Romu 12:1-21; II Peteru 1:5-11

Lesson 357 - Senior

Memory Verse
“Nitorina mo fi iyọnu Ọlọrun bè̩ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọāye, mimọ, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isin nyin ti o tọna” (Romu 12:1).
Cross References

I Irin Onigbagbọ Ninu Aye

1 Eniyan Ọlọrun gbọdọ kun fun iṣẹṣiṣe ti o li ere fun Ọlọrun, Romu 12:1, 11-13; Luku 19:12-27; Jakọbu 1:27

2 Igbesi-aye Onigbagbọ ní lati ba ti Kristi mu, ko gbọdọ fara we aṣa, ihuwasi, tabi ẹmi ti aye yi, Romu 12:2; Johannu 17:14; II Kọrinti 6:17, 18; 7:1; Ifihan 18:4

3 Ohun pataki ju lọ ti a n beere ninu igbesi-aye Onigbagbọ ni pe ki o mọ aipe rẹ ki o si maa ṣiṣẹ rè̩ gbogbo pẹlu igbona ọkan gẹgẹbi ipe rè̩, Romu 12:3-8; Owe 25:27; I Kọrinti 12:11-27; Efesu 4:1-13

4 Awọn iwa ti o maa n so igbesi-aye Onigbagbọ ro ni ifẹ ará, ifẹ inurere si eniyan gbogbo ati iṣoore, Romu 12:9, 10, 14-16; 13:9, 10; Matteu 22:37-40; I Kọrinti 13:1-13; II Peteru 1:5-11

5 Onigbagbọ ni lati maa fi ofin nla ti Ihinrere ṣe iwa hù, eyi ti Jesu Kristi ṣe apẹẹrẹ rè̩ ninu igbesi-aye Rè̩: “Maṣe jẹ ki buburu ṣẹgun rẹ, ṣugbọn fi rere ṣẹgun buburu,” Romu 12:17-21; Orin Dafidi 64:1-10; 94:1, 23; Matteu 5:38-48

Notes
ALAYE

Irin Onigbagbọ Ninu Aye

Kin ni igbesi-aye Onigbagbọ? Ni kukuru, itumọ rẹ ni wiwà laaye fun ogo Ọlọrun, ki a maa lo ara wa si ipa Kristi, ki a si jẹ iwe Rè̩ ti gbogbo eniyan mọ ti wọn si n kà. Awọn Onigbagbọ jẹ aṣoju Ijọba Ọlọrun, ikọ fun Kristi, nipasẹ awọn ẹni ti Ọlọrun n bè̩ gbogbo aye lati ba Oun laja nipa Kristi (Ka II Kọrinti 5:19, 20).

Awọn Onigbagbọ ni lati jẹ imọlẹ ninu aye (Filippi 2:15), ati apẹẹrẹ oore-ọfẹỌlọrun ti n yi ọkan pada. Bi a kò ba le dá awọn ti o jẹwọ titẹle Kristi mọ nipa igbesi-aye iwa mimọ wọn, ki a si mọ wọn fun iyara-ẹni-sọtọ wọn kuro ninu aye, yoo ṣoro ki wọn to le jẹ Onigbagbọ.

Iyara-ẹni-sọtọ kuro ninu aye jẹ ohun ti isin Kristi ati igbesi-aye Onigbagbọ n beere lọwọẹni. Ọkàn Onigbagbọ jẹ ti Oluwa, oun si jẹọmọ ibilẹ Ijọba Ọlọrun. Onigbagbọ wà ninu aye ṣugbọn ki i ṣe ti aye; oun jẹ alejo ati arin-rin-ajo ninu rè̩ (Ka I Kọrinti 5:9-11; Heberu 11:13).

Kin ni aye jẹ ti Onigbagbọ fi gbọdọ ya ara rè̩ kuro ninu rè̩? ỌrọỌlọrun tọka si gbogbo eto, gbogbo eniyan, gbogbo ẹmi ti o ba lodi tabi ti o tako ofin Ọlọrun ati Ihinrere Jesu Kristi gẹgẹ bi “aye.” Lati jẹ apakan aye tabi ki a wa ni iṣọkan pẹlu igbekalẹ ati eto rè̩, ni lati wà ni ọta si Ọlọrun. C. H. Spurgeon, iranṣẹỌlọrun pataki ni igba kan ri, sọ nipa aye pe: “Ninu eto rè̩ mẹsan ninu mẹwa ni o jẹ irọ, ọkan ti o kù jẹ imọ-ti-ara-ẹni-nikan; ati ọkan-ṣoṣo naa paapaa ni irọ ni isalẹ rè̩.” ỌrọỌlọrun sọ pe: “ẹnyin panṣaga ọkunrin, ati panṣaga obirin, ẹ kò mọ pe ibarẹ aiye iṣọta Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati di ọrẹ aiye di ọta Ọlọrun” (Jakọbu 4:4). Pe otitọ ni ọrọ yi han gbangba ninu akọsilẹỌlọrun: “Awọn ọba aiye dide, ati awọn ijoye kó ara wọn jọ si Oluwa, ati si Kristi rè̩” (Iṣe Awọn Apọsteli 4:26). AṣẹỌlọrun fun olukuluku ti yoo maa pe orukọ Kristi ni eyi: “Ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si ya ara nyin si ọtọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ kan ohun aimọ; emi o si gba nyin. Emi o si jẹ Baba fun nyin, ẹnyin o si jẹọmọkunrin mi ati ọmọbirin mi, li Oluwa Olodumare wi” (II Kọrinti 6:17, 18). Bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹsẹ Iwe Mimọ wọnni ní itumọ ti o yanju, sibẹọpọlọpọ ni o wà ninu aye ti n fẹ ní ojurere Ọlọrun ti wọn si tun n fẹ jẹọrẹ aye. Iru awọn eniyan bẹẹ nfẹ ojurere Ọlọrun ṣugbọn wọn kò le ru ẹgan Ihinrere tabi fi ara da iyà Agbelebu (Ka Galatia 5:11;Matteu 11:6; 13:21).

Ẹbọ Aaye

Ẹkọ pataki miran ti Ihinrere ati ti Isin Kristi ni pe ọmọ-lẹhin Jesu gbọdọ jọwọ gbogbo aye rè̩ fun isin ati ipèỌlọrun. Aṣayan ẹkọ wa sọ pe fifi aye wa bi ẹbọ aaye, mimọ ati itẹwọgba fun Ọlọrun ni iṣẹ-isin wa ti o tọna.

Kristi ni olori ifẹọkan ati alagbara lori igbesi-aye Onigbagbọ. Bi o tilẹ jẹ pe ohun pupọ ati awọn eniyan ni o le ni ipá lori igbesi-aye eniyan, ati awọn Onigbagbọ pẹlu, sibẹ bi Kristi ati Ijọba Ọlọrun kì i ba ṣe koko ohun ti o n ṣe akoso igbesi-aye eniyan kan, iru ẹni bẹẹ ki i ṣe Onigbagbọ. Gẹgẹ bi oorun ti duro ti aye si n yi i po, ti o si n gba ooru ti o n mu è̩da wa laaye ati imọlẹ lati inu “ina ileru” rè̩, bẹẹ gẹgẹ ni igbesi-aye Onigbagbọ ni lati maa yi Kristi po, ki o si maa gba agbara ti ẹmi ati imọlẹ lati ọdọ Rè̩.

Ọlọrun n fẹ ki ọwọ awọn eniyan Oun dí fun iṣẹ Rè̩. Ọwọ awọn eniyan aye dí pupọ ni wiwa erè ti ara wọn, lilepa opin rere fun ara wọn, wọn wa laaye fun ara wọn, ati fun anfaani ti ara wọn. Onigbagba wà laaye fun Kristi. O n wa itẹsiwaju ohun ti i ṣe ti Kristi dipo ti ara rè̩, o si jẹ alabaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun, ki i ṣe ohun igba isinsinyi nikan ni o n lepa bi ko ṣe pe fun ayeraye pẹlu! (Wo I Kọrinti 3:9). Bi ko ṣe pe eniyan ba wa laaye fun Oluwa, yoo jẹbi ayeraye yoo si di ẹni itanu. Lati ri talẹnti ẹni mọlẹ ni lati ṣe bi awọn eniyan aye ti n ṣe, awọn ti kò wa ohun ti Ọrun ti wọn si n fi t’ori t’ọrun wọn wá nkan aye (Ka Matteu 25:14-30).

Yiyipada

“Ẹ ma si da ara nyin pọ mọ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin.” Iyè jẹ ilẹkun sinu ọkan; a ko si le sọọ ju bi o ti ṣe pataki to pe ki awọn Onigbagbọ fi ero wọn sọdọ Kristi ati si ipa ti Ijọba Rè̩, ki wọṅ má si maa rò nipa aye ati ohun ti n bẹ ninu aye. Aye ti jinna si Ọlọrun to bẹẹ gẹ ti o fi jẹ pe gbogbo ọna ti eniyan mọ ni o fi n polowo è̩ṣẹ ati ohun gbogbo ti n sun ni da è̩ṣẹ. Pupọ ninu ọna idaraya ti awọn eniyan ti da silẹ ni o lumọẹṣẹ, ni o yatọ si ti ẹda, ti o si mu iwa ibajẹ lọwọ pẹlu. O jẹ ohun ti n pa ọkan run nitori pe o maa n sun eniyan dẹṣẹ.

Onigbagbọ tootọ kò ni ifẹ tabi akoko fun ohun gbogbo ti a n fi è̩tan pe ni igbadun. Ẹrọ tẹlifiṣọn jẹọkan ninu awọn ohun titun ti awọn eniyan ṣẹṣẹṣe; ti awọn eniyan ti kò nilaari ti sọ di ibajẹ to bẹẹ ti o fi jẹ pe ọkan ni ninu awọn ohun ti o lewu ju lọ fun igbesi-aye Onigbagbọ ti awọn ọdọ dojukọ loni. Awọn ile-iṣẹọti ati taba jẹ onigbọwọ meji pataki fun tẹlifiṣọn wíwò, owo gọbọi ni won si n ná lọdọọdun lati maa polowo ọja wọn. Njẹẹnikẹni tun ṣẹṣẹ le maa wadi pe “Njẹ Onigbagbọ le mu taba tabi ọti?”

Irẹlẹ

Igberaga -- wíwa ti ara ẹni, gbigbe ara ẹni ga – ni i ṣe gbongbo ohun ti o fa iṣubu Satani, ati ti ailonka ọmọ-eniyan lati igba naa. Idakeji ilepa ti ara bẹẹ ni irẹlẹ. A ko le ya irẹlẹ nipa kuro ninu Ihinrere Jesu Kristi. Ori ẹkọ naa ka pe: “Njẹ mo wi fun olukuluku enia ti o wa ninu nyin, nipa ore-ọfẹ ti a fifun mi, ki o maṣe rò ara rẹ ju bi o ti yẹ ni riro lọ; ṣugbọn ki o le rò niwọntunwọnsi, bi Ọlọrun ti fi iwọn igbagbọ fun olukuluku.” Siwaju si i, “niti ọlá, ẹ mā fi ẹnikeji nyin ṣāju.”

Onigbagbọ maa n fẹ lati dabi Oluwa rè̩. O maa n fẹ ki igbesi-aye oun fi ara pamọ sẹhin Agbelebu Kristi, pe ki ẹwa Jesu le maa tan jade. Ọlọrun sọ pe “Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi Jesu: Ẹniti o tilẹ jẹ aworan Ọlọrun, ti kò ka a si iwọra lati ba Ọlọrun dọgba: S̩ugbọn o bọ ogo rẹ silẹ, o si mu awọ iranṣẹ, a si ṣe e ni aworan enia. Nigbati a si ti ri i ni iri enia, o rè̩ ara rẹ silẹ, o si tẹriba titi di oju iku, ani iku ori agbelebu” (Filippi 2:5-8). Ọpọ eniyan ni o wa ti wọn n wi pe ko ṣe e ṣe fun eniyan lati gbe igbesi-aye ti a le fi we ti Kristi. Awọn oniyemeji ati awọn alahesọ le sọ ohunkohun ti wọn ba fẹ, ṣugbọn Jesu fi apẹẹrẹ lelẹ fun gbogbo eniyan lati tẹle. O di ara O si n ba wa gbe, awọn eniyan nipa oore-ọfẹỌlọrun, le gbe igbesi-aye mimọ, ailẹṣẹ, ti o si wùỌlọrun.

Siso Eso

Idalare a maa kan “ogbologbo ọkunrin nì” mọ agbelebu Kristi. (Wo Romu 6:1-7). Isọdimimọ a maa pa “ogbologbo ọkunrin naa” kú patapata; a tu gbongbo ẹṣẹ kuro, iwa mimọ a si kun igbesi-aye Onigbagbọ naa (Wo Luku 1:74, 75; Efesu 5:27). Nigba ti a ba si gba agbara Ẹmi Mimọ ati ina, Ẹni Ikẹta ninu Ọlọrun Mẹtalọkan yoo bẹrẹ si i tọ ni “sinu otitọ gbogbo,” agbara itọni ati iṣamọna yi ni igbesi-aye eniyan yoo jẹ ki Onigbagbọ naa le so eso pupọ (Wo Johannu 16:13; 15:8).

Kristi ni Ajara tootọ; awọn Onigbagbọ si ni ẹka. Iru eso ti Ajara n so ni awọn ẹka paapaa n so. Nitori naa ni awọn Onigbagbọṣe n so iru eso kan naa ati ṣe iru iṣẹ rere kan naa niwaju awọn eniyan gẹgẹ bi Jesu Kristi ti ṣe (Ka Johannu 14:12; 15:1-8).

Igi kekere eleso yoo bẹrẹ si i so eso ni iwọnba ti rẹ lati kekere. Bi o ti wu ki eso naa le kere to, eso ti o n so dara gẹgẹ bi yoo ti maa ri titi. Bi ọdun ti n yi lu ọdun, ti igi naa si n dagba, bẹẹ ni yoo maa so eso pupọ si i, ṣugbọn eso naa yoo jẹ iru kan naa ti o ti n so lati ibẹrẹ. Ninu bi eso naa ti pọ to ni iyatọ gbe wa -- ṣugbọn ko si iyatọ ninu iru eso ti o n so tabi didara rè̩. Bẹẹ gẹgẹ ni igbesi-aye Onigbagbọṣe bẹrẹ. O bẹrẹ si i so eso ni iwọnba kekere nipa ti ẹmi, ṣugbọn eso ti ẹmi ni o n so. Bi Onigbagbọ ti n dagba si i ninu oore-ọfẹ ati imọ Oluwa Jesu Kristi, wọn a maa so ọpọlọpọ eso ti Ẹmi Ọlọrun, ṣugbọn iru eso kan naa ni i ṣe; kiki pe eso naa pọju ti atẹhinwa ni. A ṣe alaye didagba ninu oore-ọfẹ lọna ti o dara ninu ẹkọ wa: “Ati nitori eyi naa papa, ẹ māṣe aisimi gbogbo, ẹ fi iwa rere kun igbagbọ, ati imọ kun iwa rere; ati airekọja kún imọ, ati sru kun airekọja; ati iwabi-Ọlọrun kun sru; ati ifẹ omọnikeji kún iwabi-Ọlọrun; ati ifẹni kun ifẹọmọnikeji. Nitori bi ẹnyin ba ni nkan wọnyi ti nwọn ba si pọ, nwọn ki yio jẹ ki ẹṣe ọlẹ tabi alaileso ninu ìmọ Oluwa wa Jesu Kristi.”

A le sọ pe titi lọ ni Onigbagbọ maa n fi iwa rere ati ẹwa ti n bẹ ninu Oluwa wa Jesu Kristi kún igbesi-aye rè̩. Bi Onigbagbọ ti jẹẹka lara Ajara Tootọ, o n gba oje, ti i ṣe iwà mimọ, ti i ṣe orisun iye fun ọkan, bẹẹ ni o n fi awọn oore-ọfẹ Kristi kun igbesi-aye rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Kin ni koko iṣẹ Onigbagbọ?

  2. 2 Eeṣe ti Onigbagbọ ko fi gbọdọ ni idapọ pẹlu aye?

  3. 3 Tumọ ohun ti Bibeli pe ni “aye”?

  4. 4 Bawo ni eniyan ṣe le mọ awọn Onigbagbọ yatọ si awọn eniyan aye?

  5. 5 Eeṣe ti ko fi tọna fun Onigbagbọ lati ni ipa ninu pupọ ninu ere idaraya aye?

  6. 6 Darukọ diẹ ninu iwa rere igbesi-aye Onigbagbọ.

  7. 7 Kin ni itumọẹsẹ Iwe Mimọ ti o wi pe Kristi ni Ajara ati awọn Onigbagbọ ni ẹka?

  8. 8 S̩e apejuwe bi awọn Onigbagbọṣe le maa so eso si i ninu igbesi-aye wọn.