Lesson 348 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA wipe, wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ: bi è̩ṣẹ nyin ba ri bi òdodó, nwọn o si fun bi òjo-didi, bi nwọn pọn bi àlāri, nwọn o dabi irun-agutan” (Isaiah 1:18).Notes
Iṣẹ ti Oluwa Rán
Wolii Isaiah bè̩rẹ akọsilẹ rè̩ pẹlu awọn ọrọ wọnyi: “Gbọ, ẹnyin ọrun, si fi eti silẹ, iwọ aiyé: nitori OLUWA ti sọrọ.” Isaiah tọ Israẹli wá pẹlu iṣẹ ti Ọlọrun rán si wọn.
Ọba mẹrin, rere ati buburu, ni o jẹ ni Juda ni akoko Isaiah. O gba ibukun Ọlọrun nigba ti Juda sin Ọlọrun, o si jiya nitori è̩ṣẹ orilẹ-ède naa nigba ti wọn bá n bọriṣa. S̩ugbọn oun a maa jiṣẹ ti Ọlọrun ba rán an nigba gbogbo. Igbagbọ rè̩ kò yè̩ bi o tilẹ jẹ pe alaṣẹ ilẹ naa ati gbogbo awọn eniyan naa yipada kuro lọdọ Oluwa. Ọlọrun ti fi iṣẹ kan le e lọwọ, o si jiṣẹ naa lai bikita bi awọn eniyan n fẹ lati gbọ tabi wọn kò fé̩.
Ussiah ati Hẹsekiah ti i ṣe ọba rere a maa beere ohun ti Ọlọrun sọ lọwọ Isaiah. Wọn n fé̩ lati mọ ifẹỌlọrun, Isaiah si ṣe iranwọ lati yi awọn eniyan naa pada, o si kọ wọn lati sin Ọlọrun. Nigba yii Ọlọrun a bukun ilẹ naa, inu gbogbo eniyan a si dùn lati sin Oluwa.
Aimoore
Igba miiran wà ti awọn eniyan naa buru jai gẹgẹ bi o ti ri ni ibẹrẹ ijọba Ussiah. Ọlọrun ti fi ọwọ iké̩ nla tọ wọn, ki wọn ba le fẹran Rè̩. O ti gbiyanju ki i ṣe kiki lati ṣamọna wọn gẹgẹ bi orilẹ-ède nikan, ṣugbọn gẹgẹ bi Baba ni O ti n fi ọwọ iké̩ Rè̩ṣe itọju wọn. Wò bi inu Ọlọrun yoo ti bajẹ to nigba ti wọn ba yipada kuro lẹyin Rè̩! Ẹranko ti kò ni iye ninu paapaa tilẹ mọ oore itọju oluwa rè̩, ṣugbọn fun Israẹli, ki i ṣe bẹẹ: “Mal mọ oluwa rè̩, kẹté̩kẹtẹ si mọ ibujẹ oluwa rè̩: ṣugbọn Israẹli kò mọ, awọn enia mi kò ronu.” Wọn kò tilẹ mọ pe gbogbo ibukun ti wọn n ri gbà ti ọdọỌlọrun wá. Wọn kò tilẹ dupẹ lọwọ Rè̩.
Aimore yii nikan kọ ni ohun buburu ti awọn Ọmọ Israẹli ṣe. Bi awọn eniyan kò ba naani Ọlọrun ati ofin Rè̩, wọn ki yoo naani ofin miiran pẹlu. Wọn buru to bẹẹ gẹẹ ti Ọlọrun fi wi pe kò si ilera ninu wọn. O dabi ẹni pe wọn kun fun ọgbẹ ati ooju ti n rà, ti a kò si di. Yoo ti buru to bi o ba ṣe pe egbo ti ode-ara ni o dá wọn, ṣugbọn ọkàn wọn ni o dibajẹ. Nitori è̩ṣẹ wọn, Ọlọrun mu ki a kó ninu wọn lọ si oko-ẹrú.
Ni ọdun pupọ sẹyin Ọlọrun sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe bi wọn kò ba gbọran si aṣẹ Oun, Oun yoo ṣe wọn ni ìrù, ati awọn orilẹ-ede miiran yoo si jẹ ori. Ro eyi wò! Awọn ayanfẹỌlọrun ti Ọlọrun fẹ fi ṣe ori ti wọn i ba si jé̩ ori bi wọn bá gbọran si Ọlọrun lẹnu, wọn di irù, awọn orilẹ-ède keferi si n jọba lori wọn.
A dá Idajọ Duro
Bi ko ṣe pe a ri awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun diẹ bi Isaiah kaakiri orilẹ-ède naa, Ọlọrun i ba ti pa gbogbo wọn run gẹgẹ bi Sodomu ati Gomorra. Ojo iná ati okuta iná ni a fi pa awọn ilu buburu wọnni run nitori iwa buburu wọn ti o de gongo.
Kiki wiwà laye awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun diẹ lode oni ni o mu ki Ọlọrun dáọwọ ibinu gbigbona Rè̩ duro. Awọn eniyan buburu kò yẹ si ọkan ṣoṣo ninu ibukun Ọlọrun Wọn n ṣaigbọran si I, wọn n sọrọ odi si I, wọn a si maa fi ofin Rè̩ṣe yè̩yé̩. Sibẹ awọn pupọ ni o n rò pe wọn yoo lọ si Ọrun ni iru ipo bẹẹ. Wọn rò wi pe bi wọn ba sa ti le tẹle ilana ẹsin kan, Ọlọrun yoo tẹwọgba wọn, lai fi irú igbesi-ayé ti wọn gbe pè.
Ọlọrun sọ fun awọn Ọmọ Israẹli gbangba ohun ti O rò nipa ilana ẹsin ti wọn n tẹle, nigba ti ọkàn wọn kòṣe deedee pẹlu Rè̩. O beere pe: “Kini ọpọlọpọẹbọ nyin jasi fun mi? ,… emi kún fun ọrẹ sisun agbò, ati fun ọráẹran abọpa; … Ẹ má mu ọrẹ asan wá mọ: turari jasi ohun irira fun mi; oṣù titun ati ọjọ isimi, ìpe ajọ, emi kò le rọju gbà.” Lati jé̩ẹni itẹwọgba lọdọỌlọrun tayọ lilọ si ile Ọlọrun ni Ọjọ Oluwa, ki a maa kọrin, ki a maa sọrọ rere nipa Jesu tabi ki a maa gbadura gigun nikan. O wi pe: “Nigbati ẹnyin ba gbà adura pupọ, emi ki yio gbọ: ọwọ nyin kún fun èjẹ.”
Eyi kò fi hàn pe Oun ki yoo gbọ adura ẹlẹṣẹ. Bi ẹnikẹni bá ronupiwada ti o si tọrọ idariji, Ọlọrun yoo gbọ. “Irobinujẹ ati irora aiya, Ọlọrun, on ni iwọ ki yio gàn.” S̩ugbọn eniyan ni lati yipada kuro ninu iṣe buburu rè̩ ki o ba le ri igbala.
Wọn sọ Ilu Mimọ di Aimọ
Igba kan wà ti ilu Jerusalẹmu jé̩ mimọ. Dafidi kọ akọsilẹ wi pe: “Lati Sioni (Jerusalẹmu) wá, pipéẹwà, Ọlọrun ti tan imọlẹ.” IfẹỌlọrun fun ilu mimọ Rè̩ ni eyi. A le fi ẹwà pipé ti ilu naa ní ni akoko naa wé igba kan, nitori akoko naa yoo dé ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdún nigba ti yoo jé̩ ilu mimọ ni tootọ. “Nwọn ki yio panilara, tabi ki nwọn panirun ni gbogbo oke mimọ mi, li Oluwa wi” (Isaiah 65:25).
S̩ugbọn wò iru ipo ti Jerusalẹmu wà ni akoko ti Isaiah kọ akọsilẹ yii! “Ilu otitọ ha ti ṣe di àgbere! o ti kún fun idajọ ri; ododo ti gbe inu rè̩ ri; ṣugbọn nisisiyi, awọn apania.” Gba eyi rò! Ninu Ilu MimọỌlọrun, nibi ti O fẹ ki ododo ati ohun rere nikan gbilè̩, iwa buburu ni o gbilẹ nibẹ. “Awọn ọmọ-alade rẹ di ọlọtẹ, ati ẹgbẹ olè: olukuluku nfé̩ọrẹ, o si ntọ erè lẹhin: nwọn ko ṣe idajọ alainibaba, bḝni ọran opó ko wá sọdọ wọn.” Awọn eniyan ti o wà ni ipo giga ti o yẹ lati ṣe iranwọ fun awọn alaini ati opó, kun fun iwa abè̩té̩lè̩. Wọn fé̩ọrẹ, wọn a si maa ṣiṣẹ fun erè ara wọn dipo ti wọn i ba fi ṣe iranwọ fun awọn ti o n fé̩ iranlọwọ wọn.
Ọlọrun ri gbogbo nnkan wọnyii. Ọlọrun n ri awọn aninilara lọjọ oni. O ti wi pe ọjọ ibè̩wò kan n bọ. A o mu awọn eniyan buburu wá sinu idajọ nitori iwa buburu wọn.
Asọtẹlẹ ti Isaiah sọ nipa ilu Jerusalẹmu jẹ mọ igbà Ijọba Ẹgbè̩rún Ọdún. Nigba naa a o maa pe Jerusalẹmu ni ilu ododo, ilu oloootọ. Ki yoo si awọn alaiṣootọ onidajọ mọ; bẹẹ ni awọn igbimọ yoo si wà gẹgẹ bi wọn ti ri nigba ti Dafidi wi pe, “Lati Sioni wá, pipéẹwà, Ọlọrun ti tan imọlẹ” (Orin Dafidi 50:2).
S̩iṣe Rere
Ọlọrun jẹ oloootọ si Israẹli apẹyinda, O si sọ fun wọn bi wọn ti ṣe le ri ojurere Ọlọrun. Isaiah sọ fun wọn pe: “Dawọ duro lati ṣe buburu; kọ lati ṣe rere; wá idajọ, ràn awọn ẹniti anilara lọwọ, ṣe idajọ alaini baba, gbàẹjọ opó wi.”
Ki a dawọ buburu iṣe duro nikan kò tó. Eniyan le yipada kuro ninu gbogbo ìwa buburu rè̩, ki o joko, ki o si káwọ gbera, ki o si maa yọ pe oun kò dabi awọn eniyan buburu. Eyi yii ki yoo mu ire bá a. Eniyan ni lati kọ lati ṣe rere pẹlu. A ni lati fi hàn fun araye pe Ọlọrun ti ṣe iṣẹ iyipada ninu ọkàn wa.
Iṣẹ wọnyii ki i ṣe kiki iwaasu, adura gbigba, orin kikọ, ati pe ki a maa sọrọ nipa Jesu nikan. Lati igba de igba ni Ọlọrun n sọ nipa ṣiṣe aanú fun awọn alaini ati awọn alai-ni-oluranlọwọ. Onipsalmu kọ akọsilẹ kan wi pe: “Ibukún ni fun ẹniti nrò ti awọn alaini, Oluwa yio gbà a ni igbà ipọnju” (Orin Dafidi 41:1).
Ọlọrun Alasọye
Ọkan ninu awọn ẹsẹ ti o ṣe iyebiye ju lọ ninu ỌrọỌlọrun ni a ri ninu ori kin-in-ni iwe Isaiah: “OLUWA wipe, wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ: bi è̩ṣẹ nyin ba ri bi òdodó, nwọn o si fun bi òjo-didi; bi nwọn pọn bi àlāri, nwọn o dabi irun-agutan.” Wò bi Ọlọrun ti jé̩ alaaanu ati oninuure tó! Kò tọ ki Ọlọrun tun fi aanu hàn mọ. Eniyan ti dè̩ṣẹ si Ọlọrun, o si yẹ si ikú nitori è̩ṣẹ rè̩. S̩ugbọn Ọlọrun ninu aanú Rè̩ na ọwọ Rè̩ gboorò O si n pè wi pe, “Wá.” Wá nisisiyi. Maṣe fi ọjọ igbalà dọla. Ọjọọla le pé̩ jù. “Kiyesi i, nisisiyi ni akoko itẹwọgbà; kiyesi i, nisisiyi ni ọjọ igbala” (2 Kọrinti 6:2).
“Ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ.” Awawi, nipa eredi rè̩ ti ẹni kan kò fi kuro ni ipo è̩ṣẹ, ki yoo le duro niwaju Ọlọrun. Jesu kú fun è̩ṣẹ wa, Ẹjẹ Rè̩ yoo si fọ wa funfun ju ojo-dídì nigba ti a bá kọè̩ṣẹ wa silẹ ti a si tọrọ idariji. Kò si ohun ti a le mu wá afi ọkàn wa; Oun fun wa ni ohun gbogbo. Sibẹ O wi pe Oun yoo ba wa sọ asọyé pọ. Olugbala iyanu wo ni Jesu Oluwa mi yii!
Ni akokò kan Oluwa beerè nipa Israẹli pe: “Kini a ba ṣe … ti emi kò ti ṣe?” (Isaiah 5:4). Jesu fi ohun gbogbo lelè̩ lati gbà wa kuro lọwọè̩ṣẹ, ani ẹmi Rè̩ paapaa. Kò ha yẹ fun wa lati sure tọỌ wá, ki a bẹbẹ fun aanú, ki a si tọrọ idariji è̩ṣẹ? Ki ni ṣe ti awọn eniyan yoo fi maa gàn ifẹỌlọrun?
Ki i ṣe pe Ọlọrun n wẹè̩ṣẹ nù nikan, ṣugbọn Oun a maa bukun awọn ti o n sin In. “Bi ẹnyin ba fé̩ ti ẹ si gbọran, ẹnyin o jẹ ire ilẹ na.” Dajudaju ẹni ibukun ni awọn eniyan Ọlọrun!
Idajọ lori Ọlọtẹ
A le rò pé gbogbo eniyan ni yoo fẹ lati ri igbala ki wọn si ni ibukun Ọlọrun. S̩ugbọn kò ri bẹẹ pẹlu ọpọlọpọ eniyan. Wọn n ṣọtè̩ si Ọlorun, wọn si fẹ gba ọna ti ara wọn. Eyi ni ohun ti Ọlọrun sọ nipa wọn: “Bi ẹnyin ba kọ, ti ẹ si ṣọtè̩, a o fi idà run nyin.” O si fi idi rè̩ mulẹ nigba ti o fi kun un wi pe, “Nitori ẹnu OLUWA li o ti wi i.” Nigba ti Ọlọrun ba sọ ohun kan yoo ṣẹ.
Idajọọgan ti yoo tẹle ọrọ ti Isaiah sọ ni wi pe a o kó awọn Ọmọ Israẹli ni ẹrú lọ si orilẹ-ède awọn keferi. S̩ugbọn idajọ n bọ wá sori gbogbo ẹlẹṣẹ -- bi kò ba ṣẹlẹ laye yii, yoo ri bẹẹ ni aye ti n bọ. Lẹyin ikú, idajọ.
Loni, Jesu n pe sibẹ: “Wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ.” “Ati Ẹmi ati iyawo wipe, Mā bọ. Ati ẹniti o ngbọ ki o wi pe, Mā bọ, Ati ẹniti ongbẹ ngbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o ba si fẹ, ki o gbà omi iye na lọfẹ” (Ifihan 22:17).
Questions
AWỌN IBEERE1 Ta ni rán Isaiah niṣẹ si Israẹli?
2 Irúọba wo ni Ussiah ati Hẹsekiah i ṣe?
3 Bawo ni Ọlọrun ti ṣe “tọ” Israẹli?
4 Bawo ni Ọlọrun ti ṣe fi Israẹli wéẹran-ọsin?
5 Ki ni ṣe ti Ọlọrun kò fẹẹbọ ti awọn Ọmọ Israẹli n rú?
6 Irú ipò wo ni Jerusalẹmu wà nigba ti Isaiah n kọ akọsilẹ yii?
7 Lẹyin ti Ọlọrun ti sọè̩ṣẹ Israẹli fun wọn, ki ni O beere pe ki awọn eniyan naa ṣe?
8 Ki ni yoo ṣẹlẹ si wọn bi wọn ba kọỌ?
9 Ki ni ohun ti Ọlọrun ṣeleri fun ẹni rere ati olugbọran?
10 Ki ni ohun ti O ṣeleri fun awọn ti wọn n ro ti awọn alaini?