Iṣe Awọn Apọsteli 19:21-41; Matteu 10:16-28; Luku 21:12-19

Lesson 346 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Gbogbo enia yio si korira nyin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foriti i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà” (Matteu 10:22).
Notes

Fun Oluwa

Bi Oluwa ba fa bibọ Rè̩ sẹyin, awọn ọmọde ọkunrin ati obinrin ni Ile-ẸkọỌjọ Isinmi lọjọ oni yoo ni iṣẹ lati ṣe gẹgẹ bi ọmọ-ibilẹ, boya awọn miiran paapaa ti n rò nipa iṣẹ ti wọn o ṣe ni ọjọọla. O ṣe e ṣe fun wa lati yan iru iṣẹ ti a le fi wulo ninu iṣẹ Oluwa. Ọpọlọpọ ninu awọn ọkunrin ati awọn obinrin ti wọn yọọda apa kan ninu akoko wọn fun iṣẹOluwa ni a ti kọ ni ẹkọ fun iṣẹ oojọ wọn. Awọn miiran si ti fi iṣẹ yii ṣe iṣẹ ounjẹ oojọ wọn. Nigba ti Oluwa pè wọn lati wa ṣiṣẹ fun Oun, ọpọlọpọ ni a ti pè si irú iṣẹ kan naa ti wọn ti n ṣe tẹlẹ ri. Awọn miiran n lo diẹ ninu akoko, talẹnti, ati oye ti wọn ni nigba ti anfaani naa ba ṣi silẹ, ṣugbọn awọn ẹlomiran ni anfaani lati fi gbogbo akoko wọn silẹ fun iṣẹ Oluwa.

Nigba ti awọn ọdọ ba fẹ yan iṣẹ ti wọn o ṣe, ki yoo ha jẹ didun inu Oluwa bi wọn ba yan iṣẹ ti wọn le fi wulo ninu iṣẹ Oluwa? Bi ẹni kan ba n ṣafẹri Ọlọrun, bi o ba si n sin In, iru eniyan bẹẹ yoo ni ifẹ lati ṣe ohun kan fun Oluwa. Bi eniyan kan ba fẹran Ọlọrun, yoo jẹ ifẹọkàn rè̩ lati fi ninu akoko, talẹnti, tabi imọ rè̩ fun iṣẹ Oluwa.

Alagbẹdẹ Fadaka

Awọn oniṣọnà wa ni Efesu, ti wọn n fi oriṣiriṣi ohun alumọni ilẹṣe ohun ọṣọ ati awọn nnkan miiran ti o wulo, ṣugbọn wọn kò fi ayé wọn fun Oluwa bẹẹ ni wọn kòṣiṣẹ fun Un. Kàkà bẹẹ, Satani ni wọn n ṣiṣẹ fun, nitori pe ere-oriṣa ni wọn n yá. Demetriu jé̩ alagbẹdẹ fadaka ni Efesu. O yẹ ti oun i ba maa ṣe awọn nnkan ti o wulo, ṣugbọn ere ni o n yá, nitori pe nipa ṣiṣe bẹẹ yoo ri ọpọlọpọ owó gbà. Ki i ṣe kiki pe o n ṣiṣẹ fun Satani lọna bayii nikan, ṣugbọn o tun mú wahala bá awọn Onigbagbọ pẹlu.

Nigba ti Paulu n waasu Ihinrere ni Efesu, Demetriu dá rukerudo silẹ. O pe apejọ gbogbo awọn alagbẹdẹ fadaka ti wọn n yáère. O ba awọn ẹlẹgbẹ rè̩ oniṣọna sọrọ. O rán wọn leti pe nipa yiyá ere oriṣa bayii ni wọn ti di ọlọrọ. Demetriu wi fun wọn pe wọn ti ri i wọn si ti gbọ bi Paulu ti n waasu fun awọn eniyan. Ọpọlọpọ eniyan ti o wà ni Efesu ati ibomiran gbogbo ni Asia ni wọn ti gba Ihinrere gbọ ti wọn kò si bọriṣa mọ. Koko ẹsun Demetriu ni pe iṣẹ wọn wà ninu ewu. Bi awọn eniyan bá dẹkun lati maa bọriṣa awọn agbẹgilere kò ni ri iṣé̩ṣe mọ. Ẹmi imọtara-ẹni nikan ni o mu ki Demetriu dá rukerudo silẹ laaarin awọn eniyan. Ẹwè̩, o gba awọn eniyan niyanju lati jé̩ oloootọ si ẹsin wọn ki a maa ba kọ tẹmpili oriṣa wọn silẹ, ki o si wó lulẹ.

Otitọ

Demetriu jẹri si iṣẹ ati iwaasu Paulu ninu ọrọ ti o sọ fun awọn oniṣọna wọnyii. Bọya kò tilẹ ni i lọkàn lati ṣe bẹẹ, o jẹwọ pe Ihinrere n tàn kalẹ, nitori pe “ọpọ enia” ni a n yi lọkàn pada ti wọn si n di Onigbagbọ. Gẹgẹ bi ọrọ ti Demetriu sọ, Paulu ti sọ tẹlẹ pe, “Ohun ti a fi ọwọṣe, ki iṣe ọlọrun.” Otitọ ni Paulu sọ. Nitori pe o waasu otitọ, awọn ti o gbagbọ di ominira kuro ninu igbagbọ ohun asán. Otitọ ni o n sọ eniyan di ominira.

Jesu wi fun awọn Ju ti o gbà A gbọ pe: “Bi ẹnyin ba duro ninu ọrọ mi, nigbana li ẹnyin jẹọmọ-ẹhin mi nitõtọ; ẹ o si mọ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira” (Johannu 8:31, 32).

Awọn eniyan ti o feti si ọrọ Demetriu kò fẹ otitọ to bẹẹ ti wọn i ba fi kọẹsin èké ati è̩tàn silẹ, ki wọn si fi iṣẹ ere yiya silẹ. Ta ni yoo fẹ sin iru ọlọrun ti kò le daabo bo tẹmpili rè̩?

Irukerudo

Ọrọ Demetriu mu ki awọn alagbẹdẹ fadaka wọnni kún fún ibinu. Pẹlu ariwo ati ibinu ni wọn fi tuka ninu ipade naa. Lai pẹ jọjọ, wọn ti da gbogbo ilu naa rú. Ija-igboro si bé̩ silẹ, awọn eniyan naa si mu Gaiu ati Aristarku, awọn alajọrin Paulu. Awọn eniyan naa fi ọkàn kan rọ sinu ile ibiṣire, ile-apejọ fun ilu naa. Wo bi rukerudo naa ti pọ tó! Awọn kan n sọ ohun kan! Awọn miiran n wi ohun miiran! Ọpọlọpọ ninu awọn eniyan naa ni kò tilẹ mọ idi rè̩ ti awọn eniyan fi pejọ. Wọn kò mọ ohun ti o ṣẹlẹ, ṣugbọn wọn wá lati woran.

Awọn eniyan oni-jagidi-jagan ti wọn fi ibinu mú awọn Onigbagbọ meji yii n fẹ lati jẹ wọn niyà. Lai si aniani wọn n fẹ lati dẹru ba awọn ọmọ-ẹyin Jesu ki wọn ba le fi ilu naa silẹ ki wọn má si ṣe waasu mọ.

Ifẹ fun awọn Ará

Paulu n fẹ lati wọ aarin awọn eniyan naa lọ lati ṣe iranlọwọ fun awọn ọrẹ rè̩ ti o wà ninu wahala. Awọn ọmọ-ẹyin iyoku ati awọn olori awọn eniyan ni Asia, ti i ṣe ọrẹ Paulu kò jẹ ki Paulu wọ inu ile ibiṣire naa lọ ki awọn ọlọtẹ wọnni má ba dawọ le oun naa pẹlu. Laaarin ewu, ẹru kò ba Paulu lati jé̩ ki o di mimọ fun awọn eniyan pe Onigbagbọ ni oun i ṣe. Kò bẹru lati jade lọ da awọn arakunrin rè̩ silẹ, nitori pe o fẹran wọn. Jesu wi pe bi ẹni kan ba ni ifẹ si awọn ará, eyi yii fi hàn pe ọmọ-ẹyin Jesu ni ẹni naa i ṣe. O wi pe: “Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ pe ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin” (Johannu 13:35).

Alẹksanderu yọ siwaju ọpọ eniyan naa ki o ba le ran awọn ọmọ-ẹyin meji ti a mu lọwọ. O juwọ si wọn lati dá wọn lẹkun ki oun ba le sọrọ. A ranti pe awọn ara Efesu jé̩ Keferi. Nigba ti wọn woye pe Ju ni Alẹksanderu i ṣe, wọn kò fẹ i gbọ ti rè̩. Wọn bẹrẹ si i pariwo fun iwọn wakati meji wọn n hó iho iyin si oriṣa wọn, ti ki i gbọran ti kò si le ran ni lọwọ.

Ọna Asala

Ọlọrun n wo gbogbo ohun ti o n ṣẹlẹ. Oun kò jẹ ki awọn jagidi-jagan wọnyi pa awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lara. O fi àye silẹ fun inunibini naa lati mọ bẹẹ: O si ṣe ọna abayọ silẹ fun awọn eniyan Rè̩. Yatọ si awọn jagidi-jagan alariwo ati abọriṣa wọnyii, awọn eniyan Ọlọrun wà ni ifarabalẹ ati idakẹjẹ. Wọn gbẹkẹle Ọlọrun ti i maa ran awọn eniyan Rè̩ lọwọ nigba gbogbo.

Akọwe ilu, ẹni ti a kò ni idaniloju pe ọmọ-ẹyin Jesu ni i ṣe, bá awọn ara ilu rè̩ sọrọ. O wi pe gbogbo eniyan ni o mọ pe awọn ara Efesu ni i ṣe olusin ere ti o ti ọdọ Jupiteri bọ silẹ (itan atọwọdọwọ ti awọn eniyan naa gbagbọ sa ni eyi). O gba awọn eniyan wọnyii niyanju lati dakẹjẹ, ki wọn “ki o máṣe fi iwara ṣe ohunkohun.” Bi ọran ofin ba ṣẹlẹ, ile idajọ wà nibẹ lati ṣe ayẹwo idajọọran ti a bà mu wa siwaju wọn. Bi Demetriu ati awọn alagbẹdẹ-fadaka iyoku ba ni ọran ẹsùn kan si awọn ọmọ-ẹyin Jesu, jẹ ki wọn lọ i fi wọn sùn fun awọn alaṣẹ. S̩ugbọn akọwe-ilu wi pe awọn ọmọ-ẹyin Kristi wọnyii kò ja ile-isin lole bẹẹ ni wọn kò si sọ blasfeme si oriṣa. Wọn kòṣe ohun ti o lodi si ofin. Awọn eniyan-keniyan yii si ti mú wọn lodi si ofin wọn si n dá rukerudo silẹ lai si idi kan pataki. Akọwe ilu si tú awọn eniyan ká ki awọn alaṣẹ ma ba wa beere lọwọ wọn, ohun ti o fa gbogbo rukerudo yii.

Inunibini

Iru ipo wo ni ọkàn awọn ọmọ-ẹyin yoo wà nipa ohun ti o ṣẹlẹ yii? Wọn yoo ha sé̩ igbagbọ wọn nitori pe wọn ri inunibini diẹ? Lai si aniani eyi rú igbagbọ wọn soke. Wọn gbẹkẹle Ọlọrun, O si gba wọn. Boya awọn pẹlu ni iru ọkàn kan naa pẹlu awọn ọmọ-ẹyin, awọn ti a fi sinu tubu nitori Kristi, ṣugbọn ti “nwọn si nkọrin iyin si Ọlọrun” laaarin ọganjọòru (Iṣe Awọn Apọsteli 16:25), ati gẹgẹ bi awọn Apọsteli ti wọn n yọ “nitori ti a kà wọn yẹ si iya ijẹ nitori orukọ rè̩” (Iṣe Awọn Apọsteli 5:41). Dajudaju awọn eniyan wọnyii kò pada lẹyin Oluwa. A ri i pe a darukọ wọn ninu gbogbo iwe ti Paulu kọ.

Imurasilẹ

Jesu pese ọkàn awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ silẹ lati fara da inunibini. O kilọ fun wọn tẹlè̩ pe bi a ti ṣe korira Oun bẹẹ gẹgẹ ni a o ṣe korira awọn ti i ṣe ọmọ-ẹyin Oun; bi a ba si ti ṣe inunibini si I a o ṣe inunibini si awọn naa pẹlu (Wo Johannu 15:18-20).

Awọn ọmọ-ẹyin Jesu mọ pe inunibini le de si wọn nigbakigba, ṣugbọn Ọlọrun ti fi alaafia ati ifẹ kan si ọkàn wọn ti yoo mu wọn fara da a. Bẹẹ ni, wọn tilẹ tun n dupẹ fun un. A ti sọ fun Paulu tẹlẹ pe yoo jiya pupọ lọwọ awọn onikupani. Sibẹ, bi o ti n jiya, ohun ti o n sọ ni eyi: “Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọ oju ija si wa” (Romu 8:31). Paulu wi pe kò si ohun ti o le ya oun kuro ninu ifẹ nla Ọlọrun ninu Kristi Jesu. O gba wi pe kò si iya ti o pọju fun oun lati jẹ ki oun ba le “jère Kristi.” O wi pe: “Ki emi ki o le mọọ, ati agbara ajinde rè̩, ati alabapin ninu iya rè̩, nigbati mo ba faramọ ikú rè̩; bi o le ṣe ki emi ki o le de ibi ajinde awọn okú” (Filippi 3:10, 11). Paulu fẹ wà ni imurasilẹ fun ajinde kin-in-ni; ki o ba si le jẹ aṣẹgun kikun o ṣetan lati jiya.

Awọn Ileri

Ọpọlọpọ ileri ni a ṣe fun awọn ti a n ṣe inunibini si nitori ododo. Oluwa ti ṣeleri lati wà pẹlu wọn. Ẹmi Mimọ ni yoo sọ fun wọn niti ohun ti wọn yoo wi nigba ti a ba mu wọn wa siwaju awọn alaṣẹ. “Nitorina ẹ pinnu rè̩ li ọkàn nyin pe ẹ ki yio ronu ṣaju, bi ẹ o ti dahun.”

Awọn ti o ba jiya nitori ododo yoo jé̩ alakoso ninu ijọba Kristi. “Otitọ li ọrọ na: Nitoripe bi awa ba bá a kú, awa o si bá a yè: bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba: bi awa ba sé̩ẹ, on na yio si sé̩ wa” (2 Timoteu 2:11, 12). Ibi kan ninu Iwe Mimọ ti o sọ nipa Awọn Alabukun-fun mẹnu kan inunibini: “Alabukun-fun li awọn ẹniti a ṣe inunibini si nitori ododo; nitori tiwọn ni ijọba ọrun. Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati wọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn ba nfi eke sọrọ buburu gbogbo si nyin nitori emi. Ẹ mā yọ, ki ẹnyin ki o si fo fun ayọ: nitori ère nyin pọ li ọrun: bḝni nwọn sáṣe inunibini si awọn woli ti o ti mbẹṣaju nyin” (Matteu 5:10-12).

Lode-oni, awọn eniyan Ọlọrun a saba maa bá inunibini pade. Ni ilẹ ti wa, o ṣe e ṣe ki a sun wa ni ẹsun èké, tabi ki a yà wa nipa si ẹbi wa, tabi ki a huwa aitọ si wa. Ni ilẹ ibomiran o le jẹọran ikú tabi iye. Ohunkohun ti o wu ki o jẹ, ti wa ni lati fi suuru gbàá, ninu idaniloju yii pe a le jẹ oloootọ si Kristi ati si ọna Rè̩. A ti bẹrẹ lati maa gbe igbesi-ayé wa fun Kristi, a o si mu wa lọ si Ọrun bi a ba jé̩ oloootọ. “Gbogbo enia yio si koriran yin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foriti i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà” (Matteu 10:22).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni Demetriu?

  2. 2 Bawo ni o ti ṣe lo talẹnti rè̩?

  3. 3 Ki ni ṣe ti ọkàn rè̩ kò fi lelẹ nitori iwaasu Paulu?

  4. 4 Ki ni ṣe ti a mú awọn alajọrin Paulu?

  5. 5 Bawo ni a ṣe dá wọn silẹ?

  6. 6 Ki ni inunibini?

  7. 7 Ọna wo ni a le gbàṣe inunibini si awọn ọmọ-ẹyin Kristi lode oni?

  8. 8 Ki ni o yẹ ki eniyan ṣe nigba ti a ba n ṣe inunibini si i?

  9. 9 Ki ni diẹ ninu awọn ileri ti a ṣe fun awọn ti a n ṣe inunibini si?

  10. 10 Ki ni ileri ti a ṣe fun awọn ti o ba fori ti i titi de opin?