Romu 8:1-39

Lesson 353 - Junior

Memory Verse
“Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọjujasi wa?” (Romu 8:31).
Notes

Idalẹbi fun Ẹṣẹ

Paulu le sọ pẹlu gbogbo ọkan rè̩ pe, Njẹẹbi ko si nisisiyi fun awọn ti o wa ninu Kristi Jesu.” Jesu ti da a nide kuro ninu ẹṣẹ, O si jẹ Oluwa rè̩.

Idalẹbi ọkan ni o n mu ki ara eniyan ko tiọ, ki oju ki o ti i, tabi ki o ni ẹbi ẹṣẹ ninu ọkan fun iṣe buburu tabi nitori ọrọ aidara ti o sọ. Gẹgẹ bi iṣudẹdẹ idalẹbi ikuukuu ti i tan ka oju-ọrun ti si i bo oorun, bẹẹ gẹgẹ ni iṣudẹdẹ n tan bo oju ọkan eniyan, a si pa oju Ọlọrun mọ nigba ti ẹni naa ba da ẹṣẹ. Iyọnu Ọlọrun kò si lori ẹni naa; itanṣan ogo Ọlọrun ko si si ninu ọkan naa. S̩ugbọn idalẹbi a maa bo ọkan yi bi ikuukuu ti o nipọn. Irisi oju eniyan paapaa a maa saba fi idalẹbi ti o wà ninu ọkan han.

S̩ugbọn nigba ti ẹni naa ba wa Ọlọrun ti o ba si ronupiwada ẹṣẹ rè̩, ti o si ri idariji ẹṣẹ gba, ati ti o tọrọ idariji lọwọ awọn wọnni ti o ti ṣẹ, gbogbo idalẹbi yoo kuro ninu ọkan rè̩, yoo si bọ lọwọẹbi ẹṣẹ. Nigba naa ni yoo le wi pe kò si idalẹbi mọ nisinsinyi.

Nigba kan ri Paulu ni idalẹbi nla ninu ọkan rè̩. Satani ni o n ṣe oluwa rè̩, Paulu si n gbọran si i lẹnu pẹlu. Nigba ti ẹni ibi ni ba sọ fun Paulu pe ki o ṣe inunibini si awọn eniyan Ọlọrun, ki o dè won ki o si fi wọn sinu tubu, oun a si ṣe bẹẹ. S̩ugbọn gbogbo iwọnyi ni o yi pada ninu igbesi-aye Paulu lọjọ naa ti o pade Jesu ni ọna Damasku. Wo bi itanṣan imọlẹ naa ti mọlẹ to lori rè̩ ati bi iṣudẹdẹ okunkun ti o bo o mọẽ ti to ni oju ọna rè̩ si ilu Damasku! Wo bi idalẹbi yi ti le jinlẹ to ninu ọkan Paulu nigba ti o wa ye e pe Jesu ti Nasarẹti ati awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ ni oun n pa lara! O ba a ninu jẹ -- ani lọpọlọpọ; o bẹ Jesu pe ki O dariji oun. Nigba ti Paulu ri igbala, gbogbo idalẹbi ni o kuro ninu ọkan rè̩. Bi ipé̩pẹ ti n bọ kuro ni oju rè̩, o riran, lẹsẹkẹsẹ Paulu bẹrẹ si i ṣiṣẹ fun Jesu Kristi, ẹni ti i ṣe Oluwa rè̩ titun.

Oluwa Meji

“Ko si ẹniti o le sin oluwa meji” (Matteu 6:24). Ẹni kọọkan ni o n sin Kristi tabi Satani. O ṣe e ṣe ki eniyan paarọ oluwa ti o n sin, ohun ti Paulu ṣe gan an ni yi.

O le beere, “Bawo ni emi ṣe le ni Kristi bi Oluwa mi?” Lọna kukuru, nipa gbigba adura atọkanwa si Ọlọrun, ni bi bẹẸ pe ki O dari awọn è̩ṣẹ rẹ ji ọ, ati ni sisọ fun Un pe iwọ yoo sin In. A ka ninu Ọrọ Rè̩ pe, Ẹniti o ba si tọ mi wa, emi ki yio ta a nù, bi o ti wu ki o ri” (Johannu 6:37). Nigba ti Ẹjẹ Jesu ba bo ọkan rẹ, gbogbo è̩ṣẹ rẹ ni a o fi ji; iwọ yoo si ni inudidun ati ominira. A o mu idalẹbi kuro ninu ọkan, iwọ yoo si ni agbara maa lọ má dẹṣẹ mọ. Ibẹrẹ igbesi-aye titun! Ọkan titun! Oluwa ọtun lati sìn! “Njẹ bi a si ti nda wa lare nipa igbagbọ, awa ni alafia lọdọỌlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi” (Romu 5:1).

Ewu ti o wa ninu Ẹṣẹ

Oluwa onroro ni Satani jẹ fun eniyan lati sin. A maa ṣeleri inudidun, ilera, ọrọ ati iye; ṣugbọn a maa fi ijatilè̩, aisan, oṣi ati iku rọpo wọn. Ma ṣe tọwọ bọẹṣẹ; máṣe ro pe o le fi ibi ṣiré. Ma ṣe ro pe iwọ le jẹ igbadun awọn è̩ṣẹ wọnni ti o dabi ẹni pe o kere diẹ pẹlu “faaji ailewu” wọn, ṣugbọn lai pẹ iwọ yoo ri i pe o ti bọ sinu awọn è̩ṣẹ ti o tobi ti o mu faaji ipalara nla lọwọ eyi ti o le mu ọkan rẹ lọ sinu ijiya ayeraye. Lọ kuro ninu ẹṣẹ loni. Bi iwọ ko ba yago fun ẹṣẹ, ẹṣẹ yoo pa ọ.

Ni ibi diẹ leti okun ni England ati Skọtland, o maa n digba ṣẹlẹ pe eniyan ti o n rin lori iyanrin yoo ri i pe lojiji iyanrin naa dabi ẹni pe o ṣe mọdẹmọdẹ, a si ri i pe o n lẹ mọ bata oun. Eti okun naa le dabi ibi gbigbẹ, ṣugbọn ipa ẹsẹ rè̩ yoo kun fun omi. Eniyan tilẹ le maa rin lọ lai fura si ibi ti o wa niwaju rè̩. S̩ugbọn lojiji iyanrin bo ẹsẹ rẹ mejeeji. O yipada, ṣugbọn bi o ti n gbe ẹsẹ ni kọọkan ni ẹsẹ rè̩ n wọlẹṣinṣin si i. Pẹlu àya jija, o ri i pe oun n rì sinu ilẹ rirọ. O sọẹru ori rẹ kalẹ, ṣugbọn o ti pẹ jù. Lai pẹ, iyanrin yi mu un de orukún, de ibadi, de igba-àya, de ọrùn, o figbe ta, ṣugbọn lai pẹ rara, iyanrin rọ kun ẹnu rè̩, a si pa a lẹnu mọ. Lẹhin eyi, iyanrin bo o loju, oun a si ba ara rẹ ninu okunkun biribiri ti iku! Ewu ẹṣẹ dida ti fara jọ eyi to! Ewu ti o wa ninu ẹṣẹ dida le má tete fara han bi ti ilẹ-iyanrin, ṣugbọn o lagbara bẹẹ gẹge. Lakọkọ “okele didun,” lẹhin naa yoo di bárakú, ati lai pẹ rara yoo ba ara rè̩ ninu ewu takute ti n bo ni mọlẹ kiakia ti o si n ran ni lọ sinu iparun. Apa kan ṣoṣo ni o le ṣe iranwọ lakoko ajaly yi; Ẹni kan ni o le gba ni la kuro lọwọ ikú. “Ki o si kepè mi li ọjọ ipọnju; emi o gbàọ” (Orin Dafidi 50:15).

Ere lẹhin Ijiya

O jẹ iranlọwọ nla fun Paulu lati ni Oluwa titun yi, Jesu Kristi -- bẹẹ ni, Baba titun, ani Ọlọrun tikára Rè̩. Eleyi sọ Paulu di ajogun ijọba kan, bi o tilẹ jẹ pe diẹ ni awọn ohun ini rè̩ laye. Paulu mọ pe bi oun ba ba Jesu jiya nihin ninu aye, a o ṣe oun logo pẹlu Rè̩ lọjọ kan. O mọ wi pe “ade ododo” (II Timoteu 4:8), n duro de oun.

Bi a ba jiya diẹ fun Kristi, kin ni o jé̩? A ko le fi eyi ṣe akawe ogo ti o n bọ, ni Paulu wi. Nigbakigba ti o ba ni ero pe igbesi-aye Onigbagbọ jẹ sisẹ ara ẹni kuro ninu jijẹọpọlọpọ faaji ayé, fi inu ṣiro ohun ti Paulu wi: “Nitori ero ti ara iku ni” (Romu 8:6). Nigba ti iwọ ba ro pe boya awọn eniyan ti ayé n jẹ igbadun faaji aye ju iwọ ti o jẹ Onigbagbọ, ronu nipa Paulu ti o wi pe: “Bi ẹnyin ba wa ni ti ara, ẹnyin o ku.” Ronu igbẹhin. Ronu ọjọ naa ti ẹni-giga, ẹni-rirẹlẹ, olowo, ati talaka yoo duro niwaju Onidajọ ododo. Nigba naa, kin ni yoo jẹ ipin awọn wọnni ti o n gbe igbesi-aye wọn fun igba isinsinyi nikan? Iwọ wi pe, “ṣugbọn nigba ti mo ba pinnu lati sa ipa ju ti atẹhinwa lọ pẹlu ọpọ adura, mo maa n ni wahala ti o pọ ju igba ti mo wa ni ko-gbona-ko-tutu.” Eleyi le jẹ otitọ, ṣugbọn iwọ yoo ni oore-ọfẹ ti o pọ ju ti atẹhinwa lati la wahala wọnyi ja. Paulu ti kẹkẹ pe ohunkohun ti o wu ki wahala tabi idanwo le jẹ “ohun gbogbo li o n ṣiṣẹ pọ si rere fun awọn ti o fẹỌlọrun” (Romu 8:28). Nitori naa bi Satani ba gbiyanju lati dan ọ wo ni ọna yi nipa fifi awọn ohun idigbolu si ọna rẹ, iwọ sa wi pe: “Mo le ṣai mọ idi rẹ ti eyi fi de si mi, ṣugbọn emi mọ pe mo fẹ Oluwa pẹlu gbogbo ọkan mi, Oun si fẹran mi, Oun ko jẹ fi àye silẹ pe ki eyi de ba mi bi ko ba ṣe pe fun ire mi ni.’

Ifẹ Kristi

Paulu pari ori-iwe yi pẹlu ibeere ati idahun rè̩. “Tani yio ha ya wa kuro ninu ifẹ Kristi?” Wahala, airijẹ tabi airi aṣọ bora, ewu, ogun, iku, iyẹ, awọn angẹli, awọn alagbara, ọna jijin tabi eniyan – ko si ọkan ninu awọn wọnyi ti o le ya wà kuro ninu ifẹ Kristi. Ifẹ Rè̩ ki i yẹ lae.

Eyi ha tumọ si pe nigba ti eniyan ba ti ri igbala lẹẹkan ko tun le ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ mọ ki o si ṣegbe? Bẹẹkọ, ki i ṣe bẹ rara. Otitọ ni pe ifẹ Kristi ki i yipada, ṣugbọn bi ko ba ṣe pe eniyan sun mọỌn girigiri nipa ṣiṣọna ati kika ỌrọỌlorun nigba gbogbo pẹlu ọpọ adura, ifẹ eniyan si I le di tutu. Bi ifẹ oluwarẹ ba di tutu, o wa lori ilẹ ti o lewu, nitori bi o ba ti n rin jinna si Oluwa to, bẹẹ ni o n lọ sinu aye to, ati pe lai pẹ jọjọ ko tun ni jẹọmọ Baba mọ. Lẹẹkan si i iṣudẹdẹ idalẹbi ọkan yoo kun igbesi-aye rè̩. Iwọ ha ti bọ lọwọ idalẹbi ọkan?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ẹri tani a kọ silẹninu Romu 8?

  2. 2 Kin ni itumọ ririn nipa ti ara? Ririn nipa ti ẹmi?

  3. 3 Bawo ni a ṣe le mọ bi a ba jẹọmọỌlọrun?

  4. 4 Kin ni itumọ ki a ya ni nipa kuro ninu ifẹ Kristi?

  5. 5 “Bi Ọlọrun ba wà fun wa, tani yio kọjujasi wa?”

  6. 6 Tani ohun gbogbo n ṣiṣẹ pọ si rere fun?

  7. 7 Bawo ni àkawé ijiya ti Onigbagbọ nisinsinyi ti ri pẹlu igba ti o n bọ?

  8. 8 Kin ni itumọ wiwà ninu ero ti ara? Wiwà ninu ero ti Ẹmi?