Orin Dafidi 5:1-12

Lesson 343 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Li owurọ li emi o gbà adura mi si ọ, emi o si ma wòke” (Orin Dafidi 5:3).
Notes

Isin Owurọ

Ki iwọ to fi yara rẹ silẹ ni owurọ yii njẹ iwọ ranti lati gbadura? Njẹ iwọ ranti lati kàẹsẹ diẹ ninu Bibeli pẹlu? Tabi a ha gbadura agbo-ile ninu ile rẹ ni owurọ yii bi? Owurọ jé̩ akoko ti o dara lati sin Oluwa, ki a to lọ si ile-è̩kọ, tabi ki a to bẹrẹ iṣẹ tabi eré. Ọpọlọpọ igbà ni iṣẹ oojọ eniyan maa n ṣe idiwọ to bẹẹ ti ki yoo fi ni anfaani lati báỌlọrun sọrọ, ki o si fi àye silẹ fun Ọlọrun lati ba ọkàn rè̩ sọrọ. Nibomiran Dafidi kọ akọsilẹ pe, “Li alẹ, li owurọ, ati li ọsan, li emi o ma gbadura” (Orin Dafidi 55:17).

Wiwo Oke

Dafidi wi pe, “Ohùn mi ni iwọ o gbọ li owurọ, OLUWA, li owurọ li emi o gbà adura mi si ọ, emi o si ma wòke” (Orin Dafidi 5:3). Boya ohun ti Dafidi ni lọkàn lati sọ ni wi pe oun fi igbagbọ ri firifiri oju Ọlọrun oun si ni anfaani lati mọ ifẹ rè̩. “Emi o ma fi oju mi tọọ” wọnyii ni ọrọ Oluwa ti O ti ọwọ Dafidi kọ silẹ ninu Orin Dafidi 32:8.

Njẹ baba rẹ tabi iya rẹ ha ti fi oju wòọ kọrọ lati fi hàn pe inu wọn kò dun si ọ bi o tilẹ jẹ pe wọn kò sọ ohunkohun. Lọna miiran, è̩wẹ, wọn ha fi ojurere wòọ lati fi hàn pe inu wọn dùn si iwà tabi iṣe rẹ? Nigba ti o ba gbe oju rẹ soke si Ọlọrun iwọ o mọ bi inu Rè̩ ba dùn si igbesi-ayé rẹ.

Wo bi inu baba rẹ yoo ti dùn to nigba ti iwọ ba ṣe ohun ti o wi ti o si gbé igbesi-ayéọmo rere!. Bi baba rẹ bá jé̩ Onigbagbọ oun yoo fẹ ki awọn ọmọ oun jé̩ọmọ rere ati olugbọran. Wo bi oun yoo ti korira iwà buburu, è̩ṣẹ ati ẹtàn bi o ba ri i pe ọkan ninu awọn ọmọ oun n hu iru ìwà bẹẹ! Dafidi wi pe Ọlọrun korira awọn ti n ṣiṣé̩è̩ṣẹ; O fẹran ọkàn wọn sibẹ, O si fẹ ki gbogbo eniyan yipada kuro ninu è̩ṣẹ wọn ki a si gbà wọn là, ṣugbọn O korira ọna buburu wọn, o daju gbangba pe Oun yoo si pa ara ati ọkàn awọn ẹlè̩ṣẹ ti wọn ko ba ronupiwada, run. “Ẹ kuku fòiya ẹniti o le pa ara ati ọkàn run li ọrun apadi” (Matteu 10:28).

Dafidi ni è̩ri-ọkàn rere ninu eyi ti kò si ẹbi ati idalẹbi. Nitori eyi ni o ṣe ni igboya lati gboju soke si Ọlọrun gẹgẹ bi ọmọ ti o mọ pé oun kòṣaigbọran, ti kò sọrọẹtan, ti kò si sọọrọ buburu ti o le ba ẹni keji ninu jé̩, ti o si le wo oju awọn obi rè̩ lai tiju ati lai bẹru ijiya kankan.

Ahọn Ipọnni

Awọn nnkan miiran ti Dafidi gbadura le lori ni agabagebe, ati ipọnni. Ọlọrun korira nnkan wọnyii. Dafidi si korira wọn pẹlu, bẹẹ ni olukuluku Onigbagbọ tootọ ti o fara mọỌlọrun ti o si n ba Ọlọrun rin korira wọn pẹlu, wọn ki yoo si jẹbi irúè̩ṣẹ buburu wọnyii. Awọn eniyan ti wọn ni nnkan miiran lọkàn ti wọn si n sọ nnkan miiran jade jé̩ agabagebe. Bi apọnni kan ba wa ba ọ ti o si n sọ “ọrọ didùn” fun ọ ti o si yipada lati sọ “ọrọ buburu” nipa rẹ fun ẹlomiiran lẹyin rẹ, ki i ṣe ojulowo ọré̩, o si daju pe ki i ṣe Onigbagbọ. Dafidi wi pe ọfun iru eniyan bẹẹ dabi isa-okú ti o ṣi silẹ. Isà-oku jé̩ ibi ti a n sin awọn okú si, a si ni lati bò wọn, ki oorùn buburu ati ibajẹ má ba maa ti inu wọn jade. Nitori naa o ṣanfaani ki awọn apọnni ati awọn agabagebe pa ẹnu wọn mọ tabi ki wọn fi ọwọ bòó.

Ẹ jẹ ki a jé̩ oloootọ ati olododo, ki a má si ṣe lọwọ ninu iwàè̩tàn ati agabagebe. Bi a ba n sọ otitọ lati inu ọkàn wa nigba gbogbo o le ṣai dùn mọẹlomiiran, ṣugbọn ỌrọỌlọrun sọ fun wa pe, “Otitọ li ọgbé̩ọré̩: ṣugbọn ifẹnukonu ọta li è̩tan” (Owe 27:6). Eyi yii kò fi han pe ki a maa lọ kaakiri ki a si maa mu awọn ẹlomiiran binu; ṣugbọn Oluwa yoo fun wa ni oye ati imọ bi a ti ṣe n sọrọ ki a má ba jé̩ ohun ikọsẹ fun ẹlomiiran, sibẹsibẹ ki a má si ṣe jẹ agabagebe.

Ipamọ Lailewu

Bi awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin Onigbagbọ ba le maa ranti lati gbadura ni owurọ ki wọn si maa gbe ọkàn wọn soke ni gbogbo ọjọ, Ọlọrun yoo pa wọn mọ. Wọn yoo le maa gbé igbesi-ayé ailè̩ṣẹ ati lai rúọkan ninu awọn ofin Ọlọrun. “Nitori ẹniti yoo ba fẹ iye, ti yio si ri ọjọ rere, ki o pa ahọn rè̩ mọ kuro ninu ibi, ati ète rè̩ kuro ni sisọọrọè̩tan” (1 Peteru 3:10).

Adura owurọ Dafidi ni wi pe ki Ọlọrun ṣe amọna oun. Wò bi ayọ Dafidi ti pọ to nitori pe o gbẹkẹle Ọlọrun! O le hó fayọ gẹgẹ bi gbogbo awọn ọmọỌlọrun ti ni anfaani lati ṣe nitori aabo Oluwa ti o kun fun ifẹ. Ni tootọỌlọrun tikara Rè̩ ni olupamọ ati alaabo awọn olododo. Kò ha sàn fun ọ lati ni apàtá aabo Rè̩ yi ọ ká ju agbara ati ipá aye yii lọ?

Questions
AWỌN IBEERE

1 Iru àpèle ọlá wo ni Dafidi fun Ọlọrun?

2 Akoko wo loojọ ni Dafidi wi pe oun yoo maa gbadura?

3 Ki ni ṣe ti Dafidi bẹ Oluwa pe ki O ṣe amọna oun?

4 Ki ni Dafidi sọ nipa awọn apọnni?

5 Ki ni o fi ọfun apọnni wé?

6 Ki ni ohun ti Dafidi sọ nipa awọn ti o gbẹkẹle Oluwa?

7 Ki ni ṣe ti owurọ fi jẹ akoko ti o dara fun wa lati gbadura?

8 Igba meloo ni Daniẹli n gbadura?