Lesson 363 - Senior
Memory Verse
“Ẹ jẹ ki a yọ, ki inu wa ki o si dun gidigidi, ki a si fi ogo fun u: nitoripe igbeyawo Ọdọ-agutan de, aya rè̩ si ti mura tan” (Ifihan 19:7).Cross References
I Iyawo Kristi Ri Gẹgẹ Bi Obinrin Oniwarere
1 O jẹẹni ti o ṣe e gbẹkẹle, Owe 31:10-12; Matteu 24:45-47
2 Oun a maa fi tinutinu ṣiṣẹ, Owe 31:13-19, 22-25;Gẹnẹsisi 24:18-20
3 Oun jẹ oninurere a si maa ran alaini lọwọ, Owe 31:20, 26;Orin Dafidi 112:9; Jakọbu 1:27
4 Oun ki i ṣe ọlẹ tabi alainaani, Owe 31:21, 27; Heberu 2:3
5 Ibẹru Oluwa ni o mu ki o maa so eso ti o ni iyin bayi, Owe 31:28-31; Orin Dafidi 111:10; Owe 22:4; Isaiah 11:2
II Owe Wundia Mẹwa
1 Wundia mẹwa duro de bibọọkọ iyawo, Matteu 25:1-9
2 Ọkọ iyawo de, a si pin wọn niya, Matteu 25:10-13
III Owe ti Talẹnti
1 A ṣe ipinfunni talẹnti a si mu wọn lo, Matteu 25:14-18
2 Oluwa pada bọ a si ṣe ipinya, Matteu 25:19-30
IV Iṣẹ ti a Ran si Ijọ Efesu
1 A yin ijọ naa fun ohun pupọ, Ifihan 2:1-3
2 S̩ugbọn ṣa o ti fi ifẹ iṣaaju silẹ, Ifihan 2:4
Notes
ALAYEIyawo Alailabawọn
A ṣe apejuwe iyawo Kristi gẹgẹ bi “ijọ ti o li ogo, li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi iru nkan bawọnni” (Efesu 5:27). O jẹ “wundia ti o mọ” (II Kọrinti 11:2), “o wọ aṣọọgbọ wiwẹ ti o funfun gbo” (Ifihan 19:8). Isọdimimọ -- ti i ṣe àyà funfun -- jẹọṣọ ti o ti gba nipa ẸjẹẸni naa ti o fi ara Rè̩ fun un; o si gbọdọ pa ara rè̩ mọ kuro ninu aye ni aini abawọn, ki o si maa rin ni iwa mimọ ni ọjọ aye rè̩ gbogbo. Bawo ni o gbọdọṣe maa rin pẹlu ikiyesara to, ki o le jẹọkan ninu awọn “ti a pe, ti a yan, ti nwọn si jẹ olótọ” (Ifihan 17:14). Sibẹ ipe yi ṣi silẹ fun “ẹnikẹni ti o ba fẹ” lati jẹ Iyawo Kristi.
S̩iṣe e Gbẹkẹle
Ẹ jẹ ki a ṣe akiyesi awọn wọnni ti wọn jẹ Iyawo gẹgẹ bi obinrin oniwa rere ti a ṣe apejuwe rè̩ ninu Iwe Owe 31:10-31. O ṣe iyebiye to bẹẹ ti iye rè̩ kọja iyun. Kin ni o sọọ di bẹẹ? “Aiya ọkọ rè̩ gbẹkẹle e laibẹru.” Bi o ba fa bibọ Rè̩ sẹhin fun ọdun kan tabi bi o ba fa bibọ Rè̩ sẹhin fun ọdun mẹwa, ki yoo su u, bẹẹ ni ki yio rẹẹ ki o si bẹrẹsi i fi ifẹ rẹ fun aye, ki o si maa gbá awọn ohun aye mọàya. Bẹẹ kọ! Ọkan rè̩ rọ mọ Kristi timọtimọ, Oun si gbẹkẹle Iyawo ẹ. Oun ko ni nkankan ṣe pẹlu aṣa aye yi, to bẹẹ ti yoo fi maa kun etè, maa fi ina jo irun tabi maa wọ aṣọ ti ko bo itiju. Jẹ ki wọn pe e ni ẹni ti ko gbọ faarí tabi ẹni atijọ; ọkan rẹ saa ti pinnu pẹlu Rè̩.
Panṣaga pẹlu Aye
Jakọbu ri ọpọlọpọ ti wọn ti jẹ ki aye ja ifẹ wọn gba, o si kigbe: “Ẹnyin panṣaga ọkunrin, ati panṣaga obirin, ẹ ko mọ pe ibarẹ aiye iṣọta Ọlorun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹọrẹ aiye di ọta Ọlọrun” (Jakọbu 4:4). Ijọ igbalode ti ode-oni ti ṣe panṣaga pẹlu aye, ṣugbọn wọn ki I ṣe Iyawo Kristi.
O jẹ ohun ibanujẹ lati ṣe akiyesi pe ni akoko ogun nigba ti ọpọlọpọọmọkunrin fi aya wọn ti wọn fẹran silẹ lati lọ ja fun ilu wọn; lẹhin ti wọn si lọ tan, awọn ẹlomiran wa lati gba ifẹ awọn aya wọn, wọn si fi ẹni ti o lọ jagun silẹ lati maa ṣọfọ. Pupọ awọn eniyan ni wọn n ṣe bai pẹlu ỌmọỌlọrun. Awọn ti wọn i ba jẹ olootọ si Kristi ti fun aye layè lati gba ifẹ wọn. Wọn a maa lọ si ibi igbadun aye gẹgẹ bi awọn eniyan aye ti maa n ṣe. Wọn a maa lọ si ile ijo ni alẹ, si ibi tẹtẹ ati si ibi nkan aye gbogbo. Awọn miran ti jẹ ki wahala iṣẹ gba ọkan wọn kan, itọju ohun aye si n pa wọn bi ọti, wọn si ti jẹ ki ifẹ Kristi jade kuro lọkan wọn patapata. Jesu mọọkan ti Oun le fi ọkan tan, O si n fi ọkan tan Iyawo Rè̩.
S̩iṣe Aapọn
Iyawo Kristi tayọ ki o jẹ wundia, ti a wẹ mọ ti a si wọ laṣọọgbọ wiwẹ, ti o joko ti o si gbe ọwọ le ọwọ ni ọna ẹlẹgẹ lori timtim ki o si maa reti bibọ Oluwa rè̩. Gẹgẹ bi awọn wundia ọlọgbọn, o gbọdọ ni ororo ninu kolobo rè̩ eyi ti i ṣe apẹẹrẹẸmi Mimọ. Nigba ti eniyan ba ri Ẹmi Mimọ gba, Ẹmi Ọlọrun maa n wọ inu aye ẹni naa lati maa gbe ibẹ fun idi pataki ati maa tọẹni naa, ki O si maa fun un ni agbara ati igboya ninu iṣẹ Oluwa. Bayi ni Iyawo Kristi “si fi ọwọ rè̩ṣiṣẹ tinutinu” (Owe 31:13). Oun jẹ alaapọn ninu iṣẹ ti Ọlọrun ti pe e si lati ṣe.
Ninu owe ti Talẹnti, Jesu ṣe apejuwe bi ijolootọ ati aapọn ninu iṣẹ-isin ti ṣe pataki to. Ọlọrun maa n fun wa ni anfaani fun iṣẹ-isun gẹgẹ bi agbara wa ti to. Lẹsẹkẹsẹ ti Baba Onifẹ ti n bẹ ni Ọrun ti pin awọn talẹnti ni ifẹ ti mu ki Iyawo Rè̩ bẹrẹ si i fi wọn ṣiṣẹ. “O fi oju silẹ wo iwa awọn ara ile rè̩, ko si jẹ onjẹ imẹlẹ” (Owe 31:27). Ni ibẹrẹ, boya o jọ wi pe iṣẹ rè̩ ko kọja ti awọn ara ile rè̩, ṣugbọn lai pẹ “o na ọwọ rè̩ si talaka” (Owe 31:20). O ri ẹbí ti o wa ninu aini “o fi owọ rè̩ le kẹkẹ owu,” o bẹrẹ si I hun aṣọ fun awọn ọmọde, o n bọ awọn ẹni ti ebi n pa, o si n bẹ iya ti n ṣaisan wo.
Bi awọn iṣẹ ifẹ ati iṣe-oore rẹ ti n di mimọ bẹẹ ni afo tubọ n ṣi silẹ fun iṣẹ si i. Boya a pe e lati maa lọ bẹ ile itọju alaisan wò, tabi lati maa lọ sọ itan igbala fun awọn ti o wa ninu tubu tabi fun awọn ti wọn kàn n rin kiri oju-ọna ilu wa.
Ibẹru Oluwa
O n fiye gidigidi si orukọ rere ti Oluwa rè̩ ti ko i ti i de; awọn iṣẹ ododo ti o ni iyin wọnyi si n jẹyọ lati inu ọkan rẹ ti o kun fun ọwọ ati ibẹru Ọlọrun. O jẹ ifẹọkan rẹ pe ki orukọ Rè̩ nla le ni iyin ninu ohunkohun ti oun n ṣe ninu aye.
Ororo
“O dabi ọkọ oniṣowo; o si mu onjẹ rè̩ lati ọna jijin rere wa.” Iyawo naa mọ dajudaju pe ounjẹ futẹfutẹ ti aye kò le ran oun, ṣugbọn ninu iyẹwu rè̩ o n ba Ọlọrun sọrọ nibi ti o ti n gba agbara ati oore-ọfẹ fun iṣẹ rè̩ ti o pọ, o si n mu “onjẹ” rè̩ lati ọna jijin réré wá. Igbesi-aye adura ti o n gba jẹ ki ororo nì maa sun sinu kolobo rè̩ to bẹẹ ti “fitila rè̩ kò ku li oru”.
Aini Ororo
Pataki pipa Ororo Ẹmi mọ ni a ṣe apejuwe rè̩ nipa fifi awọn wundia ọlọgbọn ati awọn alailọgbọn we ara wọn. Awọn ọlọgbọn wọle pẹlu ayọ si ibi ase igbeyawo, ṣugbọn awọn alailọgbọn nkọ? iranṣẹỌlọrun kan nigba atijọ sọ nipa wọn bayi pe: “Dajudaju, okunkun ainireti bo awọn ẹni ibanujẹ marun yi mọlẹ; wọn duro, wọn si ṣujọ si ẹnu ọna, nibi ti a ti tì wọn mọ ode pẹlu atupa wọn ti ina rẹ ti kú ti o si n fi dorodoro ni ọwọ wọn ti o n gbọn. Agogo igbeyawo ti di iro agogo ọfọ. Wọn ki i ṣe ọta ọkọ iyawo, wọn n ka ara wọn kún ọrẹ rẹ ni. Wọn fi akoko falẹ titi lai ni ohun kan ṣoṣo ti o jẹ kò-ṣe e ma-ni; ijafara naa kò si ni atunṣẹ.”
Kin ni ohun naa ti o mu iyatọ nla bayi wa laarin awọn ẹgbẹ meji yi? Gbogbo wọn ni won n reti ọkọ iyawo; gbogbo wọn ni wọn dide nigba ti igbe ta ti wọn si yi ina wọn soke lati pade rè̩. Nigba naa ni marun ri i pe awọn ti kuna lati ni ororo to. Ororo jẹ apẹẹrẹẸmi Ọlọrun. Wọn ti ṣe aibikita ni sisunmọỌlọrun timọtimọ ninu adura eyi ti i maa mu ki Ẹmi nì maa gbe inu ọkan.
Ainaani
Awọn wundia alaigbọn jẹbi ainaani nipa ti ẹmi; nitori bẹẹ a tì wọn sode kuro nibi ase igbeyawo. Ijọ ti o wa ni Efesu ti fi ifẹ rè̩ iṣaaju silẹ, o si ni lati ronupiwada. Iṣẹ rè̩, laala rè̩ ati suuru rè̩ ko ni ere kankan niwọn igba ti ifẹ akọkọ nì ti kú. A gba talẹnti lọwọọkunrin ti o ni ẹyọ kan a si gbe e sọ sinu okukun biribiri lode nitori ti o kuna lati lo o. “Awa o ti ṣe la a, bi awa kò ba nāni iru igbala nla bi eyi?” (Heberu 2:3).
Iṣipaya
Awọn ẹlomiran a maa ṣe ohun ti a ba ni ki wọn ṣe, ṣugbọn wọn ki i ri aini nla ti o wa yi wọn ka. “Ẹnyin ko ha nwipe, o ku oṣu mẹrin, ikore yio si de? wọ, mo wi fun nyin, Ẹ gbe oju nyin soke, ki ẹ si wo oko; nitoriti nwọn ti funfun fun ikore na” (Johannu 4:35). Iyawo Kristi ri i, ninu ogunlọgọọmọ-eniyan, bi ikore Ọlọrun ti pọ to ninu oko, ẹṣẹ ati ipọnju, aisan ati ìṣé̩, ijunisẹwọn ati adagbe; iwọnyi n pe e ni ija si iṣẹ. Iṣe rẹ gbogbo jẹ ti aanu, iṣẹ rè̩ si jẹ iṣẹ ifẹ ati “li ahọn rẹ li ofin iṣeun.”
Ere “Awọn ọmọ rè̩ dide nwọn si pè e li alabukunfun, ati bāle rẹ pẹlu, on si fi iyin fun u.” Ere ologo naa yoo ti to nigba ti Ọba yoo wi fun un pe: “Ẹ wa, ẹnyin alabukunfun Baba mi, ẹ jogun ijọba ti a ti pese silẹ fun nyin lati ọjọìwà” (Matteu 25:34). Ni iṣẹju naa gbogbo idanwo aye ti o ṣu dudu ti o si kun fun laalaa yi yoo parẹ kuro loju rẹ, idahun rẹ yoo si jẹ “Oluwa, nigba wo ni awa ri ti ebi npa ọ ti awa fun ọ li onjẹ? tabi ti ongbẹ ngbẹọ ti awa fun ọ li ohun mimu?” Oun yoo si dahun pe: “Niwọnbi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ, ẹnyin ti ṣe e fun mi.”
Questions
AWỌN IBEERE1 Awọn wo ni yoo jẹ Iyawo Kristi?
2 Darukọ diẹ ninu awọn iwa rere Iyawo naa.
3 Kin ni pataki jijẹ wundia nipa ti ẹmi?
4 Kin ni mu iyatọ wa laarin awọn wundia ọlọgbọn ati awọn alaigbọn?
5 Apẹẹrẹ kin ni ororo jẹ ninu Iwe Mimọ?
6 Kin ni ẹkọ pataki ti a ri di mu ninu owe awọn wundia?
7 Kin ni talẹnti?
8 Kin ni a wò ki a to pin talẹnti?
9 Kin ni oluwa naa n reti lọwọ awọn iranṣẹ rè̩ ni igba bibọ rè̩?