Lesson 352 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dè̩dè̩” (Matteu 3:2).Notes
Ilu Johannu
Ni aṣálè̩ ilẹ Judea oloke ati alapata ni iha iwọ-oorun ebute Okú Okun, ni a gbé bi Johannu Baptisti ẹni ti awọn obi rè̩ i ṣe mẹkúnnù. Boya o ṣe e ṣe fun un lati ile rẹ ki o maa ri Oke Nebo ati odo Jọrdani, ati ilu Jẹriko ti o wa ni odikeji wọn. Odo Keriti nibi ti awọn ẹyẹ-iwo ti fi ounjẹ bọ Elijah nigba ìyàn wa ni tosi. Boya Johannu tilẹ lọ bẹ ibi ti a darukọ wọnyii wò, eyi ti awọn wolii Ọlọrun ti mu ki o jé̩ ibi ọwọ. Irú agbára kan naa, àṣẹ, ati itara ti o fara hàn ninu Elijah ni a ri pẹlu ninu Johannu. Iwà ayé rè̩ ati iwọṣọ rè̩ dabi ti Elijah. Ounjẹ rè̩ ni eeṣú ati oyin igàn (Matteu 3:4), eyi ti o ṣe e ṣe ki o jẹ pe oorùn ni a fi yan an ni àyangbẹ ti adùn rè̩ fara jọ ti edé.
Iwaasu Rè̩
Johannu ni ẹni ti a fun ni anfaani lati kede wiwá Jesu. Bi è̩rọ gbohun-gbohun olohun gooro, o daju pe ohun rè̩ n dún jake-jado òke wọnni; gbogbo awọn eniyan Jerusalẹmu, Judea, ati awọn olugbe ebute Odo Jọrdani tú jade wá lati gbọ iwaasu Johannu. Awọn ọba Ila-oorùn a saba maa rán ikọ jade lati palẹọna mọ ati lati tun ọna ṣe niwaju wọn. Bakan naa ni o jé̩ iṣé̩ Johannu lati tun ọna ṣe fun wiwá Jesu si aye. “Ẹ tún ọna Oluwa ṣe, ṣe opópo titọ ni aginjù fun Ọlọrun wa. Gbogbo afonifoji ni a o gbe soke, gbogbo òkenla ati oke kékèké ni a o si rè̩ silẹ: wiwọ ni a o si ṣe ni titọ, ati ọna pàlapala ni a o sọ di tité̩ju” (Isaiah 40:3, 4). Iṣẹ Johannu ki i ṣe lati la titi ti o gboorò tabi lati sọ oke di pè̩té̩lè̩, ṣugbọn o n mú awọn eniyan pada wá si igbọran, o si n kọ wọn lati mu igberaga ati agabagebe kuro ni igbesi-ayé wọn, ki wọn si ronupiwada è̩ṣẹ wọn.
Ọrọ mẹjọ pere ni iwaasu ti o mu igbọgbẹọkàn bá awọn eniyan, ti wọn si jẹwọè̩ṣẹ wọn, ti a si ti ọwọ Johannu ṣe iribọmi fun wọn ni Jọrdani. Ki ni ohun pataki ti iwaasu Johannu duro lé lori? “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dè̩dè̩” (Matteu 3:2).
Ohun ti a le fi oju ri
Ki ni itumọ “ijọba ọrun”? A sọrọ pupọ ninu Bibeli nipa rè̩, o si ṣe danindanin ki oye eyi ki o yé wa. Jesu lo awọn àkàwé wọnyii lati ṣe apejuwe rè̩: (1) Horo irugbin mustardi; (2) iwukara ti a fi sinu iyẹfun; (3) ọkunrin oniṣowo; (4) àwọn ti a sọ sinu okun; (5) irugbin rere; (6) iṣura ti a fi pamọ sinu oko (Matteu 13:31-47); (7) baale ile kan (Matteu 20:1); (8) ọba kan ti o ṣe igbeyawo fun ọmọ rè̩ (Matteu 22:2); (9) wundia mẹwaa ti wọn lọ ipade ọkọ iyawo (Matteu 25:1). Daniẹli ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi okuta nla kan (Daniẹli 2:31-45); bẹẹ ni awọn onkọwe Majẹmu Laelae tọka si i pẹlu.
Oye eleyii le ṣe alai yé awọn ọdọmọde miiran, ṣugbọn o yẹ ki a là oju wa silẹ, ki a si ṣi eti ọkàn wa paya lati mọ ohun ti eyi jẹ. A kò fẹ dabi awọn afọju ti a sọ nipa wọn fun wa ninu itàn arosọ ti wọn fẹ mọ bi erin ti ri. Ọkan ninu wọn fi ọwọ kan ipè rè̩, o si wi pe oun ti mọ bi erin ti ri, o dabi ọkọ; ẹlomiran tun fi ọwọ kan ẹsè̩ rẹ o wi pe o dabi igi; bẹẹ ni omiran fi ọwọ kan ihà erin ti o tobi bẹrẹkẹtẹ o si wi pe o dabi ogiri. S̩ugbọn awa ki i ṣe afọju; bẹẹ ni oju wa kòṣokunkun to bẹẹ ti a o fi ka apa kan Bibeli nikan ṣoṣo – a ni gbogbo ỌrọỌlọrun, nibẹ ni a si le ri idahun si ibeere yii: Ki ni a n pe ni Ijọba Ọrun?
Jesu a maa fi “ohun ti a le fi oju ri” kọ awọn eniyan ni ohun ti Oun ni lọkàn. O sọ nipa irugbin mustardi, O wi pe, oun ni o kere ju ninu gbogbo irugbin, ṣugbọn o si dagba soke o si di igi nla, awọn ẹyẹ oju-ọrun si n gbé arin ẹka rè̩. Jesu wi pe Ijọba Ọrun dabi eleyii nì.
Awọn arinrin-ajo ti wọn ti lọ si Ilẹ Mimọ sọ fun ni pe irú irugbin mustardi yii, ti Jesu sọ nipa rè̩ wà sibẹ ni ọpọlọpọ ni ilẹ Palẹstini, omiran a si maa ga soke lọpọlọpọ. Kòṣoro fun wa lati mọ pe nigba ti a ba mu “ègún” kuro lori ayé ati nigba ti awọn igi ati ohun ọgbin yoo ni anfaani lati dagba daradara ati lai si idiwọ, igi mustardi pẹlu yoo dagba soke lọpọlọpọ.
Ọba ati Ijọba
Ijọba ni ilẹ-ọba ti o ni ọba, aafin, ité̩, idile ọba, awọn ijoye ati awọn eniyan tabi ẹmẹwa ti o wa labẹ aṣẹọba. Nigba ti Jesu Ọba ba pada de lati jọba lori ilẹ aye, a o fi idi ijọba Rè̩ kalẹ ni Jerusalẹmu “a o si fi ogo OLUWA hàn, gbogbo ẹran-ara ni yio jùmọ ri i: nitori ẹnu OLUWA li o sọọ” (Isaiah 40:5). Awọn eniyan mimọ ti wọn bá Jesu pada wa yoo ba A ṣe akoso (Ifihan 2:26, 27; 5:10), gẹgẹ bi a ti le ri ninu Ẹkọ 342. Ijọba ododo yii ti Kristi i ṣe Ọba rè̩ yoo bori gbogbo ayé. Eyi kò ha dabi igi ti o n gbilẹ titi o fi kún gbogbo ayé? Tabi bi okuta ni, ti Daniẹli sọ nipa rè̩ ti o kún gbogbo ayé.
Idagbasoke Rè̩
Igba Ihinrere ti a wà yii jẹ ipa kin-in-ni ninu Ijọba Rè̩. Lakọkọ, ohùn oniwaasu kan ṣoṣo, ti o wọ aṣọ irun ibakasiẹ jakujaku (Matteu 3:4), ni a gbọ ni aginju. LẸYIN NAA JESU DE! Ọpọlọpọ eniyan ni a gbàla kuro ninu è̩ṣẹ a si yan awọn Apọsteli mejila lati waasu Ihinrere. Wọn jade lọ, ihin naa si tankalẹ kánkán nipa ọrọẹnu. Lati igba naa wa titi di akoko yii ni a ti n ri awọn oloootọ iranṣẹỌlọrun, awọn oṣiṣẹ ati awọn ajihinrere ti wọn n kede Ihinrere ti igbala kuro ninu è̩ṣẹ fun awọn ọkàn ti o wà ninu okunkun. “A kò le ṣaima kọ wasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ède” (Marku 13:10), ki Jesu tó dé, bẹẹ ni a si n mu eleyii ṣe ni igba ikẹyin yii. Olukuluku Onigbagbọ ti a tunbi ni tootọ ni o n fẹ lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa Jesu; ni akoko ti a wà yii paapaa, pẹlu awọn ohun-elo igbalode, Ihinrere n tankalẹ kánkán.
Awọn ọkọ-ayọkẹlẹ, ọkọ oju-omi, ati ọkọ ofuurufu ni a n lo lati fi tan Ihinrere ti Igbala kalẹ. Bi o tilẹ jẹ pe ohùn Johannu ti dẹkun lati maa kede lori oke Judea, bẹẹ ni a n gbohun oniwaasu ododo yii sibẹsibẹ. Ijọ Apostolic Faith ni ipin ninu itankalẹ Ihinrere nipa iwaasu ode ti a n ṣe kaakiri igboro ilu. A n bẹ ile-tubu, ile itọju awọn alaisan, ati ibugbe awọn arugbo wò; a n wọọkọ oju-omi lọ si erekùṣù lati lọ waasu fun awọn ti o wà ni adadó; a n bẹ awọn ọkọ wò ni ebute, a si n mú awọn atukọ oju-omi wá si ile-isin; a n mú awọn ọmọde wá si Ile-è̩kọỌjọ Isinmi nibi ti a gbé n kọ ni ni è̩kọỌrọỌlọrun. A n fi iwe Ihinrere ranṣẹ lọfẹ si ilu okeere ati ẹkùn kọọkan ni orilẹ-ède wa. Ogunlọgọ eniyan ti o n gba awọn iwe wọnyii ati awọn iwe-ọwọ kekeke n ri idasilẹ kuro ninu è̩ṣẹ ati iwosan fun aisan ara wọn. Oriṣiriṣi ọna miiran ni a si tun gbà n ṣe igboke-gbodo lati mu aṣẹ Jesu ṣẹ. “Ẹ lọ si gbogbo aiyé, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda” (Marku 16:15).
Ihinrere
“Ẹsẹẹniti o mu ihinrere wá ti dara to lori awọn oke, ti nkede alafia; ti nmu ihin rere ohun rere wá, ti nkede igbala” (Isaiah 52:7). Awọn ti wọn n tan Ihinrere kalẹ jé̩ ikọ ihin ayọ, nitori pe itumọ “Ihinrere” ni “ihin ayọ”. Iwọ ha i ṣe olutan-ihinrere-kalẹ bi? Bi bẹẹ kọ, ki ni ṣe ti iwọ kò bè̩rẹ lati oni lọ lati maa funrugbin iwa rere, ifẹ, ati Igbala, ki o si maa wò bi irugbin kekere naa yoo ti yara dagba soke. Iwọ le maa bomi rin “igi mustardi” fun idagbasoke, titi Jesu yoo fi dé lati wá mu awọn ti o ti mura silẹ lati pade Rè̩. “A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiyé lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de” (Matteu 24:14). A gbagbọ pe opin kù si dè̩dẹ!
Questions
AWỌN IBEERE1 Ohùn ta ni a gbọ ni iju Judea?
2 Ki ni ṣe ti a ran an? Ki ni ọrọ iwaasu rè̩?
3 Ki ni ounjẹ rè̩? aṣọ rè̩?
4 Ta ni o jọ ninu Majẹmu Laelae?
5 Sọ awọn àkàwé mẹta ti Jesu ṣe nipa Ijọba Ọrun?
6 Awọn wo ni a ni lati kede Ihinrere fun?
7 Ọna wo ni a le gbàṣe iranwọ lati tan Ihinrere kalẹ? Iwọ ha n ṣe bẹẹ?
8 Ki ni Jesu sọ nipa Johannu Baptisti?
9 Bawo ni a ṣe mọ pe opin kù si dè̩dẹ?