I Johannu 1:1-10; 2:1-17, 24, 25, 28, 29; 3:1-24; 4:7-21; 5:1-21; II Johannu 1-6, 12, 13; III Johannu 1-8, 12-14

Lesson 361 - Senior

Memory Verse
“Bi ẹnikẹni ba wipe, emi fẹran Ọlọrun, ti o si korira arakunrin rẹ, eke ni: nitori ẹniti ko fẹran arakunrin rè̩ ti o ri, bawo ni yio ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti on ko ri?” (I Johannu 4:20).
Cross References

I Idapọ Pẹlu Ọlọrun

1 Jesu Kristi, ti I ṣe ifarahan ifẹỌlọrun si wa, nikan ṣoṣo ni ipilẹṣẹ ayọ ayeraye, I Johannu 1:1-4; 2:25; 5:11-13; Johannu 3:14, 15, 36; Iṣe Awọn Apọsteli 4:10-12; Johannu 17:2, 3

2 Imọlẹ ni Ọlọrun, awọn ti o si ni idapọ pẹlu Rè̩ ní lati rin ninu imọlẹ ki wọn si pa ofin Rè̩ mọ, I Johannu 1:5-7; 2:2-6, 24, 28; 5:1-3

3 Awọn ọmọỌlọrun ni idapọ didun pẹlu ara wọn bi wọn ti n rin ninu imọlẹ, I Johannu 1:7; II Johannu 1-6, 12, 13; III Johannu 1-4, 12-14

4 Gbogbo eniyan ni o ti ṣẹ, ṣugbọn awọn ti o ba jẹwọẹṣẹ wọn fun Ọlọrun a maa ri idariji gba, I Johannu 1:8-10; 2:1, 2; Owe 28:13; Isaiah 55:7; Iṣe Awọn Apọsteli 3:19

5 Awọn ti o fẹran aye ko ni idapọ pẹlu Ọlọrun, I Johannu 2:15-17; Romu 12:2;Titu 2:12; Jakọbu 4:4

Isọdọmọ Awọn ti o Gbagbọ

1 Ifẹ nla ti baba ni si awọn ọmọ-eniyan ti san gbese nipasẹ eyi ti wọn le fi di ọmọỌlọrun, I Johannu 3:1-3; Johannu 3:16; Romu 5:8; Efesu 2:4, 5

2 Awọn ọmọỌlọrun – eyi yi ni awọn Onigbagbọ ti a ti tunbi – ki i dẹṣẹ, I Johannu 3:4-10; 2:12-14, 29; 5:4, 5, 18-21; Galatia 6:7, 8; Jakọbu 1:27

3 Awọn ọmọỌlọrun a maa fẹran arakunrin wọn, I Johannu 3:11-19; 4:7-12, 20, 21; 2:7-11; 5:16, 17; Luku 10:25-37; Johannu 13:35; 15:12; I Peteru 1:22; III Johannu 5-8

4 Igbọran si ofin Ọlọrun a maa fun ni ni igbagbọ ati igboya ninu Ọlọrun, I Johannu 3:20-23; 4:17-19; 5:14, 15; Johannu 15:7

5 Ọlọrun a maa jẹri nitootọ si igbesi-aye awọn ọmọ Rè̩, I Johannu 3:24; 4:13-16; 5:6-10; Romu 8:16; Galatia 4:6

Notes
ALAYE

IfẹỌlọrun

Johannu, ọmọ-ẹhin ti i maa rọgbọku laya Jesu, ni a maa n saba sọrọ rè̩ bi Apọsteli ifẹ, ki i ṣe kiki nitori pe o ba Oluwa rin timọtimọ laarin ọdun mẹta iṣẹ-iranṣẹ Rè̩ nikan, ṣugbọn paapaa, nitori awọn ẹkọ ijinlẹ nipa ifẹỌlọrun ti n bẹ ninu akọsilẹ rè̩. Nitori pe Johannu jẹẹlẹri ojukoju Jesu Kristi, lati ibẹrẹ iṣẹ-iranṣẹ Rè̩ titi de iku Rè̩ lori agbelebu, ti o si ri agbara ifẹỌlọrun lori oun tikara rẹ ati lori awọn Apọsteli ti o kù, koko ẹkọ ifẹỌlọrun wọọ lọkan ṣinṣin. Ọpọlọpọọdun lẹhin eyi, nipa imisi Ẹmi Mimọ, o kọ akọsilẹ pupọ lori ẹkọ pataki yi.

“Ifẹ ni Ọlọrun,” ni Apọsteli naa kọ silẹ; ifẹ naa si fara han gedegbe ni fifi Ọmọ Rè̩ kanṣoṣo fun ni lati ra araye pada. “O tọ awọn tirè̩ wa, awọn ara tirè̩ ko si gba a. S̩ugbọn iye awọn ti o gba a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọỌlọrun, ani awọn na ti o gba orukọ rè̩ gbọ” (Johannu 1:11, 12).

Johannu jẹọkan ninu awọn wọnni ti wọn gbagbọ ti wọn si gba Jesu ni ỌmọỌlọrun. Lẹhin ti Jesu ti pada si Ọrun, Johannu wa mọ ju bẹẹ lọ titobi anfaani iyanu ti oun ti ni, lati wà pẹlu Jesu. Pẹlu imọ ti o ti odòọkan wa, Johannu le da awọn ẹlẹgan lohun lọwọ kan, awọn ti n sọ pe eniyan rere ati olukọ kan ṣaa ni Jesu i ṣe, pe: “Eyiti o ti wa li atetekọṣe, ti awa ti gbọ, ti awa ti fi oju wa ri, ti awa si ti tẹjumọ, ti ọwọ wa si ti dimu ni ti Ọrọ iye” (I Johannu 1:1). Ki i ṣe ẹran ara ati è̩jẹ ni o fi otitọ iyanu ayeraye yi han Apọsteli ayanfẹ, ṣugbọn Ọlọrun Baba ni o fi otitọ yi han lati Ọrun (Wo Matteu 16:15-17).

Iriri Ibi Titun

Johannu mọ Jesu nipa iriri, anfaani si wà fun gbogbo eniyan lati ni iru ìriri bẹẹ. Jesu sọ fun Tọmasi pe: “Nitoriti iwọ ri mi ni iwọṣe gbagbọ: alabukunfun li awọn ti ko ri, ti wọn si gbagbọ” (Johannu 20:29). Ninu akọsilẹ Apọsteli yi, otitọ kan n bẹ ti a tẹnumọ, eyi ti Jesu ti fi kọ ni lakoko iṣẹ-iranṣẹ Rè̩; eyi ni pe, lati mọ Jesu ati lati gba A gbọ ni itumọ ti o jinlẹ ju imọ tabi igbagbọ ti ọgbọn ori lọ. Otitọ iyebiye ni eyi, nitori ogunlọgọ awọn alafẹnujẹ Onigbagbọ ni oye wọn nipa Jesu kò tayọ ti ọgbọn ori, wọn si n pe eyi ni “Isin Kristi.”

A le mọ Jesu nipa irìri nikan, nigba ti awọn eniyan ba jẹwọẹṣẹ wọn ti wọn si kọ wọn silẹ, lẹhin naa ti wọn si n rin ninu imọlẹỌrọỌlọrun. Gbigba Kristi gbọ gẹgẹ bi ẹkọ Bibeli ni gbigbọran si gbogbo aṣẹ Rè̩. Nigba ti eniyan ba tọỌlọrun wa lọna bayi, nipa jijẹwọ ati kikọ awọn ẹṣẹ rè̩ silẹ, nipa gbigba Jesu Kristi gbọ ati iṣẹ irapada ti O ra fun gbogbo ẹda nipa iku Rè̩ lori agbelebu, olootọ ati olododo ni Ọlọrun lati dari ẹṣẹẹni naa ji i. Iru iriri bayi pẹlu Ọlọrun ni a n pe ni atunbi. O jẹ iriri ti o ṣe pataki to bẹẹ ti o fi jẹ pe lai si rè̩, ko si ẹni ti yoo ri Ijọba Ọlọrun (Wo Johannu 3:1-8).

Awọn ỌmọỌlọrun

Iriri atunbi maa n yi ẹnikẹni ti o kun fun iwà aye pada si ọmọỌlọrun (lai ka bi o ti jẹọmọluwabi tabi bi o ti buru to; lai ka bi ipo rè̩ ti ga to ninu aye tabi bi o ti wù ki ẹṣẹ rẹ dido to). Ifẹ si ohun ti aye a si jade kuro ninu ọkan rè̩, ifẹỌlọrun a si kun ibẹ. Idalẹbi a jade kuro ninu ọkan naa, a si ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun eyi ti yoo maa dagba siwaju ati siwaju gẹgẹ bi ọmọỌlọrun naa ba ṣe n rin ninu imọlẹỌrọỌlọrun. Ẹmi Ọlọrun paapaa maa n ba ẹmi awọn ọmọ Rè̩ jẹri pe ọmọ Oun ni wọn i ṣe.

Gbogbo ibukun iyanu wọnyi ati ju bẹẹ lọ jẹ ti awọn ọmọỌlọrun nitori akanṣe ifẹ Baba. Iṣẹ nla miran ti a tun n ṣe ninu ọkan ọmọ eniyan nipa irapada ati sisọ ni di ẹbi Ọlọrun ni ireti pe awọn ỌmọỌlọrun yoo ri Ọlọrun bi O ti ri lọjọ kan. “Olukuluku ẹniti o ba si ni ireti yi ninu rè̩, a wẹ ara rè̩ mọ, ani bi on ti mọ” (I Johannu 3:3). Ọlọrun gba ọkan kan la kuro ninu ẹṣẹ rè̩, ṣugbọn bi o ba duro ninu igbala yi, o ni lati maa dagba ninu oore-ọfẹ lati igba de igba titi a o fi gba ọkan naa sinu Ogo.

Ko si ẹṣẹ ninu igbesi-aye awọn ọmọỌlọrun. Ẹṣẹ ni rirú ofin Ọlọrun. Jesu Kristi si ti fara han lati mu è̩ṣẹ kuro. È̩ṣẹ ko si ninu Kristi, “Ẹnikẹni ti o ba ngbe inu rè̩ ki idẹṣẹ: ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ ko ri i, bẹni ko mọọ” (I Johannu 3:6). Apọsteli naa, ẹlẹri ojukoju agbara iyanu Jesu, ẹni ti o fi tọkantọkan tẹti silẹ si ọrọ ati ẹkọ Jesu, ṣe alaye yekeyeke lori ọran awọn alafẹnujẹ Onigbagbọ ti i maa dẹṣẹ. Nipa imisi Ẹmi, Apọsteli yi sọ pe ko ṣe e ṣe ki a maa dẹṣẹ ki a si tun jẹ Onigbagbọ sibẹ. “Ẹnikẹni ti a ti ipa Ọlọrun bi ki idẹṣẹ; nitoriti iru rè̩ ngbe inu rè̩: ko si le dẹṣẹ, nitoripe a ti ti ipa Ọlọrun bi i” (I Johannu 3:9). Ọlọrun maa n yi eniyan pada, a si mu ifẹ si iwáè̩ṣẹ jade kuro ninu ọkan nigba ti a ba tun ẹni naa bi.

Ifẹ si Awọn Ara

“Ninu eyi ni ifẹ wà, ki iṣe pe awa fẹỌlọrun, ṣugbọn on fẹ wa, o si ran ọmọ rè̩ lati jẹ etutu fun ẹṣẹ wa. Olufẹ, bi Ọlọrun ba fẹ wa bayi, o yẹ ki a fẹran ara wa pẹlu” (I Johannu 4:10, 11). Nihin yi a fi ye ni pe, o kọja pe bi a ba fẹ tabi bi a kò fẹ, pe awọn ọmọỌlọrun ni lati fẹran ara wọn, nitori pe aṣẹ gan an ni i ṣe. Jakejado Majẹmu Titun, a ri i wi pe iwọn ifẹ ti eniyan ni si Ọlọrun maa n di mimọ nipa bi o ti fẹran awọn ẹlomiran si tabi bi o ti ṣai fẹran wọn. “Bi awa ba fẹran ara wa, Ọlọrun n gbe inu wa, a si mu ifẹ rè̩ pe ninu wa” (I Johannu 4:12).

Ninu ọkan Onigbagbọ ifẹ si ẹnikeji rè̩ kò leke ifẹ si Ọlọrun, ṣugbọn mejeeji ni a so pọ danindanin. Ọkan lile ati ifẹỌlọrun ki i gbe pọ. O tẹ awọn ẹlomiran lọrùn ki wọn fẹran awọn ọrẹ ati ẹbi wọn, ṣugbọn wọn korira awọn ọta wọn. Jesu sọ pe, “Emi wi fun nyin, ẹ fẹ awọn ota nying, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin re, ẹṣore fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankan ba nyin lo, ti nwọn nṣe inunibini si nyin; ki ẹnyin ki o le maa jẹọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun” (Matteu 5:44, 45).

Bawo ni o ti yẹ ki ifẹ si awọn ara yi jinlẹ to? O gbọdọ jinlẹ to bẹẹ ti yoo fi le mu ki ọmọỌlọrun kan le pin ounjẹ ati ini rè̩ pẹlu arakunrin rè̩ ti ko ni. Ohunkohun ti o wu ki o jẹ ijẹwọ iwabi-Ọlọrun ẹnikẹni, ti ko ba ni ẹmi ibakẹdun fun ẹlẹgbẹ rè̩ ti o wa ninu aini, ko si otitọ ninu ijẹwọ rè̩. Ẹmi Ọlọrun pa a laṣẹ pe bi Kristi ti fi ẹmi rè̩ lelẹ fun wa, bẹẹ gẹgẹ, awa paapaa “gbọdọ fi ẹmi wa lelẹ fun awọn ara” (I Johannu 3:16). Ni igba aye Apọsteli yi, kiku iku ajẹriku wọpo, lai si aniani o ṣe e ṣe fun ọkan ninu awọn ọmọỌlọrun ki o gba ẹmi ẹni kan tabi ti eniyan pupọ silẹ nipa fifi ẹmi ti rẹ lelẹ. Ifẹ si awọn ara lọjọ oni ko gbọdọ dinku si iru eyi nì. Ẹni ti ko le fi ounjẹ rẹ fun ẹni ti ebi n pa ko ni le fi ẹmi rè̩ lelẹ fun awọn ara.

Amofin nì bi Jesu leere wi pe, “Olukọni, kili emi o ṣe ki emi ki o le jogun iye ainipẹkun?” Jesu beere lọwọ amofin naa ohun ti ofin wi nipa ibeere rẹ yi, amofin naa si sọọ. Jesu wi fun un pe, “Iwọ dahun rere: ṣe eyi, iwọ o si ye” (Luku 10:25, 28). Kin ni idahun amofin naa ti ri? “Ki iwọ ki o fi gbogbo aiya rẹ, ati gbogbo ọkan rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, ati gbogbo inu rẹ fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹnikeji rẹ bi ara rẹ” (Luku 10:27). Ere iru ifẹ yi nigba naa, yoo yọrisi iye ainipẹkun fun ẹnikẹni ti o ba ni in. Gẹgẹ bi ọpọlọpọ eniyan lode oni, amofin yi n fẹ da ara rè̩ lare, nitori bẹẹ, o bi Jesu ki o ṣe alaye ẹni ti ẹnikeji oun i ṣe fun oun. Jesu sọ itan ọkunrin rere ara Samaria, o wa beere lọwọ amofin yi ẹni ti oun rò pe i ṣe ẹnikeji fun Ju ti o bọ si ọwọ awọn ọlọṣa. Boya amofin yi tilẹ korira awọn ara Samaria, gẹgẹ bi ọpọ ninu awọn Ju ti n ṣe, nitori pe ko jẹ darukọ ara Samaria naa, ṣugbọn o jẹwọ otitọ naa: “Ẹniti o ṣanu fun u ni.” Nigba naa, Jesu wi fun un pe, “Lọ, ki iwọ ki o si ṣe bḝ gẹgẹ” (Luku 10:37).

Ranti pe itan ọkunrin rere ara Samaria ni i ṣe pẹlu iye ainipẹkun. “Tani ẹnikeji mi?” Ibeere yi kan gbogbo ẹni ti o n fẹ lọ si Ọrun. Ẹnikeji wa ni ẹnikẹni ti a ba le ṣe oore fun, tabi ti a le mu wa sọdọỌlọrun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Bawo ni o ṣe le ṣe e ṣe lati ni irẹpọ pẹlu awọn ọmọỌlọrun?

  2. 2 Awọn wo ninu awọn ọmọ eniyan ni o ti dẹṣẹ?

  3. 3 Bawo ni a ṣe le ri idariji ẹṣẹ wa gba?

  4. 4 Kin ni maa n ṣẹlẹ nigba ti ẹni kan ba n gbiyanju lati fẹỌlọrun ati aye papọ lẹẹkan naa?

  5. 5 Awọn wo ni i ṣe ọmọỌlọrun?

  6. 6 Eeṣe ti ko fi gbọdọ si ẹṣẹ ni igbesi-aye ọmọỌlọrun?

  7. 7 Eredi rè̩ ti o fi ṣe pataki pe ki awọn ọmọỌlọrun fẹran ara wọn?

  8. 8 Bawo ni o ti yẹ ki ifẹ ti ọmọỌlọrun ni si arakunrin rè̩ ti jinlẹ to?

  9. 9 Kin ni iha ti awọn ọmọỌlọrun gbọdọ kọ si awọn ẹlẹkọ eke?