Lesson 359 - Senior
Memory Verse
“Ninu ọrọ pipọ, a kò le ifẹè̩ṣẹ kù: ṣugbọn ẹniti o fi ète mọète li o gbọn” (Owe 10:19).Cross References
I Orisun Kikoro
1 Ahọn eniyan ti a kòṣe akoso rẹ jẹ ohun ti o buru lọpọlọpọ, Jakọbu 1:26; 3:1-6; Orin Dafidi 140:3;Romu 3:13
2 Oniruuru ọrọ buburu gbogbo ni ỌrọỌlọrun da lẹjọ, Jakọbu 3:7-12, 14-16
Isọro-ẹni-lẹhin, Orin Dafidi 15:1-3; 50:19-23; 101:5; Jeremiah 9:3-5, 8; Romu 1:30; II Kọrinti 12:20
(b) Ọrọ asan, Jobu 11:2; 15:3; Owe 29:11; Oniwasu 5:3; 10:12-14; Titu 1:10
(d) Ofofo, Lefitiku 19:16; Owe 17:9; 18:8; 20:19; 26:20; Romu 1:29
(e) Ifunnu, Jakọbu 3:5; Owe 27:1, 2; Matteu 6:2; Romu 1:30; II Timoteu 3:2
3 Ọlọrun yoo pa awọn ti o n sọrọ buburu run, yoo si yi ètekéte wọn sori ara wọn, II Peteru 2:10-12;Juda 8-10, 14-16; }
II Orisun Didun
1 Lati oke Ọrun wa ni gbogbo ọrọ Onigbagbọ, wọn a si maa gbe eniyan ro, Jakọbu 3:13, 17, 18; Orin Dafidi 15:3; Owe 31:26; Efesu 4:29; Kolosse 4:6; Titu 2:8; 3:2; I Peteru 3:10, 11; Ifihan 14:5
Notes
ALAYEA Da Isọrọ-Buburu Lẹbi
“Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin ti iṣe enia buburu yio ti ṣe le sọrọ rere? nitori ninu ọpọlọpọ ohun in li ẹnu isọ. Enia rere lati inu iṣura rere ọkan rè̩ ni imu ohun rere jade wa: ati enia buburu lati inu iṣura buburu ni imu ohun buburu jade wa: S̩ugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọrọ were ti enia nsọ, nwọn o jihin rè̩ li ọjọ idajọ. Nitori nipa ọrọ rẹ li a o fi da ọ lare, nipa ọrọ rẹ lia o si fi da ọ lẹbi” (Matteu 12:34-37).
Pẹlu iru gbolohun ọrọ bayi ni ỌrọỌlọrun da gbogbo isọkusọ lẹbi lai da eyikeyi si. Gẹgẹ bi odò ti n ṣàn ni ahọn ọkàn ti a ko tunbi n tu è̩ṣẹ da sinu aye. Otitọọrọ gidi ni pe, gbogbo ọrọẹnu wa lati ọjọ de ọjọ yoo pada wa da wa lare tabi da wa lẹbi titi ayeraye niwaju Ọlọrun! (Ka Juda 8, 10, 14-16).
Iru awọn esẹ Iwe Mimọ bawọnyi kọ wa pe isọrọ-buburu maa n rin pọ pẹlu iṣọtẹ si Ọlọrun ati eto iṣakoso Rè̩. Siwaju si i, gbogbo awọn ti o ba n sọrọ buburu ni yoo gba iru idajọ gbigbona kan naa ti a ṣe fun awọn ọlọtẹ si Ijọba Ọlọrun. Bi Ọlọrun ko ba gba awọn angẹli layè lati sun Satani, olori ọta eniyan lẹsun pẹlu ẹgan, wo o nigba naa bi eniyan ṣe gbọdọ kiyesara gidigidi ki won máṣe yara sọrọ tabi lati maa sọrọ buburu si ẹnikẹni tabi nipa ẹnikẹni.
Ni titẹle ẹkọỌrọỌlọrun, Paulu tọrọ aforiji lọwọ olori alufa ẹni ti oun ko tilẹ mọ pe olori alufa ni I ṣe, bi o tilẹ dabi ẹni pe o ni ẹtọ lati sọrọ nipa rè̩ bẹẹ. (Ka Iṣe Awọn Apọsteli 23:2-5; Ẹksodu 22:28; Oniwasu 10:20).
Ahọn Oloro
Ọkan ninu awọn ohun ija eṣu ti o muna ju lọ ni sisọ isọkusọ nipa ẹlomiran. Satani ni “olufisun” awọn arakunrin (Ifihan 12:10); eṣu ni o n ti ẹnikẹni nigba ti o ba n tẹnu mọ awọn ohun buburu nipa ẹlomiran bi o tilẹ jẹ pe otitọ ni wọn I ṣe.
Iṣẹ ti Onigbagbọ yatọ si wi pe ki o maa ro aṣiṣe arakunrin kan kaakiri; tabi è̩ṣẹ rè̩ paapaa, bi o ba tilẹṣe pe o ti dẹṣẹ. ỌrọỌlọrun sọ wi pe: “Ara, bi a tilẹ mu enia ninu iṣubu kan, ki ẹnyin ti iṣe ti ẹmi ki o mu iru ẹni bẹ bọ sipo ni iwa tutu; ki iwọ tikararẹ mā kiyesara, ki a má ba dan iwọ na wo pẹlu. Ẹ mā ru ẹru ọmọnikeji nyin, ki ẹ si fi bḝ mu ofin Kristi ṣẹ” (Galatia 6:1, 2). Ko ṣe e ṣe ki eniyan ṣi iru gbolohun ọrọ yi tumọ ki o si pe e ni aṣẹ fun ẹnikẹni lati maa ṣofófó tabi sọrọ isọkusọ nipa aiṣedeedee tabi è̩ṣẹẹlomiran. Iṣẹ eṣu ni lati pa ọkan eniyan run; lati maa sọrọ nipa igbesi-aye awọn eniyan ti ko le gbeniro, ti ko si jẹ fun ogo Ọlọrun, eyi jẹ riran iṣẹ eṣu lọwọ.
“Ẹniti nṣofofo fi ọran ipamọ han; ṣugbọn ẹniti nṣe olotọ-ọkan a pa ọrọ na mọ” (Owe 11:13). Siwaju si i,”Alayidayida enia da ija silẹ: asọrọkẹlẹ ya awọn ọrẹ ni ipa” (Owe 16:28). Awọn wọnyi jẹ diẹ ninu ẹsẹỌrọỌlọrun ti a le tọka si nipa fifi arakan sọrọ buburu nipa eniyan. Abajọ ti Jakọbu nipa imisi Ẹmi Mimọ fi tẹnu mọ otitọ ni, pẹ, “Ina si ni ahọn, aiye ẹṣẹ si ni: li arin awọn ẹya ara wa li ahọn ti mba gbogbo ara jẹ ti o si ntinabọ ipa aiye wa; ọrun apadi si ntinabọ on na” (Jakọbu 3:6).
Ifunnu
Ifunnu paapaa jẹ ohun buburu kan ninu ahọn eniyan ti a le fi si aye kan naa pẹlu ọrọ asan, iṣofofo ati isọrọ-ẹni-lẹhin. Bibeli sọ pe: “Ẹniti nsọ ti ara rè̩ nwa ogo ara rè̩: ṣugbọn ẹniti nwa ogo ẹniti o ran a on li olotọ, ko si si aiṣododo ninu rẹ” (Johannu 7:18). Igberaga jẹẹṣẹ ti i maa tabuku fun eniyan, iyin-ara-ẹni jẹ eso igberaga. Eredi yiyìn ara ẹni ko ju wi pe ki awọn eniyan le fi oju ẹni nla wo ni, lati gbe ni ga ati lati fun ni ni ipo ọla. Ni ọpọlọpọ igba ni a n ri i pe awọn afunnu ki i ni ohun ti wọn n pariwo rè̩ pe awọn ni, idi rè̩ ti wọn si fi n funnu ni yi. Ninu ijagun Onigbagbọ, ifunnu kan wa ti o tọ ti o si yẹ. Onipsalmu sọ pe, “Ọkan mi yio ma ṣogo rè̩ nitit OLUWA: awọn onirẹlẹ yio gbọ, inu wọn yio si mā dun” (Orin Dafidi 34:2). Onigbagbọ le ṣogo pupọ nipa Olurapada rè̩ Nla, ati nipa iṣẹ agbara Rè̩ nla si awọn ọmọ eniyan. S̩ugbọn ifunnu nipa ti ara, ẹṣẹ ni!
Orukọ OLUWA
Aabo wa fun Onigbagbọ lati bọ ninu iwa aile-fi-ete-mọ-ete. Ọlọrun ti ṣe ileri lati da awọn eniyan Rẹ lare kuro ninu gbogbo è̩sun eke ti eṣu le fi wọn sùn. ỌrọỌlọrun sọ bayi pe: “Orukọ OLUWA, ile-iṣọ agbara ni, olododo sa wọ inu rẹ, o si la” (Owe 18:10). Olododo le sa lọ sọdọỌlọrun, aabo Rè̩, yoo si pa wọn mọ kuro ninu wahala gbogbo, ati ti ibajẹ ahọn è̩tan.
Kika Orin Dafidi ori ikẹrinlelọgọta kọ wa lẹkọ nipa ète awọn eniyan buburu ati iṣẹgun Ọlọrun lori wọn. “Ẹniti npọn ahọn wọn bi ẹnipe ida, ti nwọn si fa ọrun wọn le lati tafa wọn, an ọrọ kikoro: ki nwọn ki o le mā tafa ni ikọkọ si awon ti o pe: lojiji ni nwọn tafa si i, nwọn ko si bẹru”. Kin ni aabo awọn olododo ni iru akoko bayi? “S̩ugbọn Ọlọrun yio tafa si wọn (awọn eniyan buburu) lojiji: nwọn o si gbọgbẹ. Bẹni ahọn wọn yio mu wọn ṣubu lu ara wọn: gbogbo ẹniti o ri wọn yio mi ori wọn” (Orin Dafidi 64:7, 8).
Hamani, ẹni ti o ri ojurere ọba, ṣe ilara Mọrdekai, o si ro ninu ọkàn rè̩ lati ṣe e ni ibi. O fi ọgbọn ẹwẹṣe eto igbega fun ara rè̩, ati iparun fun Mordekai. Oluwa sọ imọ rè̩ di asan, ohun naa gan an ti o ti gberò lati ṣe si Mọrdekai si pada sori oun tikara rè̩. Ọla ti oun ti pinnu fun ara rẹ pada di ti Mọrdekai (Wo Ẹsteri 7:10). Bayi ni Ọlọrun maa n mu ahọn awọn eniyan buburu pada sori ara awọn tikara wọn ti O si maa n fi iwa ika wọn pa wọn run.
Laarin iran ti o ti kọja, o ti jẹ ohun iṣogo fun awọn anikan-paṣẹ lori ilu pe bi a ba n pa irọ kan naa nigba gbogbo ti a si n tẹnumọọn, nigba ti o ba ṣe, ayé yoo gba irọ naa si otitọ. Aye paapaa gba ọrọ yi si otitọ pe nigba ti irọ ti yi aye po de idaji, n ṣe ni otitọ “S̩è̩ṣẹ n ko bata si ẹsẹ.” Awọn eniyan nipa ti ara le gba iru awọn gbolohun ọrọ wọnyi si otitọ, ṣugbọn aiṣootọ ko le tẹ ododo rì. Bẹẹ gẹgẹ ni ko si eyikeyi ninu iwà ibi ti o le pa otitọ run. Jesu Kristi sọ pe, “Emi li ọna, ati otitọ ati iye” (Johannu 14:6). Ko si irọ ti eṣu ti I pa ri, tabi ti yoo ṣẹṣẹ pa ti o le yi ỌmọỌlọrun tabi OtitọỌlọrun pada rara. Otitọ ti ỌdọỌlọrun wa; bẹẹ si ni otitọ, ohunkohun ti o wu ki o duro le lori, ko ṣe i ya nipa pẹlu Ọlọrun, nitori pe Oun ni i ṣe orisun ohun gbogbo ti i ṣe rere ati titọ.
Gbogbo ibi ati isọrọ buburu ti ọdọ Satani wa. Jesu sọ fun awọn ti wọn n ṣe atako Ọrọ Rè̩ pe: “Ti eṣu baba nyin li ẹnyin iṣe, ifẹkufẹ baba nyin li ẹ si nfẹṣe. Apania li on iṣe lati atetekọṣe, ko si duro ni otitọ; nitoriti ko si otitọ ninu rè̩. Nigbati o ba nṣeke, ninu ohun tirè̩ li o nsọ, nitori eke ni, ati baba eke” (Johannu 8:44). Nitori naa, lati pa irọ tabi ṣe aiṣootọ lọnakọna fi han pe iru ẹni bẹẹ n ṣiṣẹ fun eṣu. Ọlọrun ko le fara da aiṣootọ, awọn eke ki yoo si ni ipin ni Ijọba Ọlọrun. “Ohun alaimọ kan ki yio si wọ inu rè̩ rara, tabi ohun ti nṣiṣẹ irira ati ekek; bikoṣe awọn ti a kọ sinu iwe iye Ọdọ Agutan.” “Nitori li ode ni awọn aja gbe wa, ati awọn oṣo, ati awọn agbere, ati awọn apania, ati awọn abọriṣa, ati olukuluku ẹniti o fẹran eke ti o si nhuwa eke” (Ifihan 21:27; 22:15).
Ọkan Onigbagbọ kún fun ọṣọ rere ti i ṣe ti Oluwa, yoo si maa sọrọ lọna ti yoo fi wu Oluwa rè̩. “Ọgbọn ti o ti oke wa, a kọ mọ, a si ni alafia, a ni ipamọra, ki si iṣoro lati bẹ, a kun fun anu ati fun eso rere, li aisi ègbe, ati laisi agabagebe. Eso ododo li a ngbin li alafia fun awon ti nṣiṣẹ alafia” (Jakọbu 3:17, 18).
Questions
AWỌN IBEERE1 Kin ni mu ki ahọn jẹ alaigbọran ẹya ara?
2 Idi rẹ ti Bibeli fi sọ pe a sọ ahọn si ina ọrun apadi?
3 Tani i ṣe baba eke ati isọrọ buburu gbogbo?
4 Kin ni yoo ṣẹlẹ si gbogbo awọn ti n sọrọ ibi?
5 Bawo ni o ṣe yẹ ki Onigbagbọ maa sọrọ?
6 Kin ni ṣe ti Onigbagbọ ko gbọdọ da si ọrọ ofofo?
7 Tani i ṣe olufisun awọn arakunrin?
8 Aabo wo ni Onigbagbọ ni lati le bọ lọwọ isọkusọ ati ifi ọrọ kẹlẹ banijẹ?