I Timoteu 6:1, 2; Efesu 6:5-9; Romu 13:1-8

Lesson 358 - Senior

Memory Verse
“Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mā fi tọkantọkan ṣe e, gẹgẹ bi fun OLUWA, ki si iṣe fun enia” (Kolosse 3:23).
Cross References

I Ojuṣe Awọn Oṣiṣẹ si Awọn Ọga wọn

1 Wọn ni lati bu ọla fun awọn ti o gba wọn si iṣẹ, I Timoteu 6:1, 2; Kolosse 3:22; Titu 2:9, 10; I Peteru 2:18

2 Wọn ni lati ṣe iṣẹ wọn gẹgẹ bi fun Oluwa, Efesu 6:5-8; Kolosse 3:23

II Imọran fun Awọn Agbanisiṣẹ

1 Wọn ni lati fi ọwọ ba awọn oṣiṣẹ wọn lo, Efesu 6:9

2 Wọn ni lati san iye owo ti o tọ fun wọn, Kolosse 4:1; Jakọbu 5:4

III Iha ti Onigbagbọ Gbọdọ kọ si Ofin

1 “Awọn alaṣẹ ti o si wa, lati ọdọỌlọrun li a ti lana rẹ wa,” Romu 13:1, 2; Owe 8:15; Daniẹli 4:32

2 Awọn ti o ba ṣe rere ko le bẹru idajọ ofin, Romu 13:3, 4

3 Awọn Onigbagbọ ni lati gbọran si ofin, Romu 13:5-7; I Peteru 2:13, 14; Marku 12:17

Notes
ALAYE

A Dan Isin Kristi Wò

Nigba miran a le pin ofin Ọlọrun si ipa meji – eyi ti o jẹ iṣẹ wa si Ọlọrun ati eyi ti i ṣe iṣẹ wa si ọmọnikeji wa. A ko le sin Ọlọrun lai naani ọmọnikeji wa – aladugbo wa, ọmọ-ọdọ wa, ọga wa.

OrukọỌlọrun, ati ẹkọ Rẹ a maa jẹ ayinlogo nipa iwa awọn ọmọlẹhin Rè̩ tootọ. Aye a maa tete ri apẹẹrẹ kánkán ju fifi ilana ẹkọ lelẹ lọ. “Ẹnyin ni iwe wa, ti a ti kọ si wa li ọkan, ti gbogbo enia ti mọ, ti nwọn si ti ka” (II Kọrinti 3:2). A maa n sọẹkọỌrọỌlọrun di titobi nipa awọn ti n gbe igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn a maa n sọ blasfeme si I nitori ti awọn ti wọn n pe orukọ Rè̩, ṣugbọn ti wọn ko gbe igbesi-aye wọn gẹgẹ bi Ọrọ Rè̩. Nigba miran a maa n sọ nipa eniyan pe “Onigbagbọ tootọ ni o n lọ nì.” Bẹẹ ni a si maa n gbọ nipa ẹlomiran pe, “Bi o ba ṣe pe isin Kristi ni eyi, emi ko ni nkankan fi ṣe.”

O fẹrẹ jẹ pe ko si ibi ti a tun le ṣe akiyesi ẹsin igbagbọ ju ninu iwa Onigbagbọ lẹnu iṣẹ rè̩. Awọn alabojuto eto-iṣẹ ti lọ jinna ni ṣiṣe atunṣe anfaani eto-iṣẹ fun awọn oṣiṣẹṣugbọn ni igba pupọ ni wọn ti ṣe alainaani eto ilana Igbagbọ ki wọn ba le ṣe ohun ti wọn n fẹ. Onigbagbọ ti o n ṣiṣẹ ni lati kiyesara ki o máṣe afarawe iṣe aiwa-bi-Ọlọrun awọn ẹlẹṣẹ ninu iṣesi rẹ si awọn ti o gba a si iṣẹ.

“Ki gbogbo awọn ti iṣe ẹru labẹ iru mā ka awọn oluwa ti o ni wọn yẹ si ọla gbogbo, ki a má ba sọrọ odi si orukọỌlọrun ati ẹkọ rẹ” (I Timoteu 6;1). Ikilọ yi wa fun awọn ti a gba si iṣẹ lọjọ oni gẹgẹ bi o ti wa fun ẹru ti akoko Paulu. Bawo ni eniyan ṣe le ka ọga rẹ yẹ si ọla ti ko si ni mura lati tẹọga naa lọrun? “Gba awọn ọmọ-ọdọ niyanju lati māṣe ohun ti o wu wọn ninu ohun gbogbo; ki nwọn ki o má gbó wọn lohun” (Titu 2:9). Ọlọrun n fẹ ki awọn ọmọ-ọdọ maa tẹriba fun awọn ọga wọn. “Ẹnyin ọmọ-ọdọẹ mā tẹriba fun awọn oluwa nyin pẹlu ibẹru gbogbo; ki iṣe fun awọn ẹnirere ati oniwa tutu nikan, ṣugbọn fun awọn onrorò pẹlu” (I Peteru 2:18). Eyi jẹ ki a mọ pe a ko gbọdọ má tẹọga ibiṣẹ wa lọrun nitori pe o jẹẹlẹṣẹ tabi eniyan buburu; a kan an nipa fun wa lati tẹriba fun awọn ọga onikanra pẹlu. Eyi nì ni pe fun awọn ti ki i gbọ alaye tabi amọran, fun awọn ti i maa mọọmọṣe ibi ati agidi.

Niwọn igba ti a ko ba palaṣẹ fun wa lati ṣe ibi, a gbọdọ fun ọga ibi iṣẹ wa ni igbọran pipe. “Ki nwọn ki o má gbo wọn lohun” ni pe ki a maṣe jà wọn niyan bi ko ṣe ki a gba aṣẹ awọn olori wa.

Iṣẹ ti a S̩e fun Kristi

Onigbagbọ ti n ṣiṣẹ ni lati ṣe iṣẹ oojọ rẹ gẹgẹ bi “si Kristi; ki iṣe ti arojuṣe bi awọn ti nwu enia; ṣugbọn gẹgẹ bi awọn ẹrú Kristi, ẹ māṣe ifẹỌlọrun lati inu wa; ẹ mā fi inurere sin bi si Oluwa, ki si iṣe si enia: (Efesu 6:5-7). “Arojuṣe” jẹọrọ ti o ṣe apejuwe daradara ọna ti awọn ẹlomiran n gba ṣe iṣẹ. Wọn maa n ṣọra gidigidi lati ri i pe wọn da ọwọ le iṣẹ kan lati ṣe nigba ti alabojuto iṣẹ ba wa ni tosi, ṣugbọn gẹrẹ ti alabojuto iṣẹ naa ba ti lọ wọn a dẹọwọ iṣẹ wọn, wọn a bẹrẹsi isinmi, wọn a si maa fi akoko wọn ṣofo. Nigba ti alabojuto iṣẹ ba tun pada bọ, lẹsẹ kan naa wọn a si tun bẹrẹ si maa lọ firifiri. Awọn ẹlomiran ti ko jẹ ronu ati jale rara a maa fi akoko eyi ti oniṣẹ ti sanwo rẹ fun wọn ṣofo.

“Arojuṣe” tun ṣe apejuwe iru awọn ti i maa ṣiṣẹ ki awọn eniyan ba le ri wọn, awọn ti wọn n wa iyin eniyan ti wọn ko si ṣe iṣẹ wọn gẹgẹ bi fun Oluwa.

Itara ṣe Dandan

“Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mā fi tọkantọkan ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa, ki si iṣe fun enia” (Kolosse 3:23). Njẹ o ti i ni in lọkan ri lati ṣe inurere pataki fun eniyan kan ti iṣẹ rẹ wu ọ lori ti o si bu ọla fun? Njẹ ki yoo gba pe ki o ṣọra ki o si ṣe aapọn? Ẹ jẹ ki a gbagbe ẹni ti a n ṣiṣẹ fun; ẹ jẹ ki a mu ọkan kuro lara rè̩; dipo rè̩, jẹ ki a wo Kristi lori aga gẹgẹ bi ọga iṣẹ. Ẹni naa ti awa n ṣiṣẹ fun jẹẸni ti o fi Itẹ Rè̩ silẹ ni Ọrun ti O si fi ẹmi Rè̩ fun wa. Gẹgẹ bi Onigbagbọ, Oun ni a n ṣiṣẹ fun nisinsinyi. Boya iṣẹ wa ni lati kan iṣo mọgi, tita ọja fun awọn onibara ni ile itaja, akọwe ni ile-iṣẹ tabi gbigbẹ koto oju titi, Oluwa ni a n ṣiṣẹ fun. “Fi tọkantọkan ṣe e,” fun Un.

Njẹ o n ro pe a ko san owo ti o tọ fun ọ, tabi a ko mọ riri iṣẹ rẹ? Ranti pe “Ohun rere kohunrere ti olukuluku ba ṣe on na ni yio si gba pada lọdọ Oluwa” (Efesu 6:8). Boya asanwo-oṣiṣẹ miran ni o n wo; bi o ba n ṣiṣẹ fun Johannu o ko gbọdọ reti pe ki Billi wa sanwo fun ọ. Bi o ba n ṣe iṣẹ fun Oluwa, Oun ni ki o maa wo fun ère.

“Awọn ti o si ni oluwa onigbagbọ, ki nwọn maṣe gan wọn nitori arakunrin ni nwọn; ṣugbọn ki nwọn tubọ mā sin wọn” (I Timoeu 6:2). Onigbagbọ ko gbọdọ jẹ anfaani ijẹkujẹ nitori pe oun n ṣiṣẹ fun Onigbagbọ bi oun. Arakunrin naa ki yoo fi ọwọ lile tabi agbara mu ni bi ẹlẹṣẹ ti le ṣe; ṣugbọn sibẹsibẹ oṣiṣẹ paapaa gbọdọ fẹ lati ṣe iṣẹ oju-owo ọjọ kọọkan fun Onigbagbọ gẹge bi oun yoo ti ṣe fun ẹlẹṣẹ ti o le, ti o si maa n bere pupọ lọwọ rè̩.

Idọgba niwaju Ọlọrun

Fun awọn ọga ni Bibeli sọ pe: “Oluwa ẹnyin tikara nyin si mbẹ li ọrun” (Efesu 6:9). Awọn gbolohun ọrọ yi jẹ ki ọga iṣẹ mọ pe oun ati oṣiṣẹ oun jẹ iranṣẹ niwaju Ọlọrun. Ko si ojusaju eniyan lọdọ Rè̩. O n fẹ ki ọga ṣe olootọ gẹgẹ bi O ṣe n fẹ ki iranṣẹṣe pẹlu. “Ẹnyin oluwa, ẹ mā fi eyiti o tọ, ti o si dọgba fun awọn ọmọ-ọdọ nyin; ki ẹ si mọ pe ẹnyin pẹlu ni Oluwa kan li ọrun” (Kolosse 4:1). Ọlọrun, Ẹni ti o gbọ igbe awọn ọmọ Heberu ẹrú ti o si gba wọn kuro ni oko-ẹru Egipti ṣi n gbọ igbe awọn ti a n ni lara. “Kiyesi i, ọya awọn alagbaṣe ti nwọn ti ṣe ikore oko yin, eyiti ẹ ko san nke rara, ati igbe awọn ti o ṣe ikore si ti wọ inu eti Oluwa awọn ọmọ ogun” (Jakọbu 5:4). Ọlọrun n beere lọwọ awọn ọga iṣẹ lati san owo-ọya ti o tọ ki wọn si lo oṣisẹ wọn daradara, “laisi idayafoni,” eyi ni pe ki i ṣe fun ọga ibi iṣẹ lati maa yọ paṣan le awọn oṣiṣẹ nitori pe wọn n bẹ labẹ agbara rẹ.

Itẹriba fun Ofin

“Ọlọrun ki iṣe Ọlọrun ohun rudurudu, ṣugbọn ti alafia” (I Kọrinti 14:33). Fun ẹri, ẹ jẹ ki a wo ayika wa ki a si kiyesi iṣedeedee iṣẹọwọỌlọrun – oorun, oṣupa ati awọn irawọ, gẹgẹ bi apẹẹrẹ -- ki a si ri eto ohun gbogbo ti Ọlọrun I ṣe Olupilẹṣẹ rè̩. Ki o ba le ṣe e ṣe fun awọn eniyan lati gbe pọ ni alaafia, o ṣe dandan ki a ni ofin tabi ofin iṣakoso ìwà. Ọlọrun ni o fi eto naa lelẹ bẹẹ, o si fi Ofin Rè̩ fun Mose ki Israẹli ba le mọ bi wọn yoo ti ṣe akoso ara wọn ni Ilẹ Ileri. Titi di oni-oloni ni a si n yẹ ofin yi si gẹgẹ bi ipilẹ ofin ilẹ wa.

“Awọn alaṣẹ ti o si wa lati ọdọỌlọrun li a ti lana rẹ wa” (Romu 13:1). Ofin ti awọn eniyan n ṣe fun akoso ati iwa yiyẹ jẹ didun inu Ọlọrun. Bi awa ba n pa wọn mọ ko si idi ti a fi ni lati bẹru ofin. Bi a ba kọ lati pa ofin naa mọ, ki i ṣe awọn alaṣẹ nikan ni a ni i bẹru, ṣugbọn a ni i bẹru ẹri-ọkan wa ati Ọlọrun pẹlu. Ko buyi kun Onigbagbọ lati ṣa ofin tì, i baa jẹ mọ ofin irinna fun aabo wa tabi ilana nipa iṣẹ ti a n ṣe. “Ẹnyin ko gbọdọṣaima tẹriba, ki iṣe nitori ti ibinu nikan, ṣugbọn nitori ẹri-ọkan pẹlu” (Romu 13:5).

Nigba miran ofin miran maa n wọ iwe ofin ilẹ wa ti o tako ofin ti Ọlọrun. Iru awọn ofin bẹẹ ki i ṣe ofin tootọ, awọn Onigbagbọ gbọdọ sa gbogbo agbara wọn lati má jẹ ki iru ofin bẹẹ fi ẹsẹ mulẹ. Daniẹli ni idojukọ ofin kan ti o sọ pe ko gbọdọ gbadura, ṣugbọn o gbadura. Peteru sọ fun awọn alaṣẹ pe, “Awa ko gbọdọ má gbọ ti Ọlọrun ju ti enia lọ.” (Iṣe Awọn Apọsteli 5:29). Awọn Onigbagbọ gbọdọṣaapọn lati dibo ati ki wọn gbe ohun wọn soke lodi si awọn ofin ti kò tọna ati ofin ti o n fi idi iwa buburu bi ọti mimu ati tẹtẹ tita mulẹ. Bi awọn ofin wa ba jẹ eyi ti o tọna, gbogbo eniyan ti o mọẹtọ ni yoo maa bu ọla fun ofin wa, bẹẹ ni wọn yoo si maa san ohun “ti o tọ fun ẹni gbogbo: owo-ode fun ẹniti owo-ode iṣe tirẹ: owo-bode fun ẹniti owo-bode iṣe tirẹ, è̩ru fun ẹniti è̩ru iṣe tirẹ, ọla fun ẹniti ọla iṣe tirè̩” (Romu 13:7).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Sọọna diẹ ti a gba n sọrọ odi si ẹkọỌlọrun.

  2. 2 Kin ni awọn nkan wọnni ti oṣiṣẹ gbọdọ maa ranti nipa iwa rè̩ nibi iṣẹ?

  3. 3 Bi o ba gba iṣẹ rẹ si eyi ti o n ṣe fun Ọlọrun, bawo ni o ṣe ni lati ṣe e?

  4. 4 Kin ni aṣẹ ti a pa fun awọn ti o ni ọga Onigbagbọ?

  5. 5 Darukọ nkan meji ti Ọlọrun beere lọwọọga ti o gba eniyan si iṣẹ.

  6. 6 Iha wo ni Ọlọrun kọ si awọn alaṣẹ ati ofin ilu?

  7. 7 Sọ idi meji ti Onigbagbọ gbọdọ fi gbọran si ofin ilu.

  8. 8 Darukọ eniyan Ọlọrun kan ti o ṣaigbọran si ofin ti ko tọna kan, ki o si sọ idi ti o fi ṣe bẹẹ.