Filemoni 1 - 25

Lesson 354 - Senior

Memory Verse
“Ẹ māṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọnu, ẹ mā dariji ara nyin, gẹgẹbi Ọlọrun ninu Kristi ti dariji nyin” (Efesu 4:32).
Cross References

I Ipadabọ Onesimu

1 Iyipada ọkan Onesimu, iranṣẹ Filemoni ti ọna rè̩ buru nigba kan ri, ni o mu ki Paulu kọwe si Filemoni, Filemoni 1-12

2 Paulu fẹ gba Onesimu sọdọ ara rè̩, ṣugbọn o tun ro ti ẹtọ ti Filemoni ọga rè̩ ni, lati maa lo o gẹgẹ bi iranṣẹ rè̩, Filemoni 13, 14

3 Paulu gba Filemoni ni imọran pe, bi o tilẹ jẹ pe Onesimu gẹgẹ bi iranṣẹ ti salọ fun igba diẹ, o n pada bọ sọdọ rè̩ gẹgẹ bi arakunrin ninu Oluwa, eyi ki i ṣe fun igba diẹ, ṣugbọn titi lae, Filemoni 15, 16; Titu 2:9, 10; Efesu 6::5-9

4 A sọ fun Filemoni lati gba Onesimu gẹgẹ bi i ba ti gba Paulu tikararẹ, Filemoni 17; Matteu 10:40-42; 12:48-50; 25:40

5 Paulu fẹ ki Filemoni ka gbogbo gbese Onesimu si oun lọrùn, nipa bẹẹ o n fi apẹẹrẹẹkọ nla ti Ihinrere hàn ninu eyi ti Kristi ru gbogbo aṣiṣe wa ti o si n bẹỌlọrun sibẹ pe ki O dariji wa nitori ti Rè̩, Filemoni 18, 19; Isaiah 53:5, 12; Romu 3:24; 4:25; 5:1-21; II Kọrinti 5:18, 19; Efesu 2:13; Kolosse 1:14; I Johannu 4:10

6 Paulu ni idaniloju pe Filemoni yoo fi tayọtayọ gba Onesimu, Filemoni 19-25

Notes
ALAYE

Iyipada Onesimu

A le fi Episteli Paulu si Filemoni ṣe akawe itan ọmọ oninakuna nipa pe o jẹ akopọ gbogbo itan Ihinrere. Ironupiwada, igbala, atunṣe, ẹbọ irọpo fun ẹṣẹ gbogbo eniyan ti Kristi fi ara Rè̩ rú, ati idariji Ọlọrun – gbogbo nkan wọnyi ni a le ri ninu itan ẹru ti a yi pada yi.

Koko ọrọ ti o wa ninu Episteli yi si Filemoni ni nipa ẹru kan ti a n pe ni Onesimu. itumọ orukọ rè̩ ni “Li ere,” ṣugbọn o ti fi ara rẹ han bi alailere fun oluwa rẹ, Filemoni. O ti hu iwa buburu pupọ, lẹhin naa o fi oluwa rẹ ati iṣẹ rẹ silẹ, o si salọ. Ni Romu, Onesimu ba Paulu Apọsteli pade. A gbagbọ pẹlu ẹri ti o fidimulẹ pe a mu Onesimu ni Romu gẹgẹ bi ẹru ti o sa, a fi I sinu iṣẹọmọ-ogun Romu, ati pe iṣẹ ti a yan fun un ni lati maa ṣọ Paulu. Lọna iyanu Ọlọrun, bi Onesimu ti n salọ kuro ni ile ati kuro nidi iṣẹọga rẹ Onigbagbọ, o ba ara rẹ pada ni didè pẹlu Paulu.

Bi o tilẹ jẹ pe Onesimu dabi ọmọ buburu fun ọga rẹ Filemoni, sibẹ ayà kò fo Paulu nipa akọsilẹ rè̩ atẹhinwa. Paulu le bojuwo igbesi-aye ara rè̩ atẹhinwa, iwa rè̩ ati bi ọkan rẹ ti ri nipa Kristi. Bi o tilẹ jẹ pe Paulu ki i ṣe arufin ni ọna ti Onesimu fi gba jẹ arufin, Paulu paapaa ti huwa buburu si Ihinrere to bẹẹ ti o fi pe ara rè̩ ni pataki ninu awọn ẹlẹṣẹ. Siwaju si i, Paulu sọ pe, “S̩ugbọn nitori eyi ni mo ṣe ri anu gbà, pe lara mi bi olori, ni ki Jesu Kristi fi gbogbo ipamọra rè̩ han bi apẹrẹ fun awọn ti yio gbà a gbọ si iye ainipẹkun nigba ikẹhin” (I Timoteu 1:16).

Nitori ibalo timọtimọ ti Onesimu ni pẹlu Paulu, lai pẹ lọ titi o yipada di Onigbagbọ tootọ, a si tun un bi si Ijọba Ọlọrun.

Ẹda Titun ninu Kristi Jesu

Woli Jeremiah beere ibeere yi nigba kan: “Ara Etiopia le yi àwọ rẹ pada, tabi ẹkùn le yi ilà ara rè̩ pada? bḝni ẹnyin pẹlu iba le ṣe rere, ẹnyin ti a kọ ni ìwa buburu?” (Jeremiah 13:23). Iru ipo iṣoro bayi gan an ni Onesimu wà; bakan naa ni o ri fun olukuluku ọkan ti a ko I ti I yipada ki a si sọọ di ọtun. Onesimu kò le yi ifẹ rè̩ si iwà ibi pada, a ko tilẹ mọ boya o ni ifẹ ati yipada rara. S̩ugbọn Ọlọrun ninu aanu Rè̩ṣe amọna rẹ si ọdọẹni kan ti o le sọẹri ọkan rè̩ ti o ti kú ji, ki o si fun un ni ipinnu lati jẹ eniyan ọtọ dipo ọdaran. Nigba ti ifẹ lati ṣe rere ba dide ninu ọkan eniyan, Ọlọrun yoo fun un ni agbara lati di alaaye ati lati jẹ olododo dipo ki o jẹ okú ati ẹni idalẹbi titi ayeraye. Iwe mimọ sọ pe: “S̩ugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọỌlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ gbọ: awọn ẹniti a bi, ki iṣe nipa ti è̩jẹ, tabi nipa ti ifẹ ara, bḝni ki iṣe nipa ifẹ ti enia, bikoṣe nipa ifẹ ti Ọlọrun” (Johannu 1:12, 13).

Gbogbo iwa rere ti kò si ninu Onesimu tẹlẹ ni o bẹrẹ si han ninu iṣe rẹ lesẹkẹsẹ ti o ni iyipada ọkan. Alaiṣeefi-ọkan tan ni tẹlẹ, alaiṣootọ ninu iṣẹ rè̩, olè ati isansa nitori iwà ibi rè̩. Lẹhin iyipada ọkan rè̩, o wa yatọ patapata: o di olootọ, alaiṣeru, olootọ iranṣẹ ninu ipe Kristi, ati apẹẹrẹ Onigbagbọ rere. Lakoko yi Paulu jẹ onde ijọba Romu, ko si ni anfaani kankan. Onesimu ṣọwọn fun Paulu lati pinya pẹlu rè̩ nigba ti Onesimu pinnu lati pada sọdọọga rẹ atijọ.

Atunṣe

“Ọlọrun si bère eyi ti o ti kọja lọ” (Oniwasu 3:15). Lai pẹ titi o bẹrẹ si wa sọkàn Onesimu lati pada si ọdọ Filemoni oluwa rẹ lati ṣe atunṣe gbogbo buburu atẹhinwa. Ọfẹ ni Ọlọrun maa n fi ẹṣẹ awọn eniyan ji, ṣugbọn Oun kò gba ẹnikẹni layè lati maa lọ lai jẹwọ gbogbo iwa buburu ti o ti hù bi o ba ṣe e ṣe ati lai mu gbogbo ohun ti o ti wọ pada bọ si titọ. Ifẹ lati ṣe atunṣe igbesi-aye ti a ti lo ni ilokulo jẹ ami riri igbala tootọ. Ofin pa a laṣẹ pe a ni lati ṣe atunṣe gbogbo aṣiṣe atẹhinwa, a ni lati san oju owo ki a si fi idamarun rè̩ le e (Wo Lefitiku 6:2-5).

Nigba ti Sakeu, alaiṣootọ agbowo-ode nì yipada, o ṣe ileri fun Jesu lẹsẹkẹsẹ lati ṣe atunṣe. O wi pe: “Wo o Oluwa, àbọ ohun ini mi ni mo fi fun talakà, bi mo ba si fi è̩sùn èké gbà ohun kan lọwọẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin” (Luku 19:8).

Aanu Ọlọrun lati ipasẹ Ihinrere n kilọ fun gbogbo eniyan pe ki wọn mu anfaani ironupiwada ati idariji ẹṣẹ wọn nipasẹ iku ati ajinde Kristi lo. ỌrọỌlọrun kilọ pe: “Ẹṣẹ awọn ẹlomiran a mā lọṣāju si idajọ; ti awọn ẹlomiran pẹlu a si mā tẹle wọn” (I Timoteu 5:24). IfẹỌlọrun ni pe nipa agbara Ẹjẹ Jesu Kristi, ki ẹṣẹ gbogbo eniyan han gbangba ṣiwaju. Eyi ni pe, ki wọṅ mọẹṣẹ wọn lẹṣẹ, ki wọn si jẹwọ wọn fun Ọlọrun, ki Ọlọrun ba le dariji wọn. Bi ẹṣẹ wa ba tọ wa lẹhin kuro ni aye yi, nigba naa a o jẹẹlẹbi niwaju Itẹ IdajọỌlọrun; ṣugbọn ki yoo si idariji nagba naa, bẹẹ ni ki yoo si aanu ti yoo dawọ idajọ ododo Ọlọrun duro lori gbogbo ẹlẹṣẹ ti o kọẸjẹ Kristi silẹ.

Ọlọrun fẹ ki a ṣe atunṣe awọn aṣiṣe wa atẹhinwa laye yi bi a o ba ni ireti lati pade Rẹ ni alaafia nigbooṣe. Kikuna tabi kikọ lati ṣe atunṣe nigba ti o ṣe e ṣe yoo mu ki a yọ wa kuro ninu Ijọba Ọlọrun, yoo si mu idajọ wa daju. Nigba ti igbala Ọlọrun ba wọ inu ọkan kan, lẹsẹkẹsẹ ifẹ kan lati ọdọỌlọrun yoo mu ki ọkàn naa fẹ lati lọṣe atunṣe. Onesimu n fi ẹwà oore-ọfẹ igbala rè̩ han nigba ti o ni ọkan lati pada sọdọ oga rè̩ atijọ lati dojukọ iwa buburu rè̩ atẹhinwa. Oun ki yoo tun sa nitori ẹṣẹ rẹ mọ, nitori wọn ti kọja lọ a ki yoo si tun ranti wọn si i mọ.

Bi o tilẹ jẹ pe Paulu n fẹ ibalo Onesimu ati iranwọ rẹ lọpọlọpọ ninu iṣẹ Oluwa, sibẹ o ran Onesimu pada sọdọ Filemoni pẹlu ọpọ adura. Iwe rè̩ si Filemoni jẹ iwe ti o dara lọpọlọpọ ti o si kun fun ẹbẹ ti o mu ni lọkan pe ki Filemoni le gba ẹrú rè̩, Onesimu pada, ẹni ti o ti jẹ alailere ni saa kan ri, ṣugbọn ti o wulo pupọ nisinsinyi. O ti salọ gẹgẹ be ẹru, ṣugbọn o n pada bi iranṣẹ ati arakunrin ninu Oluwa. Paulu daba pe boya Onesimu fi igba kan lọ ki Filemoni ba le ni in lọdọ titi. Labẹ Ofin Majẹmu Laelae lẹhin ti ọmọ-ọdọ ba ti sinru fun saa kan, ọga rè̩ gbọdọ jẹ ki o maa lọ. Bi o ba si fẹ lati maa sin ọga rẹ si i, ọga rè̩ yoo lu iho si i leti. Iho eti rè̩ ni yoo jẹ ami fun ẹnikẹni ti o ba ri i ki o le mọ pe oun tikara rẹ ni o yan lati maa sin oluwa rè̩ titi aye. (Ka Ẹksodu 21:1-6; Orin Dafidi 40:6). Onesimu yan ni tootọ lati pada sọdọ oluwa rè̩ atijọ ki o ba le fi fifẹọkan ati aya rè̩ sin in gẹgẹbi si Oluwa. Ki i tun ṣe isin ti ẹru ti n bẹ ninu idè, ṣugbọn isin ati iṣẹ ti ifẹ.

Ka a Si Mi Lọrun

Iwe ti Paulu kọ si Filemoni pe ki o gba Onesimu pẹlu iyọnusi kọja bibẹbẹ lasan fun aanu ati idariji. Pẹlu awọn gbolohun orọṣokiṣoki diẹ, Paulu fi kókó Ihinrere Jesu Kristi han ni ọna ti o dara. A ti sọ Filemoni di Onigbagbọ nipa iwaasu Paulu, ṣugbọn Paulu ko beere pe ki Filemoni dariji Onesimu nitori pe wọn jẹọrẹ. Awọn ọrọ Filemoni leti Ẹni kan ti O san gbese rẹ, ti Filemoni paapaa fi bọ lọwọẹṣẹ rè̩, ati pe ki oun naa dariji Onesimu gẹgẹ bi Kristi ti dariji oun naa. (Wo Matteu 18:23-35).

Ọrọ Paulu, “Nitorina bi iwọ ba ka mi si ẹlẹgbẹ rẹ, gba a bi emi tikarami. S̩ugbọn bi o ba ti ṣẹọ rara, tabi ti o jẹọ nigbese kan, ka a si mi lọrun,” wá nipa imisi Ẹmi Mimọ; o si ṣe apejuwe ni iwọn iba ọrọ diẹ, ohun ti ẹbọ irapadà Jesu Kristi jasi, eyi ti o to fun ẹṣẹ gbogbo ẹda. Ẹlẹṣẹ, ti a wẹ mọ kuro ninu ẹṣẹ rè̩, le pada si ile Oluwa rè̩, ki o si mu ihin ilaja ti o ri gba lọdọ Kristi lọwọ. Jesu Kristi ko ha wi fun Baba Rè̩ nitori ẹlẹṣẹ-kẹlẹṣẹ ani gbogbo ẹlẹṣẹ ti yoo ba rọ mọẸjẹ Kristi fun idalare wọn pe “Gba a bi emi tikaraki”? “Nitorina bi iwọ ba ka mi si ẹlẹgbẹ rẹ, gba a bi emi tikarami. Bi o ba ti ṣẹọ rara, tabi ti o jẹọ nigbese kan, ka a si mi lọrun.” Nipa agbara Ẹjẹ Jesu Kristi, Ọlọrun n gba ẹlẹṣẹ ti o ba ronupiwada gẹgẹ bi O ti gba Ọmọ Oun tikara Rè̩, ani Jesu Kristi! Ẹtọ ti Jesu Kristi ní ni a n wo mọẹlẹṣẹ lara; aitọ ati abuku ti ẹlẹṣẹ ní ni Jesu Kristi ti san gbese rè̩ ti O si ti ṣe etutu fun.

Bi o ba “jẹọ nigbese kan” -- ẹlẹṣẹ wo ni kò jẹỌlọrun ni gbese ti o pọ to bẹẹ ti kò fi le san an? Tani kò ti i Ẹṣẹ ki o si kunà ogo Ọlọrun? Sibẹ lai ka ibi ti ẹnikẹni ti ṣe si ijọba Ọlọrun si, Jesu wi pe Oun yoo fi ara Oun dipo wọn lati bẹbẹ fun wọn niwaju Baba Rè̩. Jesu Kristi le gba ẹjọẹlẹṣẹ ti o ronupiwada wi ni awijare nitori pe O ti gba iya gbogbo ẹlẹṣẹ jẹ. “O si ru è̩ṣẹọpọlọpọ; o si n ṣipè̩ fun awọn alarekọja” (Isaiah 53:12). Oun ni Ọdọ-agutan Ọlọrun -- Ọdọ-agutan ti kò ni aleebu tabi abuku – ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aye; ati nitori Ẹbọ arukún ati arudà yi Ọlorun a maa fi ododo fun awọn wọnni ti o ba gbagbọ pe Ẹjẹ Kristi ti a ta silẹ to fun idariji ẹṣẹ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Kin ni itumọ Onesimu?

  2. 2 Eeṣe ti Onesimu fi kuro nidi iṣẹọga rẹ?

  3. 3 S̩e alaye bi Onesimu ṣe ni iyipada ọkàn?

  4. 4 Eeṣe ti Onesimu fi fẹ pada sọdọọga rè̩ atijọ?

  5. 5 Iru ipo wo ni Onesimu wa nigba ti o pada sọdọ Filemoni?

  6. 6 Idi rè̩ ti Paulu fi sọ fun Filemoni pe ki o gba Onesimu gẹgẹ bi yoo ti ṣe gba oun Paulu?

  7. 7 Fun awọn wo ni Jesu yoo sọ fun Baba Rè̩ pe “Gba a bi emi tikara mi”?

  8. 8 Ọna wo ni a gba ka ẹṣẹ awọn eniyan si Jesu Kristi lọrùn?

  9. 9 Kin ni itumọ agbara ti n bẹ ninu Ẹjẹ Jesu Kristi?

  10. 10 Eeṣe ti Ọlorun ki yoo fi gba awọn ẹlẹṣẹ bi ko ṣe pe wọn ba gba ọna Ẹjẹ Jesu Kristi?

  11. 11 Eredi rẹ ti atunṣe fi ṣe pataki?