ipalarada Awọn Eniyan Mimọ
(Bibọ Jesu bi “Ole”) Ẹkọ 164, Iwe 13
Ase Alẹ Igbeyawo Ọdọ-agutan ni
ofurufú, ati pipin èrè fun awọn
eniyan mimọ nibi Ité̩ Idajọ Kristi Ẹkọ 165, Iwe 13
Ni akoko yii, Ipọnju Nla yoo wà lori
ilẹ ayé Ẹkọ 165, Iwe 13
Ifarahan Kristi (Pẹlu awọn eniyan
mimọ lori ẹṣin funfun) Ẹkọ 166, Iwe 13
Ogun Amagẹddoni Ẹkọ 166, Iwe 13
Ijọba Ẹgbè̩rún Ọdún Kristi -- Ẹgbè̩rún
Ọdún alaafia (Awọn eniyan mimọ yoo
maa jọba wọn o si maa ṣakoso pẹlu
Kristi, Ẹkọ 168, Iwe 13
A o tú Satani silẹ fun igbà diẹ (Ogun
ikẹyin ti Gọgu ati Magọgu) Ẹkọ 168, Iwe 13
Ité̩ Idajọ Nla Funfun (A o dà awọn
eniyan buburu sinu adagun iná) Ẹkọ 169, Iwe 13
Ọrun Titun ati Aye Titun
Ayeraye -- lae ati laelae Ẹkọ 169, Iwe 13
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni Ipalaradà? Njẹ a mọ igba ti yoo ṣẹlẹ?
2 Ki ni Ifarahàn Kristi?
3 Ki ni a n pe ni Ijọba Ẹgbè̩rún Ọdún? Sọ iru ipò ti ayé yoo wà nigbanaa.
4 Nibo ni awọn eniyan yoo lọ lati wá ibi ifarapamọ kuro niwaju Oluwa? Wọn o ha ri ibi sá pamọ si?
5 Awọn wo ni Oluwa yoo fi rẹrin nigbooṣe?
6 Ki ni awọn eniyan yoo ṣe si wura ati fadaka wọn ni Ọjọ Oluwa?
7 Ki ni a n pe ni Ité̩ Idajọ Nla Funfun?
8 Awọn wo ni yoo wà nibẹ? Ironu rè̩ ha n dẹru ba ọ?
9 Ki ni ohun ti o ṣe pataki jù lọ fun wa lati ṣe?
10 Ẹnikẹni ha mọ igbà ti Jesu n bọ wá? Bawo ni a ṣe mọ pe bibọ Rè̩ sunmọ etile?