2 AwọnỌba 20:1-18; 2 Kronika 32:26, 31-33

Lesson 345 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi ti gbọ adura rẹ, emi si ti ri omije rẹ: kiyesi i, emi o wòọ sàn” (2 Awọn Ọba 20:5).
Notes

Ihin

A jiṣẹ abàmi kan fun Hẹsekiah. Isaiah, Wolii Oluwa ni o jẹ iṣẹ naa fun un. Ọlọrun ni o ranṣẹ naa wá. Hẹsekiah n ṣaisan nigba ti Isaiah lọ lati bẹẹ wo. Bi Hẹsekiah ti gbọ iṣẹ ti a rán si i yii, o yi oju rè̩ si ogiri, o sọkún, o si gbadura. Iru ihin wo ni o le mu ibanujẹ báọba to bayii?

Ọrọ ti Oluwa rán si Hẹsekiah ni eyi pe, “Palẹ ile rẹ mọ,” nitori ti yoo kú. Ọpọlọpọ eniyan ni kò mọọjọ ti wọn yoo kú. Bi Oluwa ba fa bibọ Rè̩ sẹyin, ikú jẹ ohun ti gbogbo eniyan yoo tọwo. Bibeli sọ pe, “A si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lḝkanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ” (Heberu 9:27). Niwọn-igba ti a kò mọ igba ti Oluwa yoo de tabi akoko ti awa yoo kú, a gbọdọ ri i pe ile wa ati ayé wa wà leto nigba gbogbo.

Njẹ iwọ rò pe iwọ yoo wà ni imurasilẹ lati pade Jesu bi iwọ ba ti fi ainaani kọ lati jẹwọè̩ṣẹ rẹ ki o si tọrọ idariji? Iwọ ha n fẹ lati pade Jesu pẹlu igbesi-ayéè̩ṣẹ ati aiduro ti awọn ileri ti o ti ṣe? Yoo jẹ idunnu Oluwa bi a ba “palẹ ayé wa mọ” ti a mu ki o wà ni titọ bẹẹ.

Adura

Ki Hẹsekiah to pe awọn iranṣẹ rè̩ lati ba wọn sọrọ ikẹyin, ati ki o to ṣe iwe-ogun silẹ, o yi oju rẹ si ogiri o si gbadura. A ranti pe Ahabu dubulẹ lori akete rè̩, o si yi oju rè̩ pada (1 Awọn Ọba 21:4). Ahabu wugbọ kò si fẹ ijẹun. Inu rẹ bajẹ nitori pe kò le mu ifẹ inu ara rè̩ṣẹ. S̩ugbọn Hẹsekiah yi oju rè̩ pada si ogiri ki o ba le ya ara rẹ sọtọ kuro lọdọ awọn ti o wà ninu yàrá, ki o si le ri àye lati nikan gbadura. Bakan naa, lọjọ oni, awa pẹlu le di eti wa ki a si mu oju wa kuro lara awọn ti wọn yi wa ka, ki a si maa ṣe aṣaro nipa Jesu, ki a gbadura si I, ki a si wà pẹlu Rè̩ nikan. Nigba iṣoro, ọpọlọpọ Onigbagbọ ni wọn ti fi ọkàn gbadura nigba ti kò si anfaani lati kunlẹ. Lẹnu iṣẹ, nibi eré, ati nigba ti awọn eniyan wà yi wọn ká, ọpọlọpọ Onigbagbọ ni o ti kọ lati ni idapọ pẹlu Oluwa nikan nipa fifi ọkàn gbadura.

Ohun kin-in-ni ti Hẹsekiah kọṣe nigba ti a sọọrọ yii fun un ni wi pe o gbadura. Bi o ba jẹ pe awọn ẹlomiran ni a rán iru iṣẹ bẹẹ si, wọn le fé̩ lati kọ dagbere fun awọn ọrẹ wọn, tabi ki wọn kà owó wọn, tabi ki wọn ṣe atunṣe, tabi ki wọn sọrọ ipinya. Hẹsekiah gbadura. Lai si aniani, Hẹsekiah a maa gbadura nigba gbogbo nitori pe o fẹran Oluwa. Ohun ti o fẹran ni o kọkọ wa si ọkàn rè̩. Bi a bá fẹran Oluwa, adura ni a o kọ ronu nipa rè̩ ki a to ronu nipa ohun miiran. Onigbagbọ a maa gbadura nigba ti o ba kọ ji ni owurọ; ohun ti o si maa n ṣe kẹyin ki o to sùn ni adura gbigba: a maa gbadura ki o to jẹun, ki o to bè̩rẹ iṣẹ, ati ki o to bè̩rẹ si ṣire. Bi iṣoro kan tabi ohun itunu kan ba wá si ọna rè̩ bi ọjọ ti nlọ, Onigbagbọ yoo gbadura. Ki i ṣe dandan pe ki o gba gbogbo adura wọnyii soke, ṣugbọn ki adura wọnyii saa jé̩ adura kẹlẹkẹlẹ lati inu ọkàn wá.

Iranti

Ki ni ohun ti Hẹsekiah n sọ ninu adura rè̩? O n wi fun Ọlọrun pe ki o ranti bi oun ti rin niwaju Rè̩. Hẹsekiah mọ pe Oluwa n ri ohun ti a n ṣe. Nigba miiran awọn ọrẹ wa, awọn obi wa, ati awọn olukọ wa le ṣe alai rí tabi ki wọn mọ ohun ti a ti ṣe, ṣugbọn Ọlọrun mọọn. Awọn ẹlomiran n fẹ ki Ọlọrun gbagbe ohun ti awọn ti ṣe. Hẹsekiah wi fun Ọlọrun pe ki o ranti wọn. Oun kò wi pe ki Ọlọrun ranti bi oun ti huwa si ẹbi, aladugbo tabi awọn ọta rè̩. Kò bú sẹkun pe ki Ọlọrun ki o fa ẹmi oun gùn diẹ si i. O wi pe, “OLUWA, ranti nisisiyi bi emi ti rin niwaju rẹ ninu otitọ ati ninu aiya pipe, ti mo si ti ṣe eyiti o dara li oju rẹ.”

Lẹyin ti Hẹsekiah gbadura tán, o sọkun gidigidi. Ọdọmọkunrin ni i ṣe, kò si tóẹni ogoji ọdún. Oluwa ti mu ki o ri rere nigba ayé rè̩, O si ti mu ki igba ijọba rè̩ dara. Lai si aniani, Hẹsekiah sọkun nitori pe oun i ba fẹ lati wà laaye diẹ si i ki o ba le ran awọn eniyan rè̩ lọwọ si i, ki o wulo fun Ọlọrun si i.

Esi

Ki Wolii Isaiah to fi agbaláọba silẹ Oluwa wi fun un pe ki o pada tọ Hẹsekiah lọ lati jiṣẹ miiran fun un. Ni akoko yii Oluwa ni ki Isaiah sọ fun Hẹsekiah pe Oun yoo fi ọdún mẹẹdogun kún ọjọ rè̩. Isaiah yipada lọgán o si jé̩ iṣẹ ti Oluwa rán. Awọn ẹlomiran le fà tìkọ lati lọ jiṣẹ lẹẹkeji niwọn-igba ti a ki yoo mu ti akọkọṣẹ. Gẹgẹ bi Jona ẹni ti a rán lati kede ni ilu Ninefe! O wi pe, “Niwọn ogoji ọjọ si i, a o bi Ninefe wó” (Jona 3:4). S̩ugbọn a kò pa Ninefe run nitori pe awọn eniyan naa rẹ ara wọn silẹ wọn si kepe Ọlọrun, wọn si ronupiwada. “O bà Jona ninu jé̩ gidigidi” nigba ti ọrọ ti o sọ kò ri bẹẹ mọ. Oun kò ni ifẹ si ẹmi gbogbo awọn ara Ninefe ti i ba ṣegbe bi wọn kò ba gbadura.

Idahun

Nigba ti Hesekiah gbadura, Oluwa wi pe, “Emi ti gbọ adura rẹ, emi si ti ri omije rẹ, kiyesi i, emi o wòọ sàn.” Eyi ni idahun si adura rè̩. Hesekiah tilẹ ri gbà ju eyi ti o bere lọ. Lẹyin iwosan ti ara rè̩, a tun ṣeleri idasilẹ kuro lọwọọba Siria fun Hẹsekiah ati aabo lori ilu naa. Nitori pe Hẹsekiah gbadura, o ni anfaani lati maa reti iwosan kuro ninu aisan rè̩, ki a si fi ọdún mẹẹdogun kun ọjọ ayé rè̩ ati ki a si dá a silẹ kuro lọwọọta.

Adura a maa yi ohun gbogbo pada fun wa bakan naa lọjọ oni gẹgẹ bi o ti ri fun Hẹsekiah. Ohun ti o ṣẹlẹ si Hesekiah nipa ti ara le ṣẹlẹ bakan naa nipa ti ẹmi. A kà a ninu Bibeli pe “ọkàn ti o ba ṣè̩, on o kú” (Esekiẹli 18:20), ati pe “Ikú li ère è̩ṣẹ” (Romu 6:23). Nitori naa awọn ti a kò i ti i gba ọkàn wọn la “kú nitori irekọja ati è̩ṣẹ” (Efesu 2:1) wọn yoo si ṣegbe titi lae. S̩ugbọn anfaani wà fun ẹlẹṣẹ lati gbadura, Ọlọrun yoo si gba ọran wọn rò. Iwosan wà fun ọkàn ti aisan è̩ṣẹ n pa kú lọ. Ọpọlọpọ ibukun ni a le fi kún igbesi-ayé wọn, ayeraye pẹlu Oluwa ati awọn eniyan Rè̩ yoo si jẹ ti wọn pẹlu. Adura ha ti yi ohunkohun pada ninu igbesi-ayé rẹ, nipa ti ara tabi nipa ti ẹmi?

Igbọran

Isaiah paṣẹ pe ki a mu odidi ọpọtọ wa, wọn si fi le oowo Hẹsekiah. Hẹsekiah ri iwosan nitori pe o gbọran si aṣẹ wolii Oluwa. Ọlọrun n fẹ ki a ni igbagbọ ati igbọran nigba gbogbo. Nigba miiran Ọlọrun a paṣẹ pe ki a ṣe ohun kan lati fi igbagbọ ti a ni ninu Rè̩ hàn. Akọsilẹ wà ninu Bibeli nipa awọn kan ti Ọlọrun beere igbọran lọwọ wọn lati fi igbagbọ ti wọn ni hàn, ki a to wò wọn sàn. Jesu wi fun ọkunrin kan ti ọwọ rè̩ rọ pe, “Nàọwọ rẹ.” Bi ọkunrin yii ti ṣe bẹẹ “ọwọ rè̩ si pada bọ sipò gẹgẹ bi ekeji” (Marku 3:5). A sọ fun ọkunrin alarun ẹgbà kan pe ki o dide ki o si maa rin. Ọkunrin naa “si dide, o si lọ ile rè̩” (Matteu 9:7). O si ri iwosan!

A paṣẹ fun awọn adẹtẹ mẹwaa lati lọ fi ara wọn hàn fun awọn alufaa, gẹgẹ bi Ofin (Lefitiku 14:2). “O si ṣe, bi wọn ti nlọ, wọn si di mimọ” (Luku 17:14). Jesu wi fun ọkunrin afọju kan pe “Lọ, wè̩ ninu adagun Siloamu.” Lọna kan ti a kò le sọ, ọkunrin afọju naa lọ si adagun Siloamu. “O wè̩, o si de, o nriran” (Johannu 9:7).

Niọna kan tabi ọna miiran a ni lati fi igbagbọ wa ninu Jesu hàn. Jesu wi pe, “Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ gbagbọ pe ẹ ti ri wọn gbà na, yio si ri bḝ fun nyin” (Marku 11:24). Eyi fi hàn pé nipa igbọran si Ọlọrun ati igbagbọ ninu Rè̩, a le ri idahun gbà si adura wa.

Awọn Iṣẹ-iyanu

Nigba ti Hẹsekiah gbadura ti o si gbọran si aṣẹ wolii nì, a fun un ni ami pe Oluwa yoo wòó sàn. Ojiji pada sẹyin ni iṣisẹ mẹwaa. Hẹsekiah si wi pe, “ohun ti o rọrùn” ni fun ojiji ki o lọ siwaju ni iṣisẹ mẹwaa ki o si tète wọ. Pẹlupẹlu, dipo ti awọn eniyan i ba fi ogo naa fun Ọlọrun, wọn yoo fẹ lati ṣe alaye -- pe owúsúwusù ni o bo oorùn, tabi pe bi oju ọjọ ti ri ni o jẹ ki a rò pe oorùn tète wọ. Awọn ẹlomiran a maa gbiyanju lati ronu ohun abàmi ti wọn le fi ṣalaye iṣẹỌlọrun dipo ti wọn i ba fi jẹwọ pe Ọlọrun a maa ṣe iṣẹ iyanu ni tootọ.

Lai si aniani awọn ti o wà ni yara Hẹsekiah yoo sunmọ agogo oorùn lati ṣe akiyesi rè̩ gẹgẹ bi Isaiah ti n gbadura. Ọlọrun dahun! Ojiji pada sẹyin ni iṣisẹ mẹwaa, gẹgẹ bi o ti hàn ninu agogo-orun Ahasi, baba Hẹsekiah. Oorun pada sẹyin ni tootọ niwọn ogoji iṣẹju ki o to maa yi lọ bi ti atijọ!

Ọlọrun tun ṣe iṣẹ iyanu kan ni wiwò Hẹsekiah sàn patapata ninu aisàn ti i ba pa a. O ti de oju ikúṣugbọn ni ọjọ mẹta o lagbara lati lọ si ile Oluwa.

Iyin si Ọlọrun

Lẹyin ti Hẹsekiah sàn tan o kọ akọsilẹ orin idupẹ si Ọlọrun. O sọ nipa aisàn rè̩ ati pe oun ké pe Oluwa. Hẹsekiah wi pe, “Kili emi o wi? o ti sọ fun mi, on tikalarè̩ si ti ṣe e” (Isaiah 38:15). Ohun ti o n sọ ni pe ki i ṣe wi pe Ọlọrun ṣeleri nikan, ṣugbọn Ọlọrun ti mu ileri Rè̩ṣẹ pẹlu.

Ọpọ ileri wà ninu Bibeli fun awa ti ode-oni. Nigba ti a ba gbagbọ ti a si gbọran, Ọlọrun yoo mu awọn ileri wọnni ṣẹ ninu igbesi-ayé wa. Ọlọrun ṣeleri fun Abrahamu ni ti ohun ti o ṣoro lati muṣẹ loju eniyan, ti o si dabi ẹni pe ireti kò si. S̩ugbọn Abrahamu gba Ọlọrun gbọ. “Kò fi aigbagbọṣiyemeji ileri Ọlọrun; ṣugbọn o le ni igbagbọ, o nfi ogo fun Ọlọrun; nigbati o sa ti mọ dajudaju pe, ohun ti on ba ti leri, o si le ṣe e” (Romu 4:20, 21).

Hẹsekiah fi ogo fun Ọlọrun nitori ti O dáẹmi rè̩ si. O yin Ọlọrun logo fun iwosan naa. Hẹsekiah wi pe, “Nitori iboji kò le yìn ọ, ikú kò le fiyìn fun ọ … Alāyè, alāyè, on ni yio yìn ọ, bi mo ti nṣe loni yi” (Isaiah 38:18, 19). Hẹsekiah tilẹ kọ akọsilẹ orin iyin ati ọpẹ si Ọlọrun fun lilo ninu isin. “A o kọ orin mi lara dùrù olokùn, ni gbogbo ọjọ aiyé wa ni ile OLUWA” (Isaiah 38:20).

Iyiiriwo

Nigba ti Ọlọrun mu ki oorun pada sẹyin fun ogoji iṣẹju, gbogbo eniyan ilẹ naa mọ pe ohun abàmi kan ti ṣẹlẹ. Lai pẹ jọjọ ihin tàn kalẹ nipa “ohun-iyanu ti a ṣe ni ilẹ na.” Ọba Babiloni lati ọna jijin rère rán awọn ikọ pẹlu è̩bun si Hẹsekiah. Ni akoko yii Ọlọrun fi Hesekiah silẹ, “lati dán a wò ki o le mọ ohun gbogbo ti o wà ni ọkàn rè̩” (2 Kronika 32:31). Hẹsekiah ti mọ agbara Ọlọrun, nisisiyii Ọlọrun n fé̩ yiiri Hẹsekiah wò.

Awọn ọmọ alade Babiloni kóọpọlọpọọrẹ, iwe, ati iwe-ajọyọ wá fun Hẹsekiah. Hẹsekiah fé̩ọrọ ipọnni ti iyin ati iyanu. O fi ọkàn tán awọn ikọ ilu okeere wọnyii. O mu wọn la gbogbo aafin rè̩ já, wọn si wo gbogbo iṣura fadaka, wura ati okuta iyebiye. Hẹsekiah mu wọn lọ sinu ile ohun ihamọra rè̩ nibi ti a fi awọn afọnja ohun-ija rè̩ pamọ si. Oun kò ni ohun-ija aṣiiri kan mọ nisisiyi nitori pe o ti ṣi ilẹkun ile rè̩ silẹ fun awọn aladugbo rẹ. Wọn la gbogbo ilẹ naa já, bẹẹ ni Hẹsekiah si n sọrọ igberaga lati fi hàn bi oun ti ṣe rere tó, o si n fi ara rè̩ hàn ni eniyan nla loju awọn ara ilẹ Babiloni.

Gbogbo aṣehàn asán ti Hẹsekiah ṣe yii kò dùn mọỌlọrun. A le ri pe Hẹsekiah fi gbogbo ògo aṣeyọri ti o ṣe fun ara rè̩, kò si fi ogo naa fun Ọlọrun. “Hẹsekiah kò si tun pada san gẹgẹ bi ore ti a ṣe fun u; nitoriti ọkàn rè̩ gbega” (2 Kronika 32:25). Nigba iyiiriwo, Hẹsekiah kuna nitori pe kò fi iyin ati ogo fun Ọlọrun.

IbinuỌlọrun

A tún rán wolii Isaiah si Hẹsekiah. Hẹsekiah gbà pe ni tootọ ni awọn ara Babiloni ti ri gbogbo ohun ti o wà ninu ile oun ati pe kò si ohun kan ninu iṣura oun ti oun kò fi hàn wọn. Isaiah sọọrọ Oluwa pe: “A o kó gbogbo nkan ti mbẹ ninu ile rẹ; … lọ si Babeli: ohun kan ki yio kù.” A o si tun kó awọn ọmọ Hẹsekiah ni igbekun lọ si Babiloni nitori pe o ti gbẹkẹ le awọn ọkunrin wọnni ju ati gbẹkẹle Ọlọrun lọ.

Nigba ti Hẹsekiah rẹ ara rè̩ silẹ kuro ninu igberaga ọkàn rè̩, Ọlọrun sún idajọ naa siwaju, kò si ṣẹ lọjọ Hẹsekiah. O dupẹ pe Ọlọrun fun oun ni alaafia ati otitọ ni akoko ijọba oun. Ọkàn rè̩ si ni lati kún fun iwuwo pe oun kuna niwaju Ọlọrun nigba ti a yiiri oun wò ati pe oun ni o fa ibanujẹ ti o n bọ wá sori awọn ọmọ rè̩.

Igbesi-ayé wa, lode oni, le lagbara lori awọn ẹlomiran – fun rere tabi fun buburu. Nipa gbigbe igbesi-ayé wa fun Oluwa ati nipa fifi iyin fun Un, a le mu ire wá sinu igbesi-ayé awọn ẹlomiran. Ki Ọlọrun ràn wá lọwọ ki a si le jẹ ki imọlẹ wa tàn niwaju awọn eniyan, to bẹẹ ti wọn o fi ri iṣẹ wa ki wọn si fẹ lati ṣe bẹẹ gẹgẹ; ki awọn paapaa ba le yin Ọlọrun logo nipa fifi ayé wọn fun Un!

Bawo ni eniyan ṣe le jẹ oloootọ si Ọlọrun nigba idanwo? Jobu wi pe, “S̩ugbọn on mọọna ti emi ntọ, nigbati o ba dan mi wò, emi o jade bi wura. Ẹsẹ mi ti tẹle ipasẹ irin rẹ, ọna rè̩ ni mo ti kiyesi, ti nkò si yàkuro. Bḝni emi kò pada sẹhin kuro ninu ofin ẹnu rè̩, emi si pa ọrọẹnu rè̩ mọ jù ofin inu mi lọ” (Jobu 23:10-12).

Jobu rii pe Ọlọrun ni aabo Onigbagbọ nigba aini. O gbẹkẹ le Ọlọrun nigba iyiiriwo, bẹẹ ni kò si kuna. Ọlọrun ti ṣeleri lati wà pẹlu awọn eniyan Rè̩. Ọlọrun wi pe: “On o pè orukọ mi, emi o si da a lohùn, emi o pẹlu rè̩ ninu ipọnju, emi o gbà a, emi o si bu ọlá fun u” (Orin Dafidi 91:15). Ka ohun ti Ọlọrun yoo ṣe fun awọn ti o gbẹkẹ wọn le E ninu Jeremiah 17:7, 8.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni woli ni akoko yii?

  2. 2 Ta ni ọba Juda?

  3. 3 Iru iṣẹ wo ni a rán si ọba naa?

  4. 4 Ki ni Hesekiah ṣe nigba ti o gbọọrọ wolii?

  5. 5 Ki ni ṣe ti a dáẹmi Hẹsekiah si?

  6. 6 Ọdun meloo ni a fi kún ọjọ ayé Hẹsekiah?

  7. 7 Ami wo ni a fi hàn fun Hẹsekiah?

  8. 8 Sọ iṣẹ-iyanu meji ti Ọlọrun ṣe fun Hẹsekiah.

  9. 9 Ki ni ṣe ti Hẹsekiah kuna ninu iyiiriwo rè̩?

  10. 10 Ki ni ṣẹlẹ nitori ti o kuna?