Isaiah 6:1-13

Lesson 350 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitorina Jesu pẹlu, ki o le fi è̩jẹ ara rè̩ sọ awọn enia di mimọ, o jiya lẹhin bode” (Heberu 13:12).
Notes

Iṣé̩ Isaiah

Ọlọrun ni iṣẹ pupọ fun Isaiah lati ṣe. Ọlọrun pè e lati kilọ fun awọn Ọmọ Israẹli nipa idajọ ti yoo wá sori wọn nitori è̩ṣẹ wọn; ati lati sọ fun wọn nipa Jesu, Messia ti O n bọ wá gba iyoku ile Israẹli là. Ki i ṣe pe Isaiah yoo sọ fun wọn nipa wiwa Jesu ni akọkọ nikan, gẹgẹ bi o ti ṣe nigba ti o kọ akọsilẹ wi pe: “Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rè̩: a o si ma pe orukọ rè̩ ni Iyanu, Oludamọran, Ọlọrun Alagbara, Baba Ayeraye, Ọmọ-Alade Alafia”; ṣugbọn Isaiah tun sọ nipa akoko naa ti Jesu yoo jọba ni ayé yii nigba Ijọba Ẹgbè̩rún Ọdún. “Aginju ati ilẹ gbigbẹ yio yọ fun wọn: ijù yio yọ, yio si tanna bi lili” (Isaiah 35:1). “S̩ugbọn ki ẹnyin ki o yọ, ki inu nyin ki o si dùn titi lai ninu eyiti emi o da: nitori kiyesi i, emi o da Jerusalemu ni inudidùn, ati awọn enia rè̩ ni ayọ … a ki yio si tun gbọ ohùn ẹkún mọ ninu rè̩, tabi ohùn igbe” (Isaiah 65:18, 19).

Imurasilẹ fun Iṣẹ Naa

Ki Isaiah to le sọ asọtẹlẹ nla wọnyii fun awọn eniyan naa, ọkàn oun tikara rè̩ ni lati wà ni imurasilẹ. Lai si aniani a ti gba ọkàn Isaiah là ki o to bẹrẹ si sọtẹlẹ. Ninu ipò idalare yii, o ti sọọpọlọpọ asọtẹlẹ ti o wú ni lori, o si ti waasu fun awọn Ọmọ Israẹli. S̩ugbọn ki o ba le ṣe iṣẹ nla ti o wà niwaju rè̩ lati ṣe yii, o gbà pe ki Isaiah ni ìrírí ti o jinlẹ ju bayii lọ -- eyi nì ni isọdimimọ.

Isaiah ti bẹrẹ iṣẹ asọtẹlẹ rè̩ lati igba ijọba Ussiah ọba. Ọba yii jẹ oloootọ fun ọpọlọpọọdún; ṣugbọn ni opin ijọba rẹ o ṣaigbọran si Ọlọrun, o si di adẹtẹ. A ti kọè̩kọ pe bi ọba kan ba dẹṣẹ, ọpọlọpọ ninu awọn ti o wà labẹ ijọba rẹ ni yoo tẹle apẹẹrẹ buburu rè̩. Nitori naa a mọ pe ni akoko ti Ussiah kú, iwa-ayé awọn Ọmọ Israẹli kò dán mọran mọ.

Adura fun Israẹli

Isaiah lọ si Tẹmpili lọ gbadura. Dajudaju ọràn awọn Ọmọ Israẹli wọnyii n fẹ adura gidigidi. Ọlọrun, jọwọ fun Israẹli ni ẹmi ironupiwada! Oluwa, ṣaanu fun wọn!

Bi o ti n gbadura, ogo Ọlọrun sọkalẹ sori rè̩, o si ri ninu iran bi Oluwa ti joko lori ité̩ ti o ga, ti o si gbé ara Rè̩ soke, iṣé̩tí aṣọ Rè̩ si kún Tẹmpili.

Nigba ti a ba ni iwuwo lọkàn lati gbadura fun awọn ẹlomiran, tabi fun iṣẹ Oluwa, Ọlọrun a maa fà wá mọra, awa yoo si ri diẹ ninu ogo Rè̩. Awa a maa ni idapọ mimọ pẹlu Rè̩ bi a ti n ṣiṣẹ fun Un.

Wo irú anfaani ti Isaiah i ba sọnu bi oun ba ti wi pe eniyan buburu saa ni awọn Ọmọ Israẹli, kò si ṣanfaani lati maa gbadura fun wọn. Bi igbala kò ba jamọ nnkan ni oju wọn, eredi wahala ti rè̩. Bi o ba ni irúèro bayii lọkàn rè̩, oun ki bá ti lọ si Tẹmpili lati gbadura, bẹẹ ni oun ki bá ti ri ogo Ọlọrun.

Bi o ti wù ki awọn eniyan jé̩ọlọkàn lile tó, iṣé̩ ti Onigbagbọ ni lati gbadura tọkantọkàn si Ọlọrun fun igbala wọn, ati lati ni agbára Ọlọrun ninu igbesi-ayé rè̩ to bẹẹ ti ẹlẹṣẹ yoo fi ri i bẹẹ. Awọn eniyan ti fi adura fa isọji sọkalẹ nigba miiran nibi ti awọn eniyan ti fẹrẹ sọ ireti nù péẹnikẹni le ri igbala.

“Jẹ alagbara!

Maṣe wi pe, ‘Buburu ni awọn ọjọ.

Ẹjọ ta ni?’

Ki o si kawọ gbera ki o dagunlá---Kinla!

Dide, sọrọ pẹlu igboya, ni orukọỌlọrun.”

Ogo Ọlọrun

Ki i ṣe kiki pe Isaiah ri iran Oluwa nikan ṣoṣo, ṣugbọn o ri awọn serafu duro lori itẹỌlọrun. Wọn jé̩ irúẹda ti Isaiah kò ti ri ri. Ẹni kọọkan wọn ni iyẹ mẹfa. Wọn fi iyẹ meji bo oju wọn. Wọn mọ ohun ti ẹwà iwa mimọỌlọrun jasi, wọn si le ṣe alai ka ara wọn yẹ lati wo oju Rè̩.

Nigba ti a ba bẹrẹ si woye iwa mimọ Oluwa, a o ri pe awa ko yẹ ni ẹni ti a ba maa pe ni ọré̩ tabi arakunrin Rè̩ (Heberu 2:11). “Kili enia, ti iwọ fi nṣe iranti rè̩? ati ọmọ enia, ti iwọ fi nbè̩ẹ wò?” (Orin Dafidi 8:4). Nigba ti a ba wà ni ile Ọlọrun a kò gbọdọ huwa lọná ti yoo tabuku si ogo Rè̩. Awọn serafu yii fi meji ninu iyẹ wọn bo ẹsẹ, wọn si n fi iyẹ meji iyoku fò lati mu aṣẹỌlọrun ṣẹ kánkán.

Bi awọn serafu wọnyii ti n fò yi itẹỌlọrun ka, ekinni si ke si ekeji pe, “Mimọ, mimọ, mimọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun, gbogbo aiyé kún fun ogo rè̩.” Bi awọn eniyan ba le maa yin Ọlọrun logo, wọn o mọ riri ogo ti o wa nibi gbogbo. Oju Rè̩ wà ni gbogbo ayé, ibikibi ti awọn eniyan ba si gbé n gbadura, Oun yoo wá sibẹ lati dahun. Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan maa yin Oun. Gbogbo awọn è̩da Ọrun ni wọn n yin Ọlọrun logo.

Bi awọn serafu ti n kọrin, ogo Ọlọrun kún inu Tẹmpili gẹgẹ bi eefin. Awọn opó Tẹmpili paapaa mì nipa agbára ti o wà ninu rè̩. Njẹ iwọ ha le woye irú ipò ti Isaiah wà nigba ti o ri gbogbo ogo ati agbára yii? Dajudaju yoo mọ ara rè̩ ni alai yẹ. Bẹẹ ni orilẹ-ède Israẹli kún fun è̩ṣẹ pupọ lakoko yii! Ki ni ṣe ti Ọlọrun ni lati fi ara Rè̩ hàn fun wọn ninu iru ogo nla bayii? Isaiah mọ wi pe oun ni lati ni iwà-mimọ sii ninu ọkàn rè̩. O fi irè̩lè̩ ke pe Ọlọrun lati ran oun lọwọ.

Nigba ti a ba mọ aini wa ti a si n fẹ iranlọwọ lati ọdọỌlọrun, nigba naa Oun yoo ràn wá lọwọ. Nigba ti a ba fi irè̩lè̩ tọỌ wá, Oun yoo gbọ ohùn è̩bè̩ wa yoo si dahùn.

Ọkan Funfun

Bi Isaiah ti n gbadura, ọkan ninu awọn serafu múè̩ṣé̩-iná ni ọwọ rè̩ lati ori pẹpẹ wá, o si fò wá sọdọ Isaiah, o si fi kan an ni ẹnu, o si wi pe, “Kiyesi i, eyi ti kàn etè rẹ, a mu aiṣedede rẹ kuro, a si fọè̩ṣẹ rẹ nù.”

Nigba ti a gba ọkàn Isaiah là, a ti dari è̩ṣẹ rè̩ ji i, ani awọn ohun aitọ ti o ti ṣe. S̩ugbọn ẹda è̩ṣẹ, ti a maa n mẹnu kan ninu Bibeli bi ẹyọ ohun kan ṣoṣo (è̩ṣẹ), wà nibẹ sibẹ. O yẹ ki a sọọ di mimọ. Isọdimimọ ni o n fọọkàn, ti o si n wẹẹ mọ.

Nigba ti Dafidi dẹṣẹ, o gbadura pe ki a nù irekọja oun nù kuro. Ohun ti o n sọ nihin ni pe, “Dari awọn è̩ṣẹ ti mo ti ṣè̩ ji mi.” Lẹyin eleyii ni o tun wi pe: “Wè̩ mi li awẹmọ kuro ninu aiṣedede mi, ki o si wè̩ mi nù kuro ninu è̩ṣẹ mi” (Orin Dafidi 51:1, 2). Eleyii ni n sọ nipa isọdimimọ, ọkàn funfun.

Isaiah ti gbọ bi awọn serafu ti n kọrin nipa ẹwa iwa-mimọỌlọrun. Bi oun bá fé̩ lati sin Ọlọrun ni ọna ité̩wọgbà, oun ni lati jé̩ mimọ pẹlu. Orukọ miiran ti a n pe isọdimimọ ni iwa-mimọ.

Ọlọrun wi pe, “Ẹ jẹ mimọ; nitoriti emi jẹ mimọ” (1 Peteru 1:16). Ọlọrun n fé̩ ki a jé̩ mimọni aye yii. O bura fun Abrahamu, “Pe on o fifun wa, lati gbà wa lọwọ awọn ọtá wa, ki awa ki o le ma sin i laifòya, ni mimọ iwa, ati li ododo niwaju rè̩, li ọjọ aiyé wa gbogbo” (Luku 1:73-75). Ikú kò le sọ eniyan di mimọ.

Mẹtalọkan Pesẹ

Ẹ jẹ ki a ṣe akiyesi pe Mẹtalọkan Mimọ fi ara hàn ninu iran yii. Awọn serafu n kọrin wi pe, “Mimọ, mimọ, mimọ,” wọn n yin Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ. Nigba ti Oluwa sọrọ, O wi pe, “Tali emi o rán?” O si tun beere wi pe, “Tani yio si lọ fun wa?” Ẹni ti o wa nibẹ ju Ẹni kan lọ.

Awọn miiran le wi pe, Jesu kò si ni ibi kan titi di igba ti a fi bi I ni Bẹtlẹhẹmu. S̩ugbọn nigba ti Johannu Apọsteli n sọ nipa iriri Isaiah ninu Tẹmpili, o wi pe, Jesu wà nibẹ. Johannu sọ nipa iṣẹ-iyanu ti Jesu n ṣe nigba ti O wà ni ayé, o si wi pe awọn eniyan naa kò gbà A gbọ gẹgẹ bi wọn kò ti gba Isaiah gbọ ni ọpọlọpọọdún ṣaaju akoko yii. Isaiah wi pe: “O ti fọ wọn loju, o si ti se àiya wọn le; ki nwọn má ba fi oju wọn ri, ki nwọn má ba fi ọkàn wọn mọ, ki nwọn má ba yipada, ki emi má ba mu wọn larada” (Johannu 12:40). Johannu wi pe, “Nkan wọnyi ni Isaiah wi, nitori o ti ri ogo rè̩, o si sọrọ rè̩ (Jesu)” (Johannu 12:41). Eyi yii fi hàn pe Ẹmi Mimọ ti fi hàn fun Johannu pe Jesu wà ninu Tẹmpili nigba ti a sọ Isaiah di mimọ, ni ọpọlọpọọdún sẹyin ki a tó bi Jesu ni Bẹtlẹhẹmu.

Jijẹ Ipe

Iriri ologo ni o jé̩ fun Isaiah lati ri ojurere Ọlọrun lọnà pataki bayii; ṣugbọn ogo ati ibukun ti o ri gba yii ki i ṣe fun oun nikan ṣoṣo. A fun un ni iranwọ yii lati fun un ni agbára ati ọgbọn lati sọ fun Israẹli apẹyinda nipa ti Oluwa. Gẹrẹ ti ibukun yii tẹẹ lọwọ, ni o gbọ ohun Oluwa wi pe, “Tali emi o rán, ati tani o si lọ fun wa?” O dahun lọgan wi pe, “Emi nĩ, rán mi.” O mọ ara rè̩ ni alaiyẹ sibẹ, ṣugbọn bi iṣẹ ba wà lati ṣe, o ṣetan lati ṣe e.

Ki i ṣe ohun ti o rọrùn. Awọn eniyan wọnyii ki yoo feti si Isaiah. Ọpọlọpọ igba ni yoo rò wi pe iwaasu rè̩ kò ja mọ nnkankan. S̩ugbọn Ọlọrun sọ fun un pe ki o lọ, o si gbọran. Nitori pe awọn eniyan naa fẹran è̩ṣẹ, wọn ki yoo le ri ẹwà ti o wà ninu Ihinrere. Wọn ki yoo gbọ ihin ayọ igbala. Wọn yoo sé aya wọn le to bẹẹ ti Ẹmi Ọlọrun ki yoo le wọle. S̩ugbọn sibẹ Isaiah ni lati waasu.

Yoo ti Pẹ To?

Isaiah mọ pe iṣẹ na wuwo, o si beere pe, “Yio ti pẹ to?” Yoo ti pẹ to ti Israẹli yoo maa jiya nitori è̩ṣẹ rè̩? Yoo ti pẹ to ti wọn yoo maa kọ iṣẹ ti Ọlọrun rán si wọn? Awọn Ju ti jiya fun ọpọlọpọọdún lati igbà ni, wọn si n beere sibẹ wi pe, “Yio ti pẹ to?” Yoo ti pẹ to ki wọn to mọ Messia wọn ti yoo si mu idasilẹ wá fun wọn?

A tú awọn Ju ká kuro ni ilẹ Palẹstini lẹyin ti wọn kan Jesu mọ agbelebu. Ojo dẹkun lati maa rọ sori ilẹ wọn, nitori naa ounjẹṣọwọn. Ile wọn di ibajẹ gẹgẹ bi Isaiah ti sọ tẹlẹ.

“S̩ugbọn sibẹ, idamẹwa yio wà ninu rè̩, yio si pada.” Isaiah wi pe awọn diẹ yoo pada. Jesu wi pe, “Jerusalemu yio si di itẹmọlẹ ni ẹsẹ awọn Keferi, titi akoko awọn Keferi yio fi kún” (Luku 21:24).

Akoko awọn Keferi fẹrẹ dopin. Ojo ti bè̩rè̩ si irọ ni Palẹstini, bẹẹ ni awọn Ju ti bè̩rè̩ si pada lati orilẹ-ède gbogbo lati maa gbé Ilẹ Mimọ nì. ỌrọỌlọrun ti bè̩rè̩ si ṣẹ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Sọ diẹ ninu awọn ohun rere ti Isaiah sọ asọtẹlẹ rè̩.

  2. 2 Iru imurasilẹọkàn wo ni Isaiah ni lati ṣe fun iṣẹ nla ti o wà niwaju rè̩?

  3. 3 Nibo ni Isaiah wà nigba ti o ri iran yii?

  4. 4 Ki ni Isaiah ri?

  5. 5 Bawo ni ọkàn Isaiah ti ri nigba ti o ri gbogbo ogo yii?

  6. 6 Ki ni serafu naa ṣe si Isaiah? Ki ni o si wi?

  7. 7 Ki ni ọrọ miiran ti a n lò fun isọdimimọ?

  8. 8 Bawo ni a ṣe mọ pe a le jé̩ mimọ ni ayé isisiyii?

  9. 9 Bawo ni a ṣe mọ pe Jesu wà ninu Tẹmpili lakoko yii ki a to bi I ni Bẹtlẹhẹmu?