Isaiah 7:14; 9:1-7; 11:1-5; 42:1-4; 53:1-12

Lesson 364 - Senior

Memory Verse
“Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wa li ejika rè̩: a o si mā pe orukọ rẹ ni Iyanu, Oludamọran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia” (Isaiah 9:6).
Cross References

I Ibi Iyanu Ti Kristi

1 Ọlọrun ṣeleri igbala fun Ọba Ahasi, a fi àmì kan fun un ti i ṣe asọtẹlẹ ti igbala gbogbo agbaye, Isaiah 7:1-14; 52:10

2 A ti ipasẹ wundia kan bi Jesu, eyi si mu ọrọ nipa àmi naa ṣẹ, Matteu 1:18-25

II Ileri Imọlẹ Nla Kan

1 Awọn eniyan ilu Sebuloni ati Naftali yoo ri imọlẹ nla kan, Isaiah 9:1-5; Matteu 4:12-16; Luku 2:32

2 Jesu ni Imọlẹ aye, Johannu 1:4-10; 8:12

III Iṣẹ-iranṣẹ ati Ijiya Kristi

1 Oun jẹọlọkan-tutu ati oninuure ninu iṣẹ-iranṣẹ Rè̩, Isaiah 42:1-4; Matteu 12:15-21; Johannu 12:37-41

2 Isaiah sọ asọye nipa ti ijiya Kristi, Isaiah 53:1-12; Iṣe Awọn Apọsteli 8:32-35; I Peteru 2:23, 25

IV Ọba ti O N Bọwa

1 Ijọba yoo wa ni ejika Rè̩, Isaiah 9:6, 7; 11:1-5; Ifihan 1911-21; 20:1-5

Notes
ALAYE

Ami Kan

Awọn asọtẹlẹ Isaiah nipa Kristi pọ pupọ;wọn bẹrẹ lati igba ibi Rè̩, iṣẹ-iranṣẹ Rẹ, ijiya Rẹ, iku ati Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun Rẹ. Ni akoko kan, nigba ti Ahasi Ọba Juda, kun fun ibẹru nitori pe Siria ati israẹli dimọ pọ si ile Dafidi, Ọlọrun ran woli Rẹ Isaiah si i lati mu ki o da a loju pe Juda yoo ni Olugbala kan. Ọlọrun sọ fun Ahasi pe ki o beere “ami kan lọwọ OLUWA Ọlọrun rẹ; bere rẹ, ibā jẹ ni ọgbun tabi li oke,” ṣugbọn Ahasi pẹlu ẹmi ibọwọ fun Ọlọrun, ko jẹ beere. Nigba naa ni Oluwa sọ fun ile Dafidi pe: “Nitorina, Oluwa tikalarẹ yio fun nyin li àmi kan, kiyesi i, Wundia kan yio loyun, yio si bi ọmọkunrin kan, yio si pe orukọ rẹ ni Immanuẹli” (Isaiah 7;14). Eyi ni iṣẹ-iyanu ti yoo ṣẹlẹ, ti yoo jẹ ami fun igbala Juda.

Ibi Iyanu

O le ni ẹẹdẹgbẹrin (700) ọdun ki àmi naa to ṣẹ, ṣugbọn ni ọjọ kan a ri wundia kan “o loyun lati ọwọẸmi Mimọ wá” (Matteu 1:18). Josẹfu ẹni ti a fẹẹ fun, n fẹ kọ Maria silẹṣugbọn angẹli fara han an, o si wi fun un pe: “Josẹfu, iwọọmọ Dafidi, ma foiya lati mu Maria aya rẹ si ọdọ; nitori eyi ti o yún ninu rè̩, lati ọwọẸmi-Mimọ ni. Yio si bi ọmọkunrin kan, JESU ni iwọ o pè orukọ rẹ: nitori on ni yio gba awọn enia rẹ là kuro ninu ẹṣẹ wọn” (Matteu 1:20, 21).

“Gbogbo eyi si ṣẹ, ki eyi ti a ti sọ lati ọdọ Oluwa wa li ẹnu woli ki o le ṣẹ” (Matteu 1:22). Bi o tilẹṣe pe a ni akọsilẹ ti o ye kooro nipa ibi Jesu lọna iyanu, iṣẹ ti angẹli jẹ, ami ti woli ṣeleri rẹ ati ọrọ ti Apọsteli naa sọ gẹgẹbi a ti kọọ silẹ, sibẹsibẹ awọn alafẹnujẹ aṣiwaju Igbagbọ lode oni n sẹ iwa Ọlọrun Kristi ati ibi Rè̩ lati inu wundia. Wọn gba A si eniyan kan ṣa. Awọn olukọ igbalode wọnyi ti lọ jinna to bẹẹ ti wọn yi Ọrọ Bibeli pada si eyi ti a n pe ni Revised Standard Version ninu eyi ti wọn lo “ọdọmọbinrin” dipo “Wundia” ninu asọtẹlẹ Isaiah. Ninu eyi ati ọpọlọpọ ibomiran ni wọn ti lo ọgbọn è̩wé̩ lati ta abuku si iwa Ọlọrun Kristi. S̩ugbọn otitọ naa duro lai le yi pada: ỌmọỌlọrun ni Jesu I ṣe; ami ti a si fi fun ni nipasẹ Woli Isaiah ti ṣẹ -- a bi Olugbala nla naa nipasẹ wundia kan.

Imọlẹ Nla Naa

Ipinlẹ Sebuloni ati ipinlẹ Naftali jẹ eyi ti ogun ti fọ, ti ọpọ awọn keferi si ti sọ di ahoro; awọn eniyan ibẹ ko ni iru ọlaju ti awọn ti iha gusu ilẹ Palẹstini ni, ṣugbọn a maa n wo wọn bi alailẹkọ ati ẹlẹṣẹ. A maa n ṣe apejuwe agbegbe wọn bi ilẹ “okunkun” ati “ipínlẹ ojiji iku.” Si adugbo yi, “Galili awọn Keferi, ni Ẹni naa ti wá, ẹni ti a bi ti i ṣe Ọba awọn Ju, ẹni ti Isaiah pe orukọ rẹ ni “Iyanu, Oludamọran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia” (Isaiah 9:6).

Ileri didun naa wa si ọdọ awọn ti igbesi-aye ailofin ati isọ-di-ahoro-ogun ti mọ lara: “Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun: lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ; lati mā tọọ, ati lati fi idi rẹ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ ani titi lai” (Isaiah 9:7). Iru itanṣan imọlẹ wo ni yi! Iru ireti ologo wo ni yi fun awọn eniyan ti wọn ti di atẹmọlẹ! Imọlẹ nla naa ti tan si wọn. Si ẹsun awọn akọwe ati awọn Farisi ti wọn da A lẹbi fun fifi ara-rora pẹlu awọn ẹlẹṣẹ, Jesu dahun pe, “Emi ko wá ipe awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada” (Luku 5:32). Simeoni sọ nipa Jesu gẹgẹ bi “imọlẹ lati mọ si awọn Keferi, ati ogo Israẹli enia rẹ” (Luku 2:32).

Okunkun

“Ninu rẹ ni iye gbé wà; iye na si ni imọlẹ araiye. Imọlẹ na si nmọlẹ ninu okunkun, okunkun na ko si bori rè̩” (Johannu 1:4, 5). Imọlẹ nla naa ti o tan si okunkun Naftali ni “Imọlẹ araiye.” S̩ugbọn aye ko fẹ gba A; oye Ijọba Rè̩ ko ye wọn. “Awa gbọ ninu ofin pe, Kristi wa titi lailai. Iwọ ha ṣe wipe, A ko le ṣaima gbe ọmọ-enia soke?” (Johannu 12:34). “Nitorina nigbati ọpọ ninu ijọ enia gbọọrọ wọnyi, nwọn wipe, Lotọ eyi ni woli na. Awọn miran wipe, Eyi ni Kristi na. S̩ugbọn awọn kan wipe, Kinla, Kristi yio ha ti Galili wa bi? Iwe mimọ ko ha wipe, Kristi yio ti inu iru-ọmọ Dafidi wá, ati lati Bẹtlẹhẹmu, ilu ti Dafidi ti wá” (Johannu 7:40-42).

Lati inu ọrọ awọn eniyan wonyi a ri i pe wọn ni oye apa kan Iwe Mimọ -- wi pe Ijọba rè̩ yoo wa titi, wi pe Oun ni. “Ẽkàn lati inu kukute Jesse,” ṣugbọn wọn ko mọ pe a ni lati “pa a li ara nitori aiṣedede wa” (Isaiah 53:5). Ni igba miran wọn n fẹ fi I jẹọba, oye ko si ye wọn nigba ti O “kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o maṣe fi on han” (Matteu 12:16), bi o tilẹ jẹ pe Isaiah ti wi pe “On ki yio kigbe, bḝni ki yio gbe ohun soke, bẹni ki yio jẹ ki a gbọ ohun rẹ ni igboro” (Isaiah 42:2).

“Ọdọ-Agutan fun Pipa”

Lotitọ, Jesu ni Ẹni naa ti Isaiah sọ nipa Rẹ nigba ti o wi pe “Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wa li ejika rẹ” ṣugbọn oye ko ye awọn eniyan pe ìbí Rẹ gẹge bi eniyan jẹ apa kan ninu wiwa Rẹ. Wọn ko mọ pe wíwá Rẹ ni igba ekinni gbọdọ jẹ “gẹgẹ bi ọdọ-agutan fun pipa,” gẹgẹ bi “ẹbọ fun ẹṣẹ” (Isaiah 53:7, 10). Sibẹ Isaiah ti sọ fun wọn nipa ijiya Kristi ati ibanujẹ Rè̩.

Ọkan ninu awọn asọtẹlẹ kikun ti Isaiah fun ni ni pe: “O si ṣe iboji rẹ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu ọlọrọ ni ikú rè̩” (Isaiah 53:9). A mu eyi yi ṣẹ nigba ti a kan Jesu mọ agbelebu laarin awọn ole meji – “a ka a mọ awọn alarekọja” (Isaiah 53:12) – ati nigba ti Josẹfu ọlọrọ ara Arimatea, tẹ oku Jesu si iboji oun tikara rè̩.

Ọmọ-Alade Alaafia

Awọn asọtẹlẹ Isaiah nipa Kristi ko pari si iboji, ṣugbọn o lọ siwaju titi di ọjọ nì nigba ti “yio fi ododo ṣe idajọ talaka, yio si fi otitọṣe idajọ fun awọn ọlọkan tutu aiye; on o si fi ọgọẹnu rè̩ lu aiye, on o si fi ẽmi ètè rẹ lu awọn enia buburu pa” (Isaiah 11:4). A mu ki o da ni loju ninu Iwe Ifihan wi pe eyi ṣI n bọ wa ṣẹ. “Ninu ododo li o nṣe idajọ, ti o si njagun. … Ati lati ẹnu rẹ ni ida mimu ti njade lọ, ki o le ma fi iṣa awọn orilẹ-ede: on o si mā fi ọpa irin ṣe akoso wọn” (Ifihan 19:11-15). Lori itẹ Dafidi ni Ẹni kan yoo joko ti yoo “fi idi mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai” (Isaiah 9;7). Lẹhin pipa awọn eniyan buburu pẹlu ida ti o jade lati ẹnu rè̩ (Ifihan 19:15, 21). Ọmọ-Alade Alaafia yoo gba ijọba si ejika Rè̩ yoo si bẹrẹ ijọba alaafia ti ẹgbẹrun ọdun ti o ni ibukun (Ifihan 20:1-6), pẹlu awọn ti n fẹ rin ninu imọlẹ. “Ayọ li ẹ o fi jade, alafia li a o fi tọ nyin: awọn oke-nla ati awọn oke kekeke yio bu si orin niwaju yin, gbogbo igi igbẹ yio si ṣapẹ” (Isaiah 55:12).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Kin ni ami ti Oluwa fun ni gẹgẹ bi idaniloju igbala Rè̩ fun awọn eniyan Rè̩?

  2. 2 Darukọ diẹ ninu awọn orukọ ti a fun Kristi.

  3. 3 Nibo ni ipinlẹ Sebuloni ati ti Naftali wa?

  4. 4 Nigba wo ni Imọlẹ nla naa mọ si wọn?

  5. 5 Nigba wo ni Jesu yoo fi eemi ẹnu rè̩ pa awọn eniyan buburu?

  6. 6 Nigba wo ni Jesu yoo joko lori itẹ Dafidi?

  7. 7 Awọn diẹ wo ninu awọn gbolohun ọrọ ti o wa ninu Isaiah 53 ni n tọka si Ẹjẹ Etutu Jesu?

  8. 8 Sọ diẹ ninu awọn asọtẹlẹ kikun nipa ijiya Kristi ati imuṣẹ wọn.