Isaiah 5:1-30

Lesson 349 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Egbe ni fun awọn ti npè ibi ni rere, ati rere ni ibi, ti nfi okùnkun ṣe imọlẹ, ati imọlẹṣe okùnkun” (Isaiah 5:20).
Notes

Iṣura Ọwọn fun Ọlọrun

Ọlọrun fẹran awọn ayanfẹ Rè̩, awọn Ọmọ Israẹli. Nigba kan O pe wọn ni “iṣura āyo” Rè̩ (Orin Dafidi 135:4). O wi pe, “Mo fi okùn enia fà wọn, ati idè ifẹ” (Hosea 11:4). Nigba ti orilẹ-ède Israẹli bọ kuro ni oko-ẹrú Egipti, Ọlọrun wi pe, “Mo ti rù nyin li apa iyé̩-idi, ti mo si mú nyin tọ ara mi wá” (Ẹksodu 19:4). Wò bi Ọlọrun ti fẹran Israẹli tó!

S̩ugbọn Israẹli ti fi aimoore fàsẹyin kuro ninu ifẹ yii, wọn si n bọriṣa dipo ki wọn sin Ọlọrun. Wọn kò mọ rírì gbogbo ohun rere ti O ti ṣe fun wọn; wọn si kọ lati gbọran si aṣẹ Rè̩.

Orin Isaiah

Ni ọjọ kan Ọlọrun sọ fun Isaiah wi pe ki o kọ orin lati rán awọn Ọmọ Israẹli leti ohun ti Oun ti ṣe fun wọn. “Nisisiyi, emi o kọ orin si olufẹọwọn mi, orin olùfẹ mi ọwọn ni ti ọgba àjara rè̩.” Jesu ni “ayanfẹ” Ọlọrun O si fi Israẹli wéọgbà-ajara kan lori okèẹlẹtù loju, ọgbà-ajara ti a sọọgba yika rè̩.

Ọlọrun ti fi Ilẹ Kenaani fun Israẹli, O si ti sọ ibi ti aalà ilẹ wọn dé fun wọn. Aalà wọnni ni ọgbà ti Isaiah n kọrin nipa rè̩. Abrahamu ni a kọṣeleri ilẹ yii fun; lẹyin eyi, nigba ijọba Sọlomọni ọba, awọn eniyan n gbéọpọlọpọ ninu rè̩. Bi awọn Ọmọ Israẹli bá gbọran si aṣẹỌlọrun, kò si ẹni kan ti i ba lagbara lati gbàá lọwọ wọn.

Ọlọrun ti ṣa awọn “okuta” (tabi awọn keferi) kuro ninu “ọgba àjara” naa. O ti lé awọn orilẹ-ède keferi kuro niwaju awọn Ọmọ Israẹli nigba ti wọn dé Ilẹ Kenaani. Kiki awọn Ọmọ Israẹli nikan ni Ọlorun n fẹ ki o maa gbé nibẹ. Bi wọn ba ti ṣe gẹgẹ bi Oun ti fẹ ki wọn ki o ṣe, igbesi-ayé wọn i ba kún fún ibukun, wọn i ba si ṣẹgun gbogbo ọtá.

Eso Kíkan

Ọlọrun kà awọn eniyan Rè̩ si “ayànfẹàjara” Rè̩. O gbìn wọn si ilẹ Kenaani, O si fi ohun rere gbogbo té̩ wọn lọrun. S̩ugbọn nitori pe Israẹli pẹyinda si Ọlọrun, Ọlọrun wi pe, “O si wò pe ki o so eso, ṣugbọn eso kikan li o so.” Wò o bi ijatilè̩ naa ti pọ tó!

Bawo ni ọkàn rẹ yoo ti ri bi iwọ ba ti ṣe wahala gidigidi lati ṣà okuta kuro ninu ilẹ kan, ti o si jé̩ pe ọwọ ni iwọ fi ṣà okuta wọnni lọkọọkan; ti iwọ si ṣe ọgbà yi i ká, ti o si gbin aṣayan àjara, ti o si ṣe ibi-ifunti sinu rè̩ pẹlu lati fi fún eso rè̩; lẹyin gbogbo wahala yii, nigba ti iwọ fẹ kórè ohun-ọgbin rẹ ki iwọ wa ri pe kiki eso kikan ni o wà nibẹ. Iwọ kò ri ohun kan mu jade pẹlu gbogbo iṣẹ-aṣekara ati inawo rẹ. Otubantẹ! Ohun ti Ẹni ti a sọrọ rè̩ ninu orin yii ṣe gan ni iwọ naa yoo fẹṣe: iwọ yoo wòọgbà rè̩ lulè̩, iwọ yoo si fi i silẹ fun èpo lati hù sibẹ ki awọn ẹranko si maa gbé ibẹ.

Idajọ Otitọ

Gẹgẹ bi o ti tọ, Ọlọrun pe Israẹli ati Juda lati ṣe idajọọràn ajara naa: “Kini a ba ṣe si ọgba àjara mi ti emi kò ti ṣe ninu rè̩?’ Iwọ ha le ronu ohun miiran ti o yẹ ki Oun ki o ṣe si ọgbà ajara yii ki o ba le mu eso rere jade wa?

Iwọ ha le ronu ohun miiran ti o yẹ ki Ọlọrun ṣe lati mu ki Israẹli eniyan Rè̩ṣe rere gẹgẹ bi orilẹ-ède? O mú wọn jade lati ilẹ Egipti wá, nigba ti wọn jẹ orilẹ-ède ti o wà labẹ isinru; O si fun wọn ni ilẹ eleso eyi ti a ti kọ tẹlẹ. O lé awọn ọta wọn kuro niwaju wọn. O sọ fun wọn pe awọn ni yoo maa ṣe ori, awọn orilẹ-ède iyoku yoo si jẹìrù. O fi isin otitọ lé wọn lọwọ, Ọlọrun kan ti O n gbọ adura wọn ti O si n dahun. Gbogbo nnkan wọnyii ni Ọlọrun ṣe fun awọn eniyan Rè̩.

Nigba ti Ọlọrun fẹ ki wọn ṣe ohun kan fun Oun – lati waasu igbala fun gbogbo ayé -- wọn kọ wọn si n bọriṣa. Wọn gbagbe Ọlọrun, bẹẹ ni ọkàn wọn si kún fún ibi nigba gbogbo. Wọn kò tilẹ ni ifẹ si ara wọn. “O reti idajọ, ṣugbọn kiyesi i, inilara; o si reti ododo; ṣugbọn kiyesi i, igbe.” Igbesi-ayé wọn si dabi ilẹ aṣalè̩ ti Ọlọrun dáòjo rè̩ duro.

Kò si Òjo

Ọlọrun ti kilọ fun wọn nigba ti wọn fi Egipti silẹ nipa ohun ti yoo ṣẹlẹ si wọn bi wọn bá yipada kuro lẹyin Rè̩. Ọkan ninu rè̩ ni pe Oun yoo dawọòjo duro. Ọlọrun a maa jẹ ki òjo rọ nigba ti O ba fé̩; bi O ba si sé e mọ, òjo ki yoo si rọ. Kò si ohun ti o le hù bi kò ba si omi, nitori naa ilẹ Kenaani di aṣalẹ. Kò si ẹni ti o fé̩ lati gbé inu rè̩, bẹẹ ni awọn Ọmọ Israẹli (ti a n pe ni Ju) ṣi kuro nibẹ. O tilẹṣoro fun awọn Larubawa ti o wà nibẹ lati ri koriko fun awọn ẹṣin ati rakunmi wọn, ọpọlọpọ ninu wọn si palẹ agọ wọn mọ, wọn si ṣi kuro nibẹ. Bẹẹ ni ilẹ ti i ba jé̩ọgbà-àjara eleso si pada si aṣalè̩ alaileso. Fun ọdún pupọ ni ilẹ Palẹstini wà laileso, gẹgẹ bi ijiya nitori pe awọn Ọmọ Israẹli kọ Kristi silẹ.

IfẹỌlọrun si Wa

Ẹ jẹ ki a ṣe aṣaro nipa ohun ti Ọlọrun ti ṣe fun wa. O ran Jesu Ọmọ bibi Rè̩ kan ṣoṣo lati kú fun wa. Ofin Rè̩ ni eyi, “Ọkàn ti o báṣè̩, on o kú.” Olukuluku eniyan ni o ti dé̩ṣè̩ ri ti o si yẹ si ikú, ṣugbọn Jesu yọọda lati kú dipo wa. Wò bi o ti yẹ ki a kún fún ọpé̩ tó, pe Jesu ṣetan lati gbàìyà ti wa jẹ. S̩ugbọn a ni lati ni ifẹ lati tọỌ wá ki a si gbà wa là, bi bẹẹ kọ a o jiya.

Ọpọlọpọ eniyan ni o kọ lati wá Igbalà. Jesu n sọkun lori wọn gẹgẹ bi O ti sọkun lori Jerusalẹmu ọlọtè̩: “Jerusalemu, Jerusalemu, ..igba melo li emi nfẹ radọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ ti iradọ bò awọn ọmọ rè̩ labẹ apá rè̩, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ!” (Matteu 23:37). Ẹwẹ, O tun n beerè pe, “Kini a ba ṣe .. ti emi kò ti ṣe?” Ki ni Jesu i ba tun ṣe lati múẹlè̩ṣẹ wá si ironupiwada ki O si mu wọn lọ si Ọrun?

Itọni

Jesu wá si ayé lati fi ilana iye hàn wá. Bibeli sọ fun wa bi O ti ṣe lo igbesi-ayé Rè̩, O si fẹ ki a dabi Oun. A kò le sọ pe a kò mọ bi awa i ba ti ṣe maa huwa. O fi akọsilẹỌrọ Rè̩ fun wa lati kọ wa nipa ohun gbogbo ni ayé.

Lẹyin eyi nipa ikú Rè̩ lori oke Kalfari, ati Ẹjẹ ti O ta silẹ, O fun wa lagbara lati maa gbé igbesi-ayé ailẹṣẹ. Ki ni o kù ti Oun i ba tun ṣe.

Kikú fun awọn Ọta Rè̩

Bọya o ti maa n gbọ pe ẹni kan fi ẹmi rè̩ lelè̩ fun awọn ọrẹ rè̩. S̩ugbọn iwọ kò le nireti pe ẹni kan le kú fun ọtá rè̩. Jesu ṣe bẹẹ. Paulu Apọsteli sọ fun wa pe: “O ṣọwọn ki ẹnikan ki o to kú fun olododo: .. S̩ugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa” (Romu 5:7, 8). Jesu kú fun awọn ọta Rè̩ nitori pe O fé̩ wọn O si fẹ gbà wọn là.

Kò ha tọ fun wa lati yara jé̩ ipè Rè̩? O ti ṣe gbogbo eyi ti O le ṣe lati gbà wa lọwọọrun apaadi. O n pè nisisiyi pe: “OLUWA wipe, wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ: bi è̩ṣẹ nyin ba ri bi òdodó, nwọn o si fun bi òjo-didi” (Isaiah 1:18).

Ijiya fun Aigbọran

Idajọ wọnni ti Ọlọrun pinnu sori awọn Ọmọ Israẹli yoo wá sori olukuluku ẹni ti o ba yipada kuro lọdọ Rè̩. O wi pe, “Egbe ni fun awọn ti ima dide ni kùtukutu, ki nwọn le ma lepa ọti lile; ti nwọn wà ninu rè̩ titi di alẹ, titi ọti-waini mu ara wọn gbona!” Awọn ẹlomiran rò pe kò si ohun ti o buru ninu mimu ọti lile, bi wọn kò ba ti mu amupara; ṣugbọn wolii nì tun wi pe: “Egbe ni fun awọn ti o ni ipá lati mu ọti-waini, ati awọn ọkunrin alagbara lati ṣe adàlu ọti lile!” Bi wọn tilẹ lagbara lati mu ọti lai mu amupara, sibẹsibẹ ohun ti o lodi ni. Ọrun apaadi ti ṣi ọgbun rè̩ silẹ lati gbà iru awọn ẹlẹṣẹ bẹẹ, ati awọn miiran pẹlu.

Ọlọrun wi pe eṣu ati awọn angẹli rè̩ ni a pese ọrun apaadi silẹ fun lati atetekọṣe; ṣugbọn bi awọn eniyan ba kọ lati ri igbalà, awọn pẹlu yoo lọ sibẹ.

Ọlọrun gegun fun awọn ti n pe ibi ni rere, ati rere ni ibi. Ọpọlọpọ ibi ni o wà ni aye nisisiyi ti awọn eniyan n pe ni è̩ṣẹ gbajumọ. S̩ugbọn ranti pe bi Ọlọrun ba sọ pe ohun kan kò dara, eyi nì ni pe kò dara, lai ka ohun ti awọn eniyan n wi nipa rè̩ si nnkan.

Ọlọrun gegun pẹlu fun awọn ti o n gba abẹtẹlẹ lati bo è̩ṣẹ mọlẹ -- awọn ẹni ti “o da are fun ẹni-buburu nitori ère.” Nigba ti a ba kà akọsilẹ nipa è̩ṣẹ igba-ayé awọn Ọmọ Israẹli, bakan naa ni o ri pẹlu è̩ṣẹ awọn eniyan lode oni. “Nitorina ni ibinu OLUWA fi ràn si enia rè̩.”

A kò fẹ ki eyikeyi ninu idajọègún wọnyii ki o wá sori wa, nitori naa ẹ jẹ ki a fi ọkàn wa fun Ọlọrun nigba ọdọ wa. Ẹ jẹ ki a maa rin pẹlu ikiyesara ni gbogbo ọjọ-ayé wa, ni igbọran si Ọrọ Rè̩, ki a ba le ni ibukun Ọlọrun nihin ni ayé ati awọn ti o ti lọ pese silẹ fun awọn ti wọn fẹẸ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni a fi Israẹli wé ninu orin yii?

  2. 2 S̩apejuwe ohun ti Ọlọrun ṣe si ọgbà-àjara Rè̩.

  3. 3 Ki ni O ri nigba ti O n reti eso?

  4. 4 Ki ni “awọn okuta” duro fun?

  5. 5 Ki ni iyà ti a pinnu sori ọgba-ajara nì?

  6. 6 Ki ni ohun ti Jesu ṣe fun wa?

  7. 7 Ki ni ṣe ti “ipò-okú ti fun ara rè̩ li àye”?

  8. 8 Darukọ diẹ ninu awọn ohun ti ègún Ọlọrun wà lori rè̩.

  9. 9 Ta ni a pè ki o ṣe idajọ laaarin Ọlọrun ati ọgbà-àjara Rè̩?