Romu 8:1-39

Lesson 353 - Senior

Memory Verse
“Njẹ bi a si ti nda wa lare nipa igbagbọ, awa ni alafia lọdọỌlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi: nipasẹẸniti awa si ti ri ọna gbà nipa igbagbọ si inu ore-ọfẹ yi ninu eyiti awa gbé duro, awa si nyọ ni ireti ogo Ọlọrun” (Romu 5:1, 2).
Cross References

I Iyọrisi Idalare

1 Kò si idalẹbi ninu igbesi-aye awọn ti n bẹ ninu Kristi Jesu, Romu 8:1; Johannu 3:18; I Johannu 3:20-24

2 Kristi Jesu ti sọọkan ti a tunbi di ominira kuro lọwọ ofin ẹṣẹ ati ti iku, Romu 8:2-4; Johannu 5:24; 8:32; Galatia 5:1

3 Erò ti ara jẹọta Ọlorun, kòle ri ọna ṣiṣẹ ninu ọkan ti a ti dalare, Romu 8:5-8; Efesu 4:17; Titu 1:15, 16; I Johannu 2:15, 16

4 Ẹmi Ọlọrun ati Jesu Kristi ti n gbe inu ọkan eniyan a maa sọ aye rè̩ di ọtun, Romu 8:9-13; II Kọrinti 5:17; Galatia 2:20; Efesu 3:17-19

II Igbesi-aye Nipa ti Ẹmi

1 Awọn ti a n ṣe amọna fun lati ọdọẸmi Ọlọrun wa ni I ṣe ọmọỌlọrun, Ẹmi a si maa ba wọn jẹri bẹẹ, Romu 8:14-17; Johannu 1:12; Galatia 4:4-7; I Johannu 5:6, 10

2 Igbagbọ tootọ ninu Jesu Kristi ati igbọran si gbogbo aṣẹ Rè̩ a maa fi ireti iye ainipẹkun si ọkan ẹni ti o gbagbọ, Romu 8:18-25; 5:21; Johannu 11:25, 26; I Johannu 5:11, 12

3 Ẹmi Ọlọrun a maa bẹbẹ fun awọn eniyan mimọ gẹgẹ bi ifẹ inu Ọlọrun, Romu 8:26, 27

4 “Ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ si rere fun awọn ti o fẹỌlọrun,” Romu 8:28-30; II Kọrinti 4:17; Heberu 12:11; I Peteru 4:12, 13

5 “Bi Ọlọrun bá wá fun wa, tani yio kọjujasi wa?” Romu 8:31-34; Heberu 13:6; I Peteru 3:13; I Johannu 4:4

III Awọn Onigbagbọ Aṣẹgun

1 Ninu ohun gbogbo ti o jẹ ti aye yi, Onigbagbọ tootọ ju aṣẹgun lọ, Romu 8:35-37; Luku 10:19; I Johannu 5:4

2 Ki i ṣe ohun igba isinsinyi, tabi ohun igba ti n bọ ni yoo le ya wa kuro ninu ifẹỌlọrun, Romu 8:38, 39; II Timoteu 1:12; Juda 24

Notes
ALAYE

Nipa Igbagbọ

Nigba ti Jesu sọ fun Nikodemu pe, “Lotọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a tun enia bi, on ko le ri ijọba Ọlọrun,” ijoye awọn Ju naa wi pe “Nkan wọnyi yio ti ṣe le ri bẹ?” (Johannu 3:3, 9). Ko ṣe e ṣe fun eniyan nipa ti ara lati ni imọ nipa iṣẹ ti Ẹmi Ọlọrun n ṣe. Bibeli sọ fun wa pe: “Enia nipa ti ara ko gba ohun ti Ẹmi Ọlọrun wọnni: nitoripe were ni nwọn jasi fun u: on ko si le mọ wọn, nitori nipa ti ẹmi li a fi n wadi wọn” (I Kọrinti 2:14).

S̩ugbọn, Onigbagbọ tootọ mọ pe ki I ṣe ọranyan fun eniyan lati mọ gbogbo ọna Ọlọrun ati ilana iṣẹ Rè̩, ki a to le ri ẹbun wọnni ti Ọlọrun ti pese silẹ fun gbogbo araye gbà. Ni idahun si ibeere ọgbẹni onitubu ara Filippi, “Alàgba, kini ki emi ki o ṣe ki ng le la?” awọn eniyan Ọlọrun dahun pe, “Gba Jesu Kristi Oluwa gbọ, a o si gba ọ la, iwọ ati awọn ara ile rẹ pẹlu” (Iṣe Awọn Apọsteli 16:30, 31).

Igbagbọ tootọ ninu Jesu Kristi n yọ eniyan kuro ninu idalẹbi ati ẹṣẹ, o si n sọ ni di ẹni idalare niwaju Ọlọrun, ṣugbọn Apọsteli nìṣe alaye ninu ori kẹjọ Episteli si awọn ara Romu pe lati le bọ kuro ninu idalẹI, eniyan kò gbọdọ tọ ifẹkufẹ ti ara ati ifẹ aye lẹhin, ṣugbọn a gbọdọ maa rin gẹgẹ bi itọni Ẹmi Ọlọrun ati ỌrọỌlọrun. Eto irapada Ọlọrun duro lori irubọ iku Ọmọ Rè̩, eyi ti o da ẹṣẹ lẹbi ninu ara ti o si ṣi orisun iwa ododo ti Jesu Kristi silẹ, a si mu eyi ṣẹ ninu awọn ti kò rin nipa ti ara bi ko ṣe nipa ti Ẹmi.

Iṣọta Ero ti Ara

Ninu ẹsẹ diẹ ti o ṣiwaju ati ẹsẹ diẹ ti o tẹle Romu 8:8, a ṣe alaye awọn ọrọ meji ti wọn tako ara wọn -- otitọ ti ero nipa ti ẹmi eyi ti I ṣe abayọrisi iriri ibi titun tabi idalare nipa igbagbọ ati otitọ ti ero nipa ti ara eyi ti I ṣe imujade iwa abi-nibi ati igbesi aye ẹṣẹ ti o tẹle e. Ero nipa ti ara ọta ni si Ọlọrun, “nitori ki itẹriba fun ofin Ọlorun, on kò tilẹ le ṣe e.” Ero ti ara a maa ṣe ikú pa ọkàn. Ẹni ti o ba n tẹle ero ti ara – ani ẹnikẹni ti n huwa ẹṣẹ -- o n gbe nipa ti ara, kò si le wu Ọlọrun; nitori pe ẹṣẹ ni gbongbo iṣọtẹ, nitori naa kò si le tẹriba fun Ọlọrun.

Nigba ti a ba da eniyan lare nipa igbagbọ, ki I tun de la ẹṣẹ mọ, nitori Ọlọrun a maa fun ni lagbara lati bori awọn ẹṣẹ wọnni. Eto Ọlọrun ki i ṣe lati bo ẹṣẹ mọ awọn ọmọ Rè̩ lara, bi ko ṣe lati fun wọn ni agbara lati gbe igbesi-aye ailẹṣẹ. “Jesu ni iwọ o pe orukọ rè̩: nitori on ni yio gba awọn enia rè̩ là kuro ninu ẹṣẹ wọn” (Matteu 1:21). Oluwa kò gba ẹnikẹni si ọmọ rè̩ ninu awọn “Onigbagbọ ti n dẹṣẹ.”

Nigba ti eniyan ba ri igbala, agbara nla kan yoo kọlu gbongbo ẹṣẹ tabi ẹda ẹṣẹ to bẹẹ ti ki yoo fi le gberi fun iwọn igba diẹ; ṣugbọn lai pẹ jọjọ yoo bẹrẹ si maa mu wahala wá, ayafi bi a ba fa a tu ti gbongbo ti gbongbo. A ti kan “ogbologbo ọkunrin” ẹṣẹ ni mọ agbelebu pẹlu Kristi, ṣugbọn yoo sa gbogbo agbara rè̩ lati bọ kuro lori agbelebu naa. ỌmọỌlọrun ti a ṣẹṣẹ tun bi naa ni lati tun tọỌlọrun lọ fun isọdimimọ; eyi nì ni pe ki a fa gbongbo ikoro ti i ṣe aworan Adamu tu kuro ninu ọkan nipa ibuwọn Ẹjẹ Jesu lẹẹkeji. ỌmọỌlọrun naa yio wa ni ọkan funfun. “Ogbologbo ọkunrin nì” yoo ku patapata nigba ti o ba ri isọdimimọ, ọmọỌlọrun naa a si bẹrẹ si i gbe igbe-aye aṣẹgun ni kikun.

Ero Nipa ti Ẹmi

“Bi Kristi ba ngbe inu nyin.” Kristi ninu rẹ ni iriri idalare nipa igbagbọ, ti a maa n ri gba nipa ibi titun. Bibeli sọ ni ibomiran pe: “Bi ẹnikẹni ba wa ninu Kristi, o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun” (II Kọrinti 5:17). Eyi ni ohun ti eniyan le fi mọ iru àyè oore-ọfẹ ti oun wà. Nigba ti a ba ra ẹni kan pada kuro ninu ẹṣẹ rè̩ nipa iṣẹ ibi titun, Ẹmi Kristi yoo wọ inu ọkan rè̩ yoo si maa gbe ibẹ. Ẹni naa ki yoo tun ronu tabi ṣe awọn nkan ti ara mọ gẹgẹ bi okú kò ti le ṣe nkankan mọ lẹhin ti o ti kú; ṣugbọn Onigbagbọ a maa fiyesi, a si maa gbọran si gbogbo ohun ti i ṣeti Ẹmi Ọlọrun. Iyè ati alaafia ni lati maa ronu nipa ti ẹmi, igbesi-aye ọtun yi si ni ere nlá nlà. “Bi Ẹmi ẹniti o ji Jesu dide kuro ninu okú ba ngbe inu nyin, ẹniti o ji Kristi Jesu dide kuro ninu oku yio fi Ẹmi rè̩ ti ngbe inu nyin, sọ ara kiku nyin di āye pẹlu” (Romu 8:11).

Apọsteli yi fi han pe eniyan kò le fi agbara oun tikara rẹ de ipo oore-ọfẹ giga ti Onigbagbọ. Ẹmi Ọlọrun ni amọna fun gbogbo Onigbagbọ tootọ, Jesu tikara Rè̩ ni Aṣiwaju ti o si n fọna han. “Iye awọn ti a nṣe amọna fun lati ọdọẸmi Ọlọrun wá, awọn ni iṣe ọmọỌlọrun.” “Ẹnyin wa laini Kristi, ẹ jẹ ajeji si anfani awọn ọlọtọ Israẹli, ati alejo si awọn majẹmu ileri ni, laini ireti, ati laini Ọlọrun liaiye: ṣugbọn nisisiyi ninu Kristi Jesu ẹnyin ti o ti jina rere nigba atijọ ri li a mu sunmọ tosi, nipa ẹjẹ Kristi” (Efesu 2:12, 13). A sọ awọn ti o ba gbagbọ di ẹbi Ọlọrun, wọn si di ajogun Ọlọrun ati ajumọjogun pẹlu Kristi. Ẹmi Ọlọrun a maa ba ẹmi ọmọỌlọrun tootọ jẹri lati fi idi eto iṣẹ iyanu yi mulẹ.

Awọn ti a Yiiriwo

Onigbagbọ yoo jẹ ajumọ-jogun pẹlu Kristi, “Biobaṣepe awa ba a jiya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu Rè̩.” Jake-jado Bibeli ni otitọ yi han gbangba pe awọn eniyan Ọlọrun yoo jẹ awọn ti a yiiriwo pẹlu ipọnju, ijiya ati inunibini. Bi o ti ri gan an lakoko ti awọn Apọsteli ni ibẹrẹ, bẹẹ gẹẹ ni o ri titi di oni yi, bakan naa ni yoo si ri titi Jesu yoo fi mu Ijọ Rè̩ lọ si Ọrun. A ti sọ fun ni pe Ọrun jẹ ibi ti a pese silẹ fun awọn eniyan ti a ti mua wọn silẹ fun ibẹ, idanwo ati iyiiriwo si ni ohun ti Ọlọrun maa n lo lọpọlọpọ igba lati fi pese awọn eniyan silẹ fun ibugbe ati ere wọn ayeraye. Aiba oore-ọfẹỌlọrun ré̩ ti o n bẹ ninu aye ati oriṣiriṣi ipọnju maa n mu ki ọkan ọmọỌlọrun fa si ile rè̩ọrun nigba gbogbo. “Nitori eyi ni ārẹ kòṣe mu wa; ṣugbọn bi ọkunrin ti ode wa ba nparun, sibẹọkunrin ti inu wa ndi titun li ojojumọ. Nitori ipọnju wa ti o fẹrẹ, ti iṣe fun iṣẹju kan, o nṣiṣẹ ogo ainipẹkun ti o pọ rekọja fun wa” (II Kọrinti 4:16, 17).

“Awa si mọ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ si rere fun awọn ti o fẹỌlọrun, ani fun awon ẹniti a pe gẹgẹ bi ipinnu rè̩.” Ọlọrun mọọkàn ẹni kọọkan ninu awọn ọmọ Rè̩, O si mọ dajudaju iru idanwo ti olukuluku le fi ara dà. Ki yoo jẹ ki ohunkohun ṣẹlẹ si awọn ọmọ Rè̩ ti Oun kì yoo si fun wọn lagbara to lati le gba a. Ẹrù Onigbagbọ le dabi ẹni pe o wuwo ju nigba miran; idanwo naa le dabi ẹni pe o tobi ju lati fi ara dà; íkuuku naa le ṣokunkun ki o si nipọn to bẹẹ ti a le ro pe a ki yoo tun ri oju oorun mọ, ṣugbọn olootọ ni Ọlọrun, Ọrọ Rè̩ ki yoo tase. Ni iru akoko bayi, Onigbagbọ le ri i pe oun ko le gbadura; ṣugbọn bi oun yoo ba duro, ki o si kigbe niwaju Oluwa, ọran rè̩ yoo ni ayọrisi rere. “Bẹ gẹgẹ li Ẹmi pẹlu si nran ailera wa lọwọ: nitori a ko mọ bi a ti igbadura gẹgẹ bi o ti yẹ: ṣugbọn Ẹmi tikararẹ nfi irora ti a kò le fi ẹnu sọ bẹbẹ wa” (Romu 8:26).

Imọtẹle Ọlọrun

Romu 8:29, 30 jẹ awọn ẹsẹ Iwe-ti o ni ariyanjiyan ṣugbọn ninu wọn, ohun ti Apọsteli ni n fi ye ni ni ilana ti Ọlọrun n gba ṣe iṣẹ Rè̩, ṣisẹ-ntẹle eto igbala kikun lati ibí titun titi de iṣe-ni-logo. Apọsteli yi kọwe si awọn ara Romu – ani awọn Keferi. Awọn Ju rò pe awọn ni ayanfẹỌlọrun, ati pe ko tun si orilẹ-ede miran tabi eniyan ti Ọlọrun tun le fi oju rere han fun, tabi ti O tun le pe lati sin In. A ti ọwọẸmi mi si Apọsteli yi lati kọwe pe, Ọlọrun nipa imọtẹlẹ Rè̩ mọ pe awọn Ju yoo kọ Messia wọn ati pe Oun yoo na ọwọ ipe Rè̩ si awọn Keferi ni ọna ti o ga ju ti atẹhinwa lọ lati wa sin In ninu Ihinrere Jesu Kristi. (Ohun gbogbo – ti o ti kọja, ti isinsinyi, ati ti ọjọ iwaju -- jẹ ohun ti Ọlọrun mọ lati ayeraye; nitori idi eyi gbolohun “imọtẹlẹỌlọrun” ni tootọ n fi titayọọgbọn Ọlọrun han, yatọ si oye kukuru ti eniyan ni).

“Peteru Apọsteli Jesu Kristi, si awọn ayanfẹ ti n ṣe atipo ti wọn tuka kiri si Pontu, Galatia, Kappadokia, Asia ati ni Bitinia, gẹgẹ bi imọtẹlẹỌlọrun Baba” (Ipeteru 1:1, 2). Ọlọrun mọ awọn Keferi tẹlẹ, O si pe wọn lati ba aworan Ọmọ Rè̩ dọgba. Awọn Keferi wọnyi (gẹgẹ bi wọn ti ni ominira ati agbara lati yan lati jẹ ipèỌlọrun tabi lati fa sẹhin ni ṣiṣe bẹẹ) ti wọn jẹ ipèỌlọrun, ti wọn kọẹṣẹ ati ọna buburu wọn silẹ ni a dalare. “Ọpọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a yan” (Matteu 22:14). Awọn eniyan Ọlọrun ti a dalare ni a o ṣe logo lai pẹọjọ, bi wọn ba duro ninu idalare wọn ti wọn si n dagba ninu imọ Oluwa wa Jesu.

Idaniloju eto igbala ni Apọsteli naa n tẹnumọ ninu awọn ẹsẹọrọ wọnyi ki olukuluku ba le du u lati ṣe alabapin anfaani ti Ọlọrun ṣi silẹ. Ọlọrun ti ṣe ọna bi a ṣe le ni igbala ati gbogbo iranwọ ti o yẹ fun idalare ẹnikẹni, ṣugbọn olukuluku ni ojuṣe ti o gbọdọṣe. Iṣelogo ayeraye tabi itanu ayeraye ti ẹni kọọkan yoo duro lori bi olukuluku ba ti ṣe eyi ti o jẹ ojuṣe rè̩ si ninu iyanu eto igbala Ọlọrun.

Ifẹ ti o So Wa Pọ

Bi Apọsteli yi ti n ṣe aṣaro lori awoṅ nkan wọnyi, o dabi ẹni pe ago rè̩ kun akunwọsilẹ fun ayọ, iyin ti o si gba ọkan rẹ kan ko ṣee diwọn. Pẹlu imisi Ẹmi o mu ọrọ iyanju rè̩ wa si opin lori ẹbun igbala Ọlorun, ti o wa fun gbogbo eniyan. “Tani yio ha yà wa kuro ninu ifẹ Kristi?” Paulu darukọ pupọ ninu awọn nkan aye ti o le mu awọn miran ṣubu kuro lọna igbagbọ, ṣugbọn oun le sọ pe ninu gbogbo nkan wọnyi “awa ju ẹniti o ṣẹgun lọ nipa ẹniti o fẹ wa.” Paulu mọ, nitori o ti la gbogbo nkan wọnyi kọja o si ti ṣẹgun. Ọlọrun ki I ṣe ojusaju eniyan. Bi O ba mu eniyan kan de Ọrun hẹgẹ bi aṣẹgun bakan naa ni o le ṣe fun gbogbo ẹni ti o ba tọỌ wa.

A pari iwe yi pẹlu gbolohun ọrọ ti o yẹ fun iranti: “Nitori o da mi loju pe, ki iṣe iku, tabi iye, tabi awọn angẹli, tabi awọn ijoye, tabi awọn alagbara, tabi ohun igba isisiyi, tabi ohun igba ti mbọ, tabi oke, tabi ọgbun, tabi ẹda miran kan ni yio le ya wa kuro ninu ifẹỌlọrun, ti o wa ninu Kristi Jesu Oluwa wa.” Ọta ẹmi paapaa ati awọn ewu ti a kò ri, eyi ti olukuluku Onigbagbọ ni lati dojujakọ ki yio le ya Onigbagbọ ti o ni itara kuro lọdọ Kristi, nitori iṣẹgun ti o daju wa fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle Ọlọrun patapata. Nigba ti eniyan ba ri igbala, o ha ni idaniloju ayeraye bi? Ko si ọkan ninu awọn nkan ti Apọsteli darukọ ti o le yà ni kuro lara Kristi! Ọkan kọọkan ti a gbala ni idaniloju ayeraye niwọn igba ti o ba yan lati wa lọwọ Kristi -- niwọn igba ti o ba yan lati ṣe ifẹỌlọrun. S̩ugbọn ẹni kọọkan fun ara rè̩ le ja ara rè̩ gba kuro lọwọ Kristi.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Awọn eniyan wo ni o bọ kuro lọwọ idalẹbi ẹṣẹ?

  2. 2 Kin ni itumọ ririn “nipa ti Ẹmi”? “Ririn nipa ti ara”?

  3. 3 Kin ni yoo ṣẹlẹ si awọn ti n rin nipa ti ara?

  4. 4 Kin ni èrè awọn ti n rin nipa ti ẹmi?

  5. 5 Awọn wo ni ọmọỌlọrun?

  6. 6 Bawo ni eniyan ṣe le di ọkan ninu awọn ọmọỌlọrun?

  7. 7 Tani maa n ran awọn eniyan mimọỌlọrun lọwọ nigba ti wọn ba n gbadura? Lọna wo?

  8. 8 Pari gbolohun ọrọ yi: “Bi Ọlọrun bá wà fun wa …”

  9. 9 Tani tabi kin ni le ya Onigbagbọ kuro ninu ifẹ Kristi?