2 Kronika 32:1-23; 2 Awọn Ọba 19:14-37

Lesson 344 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA Ọlọrun wa li o pẹlu wa lati ràn wa lọwọ, ati lati jà ogun wa” (2 Kronika 32:8).
Notes

Aapọn ninu Iṣẹ Oluwa

Hẹsekiah jé̩ẹni kan ti ki i ṣe iṣẹỌlọrun ni ajambaku. Ka Ẹkọ 340 iwọ o si ri iṣẹ pataki ti o ṣe. Ibukun Ọlọrun a maa tọ gbogbo awọn ti wọn ba fi gbogbo ọkàn wọn sin Oluwa lẹyin; wọn o si ṣe rere pẹlu, bi ti Hẹsekiah.

Nigba ti awọn eniyan ba n ṣiṣẹ fun Oluwa, ọpọlọpọ igba ni Satani maa n sa ipa rè̩ lati ṣe idena iṣẹ na. Jesu sọ itan kan nigba kan, nipa ọkunrin kan ti o funrugbin rere sinu ọgbà rè̩. S̩ugbọn ọta wá ni oru o si fun epo sinu alikama, o si ba ti rè̩ lọ (Matteu 13:24, 25).

IfunnuỌba Buburu Kan

A ri i ninu è̩kọ yii pe ọta n wáọna lati dena iṣẹ ti Hesekiah, ọba rere yii fẹṣe fun Ọlọrun. Sennakeribu ọba Assiria dide pẹlu awọn ọmọ-ogun rè̩ o si doti awọn ilu-olodi Juda, o gberò lati ṣẹgun wọn. Oun kò ha ti bori ninu ọpọlọpọ ogun ti o ti n jà? Sa wo o pẹlu ẹgbẹ ogun rè̩ ti o ju ọkẹ mẹsan o le ẹgbẹdọgbọn (185,000) eniyan lọ, o bẹrẹ si funnu wi pe, “Kò si oriṣa orilẹ-ède tabi ijọba kan ti o le gbà enia rè̩ lọwọ mi, ambọtori Ọlọrun nyin ti yio fi gbà nyin lọwọ mi?” Ki ni ohun ti Sennakeribu n wi yii? Oun ha n wi pe Ọlọrun Hesekiah tilẹṣe alailagbara ju awọn oriṣa orilẹ-ède keferi wọnni (2 Awọn Ọba 19:12, 13)? Ẹ jẹ ki a maa woye.

O dabi ẹni pe gbogbo ọrọ wọnni ti Sennakeribu sọ si Hesekiah kò tilẹ mi in rara, ṣugbọn nigba ti a ri iwe gbà eyi ti o kún fún ọrọè̩gan si Oluwa Ọlọrun Israẹli, Ẹni ti Hẹsekiah fẹran, ti o n bọ, ti o n sìn, ti o n gbọran si, eyi nì tayọ ohun ti o le fara dà.

Igbẹkẹle Hẹsekiah

Hẹsekiah ha rán awọn ọmọ-ogun rè̩ jade lẹsè̩kẹsè̩ lati ba ọta jà ni akoko yii ti a ti pèsè awọn ọmọ-ogun rè̩ silẹ daradara? A ti yan awọn balogun, a ti mọ awọn odi, a si ti rọ awọn ohun ijà silẹ lọpọlọpọ. Ohun gbogbo ti ṣe tán, ṣugbọn igbè̩kẹle Hẹsekiah kò si ninu awọn nnkan wọnni.

Laaarin igboro ilu ni o sọ fun awọn ẹgbé̩ọmọ-ogun rè̩ pe ki wọn maṣe bè̩ru ọba yii tabi ọpọlọpọ awọn ọmọ-ogun ti o wà pẹlu rè̩, nitori “awọn ti o pẹlu wa jù awọn ti o pẹlu rè̩ lọ.” Agbara ọpọlọpọẹgbẹọmọ-ogun ti o wà pẹlu Sennakeribu ni oun gbẹkẹle: ṣugbọn Hẹsekiah wi pe, “OLUWA Ọlọrun wa li o pẹlu wa lati ràn wa lọwọ, ati lati jà ogun wa.” Wo iru ọrọ imulọkanle yii lati ẹnu alakoso wọn! Eyii yii lé ibè̩ru kuro lọkàn awọn ẹgbè̩ọmọ-ogun Juda -- wọn ni igbẹkẹle ninu alakoso wọn.

Awọn Oloootọ Alakoso

Bawo ni ọkàn wa ti kun fun ọpẹ to lọjọ oni nipa awọn alakoso ti o mu iduro wọn fun Ọlọrun ti wọn si n ki wá laya lati gbẹkẹle Ọlọrun Hẹsekiah! Bi a ba ṣe oriire to bẹẹ ti a fi ni awọn alabojuto, awọn alufaa, ati iranṣẹỌlọrun ninu Ihinrere ti wọn le fi ìgboya gbẹkẹle Ọlọrun nigba ti ọta dide pẹlu gbogbo agbára rè̩, o yẹ ki a mọ riri wọn ki a “si mā bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn” (1 Tẹssalonika 5:13).

Nigba gbogbo ni a maa n ri awọn ẹlomiiran ti wọn n fẹ lati yẹ igbagbọ awọn eniyan ti wọn gbẹkẹle Ọlọrun ati alakoso wọn. Awọn ẹlomiiran yoo wi pe, “Tirè̩ ni ki o joko ti,” tabi ki wọn sọ gẹgẹ bi Sennakeribu ti wi, “Ẹ máṣe jẹ ki Hẹsekiah ki o tàn nyin jẹ, bḝni ki o máṣe rọ nyin … bḝni ki ẹ máṣe gbà a gbọ.” S̩ugbọn awa mọ daju pe Ọlọrun wà pẹlu awọn ti O yàn lati maa ṣe itọju agbo Rè̩, ojuṣe ati anfaani wa ni lati fi ọkàn tán wọn patapata.

Adura --Ohun Ija

S̩ugbọn iṣẹgun ko i ti dé sibẹ -- ohun kan wà ti wọn ni lati ṣe pẹlu. Ọrọ imulọkanle a maa ṣe iranlọwọ lati ki awọn ti ẹru n bà laya. Ọrọ iṣiri a maa ṣe iranlọwọ lọpọlọpọ lati sọ igbagbọẹni ti o rẹwẹsi ji. S̩ugbọn a ni ohun kan lati ṣe ju pe ki a sọ fun alaisan pe, “Tujuka, iwọ yoo gbadun!” Ohun kan ṣi tun wà ti o tayọ pe ki a rẹrin músé̩ tabi ki a ki eniyan nipa gbígbọwọ tabi ki a mu aṣayan itanna daradara wa fun awọn ti ailera sé mọle ti o wa ninu iwayá-ijà pẹlu aisan tabi irẹwẹsi. Ni tootọ awọn nnkan wọnyii dara pupọ lati ṣe, ṣugbọn ohun ìjà miiran ti o dara ju lọ wà lati fi báọta jà. Ohun ija yii ni adura, ohun ijà kan ṣoṣo ti a fi n ṣẹgun ọta – ki i ṣe adura kuṣẹkuṣẹ fun iṣẹju meji, ṣugbọn adura agbayọri ti yoo takú titi idahun yoo fi de.

Jakọbu gbadura titi di afẹmọjumọ, a si dahun adura rè̩ (Gẹnẹsisi 32:24). Elijah gbadura nigba meje ki o to ri ibeerè rè̩ gbà (1 Awọn Ọba 18:43). Hanna tẹra mọ adura pẹlu ẹkún niwaju Oluwa titi o fi gba agbayọri, bẹẹ ni “kò si fà oju ro mọ” (1 Samuẹli 1:10-18). Iru adura bawọnni ni o n mi apa Ọlọrun lọjọ oni.

Adura Hẹsekiah

Bi a ti n rò nipa Hẹsekiah Ọba, a fẹrẹ le fi oju ẹmi ri bi o ti n wọ inu ile Oluwa lọ. Iwo oju rè̩ fi itara ti o wà ni ookan aya rè̩ hàn o si mu iwe naa ti Sennakeribu, ọba Siria kọ lati fi kẹgan Ọlọrun Israẹli lọwọ; o si wi pe, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli, … iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikanṣoṣo.” Ninu adura rè̩ o jẹwọ pe ọba Assiria ti pa awọn orilẹ-ède miiran run o si ti gbe oriṣa wọn sọ sinu iná. O si wi pẹlu pe, “Nitori ti wọn ki iṣe ọlọrun, bikòṣe iṣẹọwọ eniyan, igi ati okuta: nitori naa ni wọn ṣe pa wọn run.” O bẹỌlọrun pe, “Gbà wa lọwọ rè̩, ki gbogbo ilẹọba ayé le mọ pe iwọ OLUWA iwọ li Ọlọrun nikanṣoṣo.”

Ọlọrun kò jẹ kuna lati dahun adura ti o ti inu odo ọkàn ẹnikẹni ti o n báỌlọrun rin timọtimọ, gẹgẹ bi Hẹsekiah ti ṣe. Ọlọrun rán onṣẹ kan lati ọdọ Isaiah wolii Ọlọrun lati sọ fun un pe, “Adura ti iwọ ti gbà si mi si Sennakeribu … emi ti gbọ” (2 Awọn Ọba 19:20). Oluwa wi pe Sennakeribu ki yoo wa si ilu yii, bẹẹ ni ki yoo ta ọfà kan sibẹ, ki yoo mu asà wá iwaju rè̩, ṣugbọn wi pe ọna naa ti o ba wá, ọkan naa ni yoo tun ba pada lọ. “Nitori emi o da abò bò ilu yi, lati gbà a, nitori ti emi tikara mi, ati nitori ti Dafidi iranṣẹ mi.”

Iṣẹgun

Hẹsekiah ti ja ogun naa nipa adura, iṣẹgun si de tan. A kò yinbọn, bẹẹ ni a kò ta ọfà, bẹẹ ni eefin kò si rú wuyẹ ni ibudo awọn ọta. Li oru, nigba ti awọn ọmọ-ogun Ọlọrun n sinmi ni alaafia, angẹli Oluwa la ibudo awọn ọta kọja. Ni kutukutu owurọ nigba ti awọn eniyan Hẹsekiah ji wọn ri i pe ọké̩ mẹsan-an le ẹgbẹẹdọgbọn (185,000) okú eniyan ti wà ni ibudo awọn ọta! Sennakeribu agberaga ati afunnu pada si ilẹ rè̩ ni ijatilè̩ ati itijú.

Ẹtan Eṣu

Ọna ti ọlọrun aye yii n gbàṣiṣẹ ni eyi – a maa ṣeleri iṣẹgun, ayọ, ọrọ, alaafia ati ire. Nigba pupọ ni o jẹ wi pe awọn ti wọn ba gba eké rè̩ gbọ i maa padanu ire, agbójule, ati ọla wọn. Ọpọlọpọọmọbinrin ni ọlọrun aye yii ti fọ loju, to bẹẹ ti wọn ti gbéẹwa ati iwa wundia wọn tà nipa ẹtàn eṣu, wọn si di ẹni abamọ. Bakan naa ni eṣu ti tan awọn ọdọmọkunrin miiran jẹ nipa ṣiṣeleri okiki ati ọpọlọpọ owo fun wọn ati nipa mimú wọn rò pe wọn le dẹṣẹ ati pe è̩ṣẹ wọn ki yoo si fara han.

Oluwa Ọlọrun, Alaṣẹ Ohun Gbogbo

Ni akoko yii Ọlọrun kan ti O lagbara ju Nisroku oriṣa Sennakeribu ti ṣẹgun rè̩, kinla! Nisroku ti ja ọ tilẹ, Sennakeribu. Ki ni ṣe ti iwọ kò yipada si Ọlọrun Hẹsekiah? Ki ni ṣe ti iwọ kò fi jẹwọ pe Oun ani Oun nikan ṣoṣo ni Oluwa Ọlọrun?

Sennakeribu tun pada lọ si ile Nisroku lati tun wolẹ niwaju odi oriṣa yii lẹẹkan si i. Ọlọrun ni Ọrun ri gbogbo rè̩. O to gẹẹ! Eyi yii ni igba ikẹyin, Sennakeribu, ti iwọ yoo sin oriṣa rẹ yii tabi ọlọrun miiran. Ilẹkun aanu ti sé mọọ. Anfaani lati ronupiwada ti rekọja fun ọ. Awọn ọmọ rè̩ ni o fi idà pa a ni ọjọ yii kan naa ni ile oriṣa rè̩. “Bi ẹlẹṣẹ tilẹṣe ibi nigba ọgọrun, ti ọjọ rè̩ si gùn, ṣugbọn nitõtọ, emi mọ pe yio dara fun awọn ti o bè̩ru Ọlọrun” (Oniwasu 8:12).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni Hẹsekiah ṣe lati daabo bo awọn ilu rè̩? Igbẹkẹle rè̩ ha wà ninu nnkan wọnyii?

  2. 2 Sọ awọn ọrọ imulọkanle ti o sọ fun awọn ẹgbẹọmọ-ogun rè̩. Awọn ọmọ-ogun rè̩ ha fọkàn tán alakoso wọn?

  3. 3 Ki ni ọrọ igberaga ti Sennakeribu sọ? Njẹ a ti ṣẹgun rè̩ ri?

  4. 4 Iru iwe wo ni o fi ranṣẹ si Hẹsekiah?

  5. 5 Ki ni Hẹsekiah ṣe nigba ti o ri iwe wọnni gbà?

  6. 6 Bawo ni o ṣe mọ pe a ti dahun adura oun?

  7. 7 Ki ni Sennakeribu gbẹkẹlé?

  8. 8 Sọ ohun ti o ṣẹlẹ ni ibudo awọn ọtá ni ọganjọ-oru.

  9. 9 Ki ni opin Sennakeribu?

  10. 10 Ki ni ohun ti è̩kọ yii kọ wa?