Efesu 6:1-4

Lesson 356 - Senior

Memory Verse
“Njẹ nisisiyi, ẹ fetisi temi, ẹnyin ọmọ: nitoripe ibukun ni fun awọn ti o tẹle ọna mi” (Owe 8:32).
Cross References

I Iṣẹ Awọn Ọmọ ati Awọn Obi

1 O yẹ fun awọn ọmọ lati gbọ ti awọn obi wọn ninu Oluwa, Efesu 6:1; Owe 23:22; Kolosse 3:20

2 Bi wọn ba bu ọla fun baba ati iya wọn, ileri n bẹ pe wọn yoo gbadun ọjọ aye wọn pẹ titi, Efesu 6:2, 3; Ẹksodu 20:12; Deuteronomi 5:16; Jeremiah 35:18, 19; Matteu 15;4

3 Awọn obi ni lati fi iwa pẹlẹ ba awọn ọmọ wọn lo, ki wọn si tọ wọn ninu ibẹru Ọlọrun, Efesu 6:4; Deuteronomi 4:9; 11:19; Orin Dafidi 78:4-8; Owe 19:18; 22:6; 29:17

Notes
ALAYE

Ile

Alaye kikun wa ninu Bibeli nipa iṣẹ awọn obi si awọn ọmọ ati iṣẹ awọn ọmọ si awọn obi. Ile jẹ igbekalẹỌlọrun. Ọlọrun ṣe ilana rè̩ lati jẹọkan ṣoṣo. Ni atetekọṣe Ọlọrun ri i pe ko yẹ ki ọkunrin ki o nikan wa, o si fun un ni oluranlọwọ kan. A sọ fun ni pe ọmọ ni iní Oluwa.

Ẹru nlá nlà ni o wa lori awọn obi. “Bi ile ti ri, bẹẹ gẹgẹ ni orilẹ-ede ri.” Ile ni agbara orilẹ-ede. Owe laelae miran tun sọ pe: “Ọwọ ti o gbe ọmọ ikoko (jojolo) lo n ṣakoso gbogbo agbaye.” Bi ile wa ba fọ ti o si pin si wẹwẹ, lai pẹ titi orilẹ-ede wa yoo fọ pẹlu. Bi awọn ile wa ba jẹ ile Onigbagbọ tootọ, a o ni orilẹ-ede ti ọta ki yoo le bori.

Nigba ti Oluwa tipasẹ Mose ba awọn Ọmọ Israẹli da majẹmu, gbogbo wọn lo ni lati fi ara han niwaju Rè̩ -- awọn olori wọn, awọn alagba wọn, awọn alabojuto wọn ati awọn alejo (Deuteronomi 29:9-12). Gbogbo ẹbi ni o gbọdọ wá lati wá sin Oluwa. Nigba ti Jọṣua wọ ilẹ Kenaani, o tẹ pẹpẹ kan sori oke Ebali o si ṣe ẹbọ sisun ati ẹbọ alaafia. O kọ awọn Ofin Mose sara okuta ni oju gbogbo awọn Ọmọ Israẹli. Bẹẹ ni o si tun ka gbogbo ọrọ ofin naa si eti igbọ gbogbo apejọ Israẹli, pẹlu awọn obinrin, awọn ọmọ wẹwẹ wọn ati awọn alejo ti o wa laarin wọn (Jọṣua 8:30-35). Ọlọrun ṣe igbekalẹ ijọsin fun gbogbo ẹbi.

Ni akoko ti Kristi, awọn obi maa n fẹ lati gbe ọmọ wọn tọ Jesu wa ki o le sure fun wọn. Awọn ọmọ-ẹhin da wọn lẹkun wọn si n fẹ le wọn sẹhin, ṣugbọn Jesu wi pe: “Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere ki o wa sọdọ mi, ẹ má si ṣe dá wọn lẹkun: nitoriti iru wọn ni ijọba Ọlọrun” (Ka Marku 10:13-16). A ri bi ẹkọ Jesu ti n tẹle ilana Ofin ni mimu ọmọde wa jọsin ni ile Ọlọrun. Wo bi o ti yẹ ki awọn ọmọde ṣe jẹjẹ ki wọn si ṣe ohun gbogbo tọwọtọwọ ni ile-isin! A gbọdọ jẹ ki wọn mọ nipa apẹẹrẹ ati igbani-niyanju awọn obi wọn pe iwaju Ọlọrun ni wọn wa nitootọ.

Isin Agbo-ile

Igbekalè̩ miran ti Oluwa bukun ni isin agbo-ile. Ni ile awọn Onigbagbọ atijọ, awọn obi a maa ko gbogbo ẹbi jọ ni ẹẹkan tabi ẹẹmeji nigba miran loojọ lati ka ọrọỌlọrun ati lati gbadura. Wo iru ibukun nla ti yoo wá si iru ile bẹẹ! O ṣoro fun ni lati gbagbọ pe ọpọ awọn alaigbagbọ ni a tọ ninu ile ti ifẹỌlọrun wa nibi ti awọn obi jẹ olootọ lati kọ awọn ọmọ wọn ni ỌrọỌlọrun.

Labẹ Ofin, gbogbo ile ni lati gbọọrọỌlọrun ki wọn si gbọran si i. “Gbọ, Israẹli: OLUWA Ọlọrun wa, OLUWA kan ni. Ki iwọ ki o si fi gbogbo aiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ fẹ OLUWA Ọlọrun rẹ. Ati ọrọ wọnyi ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o mā wa li aiya rẹ: Ki iwọ ki o si mā fi wọn kọ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o si mā fi wọn ṣe ọrọ isọ nigbati iwọ ba joko ni ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrin li ọna, ati nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide” (Deuteronomi 6:4-7).

Iṣẹ awọn obi ni nigba gbogbo lati fi ỌrọỌlọrun kọ awọn ọmọ wọn ni ile. Ọpọlọpọ ni o fi iṣẹ yi silẹ fun olukọ ile-ẹkọỌjọ Isinmi tabi fun oniwaasu lati ṣe ni Ọjọ Isinmi. Oluwa sọ nipa ti Abrahamu pe: “nitoriti mo mọọ pe on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ ati fun awọn ara ile rẹ lẹhin rẹ, ki nwọn ki o mā pa ọna OLUWA mọ lati ṣe ododo ati idajọ” (Gẹnẹsisi 18:19). A le ri i nihin iru igbẹkẹle ti OLUWA ni ninu Abrahamu. Njẹ O ha ni iru igbẹkẹle bẹẹ ninu wa loni?

Ọkan ninu awọn ibi igba isinsinyi ni pe awọn ọmọ ni o n ṣe akoso awọn obi wọn, ki i ṣe awọn obi ni o n ṣe akoso awọn ọmọ wọn. Wo bi awọn ọdaran ọmọ ti pọ to nitori awọn iru iwa bayi. A mọ iru idajọ ti o wa sori Eli, alufa, nigba ti awọn ọmọ rè̩ sọ ara wọn di ẹlẹgbin ti oun ko si da wọn lẹkun. Bi Oluwa ba fi awọn ọmọ si itọju wa, a gbọdọ fi akoko silẹ lati boju to wọn. Wọn ni ẹmi ti ki i ku, nitori bẹẹ a ko gbọdọ jẹ ki wọn dagba bi ọmọ ti ko ni ile, ti o dagba si oju titi, lai fi ỌrọỌlọrun kọ wọn.

Iṣẹ Awọn Obi si Awọn ọmọ Wọn

“Ẹnyin baba, ẹ maṣe mu awọn ọmọ nyin binu.” Ki a ba ọmọde wi, ki a si nà wọn jẹẹkọ ti a kọ ni yekeyeke ninu Bibeli. Ẹṣẹ abinibi ti a bi mọ awọn ọmọ yoo ti wọṅ lọ sinu ọpọlọpọ iwa buburu ati iwa ẹṣẹ bi ko ṣe pe awọn ọbi ba gba a ni iṣẹ lati maa ṣọ wọn ati lati da wọn lẹkun. O gba ọpọlọpọọgbọn ati ifẹỌlọrun lati le tọọmọde si ọna ti o tọ. Awọn obi miran a maa ba awọn ọmọ wọn binu wọn a si maa gba wọn sibi gba wọn sọhun: eyi fẹrẹ buru ju ki a má tilẹ jẹ wọn niya rara. Bi awọn obi yoo ba fi inu tan awọn ọmọ wọn ki wọn si maa fi ifẹ ati inurere ṣe alaye iyatọ ti o wa laarin rere ati buburu, eyi yoo jẹ ki o ye ọmọ naa gbangba idi rè̩ ti a fi n jẹ oun niya. Awọn obi miran a maa ba awọn ọmọ wọn gbadura pọ ki wọn to jẹ wọn niya, eyi yi dara paapaa nigba ti ọmọ naa ba ti dagba to lati ni oye to bẹẹ. Ọdọmọkunrin ọmọọdun mejila kan wa ni ile kan ti o korira obinrin kan ti n gbe ibẹ, a si maa sọọrọ buburu si obinrin naa. Iya ọmọ yi a si pe e wọ inu yara a si sọ fun un pe oun ki yoo gba a laye lati maa sọrọ bẹẹ. Lẹhin eyi awọn mejeeji a si jọ gbadura. Ni ọjọ kan iya rè̩ tun pe e wọ inu yara, ọmọ yi si sọ pẹlu iyanu pe, “Iya, emi ko ti i sọ ohunkohun lati igba ti a ti jọ gbadura.”

Ile-Ẹkọ Gbogbo-gbo

Awọn Ile-ẹkọ ti gbogbo-gboo dabi ẹni ti n ro pe awọn ti jogun awọn ọmọ wa, wọn si n fẹ ni aṣẹ kikun lati tọ wọn si ọnakọna ti o ba tẹ wọn lọrun. Wọn ti ṣe ilana ẹkọ silẹ eyi ti yoo ṣoro fun awọn obi ti o ba jẹ Onigbagbọ lati fi ara mọ patapata. Ijo jijo, ọkan ninu awọn ibi ti o ga ju lọ ni ode oni ni a n kọ awọn ọmọ ni ọpọlọpọ ile-ẹkọ. Aṣọ ti wọn n wọṣire idaraya paapaa lodi si ẹkọ ti o yẹ fun awọn ọmọ Onigbagbọ. Awọn iwe ti n bẹ ni ile-ikawe wọn gbogbo ki i ṣe iru eyi ti o yẹ ki ọmọ Onigbagbọ maa ka. Awọn obi miran maa n ṣe ayẹwo awọn iwe ti awọn ọmọ wọn n gba lati ile-ikawe wa ka ni ile; ti wọn ko ba yẹ ni kika fun awọn ọmọ, wọn a dá wọn pada. O yẹ ki gbogbo awọn obi maa ṣe eyi. Ẹkọ ti a ba fi kọ awọn ọmọ wa ni wọn yoo dagba sinu rẹ.

Igbagbọ Rọrun

Ọkan ọmọde rọ pupọ. Bi awọn obi ko ba ti i tan ọmọde jẹ nigba kan ri, yoo gbẹkẹle wọn patapata. A le kọọmọde nipa Jesu ni igbakigba ti ọmọ naa ba ti le pe Orukọ Jesu. Otitọ igbagbọ wọn yoo maa doju ti awọn obi wọn nigba pupọ. Ni igba miran awọn obi ti ara wọn ṣe alaida maa n ri iwosan nipa adura ọmọde. Ọkan ọmọde ki i pẹ gbọgbẹ nitori naa o yẹ ki awọn obi maa ṣọra bi wọn ṣe n sọrọ ati bi wọn ṣe n huwa niwaju wọn. Wo bi o ti jẹ ojuṣe nlá nlà to lati tọọmọde ni ọna ti yoo tọ!

Aigbọran si Obi

Ninu Iwe ti Paulu kọ si Timoteu o sọ wi pe ni ikẹhin ọjọ awọn ọmọ yoo jẹ aṣaigbọran si obi. Ninu ile melo loni ni o ti le ri awọn ọmọ ti o gbọran si obi? Ni ọdun diẹ sẹhin, eṣu ṣe eto ọgbọn è̩wẹ ti o buru jai ju eyi ti a le fi ọkan ro lọ lati ba aye awọn ọmọ wa jẹ. O yọ kẹlẹ wọ inu ọkan awọn olukọni wa lati maa sọ pe awọn ọmọde gbọdọ ni ominira lati huwa, lati ronu ati lati ṣe bi wọn ba sa ti fẹ lai si idiwọ tabi idalẹkun ẹnikẹni, bi ko ṣe pe ki a gba wọn laye lati dagba gẹgẹ bi wọn ti n fẹ. Eso irugbin ẹkọ yi ni orilẹ-ede n ka loni. Ko si igba ti iwa ailofin gbilẹ ri bi ti akoko yi. Pupọ ninu awọṅọdaran ode-oni jẹ awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko to ogun ọdun.

A ko le ṣáỌrọỌlọrun tì ki a si ni ireti pe ki awọn ọmọ wa jẹ apẹẹrẹ rere. Bibeli sọ pe, “Li aiya ọmọde ni were di si; ṣugbọn paṣan itọni ni yio le e jina kuro lọdọ rẹ” (Owe 22:15). Ohun ti ẹkọ wa palaṣẹ ni pe “Ẹnyin ọmọ, ẹ mā gbọ ti awọn obi nyin ninu OLUWA: nitoripe eyi li o tọ.” Wo bi yoo ti dun mọ ni to lati lọ si ile kan nibi ti a gbe n kọ awọn ọmọ lati gbọran!

“Bọwọ fun baba ati iya rẹ: (eyi ti iṣe ofin kini pẹlu ileri).” Ileri naa ni, “Ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wa pẹ li aiye.” Obi melo ni o ti joko ti wọn ti ba awọn ọmọ wọn jiroro ti wọn si ti sọ fun wọn nipa ofin yi ati ileri iyanu ti OLUWA ti ṣe. O rọrun fun awọn ọmọde lati gbọran si OLUWA bi a ba ti kọ wọn lati maa gbọran si awọn obi ninu ile. A ni awọn apẹẹrẹ rere diẹ ninu Bibeli nipa awọn ọmọde ti igbesi-aye wọn jẹẹkọ: Isaaki, Josẹfu, Samuẹli, Timoteu ati awọn miran bẹẹ bẹẹ.

Awọn ọmọde gẹgẹ bi Apẹẹrẹ

A gba awọn ọmọde niyanju pe ki wọn ranti Ẹlẹda wọn ni igba ewe wọn. “Iṣe ọmọde papa li a fi imọọ, bi iwa rẹṣe rere ati titọ” (Owe 20:11).

Awọn ọmọde ni ipa ti wọn ninu Ihinrere, a si ni awọn apẹẹrẹ diẹ ti o yanilẹnu ti Oluwa ti lo lati sọ nipa Ọlọrun ati lati fi ayọ ati inudidun fun ẹlomiran. A ranti ẹrubinrin kekere kan ti o sọ fun olori-ogun Siria nì nipa bi o ti ṣe le ri iwosan gba ni ilẹ Israẹli. O wá, ki i si ṣe pe o ri iwosan gba nikan, ṣugbọn o ri igbala fun ọkàn rè̩ pẹlu.

Lẹhin naa, a tun ranti Samuẹli ọmọkunrin kekere ti iya rè̩ ti ya sọtọ lati fi gbogbo aye rè̩ fun iṣẹ-isin ni ile Ọlọrun. A maa ṣe iranṣẹ fun alufa ninu Tẹmpili, o si dagba, o di woli Ọlọrun tootọ, alagbayọri adura nla, ati ẹni ti n jere ọkàn.

A tun ranti ọmọkunrin kekere ni pẹlu, ẹni ti o yọọda ounjẹ rè̩ fun Jesu ki o le fi bọọpọlọpọ eniyan. Gbogbo apẹẹrẹ wọnyi yẹ ki o fun awọn ọmọde ni iṣiri lati maa gbọran si awọn obi wọn ati si Oluwa.

Ronu nipa awọn ọmọ kekere laarin ogunlọgọ eniyan ti wọn n ya imọ-ọpẹ sọna fun Jesu nigba ti o gun kẹtẹkẹtẹ wọ Jerusalẹmu. Gbọ ohun awọn ewe ti n kigbe: “Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun li ẹniti o mbọ wá li orukọ Oluwa!” (Matteu 21:9).

Loni a n reti ki Jesu tun pada wá. Bawo ni awọn ọmọ wọn ni yoo ti yọ pọ to, ti wọn yoo gbọ ohun ipe nitori igbe aye iwa mimọ ti wọn n gbe, wọn yoo si kigbe pe, “Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun li ẹniti o mbọ wa!”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Sọ awọn ẹsẹ Bibeli ti o fi han pe awọn ọmọde gbọdọ gbọran si awọn obi wọn lẹnu.

  2. 2 Sọ diẹ ninu awọn ayọrisi aigbọran awọn ọmọ si obi.

  3. 3 Ka ofin kinni pẹlu ileri.

  4. 4 Sọọ ni ọrọ ti rẹ awọn aṣẹ ti Mose fi fun awọn obi, ibiti o yẹ ati igba ti o yẹ lati maa fi ọrọỌlọrun kọ ni.

  5. 5 Ka awọn ọrọ ti Jesu sọ lati ori nipa wiwá awọn ọmọde si ọdọ Rè̩.

  6. 6 Darukọ awọn eniyan diẹ lati inu Bibeli ti wọn ṣe akoso ile wọn daradara.