Isaiah 55:1-13

Lesson 360 - Senior

Memory Verse
“Ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orungbẹ ki yio gbẹẹ mọ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ, ti yio mā sun si iye ainipẹkun” (Joahnnu 4:14).
Cross References

I Ipe si Gbogbo Ẹni ti Orungbẹ n Gbẹ

1 Ẹnikẹni ti orungbẹỌlọrun ba n gbẹ ni a o tẹlọrun lọfẹ, Isaiah 55:1; Matteu 5:6; Johannu 4:14; Ifihan 22:17

2 A ṣe ikilọ fun gbogbo awọn ti n wa otitọ ni ibi gbogbo ti ko tọ, Isiaih 55:2; Oniwasu 11:9; Luku 12:15, 19-21

3 A ran iṣẹ kan, a si ṣe ileri kan fun awọn ti wọn feti si ipe Ọlọrun, Isaiah 55:3; Romu 10:17; II Timoteu 3:15; Heberu 6:17-19; 8:10; 9:15; fi we Orin Dafidi 89:3, 27-35; Iṣe Awọn Apọsteli 2:29-35; ati II Samuẹli 23:5

4 A ṣeleri Kristi gẹgẹ bi Olugbala gbogbo eniyan, Isaiah 55:4, 5; Luku 19:10; Matteu 18:11-14; 1:21

II Awọn Igbesẹ kuro ninu è̩ṣẹ wá sinu Igbala

1 Iṣisẹ kinni, “Ẹ wa OLUWA”, fi itara ti onirobinujẹẹlẹṣẹ gbọdọ ni han, Isaiah 55:6; Luku 11:10; Deuteronomi 4:29; Jeremiah 29:13

2 Iṣisẹ keji, “Ẹ kigbe pe e”. n tọka si eyi pe adura jẹ ohun ọranyan, Isaiah 55:6; Hosea 14:2; Luku 18:13, 14; II Kronika 7:14

3 Iṣisẹ kẹta, “Jẹki enia buburu kọọna rè̩ silẹ” fi han pe ẹlẹṣẹ ni lati kọẹṣẹ rè̩ silẹ, Isaiah 55:7; Owe 28:13; Efesu 4:21-23; Esekiẹli 33:14-16

4 Iṣiṣẹ kẹrin “Jẹki o yi pada si OLUWA” fi han pe ironupiwada jẹọranyan, Isaiah 55:7; Joẹli 2:13; Orin Dafidi 34:18; Luku 15:18, 19

5 Iṣisẹ karun jẹ idahun oore-ọfẹỌlọrun: ani aanu ati idariji, Isaiah 55:7; Romu 2:4; Titu 2:11, 12; Luku 15:20

III Idaniloju Igbala ninu ỌrọỌlọrun

1 Ero ati ọna Ọlọrun ga rekọja ti ọmọ eniyan, Isaiah 55:8, 9; Orin Dafidi 8:1-9; 18:30; 40:5

2 ỌrọỌlọrun, gẹgẹ bi ojo, ni lati mu eso jade wa, Isaiah 55:10, 11; I Kọrinti 3:6, 7

3 Ayọ nla ni a fi fun awọn ti o ri igbala, Isaiah 55:12; 12:3; Orin Dafidi 51:12; Romu 14:17; Johannu 15:11; 17:13

4 A fi ẹni iwa-bi-Ọlọrun we alaiwa-bi-Ọlọrun, Isaiah 55:13; Orin Dafidi 1:1-6

Notes
ALAYE

Isaiah, Woli Ọlọrun

Isaiah, Woli Ọlọrun n bẹ lakoko Ijọba awọn mẹrin ninu awọn ọba Juda. Lakoko Ijọba Hẹsekiah, nigba ti a mu isin Ọlọrun ti a ti kọ silẹ pada, isọji nla dide kaakiri ijọba naa, awọn eniyan orilẹ-ede naa si yipada si Ọlọrun. Akoko yi sun mọ igba ti ọjọ aye Isaiah n lọ si opin, lai ṣe aniani eyi jẹ abayọrisi iṣẹ iranṣẹ ti eniyan Ọlọrun yi fi gbogbo aye rè̩ṣe. Nipa imisi ati itọni Ẹmi-Mimọ, Isaiah fi oye eto iyanu Ọlọrun ti o ga ju lọ nipa wiwa si aye Kristi, ituka ati impadabọ orilẹ-ede Israẹli ati Ijọba Ẹgbẹrun ọdun ye ni.

Bi o tilẹ jẹ pe pupọ ninu awọn asọtẹlẹ Isaiah jẹ nipa Israẹli ati lori ibalo Ọlọrun pẹlu wọn, o han gbangba pe pupọ ninu awọn asọtẹlẹ wọnyi tọka si awọn Keferi pẹlu. Niwọn bi Ọlọrun ohun gbogbo ti jẹỌlọrun fun ohun gbogbo, ti Ọrọ Rè̩ ko si le yipada ninu iwa ati pipe Rè̩, ani ninu eyi ti o kere ju lọ ninu aanu ati iṣẹ Oore Rè̩; bi o si ti le jẹ pe eto Ọlọrun da orilẹ-ede Ayanfẹ naa ya sọtọ lati bukun wọn ati lati kọ wọn, ki gbogbo aye ba le ri igbala, ko ni lodi lati ni ireti pe iṣẹ Rè̩ ti o fi ran Woli naa, ẹni ti oun le fi ọkan tan nipa eto Rè̩ ayeraye yoo jẹ ti gbogbo eniyan nigba gbogbo ati nibi gbogbo.

Ofin gẹgẹ bi a ti fi le Mose lọwọ jẹ iṣiṣẹ pataki ninu ilọsoke ati itẹsiwaju ifihan eto Ọlọrun. Awọn woli jẹ oniwaasu tabi awọn ti wọn n ṣe alaye Ofin. Majẹmu Titun to awọn woli si ipo oniwaasu ỌrọỌlọrun. Lati sọ asọtẹlẹ ni lati waasu ỌrọỌlọrun. Ẹnikẹni ti o ba ṣe iwaasu kan ti ko wa ni idọgba patapata pẹlu ỌrọỌlọrun jẹ woli eke, gbogbo awọn ẹni-iwa-bi-Ọlọrun si gbọdọ kọ iru iwaasu bẹẹ (Galatia 1:7-9; II Johannu 10, 11).

Ipe Ọlọrun fun Gbogbo Eniyan

Nihin yi, ninu ori iwe yi, a ni akopọ gbolohun Ọrọ ti Ihinrere. Nihin yi a le ri i ka pe Ihinrere wa fun gbogbo eniyan – olowo ati otoṣi, ọmọwe ati alaimọwe, ominira ati awọn ẹniti a n nilara. Iṣẹ yi sọ pe a ko bu ẹnikẹni sẹhin, bẹẹ ni a ko si yọẹni kan silẹ ninu awọn ileri rè̩. Awọn gbolohun ọrọ wọnyi ṣe akotan gbogbo-gboo gẹgẹ bi ọrọ pataki ti o kadi Bibeli ti sọ pe “Ẹnikẹni ti o ba fẹ”.

Jẹ ki awọn ti n kọ ni pe igbala Ọlọrun wa fun awọn aṣayan eniyan diẹṣe alaye otitọ nì ti o sọ pe “gbogbo ẹniti ongbe ngbẹ” ni a pe ki o wa mu ninu omi iye naa lọfẹ. Jẹ ki awọn ti n lọỌrọỌlọrun ni iru ọna bẹẹ ti wọn si n fi aala si ipe Ọlọrun lati inu imọ ori wọn tẹ ara wọn lọrun bi wọn ba yan lati ṣe bẹẹ. Awọn ti wọn n fẹ ibukun Ọlọrun ju ohunkohun miran lọ le ri itunu ati idaniloju ninu otitọ yi pe ẹniti ko ni owo le wa, ki o ra, ki o si jẹ “laini owo ati laidiyele.”

A ko fẹ alaye miran siwaju si i lori awọn ọrọ wọnyi. Awọn ti wọn n fẹṣi wọn tumọ le lo ọpọlọpọ ijiyan lati gbe imọ ti wọn kalẹ, ṣugbọn sibẹ ipe Ọlọrun ti ko ni abula si gbogbo eniyan duro lai yipada. Ipe naa gan an ni a ṣe alaye rè̩ ninu awọn ọrọ diẹ naa ti o yanju, ti ko si ṣe e tako. “Awọn ero ọna na, bi nwọn tilẹ jẹ ope, nwọn ki yio ṣi i”(Isaiah 35:8).

Gbogbo Ihinrere Jesu Kristi, ninu gbogbo ẹkun ẹwa rè̩ yanju kedere bẹẹ gẹgẹ. Bẹẹ ni o jẹ alai labula, ti ko ṣe e ri wi si, ti ko ṣe e pe lẹjọ, ti ko si ṣe e yipada. Ko si ọmọ eniyan ẹni kiku ti o ti i de opin giga Ihinrere; ko si ẹni ti o si le mọ jijin rè̩ ninu aye yi; gigun ati ibúọrọ naa pẹlu gbogbo ipese rè̩ ko ṣe e diwọn – ani ko ṣe e fi ọkan ro. Bẹẹ si ni iṣẹ naa rọrun to bẹẹ ti o fi jẹ pe gbogbo ohun ti a ni lati mọ nipa rè̩ ki a to le ba Ọlọrun ṣe ilaja ni o le ye wa pẹlu irọrun.

Nihinyi, ninu ori iwe yi, a so fun wa pe akoko kan wa ti a le wa Ọlọrun, itumọ eyi si ni pe opin wa fun iru akoko bẹẹ. Eyi paapaa ko yatọ si ẹkọ Oluwa wa ati ti gbogbo awọn Apọsteli. Akoko aanu Ọlorun yoo wa si opin, ọjọ idajọ Rè̩ yoo si bẹrẹ gẹgẹ bi ilẹ ti n mọ ti ilẹ si n ṣu lati igba ti aye yi ti ṣè̩.

Ọlọrun Ayeraye ati Majẹmu Rè̩ pẹlu Wa

Ayeraye ni Ọlọrun ninu iwa ati ẹwa Rè̩; nitori bẹẹọna ati ero Rẹ ga ju ti wa lọ. Awa jẹ ti aye; Oun wa titi lae. Ọlọrun a maa wo ọkan ọmọ eniyan, ṣugbọn eniyan a maa wo oju. Ọlọrun mọ ete ti o pilẹ iwà ti a hu tabi ọrọ ti a sọ, ṣugbọn iwa ti a hu nikan ni a ri, tabi ọrọ ti a sọ nikan ni a gbọ. Lati ipilẹṣẹ ati ni gbogbo igba, Ọlọrun pe ninu iwa mimọ, ṣugbọn lati ipilẹṣẹ awa jẹ ti “ara ti a ta sabẹẹṣè̩.” Ọlọrun ko ṣe e diwọn lọnakọna yatọ si opin ti o ti fi le ara Rè̩ tikara Rè̩ ni fifun ọmọ eniyan ni anfaani lati lo ifẹọkan rè̩. Opin wa fun agbara wa niwọn bi o ti ṣe pe “a nriran baibai ninu awojiji”, “a si nmọ li apakan (pere)”. A mọ pe igbala Ọlọrun to fun gbogbo eniyan, “lati gba wọn la titi de opin ẹniti o ba tọỌlọrun wa nipasẹ rè̩ (Jesu).” Nitori pe Ọlọrun ga ju lọ ninu ohun gbogbo, ati pe Oun ko si le ṣe aṣiṣe ninu ohunkohun, a le ri i pe igbala Rè̩ gbooro pupọ to bẹẹ ti ipese rẹṣe e gba mu ju bi o ṣe le ye wa tabi mọ lọ.

Bi awa o ba jẹ tẹti silẹ ki a si tọỌlọrun wá, ki a si gbọọrọ oore-ọfẹ Rè̩, ki a si gba ileri Rè̩ ti o logo, a le beere imuṣẹ ileri Rè̩ fun wa: “Emi o si ba nyin da majẹmu ainipẹkun, ani anu Dafidi ti o daju.” Nihin a tun ri gbolohun ọrọ miran ti o ga ni ọlá ti o si mu iṣiyemeji lọwọ to bẹẹ ti a fi ro pe kò le ṣe e ṣe fun wa – ninu aye yi – lati mọ itumọ rẹ ni kikun.

“Emi o si ba nyin da majẹmu ainipẹkun.”Ọlọrun ayeraye nikan ni o le da majẹmu ainipẹkun. Adehun laarin awọn eniyan tabi awọn ọrilẹ-ede ko ni laari mọ bi agbara ati mu un ṣẹ kò ba si. Iwọn igba ti eniyan ba wa laaye nikan ni ifẹọkan rè̩ le duro, ni o si le mu un ṣẹ. S̩ugbọn awọn ileri Ọlọrun kò le kuna, nitori pe Ọlorun kò le ṣeke bẹẹ ni Oun ko si le kú. O gbe Ọrọ Rè̩ ga ju Orukọ Rè̩ lọ. A fi idi Ọrọ Rè̩ mulẹ titi lae ni Ọrun. Ati lati fi han pe ifẹ Oun ati ipinnu Oun fun awa ti a n jẹ orukọ mọỌn, ti a si ya ara wa sọtọ fun ipa ti Rè̩ ki yoo yipada, ki i ṣe pe O ṣe ileri nikan, ṣugbọn O tun fi idi rè̩ mulẹ nipa ibura. Ati “bi ko ti ri ẹniti o pọju on lati fi bura, o fi ara rẹ bur …Nitori enia a mā fi ẹniti o pọju wọn bura: ibura na a si fi opin si gbogbo ijiyan wọn fun ifẹsẹ mulẹọrọ. Ninu eyi ti bi Ọlọrun ti nfẹ gidigidi lati fi aileyipada imọ rè̩ han fun awọn ajogun ileri, o fi ibura sārin wọn. Pe, nipa ohun aileyipada meji ninu eyiti ko le ṣe iṣe fun Ọlọrun lati ṣèké, ki awa ti o ti sa sabẹ abo le ni iṣiri ti o daju lati di ireti ti a gbe kalẹ niwaju wa mu” (Heberu 6:13-18).

Njẹ, tani awọn wọnyi, ti Ọlọrun ba da majẹmu ti Ọrọ Rè̩ fi han yi, Ọrọ ti ko si le yipada eyi ti Oun fi idi rẹ mulẹ nipa ibura ti Oun tikara Rè̩ bu? Tani ninu wa ti o ni ẹtọ si iru anfaani bẹẹ ti Olodumare Ẹlẹda ti ṣeleri fun alaafia wa igba isinsinyi ati ti ayeraye, eyi ti a kò yẹ fun, ti a kò si le san ohunkohun fun? Tani ẹni naa ti o le duro niwaju Ọlọrun nitori mimọọṣe rẹ lati ba A sọ asọye tabi ki o maa ja fun ẹtọ tabi anfaani ti o n fẹ?

Ori ẹkọ wa fi han wa pe awọn eniyan kọọkan ti o ni anfaani lati jẹ ajogun ileri Majẹmu naa, ni awọn ti ebi n pa ọkan wọn, ti oungbẹ omi iye si n gbẹọkan wọn, ti wọn si n wa itẹlọrun fun ebi ti n pa wọn ati oungbẹ ti n gbẹ wọn lati ibiti o tọna. Wọn “ko fẹran aiye tabi ohun ti mbẹ ninu aiye” (I Johannu 2:15). Nidakeji ẹwẹ awọn wọnyi ni o “tete wa ijọba Ọlọrun na ati ododo rẹ” nitori naa a fi “gbogbo nkan wọnyi” kun un fun wọn (Matteu 6:33).

Njẹẹni kọọkan ti a fi ojurere han fun wọnyi ni ẹtọ si anfaani wọnyi bi? Gẹgẹ bi ẹtọ wọn, nda o! Njẹ wọn yẹ fun wọn bi? Nipa ipo ati aṣeyọri wọn, ogún tabi ogún-ibi, bẹẹ kọ rara! Njẹ wọn to tan fun ara wọn lọnakọna lati le duro niwaju Ọlọrun Olodumare lati gba ẹjọ ara wọn rò gẹgẹ bi eniyan ti i duro ni ile-ẹjọ ninu aye yi? Ko si ọna ti wọn le gba ṣe bayi rara! Njẹ kin ni idi pataki, nigba naa, ti awọn nkan wọnyi fi ṣe e ṣe fun awọn eniyan naa ti a fi ojurere han fun ti a si ti fi awọn anfaani wọnyi fun ẹni kọọkan awọn ti a fi i fun? Ohun kan ṣoṣo ni: aanu ati ifẹỌlọrun Ẹni ti O fi Ọmọ bibi Rè̩ kan ṣoṣo fun ni lati san gbèsèè̩ṣè̩ wa, ikuna wa, ainaani wa ati ailera wa gẹgẹ bi ọmọ-eniyan, ati lati di ọgbun ti n bẹ laarin Olodumare Ẹlẹda ati ẹda ọwọ Rè̩.

Aanu ati Ifẹ Ailopin Ọlọrun Ayeraye

Nihin a ri aanu ailopin ati ifẹ ti kòṣe e diwọn ti a fi han. Ọlọrun ko ni ilo ohunkohun ti a ni, ti a jẹ, tabi ti a le ṣe. Awa, nipa yiyan ẹṣẹ, a ti yan ọna ti ara wa, a ti ṣa A tì, a ṣai ka A si, a si ti KọỌ silẹ. SibẹsibẹỌlọrun alaanu yi ti ṣe eto fun yiyọ wa, fun igbala wa, ati fun iṣelogo wa. Oun ti fun wa ni ẹmi, eyi ti, nipa agbara imọ Rẹ, ki yoo kú rara. Niwọn-igba ti o ṣe pe Ọlọrun ki i yipada, ati niwọn igba ti o ṣe pe O pé ni ọna Rẹ gbogbo, ki i ṣe pe ẹmi Rè̩ ti o ti fi sinu eniyan ki yoo ku nikan, ṣugbọn ko tilẹ le kú rara. Ọkan ti o taku sinu ṣiṣa Ọlọrun tì tabi kikọỌ silẹ wa ninu ewu ipọnju ayeraye.

Ki i ṣe ifẹỌlọrun pe ki ẹnikẹni ṣegbe; bi o tilẹṣe pe o mọ dajudaju lati ibẹrẹ wa ohun nlá nlà ti yoo gba A ki a to le ra eniyan kan ṣoṣo pada, sibẹsibẹ, tifẹtifẹ ni o fi san owo irapada naa. Ki i ṣe ohun kan bi ko ṣe ọpọlọpọ aanu ati ifẹ ailoṣuwọn ni o le ṣe iru eto bẹẹ, pe ki awọn ti wọn ti gan aanu ati ifẹ naa nigba kan ri ṣugbọn ti wọn ronupiwada ẹṣẹ ati iṣọtẹ wọn, ba le bọ kuro ninu ipo oṣi wọn ki wọn si ni ibujoko ni ọrun – ojurere ti wọn ko lẹtọ si, ti owo ko si le ra.

Awa gẹgẹ bi ọmọ-eniyan maa nda ọgbọn lati mu ifẹọkan wa ṣẹ tabi lati maa wa faaji fun ara wa. Ki a to dawọ le ati mu awọn nkan wọnyi ṣe, a maa n kọkọ joko ṣiro ohun ti yoo gba wa. Njẹ a o le pari ohun ti a fẹ dawọ le yi? Njẹ a o le ṣe eyi lai pa awọn nkan miran ti a ni lọkan lati ṣe lara? Njẹ ohun ti a dawọ le yi le mu ere tabi anfaani kankan wa ba wa gẹgẹ bi a ṣe ni in lọkan pe yoo ri? Awọ ibeere wọnyi ati ọpọlọpọ miran ti o maa n wa siwaju wa ni a kọkọ gbọdọ yanju rè̩ ki a to dawọ le ati ṣe ohunkohun rara ninu iṣẹ ti o wa niwaju wa. Ni igba pupọ o maa n jẹọranyan fun wa lati pa eto kan tì ki a ba le ni idaniloju iyọrisi rere ti omiran.

S̩ugbọn pẹlu Ọlọrun iṣẹ irapada ki i ṣe arosẹhìn tabi yiyan ọna miran nitori ijatilẹ ti o ba pade ninu eto ti akọkọ. Ọlọrun mọ lati ibẹrẹ bi gbogbo nkan yoo ti ri ni ọjọ iwaju. O mọ awọn ohun wọnni ti yoo yẹ lati mu ifẹ Rè̩ lori wa ṣẹ. O mọ gbese ti Ọmọ Rè̩ ni lati san. S̩ugbọn Oun ko lọra bi o tilẹ jẹ pe gbese naa tobi pupọ.

Ọlọrun ṣe Eto naa. A si san gbese naa. O nawọ ipe. Lẹhin naa O ran Ẹmi Rè̩ jade lati rọ awọn eniyan ki wọn gba Eto naa ki wọn si ri igbala Rè̩. O si n ṣe ohun gbogbo ti o yẹ nipa Eto naa fun iṣelogo wa nigbooṣe.

O ti sọ fun wa pe: “Ẹ wa OLUWA … ẹ pe e … jẹ ki enia buburu kọọna rè̩ silẹ, ki ẹlẹṣẹ si kọ ironu rè̩ silẹ: si jẹ ki o yipada si OLUWA, on o si ṣanu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi ji li ọpọlọpọ.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Tani a nawọ ipe ti a ri ni ẹsẹ kinni ẹkọ wa yi si?

  2. 2 Kọ I Johannu 2:15-17 sori.

  3. 3 Kin ni ṣe ti a ni idaniloju pe eto Ọlọrun fun igbala yoo jẹ ti wa pẹlu?

  4. 4 Kin ni Ọlọrun ṣe ni afikun ọrọ Rè̩ ti o fun wa eyi ti o fi ọkan wa balẹ nipa awọn anfaani igbala Rè̩?

  5. 5 Kin ni idi ti awọn eniyan fi maa n bura? Eeṣe ti Ọlọrun paapaa fi ṣe bẹẹ nipa ọran igbala wa?

  6. 6 Kin ni awọn iṣisẹ si igbala?

  7. 7 Iwe Mimọ wipe: “Ore-ọfẹ li a ti fi gba nyin la nipa igbagbọ.” Kinni oore-ọfẹ? Kin ni igbagbọ? Bawo ni a ṣe n ni igbagbọ?

  8. 8 Ero Ọlọrun ati ọna Rè̩ ga ju ti eniyan lọ. Sọ ohun diẹ ti o fi eyi han. Ọna wo ni otitọ yi fi fara kan eto igbala Rè̩?

  9. 9 Darukọ diẹ ninu awọn ibukun ti igbala Ọlọrun maa n mu ba wa.

  10. 10 Yan Orin Dafidi kinni gẹgẹ bi ori iwe ki o si ṣe alaye iyatọ laarin ẹni-iwa-bi-Ọlọrun ati alaiwa-bi-Ọlọrun.