I Kọrinti 13:1-13

Lesson 355 - Senior

Memory Verse
“Ati bori gbogbo nkan wọnyi, ẹ gbe ifẹ wọ, ti iṣe amure iwa pipe” (Kolosse 3:14).
Cross References

I Ifẹni -- Eti ti I ṣe IfẹỌlọrun

1 Ifẹ ni koko ati akopọè̩sìn otitọ. Ẹbun ahọn, isọtẹlè̩, imọ, igbagbọ, iṣoore ati itara fun otitọ -- iwọnyi kò mu igbala wa, I Kọrinti 13:1-3; Deuteronomi 6:5; Lefitiku 19:18; Deuteronomi 10;12, 13; Marku 12:28-31; Luku 10:25-28

2 A ṣe alaye awọn eso rere ti n bẹ ninu ifẹni tabi IfẹỌlọrun, I Kọrinti 13:4-7; Owe 10:12; I Peteru 4:8; II Johannu 5

3 Isọtẹlẹ, ẹbun-ahọn, ati imọ yoo dopin, ṣugbọn ifẹỌlọrun wa titi lae, I Kọrinti 13:8-10; Kolosse 3:14

4 A ṣe apejuwe ipo aipe ti ọmọ eniyan wà, I Kọrinti 13:11, 12; II Kọrinti 3:18; 5:7; I Johannu 3:2

5 Ifẹ ni ohun ti o tobi ju lọ, I Kọrinti 13:13; Matteu 5:44; Romu 13:10; Johannu 13:34; 15:9, 13, 17; Heberu 13:1; I Johannu 3:1; 4:7-12, 17-19

Notes
ALAYE

Ijọ Kọrinti

Oṣu mejidinlogun ni Paulu lo ni Kọrinti, ti o fi n waasu fun awọn ara Kọrinti. A ti dá Ijọ ti o lagbara silẹ; ṣugbọn lẹhin ti Paulu kuro nibẹ, iyapa ati ẹkọìṣìnà ti yọ wọ aarin wọn. Awọn Hellene fẹran ki woṅ maa ṣe apọnle eniyan. Paulu kọ Episteli yi lati ṣe atunṣe awọn nkan wọnyi. Ori ikẹtala iwe yi jẹ iyanu, a si ka a si ọkan ninu awọn ti o ṣe pataki ju lọ ninu Bibeli. O yẹ ki ẹni kọọkan le kọọ sori.

Ẹni kan ti sọ pe, “Ifẹ ni aworan Ọlọrun gan an ninu ọkan; nitori pe ifẹ ni Ọlọrun. Nipa igbagbọ ni a maa n ri nkan gba lọwọẸlẹda wa; nipa ireti a maa n foju sọna fun ọjọ iwaju ati ayeraye; ṣugbọn nipa ifẹ ni a fi n jọỌlorun; ati pe nipa ifẹ nikan ni a o fi ni ẹtọ lati jẹ igbadun ọrun ti a o si fi jẹọkan pẹlu Rè̩ titi ayeraye.” Ifè̩ ni akoja ofin. Ofin ko lagbara lati yi igbesi-aye eniyan pada, ṣugbọn Kristi, ti I ṣe Ifẹ di eniyan, ṣe e!

Ibi Titun

Johannu Apọsteli sọ gbangba pe “Ifẹ ni Ọlọrun; ẹniti o ba si ngbe ninu ifẹ o ngbe inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rẹ.” A fun wa ni iwọn ifẹỌlọrun , nipa ododo Jesu Kristi nigba ti a ba tun wa bi. Iyatọ wa ninu ifẹỌlọrun ati ifẹ ti eniyan. A bi wa sinu aye yi pẹlu ifẹ ninu wa iru eyi ti o mu ki awọn obi fẹran awọn ọmọ wọn, ati ifè̩ diẹ tabi pupọ ti a ni si ẹda eniyan. Awọn ẹranko paapaa ni ifẹ si awọn ọmọ wọn. S̩ugbọn è̩ṣẹ dapọ mọ ifẹ yi ninu ọkan eniyan, eyi ni ẹṣẹ ti a gbìn sibẹ nigba ti eniyan ṣaigbọran si Ọlọrun ti o si ṣubu kuro ninu ifẹ pipe ati ipo ailẹṣẹ. Ki eniyan to tun le pada di aworan Ọlọrun, a gbọdọ yi i pada. A gbọdọ sọọ di ẹda titun. Jesu pe iyipada yi ni ibi titun. Awọn eniyan ti gbiyanju lati fi ohun pupọ dipo ibi-titun yi. Wọn ti dan ẹkọ wo, wọn dan ṣiṣe atunṣe nkan wo, didarapọ mọ ijọ kikọnfaaamu, oore ṣiṣe, ṣiṣe iranwọ fun talaka ati alaini, lati fi dipo iyipada ọkan. Jesu wi pe ẹni ti o “ba gba ibomiran gun oke, on na li ole ati ọlọṣa” (Johannu 10:1). Asan ni gbogbo ilakaka eniyan lati de Ọrun lọna miran yatọ si ọna ibi titun. “Bikoṣepe a tun enia bi, on ko le ri ijọba Ọlọrun” (Johannu 3:3).

Isọdimimọ

Bi o ti ṣe pe ifẹ n wọ inu nigba ti a ba tun wa bi, o ṣe e ṣe ki “a mu ifẹ ti o wa ninu wa pe” (I Johannu 4:17), nipa iriri ti o tun jinlẹ si i ti a n pe ni isọdimimọ, iṣẹ oore-ọfẹ keji ti o daju, ti o n ṣẹlẹ lẹsẹ kan naa. “Ẹnikẹni ti o ba npa ofin rẹ mọ, lara rè̩ li a gbe mu ifẹỌlọrun pe nitõtọ” (I Johannu 2:5). “Ifẹ pipe” jẹ orukọ miran fun “iwa mimọ,” “pipe Onigbagbọ,” tabi isọdimimọ,” eyi si maa n ṣe e ṣe nigba ti a ba tu gbongbo ẹṣẹ kuro ninu ọkàn nipa ibuwọn Ẹjẹ Jesu Kristi. “Kristi si ti fẹran Ijọ ti o si fi ara rẹ fun u, ki on ki o le sọọ di mimọ lẹhin ti a ti fi ọrọ wẹẹ mọ ninu agbada omi. Ki on ki o le mu u wa sọdọ ara rẹ bi ijọ ti o li ogo, li aini abawọn, tabi alebu kan, tabi iru nkan bawọnni, ṣugbọn ki o le jẹ mimọ ati alaini abuku” (Efesu 5:25-27)

Ahọn

Ọpọlọpọ oniwaasu olohun iyọ ni o wa. Ni ọpọlọpọ igba ni a maa n gbọ iru ọrọ bayi “Gẹẹsi yọ lẹnu rẹ.” S̩ugbọn bi ifẹỌlọrun kò ba kun ọkàn oniwaasu naa, gbogbo aṣaro ọrọ rè̩ daradara, ati gbogbo gẹẹsi rẹ to gbadun dabi idẹ ti n dun ati bi kimbali olohun gooro. Pupọ awọn ọkàn ti ebi n pa lo ti jade ni ile isin nlá nlá lai ni itẹlọrun nitori pe awọn oniwaasu kuna lati ni ohun kan ti o ṣe pataki ju lọ -- IfẹỌlọrun.

Igbagbọ

A sọ fun ni ninu Heberu Ori Kọkanla pe “Igbagbọ ni idaniloju ohun ti a nreti, ijẹri ohun ti a ko ri” ati pe nipa igbagbọ ni a ṣẹgun ilẹọba, a di awọn kiniun ni ẹnu, a si ji awọn oku dide laaye. Jesu yin obinrin ara Sirofenikia fun igbagbọ rẹ, ẹni ti o fi irẹlẹ bẹbẹ fun iwosan ọmọbinrin rẹ: Jesui wi pe, “Igbagbọ nla ni tirẹỌmọbinrin yi.” Ẹ jẹ ki a ranti igbagbọ ti balogun-ọrun paapaa, ẹni ti o bẹbẹ fun iwosan ọmọ-ọdọ rè̩. Jesu sọ pe Oun ko i ti i ri iru igbagbọ nla bi eyi ni Israẹli. Ohun iyanu nla pupọ ni o ti ṣẹlẹ nipa igbagbọ. S̩ugbọn Paulu fi han pe bi ko ṣe pe igbagbọ ba dapọ mọ ifẹỌlọrun ninu ọkàn, ki yoo ṣe ọkàn ni ire kankan. Igbagbọ nikan ki yoo to lati ṣi ilẹkun perli ọrun fun ni.

Okiki

Ọpọlọpọ awọn ọlọrọ ni o ti yọọda owo wọn fun iṣẹ oore, wọn fi owo ṣe iranwọ fun ọpọ ile-ẹkọ giga, ọpọ ile itọju alaisan ati iru awọn ibi bẹẹ bẹẹ. Awọn ẹlomiran tilẹ ti lọ jinna ju bẹẹ to bẹẹ ti wọn ti fi ara wọn fun igbekalẹ ti wọn pọnle. S̩ugbọn Kọrinti ori ikẹtala fi ye ni gbangba pe bi ko ṣe pe a ba ni ifẹỌlorun ninu ọkan, gbogbo awọn nkan wọnyi ki yoo fun wa ni ere kankan. Orukọ wa, okiki wa ati ohun gbogbo ti a ni yoo parẹ bi ọjọ ti n lọ. Ẹkọ ti o ga ju lọ, imọ iṣẹ-ọna ati oyè-ẹkọ ti o ga ju lọ, imọ-ijinlẹ ati imọ awari ogbọn, ṣiṣe ohun titun ti igbalode ko le mu kekere ninu ifẹỌlọrun wọọkan ẹnikẹni. Ẹbun ọfẹỌlọrun ni ti a fi ẸjẹỌmọ Rè̩, Jesu ra; nipa gbigba Jesu Kristi Oluwa wa gbọ ni a si le fi ni in.

Awọn Ami Ifẹ

Paulu ṣe alaye ifẹ, o fọọ si wẹwẹ, o si sọ fun ni ohun ti ifẹ i ṣe gan an. IfẹỌlọrun ninu ọkan a maa mu ki eniyan le fara mọ ofin iṣoore. Itumọ eyi ni pe ki i ṣe oniwa-tutu ati onifarada nikan, ṣugbọn oun jẹ olootọ si awọn ọkàn wọnni ti wọn jẹ alaiṣootọ si ara wọn. Ọpọlọpọ eniyan ni o jẹ alaiṣootọ si ara wọn, wọn a si maa gbiyanju lati bo aiṣootọ yi mọlẹ ninu ọkan wọn. Wọn n fẹẹni kan ti o ṣe onunuure ti o si gbọn lati ṣe iranlọwọ fun wọn lati tu aṣiiri ohun ti wọn n bo ti o si le mu wọn padanu ẹmi wọn nikẹhin bi wọn kò ba ronupiwada. Inu-rere jẹ iwa-ọrun ti a ṣiṣẹ rẹ ninu ọkan ti o si maa n jẹ yọ ninu ọrọẹnu.

Ẹni ti o ba ni ifẹ ki i ba arakunrin rè̩ jẹ. O ṣe e ṣe ki o ba a wi, ki o si kilọ fun un, ṣugbọn labẹ ibawi nì ni ofin iṣeun n bẹ lati bu ororo si i. Jẹjẹ ni ifẹ, o si ẹmi ibanikẹdun ninu ara rè̩, a maa ṣeun a si maa ran awọn ẹlomiran lowọ. Ki i maa da ijọgbọn silẹ. Ifẹ a maa mu ki eniyan fẹ lati fi ti awọn ẹlomiran ṣiwaju. Ifẹ ki i ṣe ainitẹlọrun si ayọ ati igbega awọn ẹlomiran. Ki i gbe ara rẹ siwaju, ki i si fẹ ki a ṣe afiyesi tabi ki a yin oun. Ifẹ ki i yara ṣe idajọ tabi yara ba awọn ẹlomiran wi. Ifẹ ki i fẹ fi han bi oun ti ṣe pataki to. Irẹlẹ tootọ a maa dide lati inu è̩kún ibukun Ọlọrun ninu ọkan.

Awọn eniyan, tabi ohunkohun ti o wu ki o ṣẹlẹ, ki i mu ifẹ huwa lodi si ipo rè̩ ninu aye. Ifẹ tootọ a maa mu ki ẹni ti o ba ni in ṣe iru ohun ti o kun fun ironu ti o tọ ti o si yẹ nipa ohunkohun ti o ba ṣẹlẹ. Ifẹ ki i maa wa ohun ti ara rẹ, ki i si i ni itẹlọrun bi ko ṣe ninu ire, irọrun ati igbala awọn ẹlomiran. Ninu otitọ nikan ṣoṣo ni o maa n yọ. A maa farada ailera ati ikuna awọn ẹlomiran, a si maa gba eyi ti o dara ju lọ ti o ṣe e gbagbọ nipa eniyan, a maa ni ireti fun igbala ati ilọsiwaju awọn eniyan ni ibi gbogbo, a si maa fi ara da idanwo ati ipọnju pẹlu igboya. Ko si ẹni ti o le wa ni imurasilẹ tootọ fun ogo ayeraye bi ko ṣe pe ifẹỌlọrun yi ba jinlẹ gidigidi ninu ọkan ati ẹmi ẹni naa.

Ifẹni

Ifẹ ki i yẹ lae. Isọtẹlẹ yoo dopin, ẹbun ahọn yoo dopin, imọ yoo parẹṣugbọn ifẹỌlọrun yoo duro laelae. Ni orilẹ-ede okunkun Afrika nibi ti David Livingstone jẹ eniyan alawọ funfun kinni ti o kọkọ wọ inu awọn ilu ti o jinna si eti okun lọ, a sọ fun ni pe nigba ti a ba darukọ rẹ, oju awọn eniyan dudu wọnyi a maa fani mọra bi wọn ti n sọrọ nipa oniṣegun oninuure naa ti o ti wa si ilẹ wọn ni ọpọọdun sẹhin. Wọn kò gbọ ede rè̩, ṣugbọn wọn mọ bi ifẹọkàn rè̩ ti to si wọn. Bi a ba gba oore-ọfẹ kekere nì ti ifẹ Onigbagbọ sinu ọkan wa, iṣẹ wa yoo yori si rere. Kò si ohun ti o tobi ju eyi lọ ti a tun le di mu.

Eyi ti o Tobi Ju Lọ

Njẹ nisinsinyi, igbagbọ, ireti ati ifẹ n bẹ, ṣugbọn eyi ti o tobi ju ninu wọn ni ifẹ. “Lati ni ifẹọpọlọpọ ni lati gbe igbesi-aye itẹlọrun lọpọlọpọ, lati fẹran titi aye, oun ni lati wà titi lae” ni iranṣẹỌlọrun kan wi. Nitori naa iye ainipẹkun so pọ mọ ifẹ.

Laisi igbagbọ ko ṣe e ṣe lati ba Ọlọrun rin. Igbagbọ n mu wa sunmọỌlọrun, ati pe nipa igbagbọ ni a si fi n ba Ọlọrun rin. O jẹọkan ninu awọn ohun mẹta ti o tobi: Ireti lo maa n mu ọkan fó, a si maa mu ni tẹ atẹsiwaju. Ireti ni fifi igboya fi oju sọna fun ohun ti n bọ. Aṣibori wa ni ireti igbala. A maa n wọọ ni gbogbo igba. Lai si ireti, ọkàn a ṣaisan a si kú. Ni wakati iṣudè̩dè̩ paapaa ireti yoo dide fun iranwọ wa. Igbagbọ ati ireti ni a maa n mu rin ajo aye yi ja, ṣugbọn ifẹ ni yoo ba wa lọ si ayeraye. Eyi ti o tobi ju ninu wọn ni ifẹ!

IfẹỌlọrun bo ti dara to!

Alaini ’wọn alagbara

Yoo wa titi ayeraye

Orin awọn mimọ at’angẹl.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Kin ni awọn ohun nla mẹta ti a fi we ara wọn ninu ẹkọ yi?

  2. 2 S̩e apejuwe igbagbọ.

  3. 3 S̩e apejuwe ireti.

  4. 4 S̩e apejuwe ifẹni.

  5. 5 Sọ iyatọ ti o wa laarin ifẹ eniyan ati ifẹỌlọrun.

  6. 6 Kin ni iwaasu tabi ẹri-jijẹ jọ bi ifẹỌlọrun kò ba si ninu ọkàn?

  7. 7 Kin ni n sọ eniyan di Onigbagbọ tootọ?

  8. 8 Darukọ diẹ ninu awọn eso ifẹỌlọrun.