Nahumu 2:3, 4; II Timoteu 3:1-5; hnII Peteru 3:3, 4; Jakọbu 5:7, 8; Matteu 24:3-28

Lesson 362 - Senior

Memory Verse
“S̩ugbọn eyi ni ki o mọ, pe ni ikẹhin ọjọ, igbà ewu yio de. Nitori awọn enia yio jẹ olufẹ ti ara wọn, olufẹ owo, afunnú, agberaga, asọrọbuburu, aṣaigbọran si òbi, alai lọpẹ, alaimọ, alainifẹ, alaile-dariji-ni, abanijé̩, alaile-kó-ra-wọnnijanu, onroro, alainifẹ-ohun-rere, onikupani, alagidi, ọlọkàn giga, olufẹ fāji jù olufẹỌlọrun lọ; awọn ti nwọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn ti nwọn sé̩ agbara rè̩: yẹra kuro lọdọ awọn wọnyi pẹlu” (II Timoteu 3:1-5).
Cross References

I Awọn Ami ti o wa ninu Iwe Nahumu ati ninu II Timoteu

1 A ṣe apejuwe ọkọ ayọkẹlẹ iwoyi yekeyeke, Nahumu 2:3, 4

2 A sọ asọtẹlẹ nipa gige igi firi lulẹ, Nahumu 2:3

3 A ṣe apejuwe gbogbo iwa ibajẹ ni ikẹhin ọjọ, II Timoteu 3:1-5, 13; Jakọbu 5:5

II Awọn Ami ti o wa ninu Iwe Peteru ati ti Jakọbu

1 Awọn ẹlẹgan yoo maa kọ ni ni ẹkọ odi nipa iṣẹda eniyan, II Peteru 3:3, 4; Romu 1:20-22

2 Ikojọpọ awọn ẹni igbala yoo ṣẹlẹ lẹhin Arọkuro Ojo, Jakọbu 5:7, 8; Joẹli 2:23-29; Iṣe Awọn Apọsteli 2:16-18

III Awọn Ami ti o wa ninu Iwe Matteu

1 Woli eke pupọ yoo si dide, Matteu 24:3-5, 11, 23-26; I Timoteu 4:1-3; I Johannu 2:18

2 Idagiri ogun yoo wa nibi gbogbo agbaye, Matteu 24:6, 7; Marku 13:7, 8; Luku 21:9, 10

3 Iyan ati ajakalẹ-arun ati isẹlẹ yoo wa nibi pupọ, Matteu 24:7, 8

4 A o ṣe inunibini si awọn Ju, Matteu 24:9, 10; Johannu 16:2; Amọsi 9:l, 10

5 Iṣubu kuro ninu igbagbọ yoo wa, Matteu 24:12, 13; II Tẹssalonika 2:3

6 A o waasu Ihinrere kaakiri gbogbo orilẹ-ede, Matteu 24:14; 28:19, 20

7 A sọ nipa ti Ipọnju Nla na ti o n bọ wa sori aye, Matteu 24:15-22; Daniẹli 12:1

8 Dide Oluwa yoo dabi kikọ manamana, Matteu 24:27, 28, 42-44

Notes
ALAYE

Ariwo Kè̩kẹ

Ni o din diẹ ni ọgọrun ọdun sẹhin, awọn aṣiwaju wa nini kẹkẹẹlẹṣin fi ori la igba la iju nibi ti ọna ko si ki wọn to de eti okun ni iha iwọ-oorun ilu Amẹrika. Lode oni, ọkẹ aimoye oriṣiriṣi ọkọ ayọkẹlẹ ni o n lọ ti o n bọ ni opopo ọna ti o gbooro kaakiri orilẹ-ede wa. Ijamba oju ọna paapaa tun ti yatọ, o ti kuro ni ijamba inu igbo didi awọn ara India, o ti di ti iforikori awọn ọkọ ayọkẹlẹ mẹẹdogun laarin iṣẹju kọọkan, pẹlu ifarapa eniyan meji laarin iṣẹju kọọkan, ati pipa eniyan kan ni iṣẹju mẹrinla-mẹrinla si ara wọn. Njẹẹnikẹni le fọkan ṣiro iru iyipada bayi? O ṣoro pupọ. S̩ugbọn, duro gbọ; woli kan ti o kọ akọsilẹ ni ẹẹdẹgbẹrinla ọdun sẹhin: “Kẹkẹ ogun yoo mā kọ bi iná … mā gbun ara wọn ni ọna gbigboro, nwọn o dabi etufu, nwọn o kọ bi manamana” (Nahumu 2:3, 4). Iru apejuwe wo ni eyi – “Yio mā kọ bi ina” itanṣan ina-oju mọto ti n kọja lọ laarin okunkun; “ariwo kẹkẹ ni igboro” – fifi ikanju fun fere nigba ti eniyan kan ba n duro pẹ lati gba aṣẹ kọja maa lọ; “nwọn o si mā gbún ara wọn” – o le ni irinwo ọkẹ ikọlukọgba awọn ọkọ ayọkẹlẹ laarin ọdun kan; “ni ọna gbigboro” -- awọn ọna olopopo mẹjọ-mẹjọ ni o wọ awọn ilu ti o wà ni Amẹrika; “nwọn o dabi etùfu” – duro si ibi ti àyè gbe wa ki o si ṣe akiyesi wọn ni alẹọjọ kan; “nwọn o kọ bi manamana” – ririn mile kan laarin iṣẹju kan ti pẹ ju loju awọn ọna opopo ilu Amẹrika. Nahumu ni lati ti ṣe akiyesi awọn ọkọ ayọkẹlẹ wa.

Kin ni idi rè̩ ti a fi fi iru iṣipaya bayi han woli naa? Apẹẹrẹ kin ni eyi jasi? O ṣe ami “ọjọ imurasilẹ rẹ”. A fi awọn ami wọnyi fun ni lati ṣi awọn eniyan leti lati wà ni imurasilẹ fun bibọ Oluwa. Ẹ jẹ ki a ṣe akiyesi awọn ami wọnyi pẹlu awọn ami miran nipa ipadabọ Rè̩.

Igi Gẹdu

“Igi firi li a o si mi tìti” (Nahumu 2:3). Bi a ba n wàọkọ lọ si eti okun lori ọkan ninu awọn opopo nla ni ilu Oregon, a o kọja laarin ọwọ igi firi nlánlá daradara kan. Bi a ba da mọto duro lati jẹ igbadun igbo tutu yọyọ yi, a maa n mọọn lara bi a ti kere to ati pe a da nikan wa pẹlu ẹda. A gbe iṣisẹ bi melo kan si aarin awọn igi naa. Imọlẹ tan ka aarin awọn igi wọnni kanlẹ; papa oko tutu ni tabi adagun omi? S̩iṣe akiyesi daradara fi han pe awọn oke nibi ti wọn ti ge igi ni a n wo. Irora mu wa bi a ti ta kiji lati ranti pe ẹgbẹ igbo kan ni a wa. Ohun ti o kùṣaa ni ami tabi ralẹralẹ igi firi ti o ti fi igba kan bo awọn ori oke wọnni mọlẹ. A ti mi awọn igi firi naa tìtì. Ọjọ imurasilẹ Rè̩ ni. Ni ibẹrẹ o dabi ẹni pe isopọ diẹ lo wa laarin igi firi ati awọn kẹkẹwọnni ninu asọtẹlẹ Nahumu. S̩ugbọn bi a ti n wa ọkọ lọ lọna opopo nla naa, bẹẹ ni a ri ti ọkọẹru n tẹle ọkọẹru pẹlu igi gẹdu gbọọrọgbọọro ninu wọn ti wọn si n sare kọja lọ si ẹrọ ilagi. A le ri iru isopọ timọtimọ ti o wà laarin ọkọ ilẹ ati ibi iṣẹ igi lila. Awọn mọto gẹdu ati oriṣiriṣi iṣẹ ti o jẹ mọ igi ti parapọ wọ inu igbo tutu wa, igi firi si wo lulẹ bẹẹrẹbẹẹ bi ibi ti erin gbe gbija ninu igbo.

Ẹkọ AgbekalẹỌgbọn-ori nipa Iṣẹdalẹ Eniyan

“Ati gẹgẹ bi wọn ti kọ lati ni iro Ọlọrun ni imọ wọn, Ọlọrun fi wọṅ fun iye rira” (Romu 1:28). Ni iran ti o ti kọja lọ, ninu awọn ile-ẹkọ ati ile-ẹkọ giga ti wọn i ba ti kọ awọn ọdọmọkunrin ati awọn ọdọmọbinrin bi a ṣe le gbe igbesi-aye ti o peye ti o niyelori, ti o si kun fun eso rere, a ri i pe a tọ awọn ọdọ lati gba ẹkọ-kẹkọ ti ọgbọn ori nipa iṣẹdalẹ eniyan, pe n ṣe ni eniyan dagba lati inu ẹran-omi ti ko ni laarin kan; pe Ọlọrun ki i ṣe Ẹleda aye, pe Bibeli kò ba ẹkọọgbọn-ori mu, ati pe ko ba ode-oni mu mọ, pe ọlọrun ni awọn ọmọ-eniyan i ṣe, pe ọmọ-eniyan ko si labẹ aṣẹỌlọrun tabi ti eniyan, pe ko si Ọrun rere ati ọrun apaadi. Wọn a maa wi pe, “Kin ni ṣe ti a kò le fun ọkàn tabi ara wa ni ohunkohun ati ohun gbogbo ti wọn ba n fẹ lode oni?”

Ẹkọọgbọn-ori nipa iṣẹdalẹ eniyan ti o sọ pe n ṣe ni eniyan deede dagba lati inu iru ẹda miran titi o fi de ipo ti o wa yi ti tan yika gbogbo orilẹ-ede aye. Oniwe irohin kan kọ bayi pe, “Ko i ti i si ohun ti o ṣe itẹwọgba ti o si ni agbara iyipada lori ero ọmọ-eniyan nibikibi bi ẹkọ-kẹkọ ti ogbọn-ori yi, lati igba ti Ọgbẹni Darwin ti kọ iwe rè̩ ti o pe orukọ rè̩ ni Ipilẹṣẹ Oriṣiriṣi Ẹda, ni ọdun 1859. Bọya awa naa si le fi kun un pe ko ti i si ohun kan ti a tẹwọgba ti o ni agbara ati imisi eṣu ninu bi rè̩.

Peteru sọ tẹlẹ pe ami ọjọ ikẹhin yoo jẹ “awọn ẹlẹgan, nwọn o mā rin nipa ifẹ ara wọn, nwọn o si mā wipe, nibo ni ileri wiwa rè̩ gbe wà? lati igbati awọn baba ti sun, ohun gbogbo nlọ bi nwọn ti wa ri lati igba ọjọ iwa” (II Peteru 3:3, 4). Pupọ eniyan ni o n sọ lọjọ oni wi pe awọn gba Ọlọrun gbọ, sibẹ wọn tun gba ẹkọọgbọn-ori nipa iṣẹdalẹ eniyan wọn si sẹ akọsilẹ Bibeli nipa iṣẹda aye. Wọn sẹỌlọrun Ẹni ti O da wọn, wọn si ti gbe ọlọrun atọwọda ti wọn kalẹ. Ipẹgan wọn yi jẹ ikilọ fun Onigbagbọ tootọ pe igba ikẹhin ni eyi.

Ifẹkufẹ ati Ogun

“Ririn nipa ifẹ ara wọn” ti mu ki iran yi wa ni ipo ogun jija nigba gbogbo. “Nibo ni ogun ti wa, nibo ni ija si ti wa lārin nyin? lati inu eyi ha kọ? lati inu ifẹkufẹ ara nyin, ti njagun ninu awon ẹya ara nyin? Ẹnyin nfẹ, ẹ ko si ni: ẹnyin npa, ẹ si nṣe ilara, ẹ ko si le ni: ẹnyin nja, ẹnyin si njagun” (Jakọbu 4:1, 2). “Orilẹ-ede yio dide si orilẹ-ede ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba” (Matteu 24:7). Ija ti Jesu sọ pe yoo ṣe ami wiwa Oun yi bẹrẹ lati inu ifẹkufẹọkàn ti o ti sọỌlọrun kalẹ lati ori ìtẹ ti o si ti gbe eniyan gun ori ìtẹ.

Ọkan ti a ba jọwọ rẹ fun ifẹkufẹ ara rè̩ yoo ni ifasẹhin kiakia, bẹẹ gan an ni o ṣe ri loni ti a fi wa ni ipo ti Paulu pe ni igba ewu ti igba ikẹhin: Onigberaga eniyan a maa ṣogo lori imọ ati aṣeyọri rè̩ gbogbo; sibẹẹ wo ibajẹ ti o sọọran agbaye da. O ti kọọpọlọpọ iwe lori ẹkọ imọọkàn ọmọde, ṣugbọn oun ko le fi opin si iwa abuku ati ẹṣẹ awọn ọdọ. “Alainifẹ” ati “aṣaigbọran sí obi” ṣe apejuwe iru ipo ti ọpọlọpọ ile wa ni Amẹrika nibi ti ọkan ninu igbeyawo mẹta maa n pari si ikọsilẹ, awọn ọmọ a si di agbatọ ile-ẹjọ. Ẹgbẹẹgbẹrun awọn alaile-ko-ara-wọn-nijanu ati alailakoso ọdọ ti ko to ọmọ ogun ọdun, ni wọn ti n mu “ohun oloro” fun igbadun igba diẹ, lai pẹ jọjọ wọn a si di onroro, ati ọdaran ti o buru ju lọ nitori ki wọn ba le maa ba iwa buburu wọn lọ. Igba ewu ti de.

Awọn Woli Eke

“Abanijẹ,” “alaile-dariji-ni,” ati “onikupani” -- ọrọ wọnyi ko ṣe apejuwe kiki ọna ipolowo ati iwa awọn Ẹgbẹ-alohun-gbogbo ṣọkan ti Russia nikan, ṣugbọn wọn tun ṣe apejuwe ipo ifasẹhin ti o maa n han sita laarin awọn alaṣẹ Ijọba wa. Aṣa “Kikun oju” ti wọ aarin awọn ẹlẹsin paapaa, ti wọn si n sọọ gbangba pe ko ṣe e ṣe lati gbe lai dẹṣẹ. Awọn alagidi, ọlọkan-giga ti wọn gba oye oniwaasu ninu ẹkọ Bibeli maa n kẹgan awọn ti wọn n waasu ẹkọ ayebaye ti ironupiwada, wọn maa n fi Ẹjẹ iwẹnumọ ti Kalfari ṣe ẹlẹya; bẹẹ ni wọn si maa n ṣẹfẹ nipa pe Ọlọrun ni Kristi i ṣe: “Awọn ti wọn ni afarawe iwabi-Ọlorun, ṣugbọn ti nwọn sẹ agbara rè̩: yẹra kuro lọdọ awọn wọnyi pẹlu” (II Timoteu 3:5).

Ki i ṣe wi pe a ni awọn “oluwosan” nikan ti wọn n lọ kaakiri ti wọn fi Ihinrere Kristi ṣowo, ṣugbọn ọpọlọpọ ni o tilẹ wa ti wọn nsọ pe awọn ni iwa Ọlọrun, bẹẹ ni wọn si ti ni ọmọ-ẹhin ti o pọ jọjọ. Jesu kilọ pe: “Awọn eke Kristi, ati eke woli yio dide, nwọn o si fi ami ati ohun iyanu nla han; tobẹ bi o le ṣe nwọn o tan awọn ayanfẹ papa” (Matteu 24:24). A kilọ fun wa pe ki a máṣe fi ara wa fun itanjẹ bi o tilẹṣe pe wọn ṣe iṣẹ-iyanu nlá nlà, ṣugbọn ki a ṣe akiyesi igbesi-aye ati ẹkọ awọn ti wọn n kọ ni nipa Kristi wọnyi: “Si ofin ati si ẹri: bi nwọn ko ba sọ gẹgẹ bi ọrọ yi, nitoriti ko si imọlẹ ninu wọn ni” (Isaiah 8:20).

Iyan, Ajakalẹ-arun ati Isẹlẹ

Bá arun ẹgba ja, bá ikọẹgbẹ ja, ba arun jẹjẹrẹ ja -- oriṣiriṣi ipolowo wọnyi pẹlu aṣẹ, iṣagbe fun owo ati ọna miran gbogbo lati ko owo jọ n ran wa leti pe ajakalẹ-arun ti i ṣe ami igba ikẹhin n pọ si i ni “ibi pupọ” bi o tilẹ jẹ pe imọ iṣẹ-iṣegun igba isinsinyi n ga si i. Ìyàn paapaa ti bẹ silẹ ninu aye; irohin ijọba China sọ pe ẹgbaaji-din-igba ọkẹ eniyan ni China ni ebi n pa. Iṣẹlẹ tun jẹ nkan miran ti o n ran wa leti pe dide Oluwa sun mọ tosi. Akọsilẹ isẹlẹ ti o wa ni ọgọrun ọdun sẹhin pọ pupọ ju eyikeyi ti o ti wa lati igba ibi Kristi; ati titi di akoko yi iṣẹlẹ pupọ ti wa ninu ọgọrun ọdun ti a n lo lọ yi ju ti inu ọgọrun ọdun ti o pari ṣiwaju rè̩ lọ.

Ipoṣe ati Iyọṣuti si

Pe kikorira awọn Ju kaakiri aye lati ẹhin wa n pọ sii fi han pe Oluwa fẹrẹ de; a ko si gbọdọ gbe oju fo o da. “A o si korira nyin lọdọ gbogbo orilẹ-ede nitori orukọ mi” (Matteu 24:9). Ni akoko ti wa yi ọpọlọpọ orilẹ-ede ni o ti doju sọ awọn Ju ti wọn si pinnu lati pa wọn run; ni awọn ibomiran ẹwẹ, gẹgẹ bi orilẹ-ede wa, Ju jẹẹni è̩sín ati ikorira ni igba gbogbo.

Ami Ikẹhin

“A o si wāsu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede, nigbana li opin yio si de.” O jọ wi pe ami ti o kẹhin si dide Rè̩ ni wiwaasu Ihinrere fun gbogbo orilẹ-ede, niwọn bi a si ti le mọ, ami yi paapaa naa ti ṣẹ. N jẹ iwọ ti mura silẹ fun bibọ Rè̩?

“Kiyesi i, agbẹ a mā reti eso iyebiye ti ilẹ, a si mu suru de e, titi di igba akọrọ ati arọkuro òjo. Ẹnyin pẹlu ẹ mu sru; ẹ fi ọkan nyin balẹ: nitori dide Oluwa kù si dẹdẹ” (Jakọbu 5:7, 8). Ni Palẹstini ojo akọrọ maa n rọ lakoko ifunrugbin, arọkuro si maa n rọ ni akoko diẹṣiwaju ikore lati le mu ki eso gbo daradara. Akọrọ Ojo ti Ẹmi rọ ni Ojọ Pẹntekọsti, ki irugbin Ihinrere ti a n fun sori gbogbo ilẹ-aye le fi gbongbo mulẹ. Arọkuro Ojo ti bẹrẹ si rọ lati ọdun 1906. (Wo Ẹkọ 281). Ojo yi rọ ki o le mu eso gbọ fun ikore. “Dide Oluwa sunmọ tosi.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 S̩e apejuwe ọkọ ayọkẹlẹ ti Nahumu sọọrọ nipa rè̩.

  2. 2 Bawo ni ikọsilẹ pupọ tọkọ-taya ni orilẹ-ede wa ṣe jẹ ami igba ikẹhin?

  3. 3 Sọ apẹẹrẹ awọn eniyan ti wọn jẹ “olufẹ faji ju olufẹỌlọrun lọ.”

  4. 4 Ọna wo ni ẹkọọgbọn-ori nipa iṣẹdalẹ eniyan gba wọ inu ami bibọ Kristi?

  5. 5 Kin ni ami ti o kẹhin ti a o mu ṣẹṣaaju dide Oluwa?

  6. 6 Kin ni itumọ “ojo akọrọ ati arọkuro” nipa ti ẹmi?

  7. 7 Sọ apẹẹrẹ awọn onikupani ni akoko ti wa yi. Alaile-dariji-ni.

  8. 8 Darukọ diẹ ninu awọn isẹlẹ nla ti o ṣẹlẹ ni ọdun diẹ sẹhin.

  9. 9 Darukọ diẹ ninu awọn ajakalẹ-arun ti igba ikẹhin.

  10. 10 Sọ apẹẹrẹìyàn ti akoko wa yi.

  11. 11 Nigbawo ni Oluwa yoo de?

  12. 12 Ami wo ni o ku lati mu ṣẹ?