Iṣe Awọn Apọsteli 20:1-38

Lesson 347 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bi ẹnikan ba wasu ihinrere miran fun nyin jù eyiti ẹnyin ti gbà lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu” (Galatia 1:9).
Notes

Pipa Igbagbọ Mọ

Paulu fẹrẹ pari irin-ajo rè̩ kẹta fun itankalẹ Ihinrere. Ọpọlọpọ eniyan ni o ti ri igbala nipasẹ iwaasu rè̩; ṣugbọn nibi gbogbo ti o lọ ni a ti ri awọn eniyan ti wọn tako Ihinrere ti o n waasu.

Iṣẹ iranṣẹ Paulu ki i ṣe eyi ti o rọrun rara. Oluwa ti sọ fun Paulu tẹlẹ nigba ti O kọ pè e pe yoo jiya pupọ nigbooṣe. S̩ugbọn Paulu kò jẹ ki eyi ṣi oun lọwọ iwaasu rara. Lai fi gbogbo inunibini ti o ti fara dà pè, sibẹ o sọ ni opin ẹmi rè̩ pe, “Emi ti pa igbagbọ mọ.”

Ọpọlọpọ awọn ọdọ ti i ṣe iranṣẹỌlọrun ni o ti bè̩rẹ pẹlu igbona-ọkàn ati itara lati waasu gbogbo ỌrọỌlọrun; ṣugbọn ni ọjọ ogbó wọn, wọn ti gbé itara ati waasu gbogbo ỌrọỌlọrun sọnu. Bawo ni ọpẹ wa ti pọ tó fun apẹẹrẹ eniyan bi ti Paulu, ti o fi hàn gbangba wi pe o ṣe e ṣe lati kún fún itara ati lati wà ni iduro ṣinṣin titi opin ẹmi wa. A si tun dupẹ fun awọn apẹẹrẹ ti a ni ni akoko ti wa yii pẹlu -- awọn wọnni ti wọn ti jẹ oloootọ titi de oju ikú.

Paulu ti ṣe iṣẹ ti Oluwa pe e lati ṣe, lai fẹ mọ bi awọn eniyan gbọ ti rè̩ tabi bẹẹ kọ. O wi pe: “Emi kò fà sẹhin lati sọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun nyin.”

Ọsẹ Kan ni Troasi

Paulu ati awọn ọrẹ rè̩ duro fun ọjọ meje ni Troasi, ni Ọjọ Oluwa wọn lọ pade awọn ọmọ-ẹyin ti o wà ni ilu yii lati jọsin. S̩aaju akoko yii awọn ọmọ-ẹyin wọnyii kò ni anfaani pupọ lati gbọọrọ lẹnu Paulu, nitori naa o ni ohun pupọ lati ba wọn sọ. O fa iwaasu rè̩ gun di ọganjọ-oru. Ọmọkunrin kan wà nibẹ ti o n tòògbé. O joko ni oju fèrese, nigba ti oorun wọọ lara o si ṣubu lulẹ. Ori okè kẹta ni o ti ṣubu lulẹ, o si kú. Gbogbo awujọ ni o daamu pupọ. S̩ugbọn Paulu ni igbagbọ pe Ọlọrun yoo dáẹmi ọdọmọkunrin naa pada. O ṣe gẹgẹ bi Elijah ati Eliṣa ti ṣe nigba ti wọn ji ẹni ti o kú dide: o “wolẹ bò o,” o gbá a mọra, o si fi gbogbo ọkàn rè̩ gbadura. O sọ fun awọn eniyan naa ni ohùn jẹjẹ pe, “Ẹ má yọ ara nyin lẹnu; nitori ẹmi rè̩ mbẹ ninu rè̩.” A ti gbe e dide ni orukọ Jesu Kristi, nitori ẹni ti Paulu ti mura tán lati jiya ati lati kú.

Ninu gbogbo iṣẹ-iranṣẹ Paulu ohun ti o jé̩ kókó iwaasu rè̩ ni Jesu Kristi, Ọmọ MimọỌlọrun. Nitori pe o fi gbogbo ọkàn rè̩ gbẹkẹle Jesu, eyi jé̩ ki o le ṣe ọpọ iṣẹ-iyanu ni orukọ Rè̩.

Kò si Ọrọ Didun

Paulu ti gbéọjọ pupọ ni Efesu bẹẹ ni o tun n fẹ lati bá awọn alakoso ninu ijọ ti o wà nibẹ sọrọ. O mọ pe oun kò tun ni wá si ọdọ wọn mọ, nitori naa o pè wọn lati sọọrọ itọni ikẹyin fun wọn, ati lati kilọ fun wọn nipa ewu ti o wà niwaju.

Paulu ti waasu pe a ni lati tún eniyan bi. O ti kilọ fun awọn eniyan nipa è̩ṣẹ, ibọriṣa, ati awọn ti wọn fẹ lati lọ si Ọrun nipa ṣiṣe iṣẹ rere dipo ki wọn gbà Jesu gbọ. Oun kò sọ “ọrọ didun” fun awọn eniyan naa ri lati fi wá ojurere wọn, ati lati jé̩ gbajumọ laaarin wọn. Ọrọ igbala ẹmi wọn jẹẹ lọkan. O mọ wi pe ọjọ kan n bọ ti gbogbo awọn ti wọn n gbọ iwaasu rè̩ yoo duro niwaju Jesu fun idajọ. Bi wọn kò ba bọ lọwọè̩ṣẹ a o dà wọn sinu iyà ainipẹkun.

Ki ni yoo ha ti ri bi Paulu kò ba sọ fun wọn pe a ni lati gbà wọn là kuro ninu è̩ṣẹ? Wọn yoo ṣegbe, oun yoo si jẹbi! S̩ugbọn Paulu le wi nisisiyii pe, “Emi kò fà sẹhin lati sọ ohunkohun ti o ṣanfani fun nyin.” O tun wi pẹlu pe “Ọrùn mi mọ kuro ninu è̩jẹ enia gbogbo.”

Awọn Oluṣọ

Bawo ni inu rè̩ ti dùn tó lati ri pe oun ti sa gbogbo ipa oun lati fi ọna igbala hàn wọn! Wọn ki yoo le tako o ni ọjọ idajọ wi pe, “Iwọ kò sọ fun mi.”

Wolii kan kọ akọsilẹ nigba kan wi pe bi oluṣọ kan ba kuna lati kilọ fun awọn eniyan nipa ibi ti n bọ, bi ibi ba si bá awọn eniyan naa, Ọlọrun yoo beere è̩jẹ wọn lọwọ oluṣọ naa. Paulu kilọ fun awọn ara Efesu pe ikú li ere è̩ṣẹ, ati pe wọn ni lati ronupiwadà ki a si gbà wọn là ki wọn to le lọ si Ọrun; nitori eyi ọrùn rè̩ mọ kuro ninu è̩jẹ wọn.

Awọn Ikooko Buburu

Awọn eniyan ti o wà ni ijọ Efesu gba iwaasu Paulu gbọ a si ti gbà wọn là, ṣugbọn eyi ki i ṣe opin ija ti wọn ni lati bá Satani jà. Paulu sọ fun wọn pe lẹyin ti oun ba ti lọ tán awọn “ikõkò buburu” yoo wọ aarin wọn, “li aidá agbo si.”

Ki i ṣe awọn ẹranko ni o n tọka si nihin yii bi ko ṣe awọn oniwaasu èké ti yoo wá saarin wọn lati wá bì gbogbo iwaasu Paulu wó. Paulu wi pe, “S̩ugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati ọrun wá, ni o ba wasu ihinrere miran fun nyin jù eyiti a ti wasu fun nyin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu” (Galatia 1:8). O mọ pé awọn oniwaasu yoo wá ti yoo wi pe ki i ṣe ọràn-an-yàn pe ki a di atunbi. Awọn miiran yoo wi pe o ṣe e ṣe fun eniyan lati ri igbala ati isọdimimọ papọ lẹẹkan naa. Awọn miiran yoo wi pe ki i ṣe dandangbọn fun eniyan lati lọṣe atunṣe fun awọn ti o ti hu iwa ti kò tọ si. Gbogbo nnkan wọnyii, ati ju bẹẹ lọ, jẹè̩kọèké. Ẹni ti o ba n waasu nnkan wọnyii di ẹni ifibu.

Awọn ti a fi Ẹjẹ Rè̩ Rà

Ijọ yii ṣọwọn fun Paulu. O ti ṣetan lati fi ẹmi rẹ lelẹ ki awọn eniyan wọnyii ba le ri igbala. S̩ugbọn ijọ tilẹ tun ṣọwọn ju eyi lọ fun Oluwa nitori pe Ẹjẹ Rè̩ ni O ti fi rà a. Kò sí ohun miiran laye ti o le san gbese è̩ṣẹ wa. Jesu ta Ẹjẹ Rè̩ silẹ lati sanwo irapada wa, nitori naa a ṣọwọn fun Un gidigidi.

Irinṣẹ Eṣu

Ki i ṣe kikì pe awọn oniwaasu èké yoo wá sinu agbo lati mú wọn gba ọna ti o rọrun nikan, ṣugbọn awọn miiran laaarin wọn yoo sé̩ igbagbọ. Wọn yoo di agberaga, wọn a si fẹ ki awọn eniyan fẹran wọn ki wọn si maa búọlá fun wọn dipo Jesu ati awọn iranṣẹ Rè̩ tootọ. Wọn a maa fi ète wọn pọn awọn eniyan, wọn a si maa fi abẹtẹlẹ wá ojurere wọn, wọn a si fà wọn sẹyin kuro ninu ijọ sinu è̩kọ titun.

Ki i ṣe aarin ijọ Efesu nikan ni eyi gbéṣẹlẹ. Ọkan ninu awọn ohun ija Satani ti o n fi ba awọn Onigbagbọ jà ni igberaga. A maa tọẹni ti n rìn nipa ti ẹmi wá, a si maa sọ si i leti kẹlẹkẹlẹ pe eniyan pataki ni i ṣe ati pe o kún fun iṣẹ rere pupọ. O si le wi pẹlu pe awọn eniyan kò mọ riri iṣẹ rè̩ ati pe o yẹ ki o fa oju awọn ti yoo mọ rírì iṣẹ rè̩ mọra.

Awọn ẹlomiran a maa wi pe, “Kuro lẹhin mi, Satani, --- nitori iwọ ko rò ohun ti iṣe ti Ọlọrun, bikoṣe eyiti iṣe ti enia.” Igbagbọ awọn eniyan bẹẹ a maa fidimulè̩ ninu Ọlọrun ati awọn alakoso ti O fi sibẹ. S̩ugbọn awọn ẹlomiran yoo feti si i, lai pẹ wọn a bè̩rẹ si i rò pé awọn eniyan kò kà wọn si mọ. Bi wọn kò ba le pa gbogbo ijọ lọkàn dà si ọna ti wọn, wọn yoo fa awọn eniyan diẹ bọdi, wọn yoo si dá ijọ ti wọn silẹ. Bayii ni ọpọlọpọẹsin èké ti ṣe bẹrẹ.

Jesu wi pe bi a ba gbé Oun soke, Oun yoo fa gbogbo eniyan sọdọ ara Rè̩. Iwaasu Paulu nigba gbogbo duro lori Jesu, bẹẹ ni kò si fẹ gbé ara rè̩ ga. O sọ pe oun ti sin Oluwa pẹlu “irẹlẹọkàn gbogbo, ati omije pipọ, pẹlu idanwò.”

Nigba kan awọn eniyan ni akanṣe ifẹ si Paulu. Awọn ẹlomiran si yan iranṣẹỌlọrun kan ti a n pe ni Apollo fé̩. Paulu beerè: “Kini Apollo ha jẹ? kini Paulu si jẹ? bikoṣe awọn iranṣẹ nipasẹẹniti ẹnyin ti gbagbọ” ninu Jesu (1 Kọrinti 3:5). O beerè pe: “Iṣe Paulu li a kàn mọ agbelebu fun nyin bi? tabi li orukọ Paulu li a baptisi nyin si?” (1 Kọrinti 1:13). Iṣẹ ti wa ni lati waasu Jesu, ki i si i ṣe eniyan. Ni tootọ a maa n bu ọlá ati ọwọ fun awọn ti wọn sọ fun wa nipa Jesu; ṣugbọn ẹ jé̩ ki a ranti pe Jesu ni Apata ti a kọle igbagbọ wa le lori. Bi gbogbo eniyan tilẹ kùna, Oun yoo duro laelae.

Ninu Iṣọkan Ẹmi

Fun ọdun mẹta ni Paulu fi n kilọ fun awọn eniyan wọnyii nipa ewu ti ó wà ni ọjọ iwaju. Akoko tó lati fi wọn silẹ, o si gbadura pe ki Ọlọrun pa wọn mọ ninu oore-ọfẹ Rè̩.

Iṣoro wà niwaju fun Paulu. O wi pe: “Ọkàn mi nfà si ati lọ si Jerusalẹmu, laimọ ohun ti yio bá mi nibẹ: bikoṣe bi Ẹmi Mimọ ti nsọ ni ilu gbogbo pe, ide on iya mbẹ fun mi.” Awa ha le fi igboya tè̩ siwaju bi Paulu ti ṣe bi a ba mọ pe wahala wà fun wa niwaju? Bi a ba mọ pe ninu ilu kọọkan ti a ba wọ, ẹni kan wà nibẹ ti o n fẹ lati ṣe wa ni ibi? A ha le tè̩ siwaju sibẹ lati maa tan Ihinrere kalẹ?

Ihinrere ha ṣe pataki fun wa to bẹẹ ti a le fi ẹmi wa lelẹ fun un? Ọkẹ aimoye eniyan ni o ti ṣe bẹẹ bi ọdún ti n gori ọdún. Wọn kò ka ẹmi wọn si titi de oju ikú, wọn si le wi pẹlu Paulu pe: “Lati isisiyi lọ a fi ade ododo lelẹ fun mi, ti Oluwa, onidajọ ododo, yio fifun mi li ọjọ na, ki si iṣe kiki emi nikan, ṣugbọn pẹlu fun gbogbo awọn ti o ti fẹ ifarahàn rè̩” (2 Timoteu 4:8).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni Paulu sọ nipa igbagbọ rè̩ nigba ti ọjọ ayé rè̩ n lọ si opin?

  2. 2 Bawo ni “ipinnu Ọlọrun” ti Paulu waasu rè̩ ti pọ tó?

  3. 3 Ki ni ṣẹlẹ si ọdọmọkunrin ti o ṣubu lulẹ lati ojú ferese nigba ti Paulu waasu titi di ọganjọ oru?

  4. 4 Ki ni Paulu sọ nipa ihinrere miiran ti o yatọ si eyi ti o ti waasu?

  5. 5 Eeṣe ti ijọ fi ṣọwọn fun Jesu?

  6. 6 Tani Paulu ni lọkan nigba ti o n sọ nipa awọn ikookò?

  7. 7 Darukọọkan ninu awọn irinṣẹ Satani?

  8. 8 Ọna wo ni Satani n gbà dán Onigbagbọ wò?

  9. 9 Bawo ni Ihinrere ti ṣe pataki tó fun Paulu?