Lesson 351 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Iwọ ni ibi ipamọ mi ati asà mi: emi nṣe ireti ninu ọrọ rẹ” (Orin Dafidi 119:114).Notes
ỌrọỌlọrun
Wolii ni Isaiah i ṣe. O sọỌrọỌlọrun fun awọn Ọmọ Israẹli a si kọ akọsilẹọrọ rè̩ sinu Bibeli fun anfaani gbogbo eniyan. Ọlọrun mi si Isaiah lati sọ asọtẹlẹ awọn ohun ti o n bọ wa ṣẹ, awọn miiran ninu asọtẹlẹ Isaiah ti ṣẹ. Isaiah sọ asọtẹlẹìbí Olugbala. O wi pe: “Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa” (Isaiah 9:6). Eyi ṣẹ nigba ti a bi Jesu. Isaiah si tun wi pe: “A ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rè̩, ati nipa ìna rè̩ li a fi mu wa lara da” (Isaiah 53:5). Ọrọ wọnyii n tọka si kikan Jesu mọ agbelebu eyi ti o ṣẹlẹ lẹyin ọdún pupọ.
Ti a o Muṣẹ
A kò i ti i mu awọn miiran ṣẹ ninu asọtẹlẹ Isaiah. Isaiah ati awọn wolii miiran sọ asọtẹlẹ nipa Ipọnju Nla. Kò ti i ṣẹlẹṣugbọn o le wá sori ayé ati awọn eniyan ti o wà ninu rè̩ lai pẹ jọjọ.
Ipọnju jé̩ igba ati akoko ìyà ati iṣé̩. Ipọnju Nla yoo buru to bẹẹ ti kò si è̩dá ti yoo le là a bi kòṣe pe a ke ọjọ wọnni kuru. Isaiah wi pe, “enia diẹ li o si kù.” Ipọnju yii yoo tobi ju igba ijiya miiran gbogbo lọ, “irú eyi ti kò si lati igba ibẹrẹọjọìwa … irú rè̩ ki yio si si” (Matteu 24:21). Ipọnju Nla yii yoo bá gbogbo eniyan ti o wà lori ilẹ ayé. Ki yoo si aanu rara. Gbogbo eniyan ni yoo jiya -- awọn oṣiṣẹ ati awọn ọgá wọn, awọn eniyan ati awọn alufaa èké wọn, olutà ati olúrà, ọlọrọ ati tálákà.
Aye yoo Mì
Ki ni yoo ṣẹlè̩ si ayé ati awọn olugbe inu rè̩ nigba Ipọnju Nla yii? Ilè̩ tikara rè̩ yoo di aṣalẹ yoo si “bajẹ patapata.” Ilẹ ayé yoo wà ni ipo ahoro, ikọsilẹ ati iparun. Isẹlẹ nla yoo sè̩. Isaiah wi pe: “Ipilẹ ilẹ si mi … ilẹ mi-titi. Ilẹ yio ta gbọngbọn sihin sọhun bi ọmuti, a o si ṣí ni idi bi agọ.”
“OLUWA … si yi i po.” Gbogbo oke ati erekuṣu ni “a si ṣi kuro ni ipò wọn” (Ifihan 6:14) wọn ki yoo si si mọ (Ifihan 16:20). Awọn irawọ yoo ja silẹ; oṣupa yoo “si dabi ẹjẹ” oorùn yoo si “dudu bi aṣọ-ọfọ onirun” (Ifihan 6:12, 13). Isaiah wi pe: “Ilẹ nṣọfọ, o si nṣá, ayé nrù o si nṣá.”
A Kọọ Silẹ
A o kọ awọn eniyan ati ilẹ naa silẹ lai ni olutunu. Wọn yoo di alailera ati alailagbara. A o rẹ agberaga silẹ. “Olukuluku ile li a se, ki ẹnikan má bà wọle.” Kò si ayọ tabi inudidùn. Orin ki yoo mú inu eniyan dùn mọ, ki yoo si ohunkohun lati mu ọkàn yọ. “Gbogbo ayọṣú okunkun, ariya ilẹ naa lọ.” Ki yoo si àyè asala fun awọn eniyan ayé. Awọn ti o sá fun è̩rù kan yoo bọ sinu omiran. “Ẹniti o sá kuro fun ariwo ibè̩ru yio jìn sinu ọfin; ati ẹniti o jade lati inu ọfin wá li a o fi ẹgé̩ mu” (Isaiah 24:18).
Igba Ipọnju Nla yoo jé̩ akoko ajalu – ki i ṣe ọkan ṣoṣo, ṣugbọn ogunlọgọ. Johannu Ayanfẹ ri firifiri Ipọnju Nla ti Isaiah kọ akọsilẹ nipa rè̩. Johannu ri ajalu wọnyii, bi wọn ti n ṣẹlẹ lera-lera gẹgẹ bi igba ti awọn ẹlẹṣin n gun ẹṣin lori ilẹ ayé. Ogun, ìyàn, ikú, ajakalẹ-arun, ijambá, yoo ṣẹlẹ lori ilẹ ayé gẹgẹ bi a ti kọọ silẹ ninu Ifihan ori 6. Lọna bayii ni a o jẹ eniyan buburu niya. “A o si ko wọn jọ pọ, bi a iti kó ara tubu jọ sinu ihò, a o ti wọn sinu tubu” (Isaiah 24:22).
Ijiya
Ki ni ṣe ti gbogbo ipọnju yii n bọ wá sori ayé? Isaiah sọ idi rè̩. O wi pe: “Ilẹ pẹlu si di aimọ li abẹ awọn ti ngbe inu rè̩; nitori wọn ti rúofin, wọn pa ilàna dà, wọn dà majẹmu aiyeraiye. Nitorina ni egún ṣe jẹ ilẹ run, awọn ti ngbe inu rè̩ di ahoro.” A sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe a o bukun wọn bi wọn bá gbọran si àṣẹỌlọrun. Bi wọn báṣaigbọran si Ọlọrun ati si Ọrọ Rè̩, egún yoo wá sori wọn. Mose wi pe, “Ẹ gbéọkàn nyin lé gbogbo ọrọ … nitoripe ìye nyin ni” (Deuteronomi 32:46, 47).
Nipasẹọrọ awọn wolii wọnyii a ti sọ fun awa pẹlu nipa ohun ti yoo ṣẹlẹ bi a báṣaigbọran si Ọlọrun, bi a ba pa ofin Rè̩ dà, bi a ba dà majẹmu Rè̩. Lode oni ọpọlọpọ eniyan ni o n tapa si Ọlọrun ati ofin Rè̩: wọn sọ owó di ọlọrun wọn; wọn si n gbé igbesi-ayé iwa buburu lai bikita. S̩ugbọn ni ọjọ ibinu Oluwa, wọn o ju oriṣa fadaka ati oriṣa wura wọn si ekute ati si àdán (Isaiah 2:20), wọn yoo fé̩ fara pamọ ninu ihò ilẹ ati ihò apata; wọn o si ké si awọn apata ati awọn òke ki o wó lù wọn lati pa wọn mọ kuro ninu idajọỌlọrun (Ifihan 6:15, 16).
Ki yoo si asala nigba ti ibinu Oluwa ba tú jade sori awọn orilẹ-ède (Isaiah 34:2). Ọpọlọpọ ni yoo kú “nitori ọjọẹsan OLUWA ni” (Isaiah 34:8). Oluwa yoo jẹ awọn eniyan ayé niyà nitori aiṣedede ati iwa buburu wọn (Isaiah 26:21).
Ibi Aabo
Kò ha si ibi aabo kuro ninu ibi nlá nlà ti Isaiah wi pe yoo wá sori ayé yii? Isaiah kọ akọsilẹọrọỌlọrun: “Wá, enia mi, wọ inu iyè̩wu rẹ lọ, si se ilẹkun rẹ mọ ara rẹ: fi ara rẹ pamọ bi ẹnipe ni iṣé̩ju kan, titi ibinu na fi rekọja” (Isaiah 26:20). Ni tootọ ibi isadi kan wà fun awọn eniyan Ọlọrun. S̩aaju akoko Ipọnju Nla, Kristi yoo pada wa mú awọn eniyan Rè̩ kuro ni ayé yii lati wà pẹlu Rè̩. “Nitori Oluwa tikara rè̩ yio sọkalẹ lati ọrun wá ti on ti ariwo, pẹlu ohùn olori awọn angẹli, ati pẹlu ipèỌlọrun; awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ jinde: nigbana li a ó si gba awa ti o wà lāyè ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun; bḝli awa ó si ma wà titi lai lọdọ Oluwa” (1 Tẹssalonika 4:16, 17).
Ti Murasilẹ
Ibi isadi ti o wà lọdọ Kristi wà fun kiki awọn eniyan Rè̩ nikan. Ohun ti o yẹ ki o gba ọkàn wa kan ni lati ri i daju pe ti Jesu ni awa i ṣe ati pe a ti mura silẹ lati pade Rè̩. Bibeli kọ wa pe a ni lati rin ninu gbogbo imọlẹ ti Ọlọrun fi fun wa bi a ba fẹ jẹ aṣẹgun kikún, ti o ti mura silẹ lati pade Jesu. Awa ti a ti ni imọlẹ yii ti kọè̩kọ ninu Bibeli pe a ni lati ni idaniloju pe a dari è̩ṣẹ wa jì wá, ki a gbé igbesi-ayé iwa-mimọ, ki a si kún fun Ẹmi Mimọ ki a ba le wà ni imurasilẹ fun bibọ Jesu.
Eniyan le ri idariji è̩ṣẹ rè̩ gbà bi o ba gbadura ti o si tọrọ idariji lọdọỌlọrun (Ka Owe 28:13, ati 1 Johannu 1:9). Lẹyin ti eniyan ba ti ri igbala, a ni lati sọọ di mimọ. Nipa gbigba adura ati nipa fifi ara ẹni rubọ fun Ọlọrun ni a le fi ri isọdimimọ gbà, iriri ti yoo fa gbongbo è̩ṣẹ tu kuro ninu ọkàn ti yoo si fun ni ni anfaani lati gbé igbesi-ayé iwa-mimọ. “Nitori eyi ni ifẹỌlọrun, ani wiwà ni mimọ nyin” (1 Tẹssalonika 4:3). Ki i ṣe kiki pe ifẹỌlọrun ni fun eniyan lati gbé igbesi-ayé iwa-mimọṣugbọn Ọlọrun kàn an nipa pẹlu, nitori pe Iwe Mimọ sọ fun ni pe, “Ẹ mā lepa alafia pẹlu enia gbogbo, ati iwa mimọ, li aisi eyini kò si ẹniti yio ri Oluwa” (Heberu 12:14).
Iriri miiran tun wà ti a ni lati ni lati le rin ninu imọlẹ ti a fi fun wa, ki a si wà ni imurasilẹ de bibọ Jesu. Eyi yii ni agbara Ẹmi Mimọ ti Jesu ṣeleri fun awọn ọmọ-ẹyin (Iṣe Awọn Apọsteli 1:5), ti a si ti ṣeleri fun “gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:39). Ẹmi Mimọ a maa fun ni ni agbára lati ṣiṣé̩ ati lati jé̩ẹlẹri fun Oluwa. Iwọ ha ni awọn iriri wọnyii bi? Iwọ ha ti murasilẹ fun bibọ Jesu? Bi ipèỌlọrun bá dún ni wakati ti a wà yii gan an, iwọ yoo ha pade Rè̩ ni ofuurufu?
Ki i ṣe kiki Ipọnju Nla nikan ni Isaiah sọ fun wa nipa rè̩, ṣugbọn o sọ fun wa pẹlu nipa ibi-aabò kan fun awọn ọmọ-lẹyin Jesu. Onipsalmu paapaa sọ nipa ibi-aabò. O wi pe, “Ọlọrun Jakọbu li àbo wa” (Orin Dafidi 46:11), Dafidi wi pe: “Ohun kan li emi ntọrọ lọdọ OLUWA, on na li emi o ma wakiri: ki emi ki o le ma gbe inu ile OLUWA li ọjọ aiyé mi gbogbo, ki emi ki o le ma wòẹwà OLUWA, ki emi ki o si ma fi inu-didun wo tẹmpili rè̩. Nitori pe ni igba ipọnju on o pa mi mọ ninu agọ rè̩, ni ibi ikọkọ agọ rè̩: ni yio pa mi mọ” (Orin Dafidi 27:4, 5).
A kò gbọdọ jé̩ ki àyà fò wá. A le jé̩ aṣẹgun nipa igbagbọ. Ẹ máṣe jé̩ ki ọrọ Isaiah daya fò wá, ṣugbọn ẹ jé̩ ki a murasilẹ, ki a si maa ṣiṣẹ, ki a maa ṣọna, ki a si maa duro de bibọ Oluwa, nipa bẹẹ ki a le bọ ninu Ipọnju Nla ti o n bọ wá sori ayé.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni iṣẹ wolii?
2 Asọtẹlẹ Isaiah wo ni o ti ṣẹ bayii?
3 Ki ni a n pe ni ipọnju?
4 Ki ni ṣe ti Ipọnju Nla fi n bọ wá?
5 Nibo ni yoo gbe ṣẹlẹ?
6 Ki ni yoo de ba awọn eniyan nipasẹ Ipọnju yii?
7 Ki ni yoo ṣẹlẹ si oorùn, oṣupa, ati irawọ?
8 Bawo ni awọn olododo yoo ṣe sá asala kuro ninu Ipọnju naa?
9 Ki ni eniyan ni lati ṣe lati murasilẹ fun bibọ Oluwa?
10 Bawo ni a ṣe mọ pe Ipọnju n bọ?