Luku 24:46, 47; 14:21-23; Marku 16:15; Matteu 28:18-20

Lesson 365 - Senior

Memory Verse
“Nitorina ẹ lọ, ẹ mā kọ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si mā baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ: ki ẹ ma kọ wọn lati ma kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye. Amin” (Matteu 28:19, 20)
Cross References

I Ipe fun Iranwo Lati Makedonia

1 Jesu paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ lati waasu Ihinrere nibi gbogbo, Luku 24:46, 47; 10:1, 2; 14:21-23; Matteu 10:7-14, 23; 28:18-20

2 Kikede Ihinrere jẹ iṣẹ ti o fẹ kanjukanju, awọn eniyan Ọlọrun si ni lati maa sọ ti ihin ayọ igbala fun gbogbo ẹdá, Marku 16;15; Johannu 4:6-8, 31-38; Matteu 20:6, 7; Romu 13:11, 12; I Tẹssalonika 5:4-8; Matteu 25:24-30

3 Iran ara Makedonia ti a fi han Paulu jẹ apẹẹrẹ ipe Ihinrere fun olukuluku Onigbagbọ, Iṣe Awọn Apọsteli 16:9, 10; 26:16-20

4 Ọrọ Ihinrere ni lati lọ titi de gbogbo opin aye, Matteu 24:14; Orin Dafidi 96:3; Isaiah 42:4

Notes
ALAYE

Ikore ti o Pọn

Nigba ti Jesu dáẹlẹmi-eṣu ara Gadara silẹ lọwọ agbara ẹmi aimọ, tọkantọkan ni o fi fẹ maa tẹle Jesu lẹhin ni ibikibi ti O ba n lọ. S̩ugbọn Jesu sọ fun un pe ki o pada si ile rè̩ ki o si fi ohun nla ti Ọlọrun ṣe fun un han. Bi o si ti pada ni o bẹrẹ si rohin ni ilu rè̩ ohun nla ti Ọlọrun ṣe fun un, ati nipa ṣiṣe bẹẹ o di ajihinrere ni ilu rè̩. Ko ti i si ẹnikẹni ti o ni iyipada ọkan ni tootọ ti ki yoo ni ifẹ lati tan ihin igbala nla Ọlọrun kálẹ. Ẹmi ajihinrere ko ṣe e ya sọtọ kuro lara Ihinrere, nitori pe lati tan ọrọ Ihinrere ka gbogbo aye kan gbogbo eniyan.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan le jẹ funfun, dudu, pupa rusurusu, tabi pupa gan an, ṣugbọn ọkan naa ni ọkàn ọmọ-eniyan ni ibikibi ni agbaye. Ẹṣẹ ni ẹṣẹ n jẹ ni ibikibi ati ni iran-kiran; bakan naa ni Ẹjẹ Jesu Kristi ṣe dandan nibi gbogbo lati wẹẹlẹṣẹ nu.

Ihinrere wà fun ẹni gbogbo ati si eniyan gbogbo, o si jẹ iṣẹ idunnu fun awọn eniyan Ọlọrun lati sọ otitọ Rè̩ ni ibikibi ti a ba le ri eniyan. Ni ọpọlọpọ igba ni Ọlọrun maa n bukun awọn eniyan Rè̩, A si fun won ni ọpọlọpọ nkan ini ti aye ti o dara, alabagbe Onigbagbọ, irẹpọ, ayọ alaafia. S̩ugbọn fifun ni ni awọn nkan wọnyi duro lori idi kanṣoṣo: pe ki a le lo wọn lati ran awọn ẹlomiran lọwọ. A pa Sodomu ati Gomorra run nitori pe won gberaga, wọn ni ọpọlọpọ akara (nkan ini), wọn ya ọlẹ, wọn ko si ran awọn otoṣi ati alaini lọwọ (Wo Esekiẹli 16:49). Israẹli loni jẹẹni iyọ-ṣuti-si, awọn eniyan ti a n ṣe inunibini si nitori pe wọn kọ lati lo ohun ti Ọlọrun fifun wọn fun anfaani arakunrin kan. S̩ugbọn ibukun ni fun awọn ti wọn n sa gbogbo ipa wọn fun itankalẹ Ihinrere.

Aye tobi, awọn eniyan inu rẹ si pọ, akọmọna Onigbagbọ fun iṣẹ ni “pẹlu ikanju.” Ilẹọjọ kan ko le mọ ki a má ri ailonka ẹmi ọmọ-eniyan ti yoo kọja lọ si ayeraye, igbesi-aye ti wọn si ti gbe ti yanju ayè ti wọn yoo wa ni ayeraye. Ki iṣẹỌlọrun si le tete tẹ siwaju ni Oluwa ṣe n pe gbogbo Onigbagbọ pe: “Ẽṣe ti ẹnyin fi duro lati onimoni li airiṣe?…Ẹ lọ pẹlu sinu ọgba-ajara; eyi ti o ba tọ li ẹnyin o ri gba” (Matteu 20:6, 7). IṣẹẸmi Mimọ ni lati da awọn ẹlẹṣẹ lẹbi ẹṣẹ wọn, lati ba ni wi, lati pe awọn eniyan wa si idajọ, ati lati sọ ohun ti n bọ wa. ỌmọỌlọrun, paapaa ẹni ti a ti sọ di mimọ, ti a si ti fi Ẹmi Mimọ wọ -- pẹlu itọni ati iṣakoso Ẹmi Mimọ -- yoo jade lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun, yoo si maa ba Ẹmi Mimọṣiṣẹ ni ifọwọ-so-wọ-pọ.

Nigba ti awọn ọmọ-ẹhin de ba Jesu nibi ti o ti n ba obinrin ara Samaria sọrọ ni ibi kanga Jakọbu, wọn sọ fun Un pe ki O jẹun. O sọ fun wọn pe Oun ni ounjẹ lati jẹ ti wọn kò mọ. Nitori ti òye ohun ti O n sọ kò ye wọn, wọn rò pe ẹni kan ti mu ounjẹ wa fun Un. S̩ugbọn O wa ṣe alaye fun wọn pe ounjẹ ti Oun ni ti o si maa n fun Oun lagbara ni lati ṣe ifẹ Baba Oun ti o ran Oun, ati lati pari iṣẹ naa. Ni ọna bayi ẹsẹ olukuluku ọmọỌlọrun maa n fẹrẹ lọna ajo yi nipa mimọ daju pe oun n ṣe ifẹ Baba. Iru imọ bayi ni ọpọlọpọ igba a maa dabi ẹni pe ki i tilẹ jẹ ki o rẹ awọn Onigbagbọ tabi ki agara da wọn lati maa polowo Ihinrere. Iṣẹ Baba ni ohun ti o jẹ okàn ati ayé Kristi run, a si sọ eyi nipa Rè̩ pe: “Nitori ti itara ile rẹ ti jẹ mi tan” (Orin Dafidi 69:9). Lilakaka lati ṣe ifẹ Baba Rè̩ lo jẹ igbesi-aye Kristi run; bakan naa gẹgẹ bi iwọn agbara ati oore-ọfẹ ti Ọlọrun fi fun ni, Onigbagbọ gbọdọ ni ifẹ kan ati itara ti o bori ifẹ tabi itara miran fun ọkàn awọn eniyan.

A ni ojuṣe kan niwaju Ọlọrun. Ẹ máṣe jẹki oju wa fọ si ohun ti o yẹ ki a ṣe. A ni lati gbadura gidigidi pe ki Ọlọrun le mu ọgọọrọ eniyan wọnyi ti aarẹ ti mu, ti ọkàn wọn si kún fun ẹṣẹ wa si ile, ati pe ki Ọlọrun le fun wa ni ago omi tutu kan lati fun wọn mu – ago itunu, ti Ihinrere pe ọna kan wà lati kuro ninu ẹṣẹ ati ọna lati sala kuro ninu ikú ayeraye nipa iku ati ajinde Jesu Kristi.

Gbogbo wa ko le jade lọ si gbogbo orilẹ-ede. S̩ugbọn a dupẹ lọwọỌlọrun pe o ti fun wa ni anfaani lati lọ si gbogbo agbaye nipa adura ati nipa ikaanu ọkàn ti o maa n mu agbara Ọlọrun sọkalẹ lati gbala, lati sọdimimọ, lati fi Ẹmi Mimọ ati iná wọni – ti n mu ọkan jade kuro ninu okunkun wa sinu imọlẹ. Awọn ti ko le jade lọ le fi ohun ini wọn ṣe iranlọwọ; wọn le fi tọkantọkan ṣe ohunkohun ti ọwọ wọn ba ri ni ṣiṣe -- kikọ ile Ọlọrun, titọju awọn alaisan, tabi sisọ Itan Irapada ni ẹba ọna, tabi lilọ si ile itọju awọn alaisan, titan Ihinrere kalẹ nipa pipin awọn iwe itankalẹ Ihinrere, tabi ṣiṣe ohunkohun ti Ọlọrun ba fun wọn lati ṣe. Ohunkohun ti a ba si ṣe, ẹ jẹ ki a ṣe e, ki i ṣe fun iyi ati ogo ara wa, ṣugbọn ki o jẹ fun ọla ati ogo Ọlọrun nikan.

Awọn Ajihinrere, ni Ile ati Lokeere réré

Pupọ awọn ẹgbẹ Onigbagbọ ati awọn ẹgbẹ ijọ miran ni o pin eto iṣẹ itankalẹ Ihinrere si ipa meji; awọn ti n bojuto iṣẹ-iranṣẹ ti ile, ati awọn ti n bojuto iṣẹ ijọ ti okeere. Awọn ti n bojuto iṣẹ ti ile nigba gbogbo a maa sa gbogbo agbara ti wọn ba le sà lati waasu ati lati jere ọpọlọpọọkan ni ile ati ni gbogbo agbegbe. Kikọ awọn ile-isin ni agbegbe ati fifi ẹsẹ awọn Onigbagbọ mulẹ ni ile ni a n pe ni “abojuto iṣẹ ti ile.” A ko gbọdọ rò pe ṣiṣe abojuto iṣẹ-iranṣẹ ti ile ko gba agbara tabi pe ko ṣe danindanin bi ṣiṣe abojuto iṣẹ iranṣẹ ti ilẹ okeere. Ni igba miran, o maa n jẹ pe nipa iranlọwọ awọn Onigbagbọ ti o wa nile ni iṣẹ ilẹ okeere fi le maa lọ deedee.

Nibi ti awọn eniyan ba jẹ alakikanju ninu abojuto iṣẹ ti ile, won a maa saba ya bàra si iṣẹ miran ti o tun tobi. Otitọ si ni pe nigba ti awọn ẹgbẹ Onigbagbọ kan ba ran ninu wọn jade lọ si ilẹ okeere lati lọ waasu Ihinrere, Ọlọrun maa n bukun ijọ ti o wa nile ki wọn ba le ṣe iranwọ fun awọn ti o jade lọ.

Apẹẹrẹ pataki awọn ẹgbẹ ajihinrere bawọnyi ni Ẹgbẹ Ajumọka Bibeli kan ti awọn atukọ Onigbagbọ ti inu ọkọ oju-omi, ti o n gbe ọkọ ofurufu, ṣe onigbọwọ fun lakoko ogun ajakaye keji. Orukọọkọ oju-omi naa ni U.S.S. Enterprise. Awọn ọmọkunrin wọnyi ko ẹgbẹ atan-Ihinrere-kalẹ kan jọ lati ṣe itilẹhin fun isin ti wọn n ni deedee ninu ọkọ, fun idi pataki lati le jere diẹ ninu awọn ẹlẹgbẹ wọn ninu ọkọ fun Kristi. Bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ wahala ni o wa fun awọn oṣiṣẹ inu ọkọ ni akoko ogun, sibẹ a ri awọn ọkunrin ti o gba Kristi gbọ. Pẹlupẹlu, Ẹgbẹ Ajumọka Bibeli yi tun ni ipa ti o ṣe pataki ninu abojuto iṣẹ okeere. Awọn ọkunrin wọnyi jẹ ajihinrere tootọ, wọn si ṣiṣẹ lati jere awọn ti o wa ni tosi wọn, bẹẹ ni wọn si tun ṣe iranlọwọ fun awọn ti wọn n ṣiṣẹ okeere.

Si Gbogbo Ẹda

O jẹ ifẹỌlọrun ti o han gbangba pe ki gbogbo ọkan ti o wa laaye mọ nipa oore-ọfẹ Kristi ti o n gbala. Ọlọrun ti bukun olukuluku ẹni ti n lakaka, i baa ṣe awọn diẹ tabi awọn pupọ lati mu aṣẹ Jesu ṣẹ pe, “Ẹ mā wasu Ihinrere fun gbogbo ẹda.”

Ni Gbogbo Ede

Charles Wesley kọ akọsilẹ pe, “Emi ’ba l’ẹgbẹrun ahọn fun’yin Olugbala.” Bi o tilẹ jẹ pe o ṣoro fun ẹni kan ṣoṣo lati korin iyin si Oluwa ni ẹgbẹrun èdè, sibẹ o ti ṣe e ṣe nipa iwe titè̩. Ninu irohin wọn fun ọdun 1952, Ẹgbẹ Olutẹ Bibeli ti ilu Amẹrika sọ gbangba pe Bibeli, tabi apa kan ninu rè̩ ni awọn ti tẹ ni ọtalelẹgbẹrun o din ookan (1,059) èdè. A ti tẹ gbogbo Bibeli jade ni igba-din-mẹta (197) èdè, a ti tẹ Majẹmu Titun jade ni ọtalerugba èdè o din mẹta (257) ati pe o kere tan, wọn ti tẹ Ihinrere kan tabi awọn odindi ori Iwe Bibeli miran ni arunlelẹgbẹta (605) ede. O tun ku aadọrun (90) ede miran ninu eyi ti wọn ti tẹ diẹ ninu ori Iwe kan ninu Bibeli.

Onipsalm sọ pe, “Oluwa ti sọrọ: ọpọlọpọ si li ogun awọn ẹni ti nfi ayọ rohin rẹ” (Orin Dafidi 68:11). Iṣẹ titẹ Iwe Ihinrere ti inu Bibeli jade ti o si n ṣe iyipada ọkan awọn ẹlẹṣẹ jẹ eyi ti o fara sin fun aye gidigidi. S̩ugbọn o n lọ lojoojumọ, nipa ọwọ awọn diẹ ti wọn fara wọn rubọ, o si fara jọ owe ti iwukara ati akara pupọ. Iwukara ti a fi pamọ ninu oṣuwọn iyẹfun mẹta, ti sọ gbogbo akara di wiwu. (Wo Matteu 13:33). A kò sọ ninu iwe Mimọ pe gbogbo aye ni yoo yipada si Kristi, ṣugbọn a sọ pe: “A o si wāsu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède, nigbana ni opin yio si de” (Matteu 24:14).

Lati iran kan de ekeji ni a ti n waasu Ihinrere pẹlu idoju-ija-kọ kikoro. Awọn eniyan ti o tumọ Bibeli si awọn ede miran, nigba pupọ ni wọn tun maa n fi ẹmi wọn lelẹ fun iṣẹ yi ti wọn ti ṣe. Ọlọrun ko fi ara Rè̩ silẹ lai ni ẹlẹri, ko si si iwe kan ti a tẹ jade ri ti o ti i lokiki bi Bibeli. Lati ọdun de ọdun, oun ni “Iwe ti o ta ju lọ” ninu gbogbo iwe. Ni ọdun 1952 awọn Ẹgbẹ Olutẹ Bibeli ti ilu Amẹrika ta adọtalelẹgbẹta ọkẹ (13 million) Bibeli ati Majẹmu Laelae ati Titun kaakiri.

Bi o tilẹ jẹ pe a ni awọn eniyan ti o ni ero ti o lodi, ko ti i si ohun kan ti o fa ọkan eniyan kọọkan mora bi Bibeli, nitori pe o jẹ iwe iye ati iwe ayeraye. O sọ nipa ifẹỌlọrun fun eniyan kọọkan, oun si ni aworan ọna si Ọrun. A le ri i bi o ti wu eniyan to ninu apẹẹrẹ awọn eniyan ti wọn n gbe Erekusu Hebrides niha guusu okun Pacific ni iwọn ọdun diẹ sẹhin. Gbogbo awọn eniyan wọnyi para pọ, wọn si ṣiṣẹ fun ọdun marun lati ri owo ra ẹrọ itẹwe Bibeli ni ede wọn, ki woṅ le ka nipa Ẹni ti o fẹran ọkan wọn, ti O si fi ara Rè̩ fun wọn.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Nibo ni Jesu ti paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ pe ki wọn waasu Ihinrere?

  2. 2 Kin ni idi ti iwaasu Ihinrere fi mu kanjukanju lọwọ?

  3. 3 Kin ni itumọ gbolohun ọrọ yi: “Ipe Makedonia”?

  4. 4 S̩e alaye Ọrọ yi: “abojuto iṣẹ ti ile” ati “abojuto iṣẹ ti okeere”.

  5. 5 Oriṣi ede melo ni a ti tẹ apa kan Bibeli jade?

  6. 6 Iwe wo ni o ni okiki ju lọ ninu gbogbo iwe ni gbogbo igba?

  7. 7 S̩e alaye ohun ti Jesu ni lọkan nigba ti O wi fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ pe Oun ni “onjẹ” ti wọn kò mọ.