Lesson 354 - Junior
Memory Verse
“Bi on ti jẹọlọrọ rí, ṣugbọn nitori nyin o di talaka” (II Kọrinti 8:9).Notes
Paulu Onde
Nitori pe Paulu n waasu nipa Jesu, a ti sọọ sinu tubu ni Romu, ni Itali. Ki i ṣe ọdọmọkunrin mọ, o si jẹ ifẹọkan rè̩ lati wà pẹlu awọn eniyan Ọlọrun ninu awọn ijọ ti o ti da silẹ. Yio ti dun mọọ to lati tun di omnira lẹkan si i.
S̩ugbọn ko rẹwẹsi, nitori o gbagbọ pe nipa adura awọn Onigbagbọ a o tu oun silẹ laipẹ. Nigba ti o wà nibẹ, o kọ awọn iwe iṣiri si awọn eniyan Ọlọrun, awọn iwe wọnyi ti o jẹ ati ọwọỌlọrun wa jẹ apakan Iwe MimọỌlọrun ti a n pe ni Bibeli.
Awọn irin, ẹwọn ati è̩ṣọ ile-tubu kò le de ẹmi ọmọỌlọrun tootọ. “Ọkàn ati ẹri-ọkàn awọn baba wa wà li ominira sibẹ, biotilẹṣepe wọn wà ninu ide ṣẹkẹṣẹkẹ ninu ile-tubu ti o ṣokunkun.” Eniyan Ọlọrun kan ti a sọ sinu tubu sọ pe wura li a fi bo awọn ẹwọn ti a fi de e. Onde miran fun Oluwa wi pe awọn okuta ti a fi kọ ile-tubu na dabi iyùn.
Ẹniti a yi lọkan pada
Bi Paulu ti joko, pẹlu kalamu lọwọ rè̩, ọkàn rè̩ ti o kun fun ifẹ nla lọ sọdọ awọn ẹlomiran. A kò mọ iye awọn eniyan ti a gbala nipa sẹ iṣẹ-iranṣẹ Paulu, ṣugbọn ọkan ninu ọpọ eniyan ti o wa sọdọ Jesu lati ọwọ Paulu ni ọdọmọkunrin kan ti a n pe ni Onesimu. Ọdọmọkunrin yi, ẹni ti i ṣe iranṣẹ Filemoni ni ilu Kolosse, di alaini inudidun o si ti sa kuro lọdọ oluwa rè̩ lọ si Romu. Gẹgẹ bi ẹru ti o sa, o ṣeeṣe ki a ti fi ipa mu Onesimu lati di ọmọ-ogun Romu ti a yan lati ṣọ Paulu. Ni kukuru, o ti gbọ ti Paulu n sọ nipa Jesu, o si ti di Onigbagbọ.
Lọjọ oni paapa awọn onitubu ati awọn ounde ma n gbọ nipa Jesu nigba ti awọn oṣiṣẹ Ihinrere ba lọ si awọn ile-tubu lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa ohun ti Ọlọrun ṣe fun wọn, ati nigba ti wọn ba n pin iwe-itankalẹ Ihinrere. Ọpọlọpọ li o ti ni idalẹbi ọkàn fun è̩ṣẹ ti a si ti gbala nipsẹ iṣẹ bayi.
Nisisiyi ti Onesimu ti ri igbala o le jẹ oluranlọwọ fun Paulu. Inu wọn yio ti dun to laarin awọn wakati wọnni ti wọn jọ lo pọ ninu idapọ ti Onigbagbọ! Adura ati kikọ orin iyin wọn si Ọlọrun yoo ti pọ to!
Pipada lọ si ọdọ oluwa rẹ
S̩ugbọn Paulu kò huwa anikanjọpọn ki o si da Onesimu duro sọdọ ara rè̩ nibẹ. O gbọdọ ran an pada lọ sọdọ Filemoni oluwa rè̩. Yoo ha tẹwọgba Onesimu bi? Yoo ha gba a pada si ipo rè̩ gẹgẹbi iranṣẹ? tabi yoo ṣe alaiyọnu si i nitori sisalọ ti o ti salọ. Ki i ṣe pe Onesimu huwa lodi si orukọ rè̩ nikan itumọ eyiti iṣe “li èrè,” ṣugbọn o ti ṣẹ oluwa rè̩ pẹlu. Paulu yoo kọ iwe si Filemoni yoo si fi ran Onesimu; nigba naa ohun gbogbo yoo bọ si titọ.
Iwe Paulu
Episteli ti Paulu si Filemoni, tabi Iwe Filemoni, jẹ iwe ti Paulu kọ ti o si bẹbẹ pe ki Filemoni gba Onesimu pada si ibi iṣẹ rè̩ lẹẹkan si i. Paulu mọ pe ifẹ nla ti Filemoni ni ninu ọkàn rè̩ yoo jẹ ki o le dariji iranṣẹ yi ti o ti huwa aiṣootọ lẹkan ri. Yoo si tẹwọ gba Onesimu, ki iṣe gẹgẹbi iranṣẹ lati maa ba iṣẹ rè̩ lọ nikan, ṣugbọn yio gba a gẹgẹ bi arakunrin ninu Kristi ati gẹgẹbi oṣiṣẹ rere fun Oluwa pẹlu.
Atunṣe
Onesimu nfẹ lati mu ohun gbogbo ti o wọ ti o ti ṣe si oluwa rè̩ bọ si titọ. Olukuluku ẹlẹṣẹ ti o ba ronupiwada è̩ṣẹ rè̩ ti o si ri idariji gbà nfẹ lati mu awọn ohun ti o wọ bọ si titọ. Bi o tilẹ jẹ pe o le ma jẹ ohun ti o rọrun lati ṣe, sibẹsibẹ yoo tọ awọn ti o ti ṣe aidara si lọ yoo si beere fun idariji; yoo san awọn owo ti o ti ji pada tabi eyiti o ti fi ọna eru gbà; yoo jẹwọ awọn irọ ti o ti pa, yoo si mu ohun gbogbo ti o wà ni ipa rè̩ bọ si titọ. “Bi enia buburu ba mu ògo pada, ti o si san ohun ti o ti ji padà, ti o si nrin ni ilana ìye li aiṣe aiṣedẽde; yiyè ni yio yè, on ki o kú” (Esekiẹli 33:15).
Onesimu ko ṣe atunṣe laisi iranwọ, bakanna ni iwọ tabi emi kò le ṣe atunṣe laisi iranwọ. Paulu ba Onesimu ṣipẹ, Kristi yoo jẹ oludamọran lọjọ oni fun olukuluku ti o ni atunṣe lati ṣe (Isaiah 9:6). Bi a ba beere pe ki o tọ wa ati ki O ṣamọna wa, Oun yoo ran wa lọwọ lati mọọna ti o dara julọ lati ṣe atunṣe wa, ati pe Oun yoo ran ẹniti a ti ṣẹ lọwọ lati ni oye ohun ti a n sọ ati lati dariji.
Ere inu-rere
Nigba miran a ma n huwa rere tabi ki a ṣoore fun eniyan nitori ti ẹlomiran. A ka ninu Bibeli nipa ọmọkunrin kekere kan ti o yarọ lati igba ti o jẹọmọọdun marun pere. Jonatani, ẹniti i ṣe baba ọmọkunrin yi ti jẹọrẹ kori-kosun Dafidi. Lotitọ, Dafidi ati Jonatani fẹran ara wọn lọpọlọpọ. Nigba ti Dafidi jọba, o ranṣẹ si ọmọ-kunrin arọ yi o si wi fun un pe ki o máṣe bè̩ru. O ni oun yoo ṣoore fun un nitori ti Jonatani baba rè̩, ati pe oun yoo fun un ni ọpọọrọ, ati pe ni gbogbo ọjọ-aye rè̩ yoo ma jẹun lori tabili ọba. Dafidi ko gbagbe iṣẹ-oore Jonatani si i, anfaani si ṣi silẹ fun un nisisiyi lati ṣe oore fun Mefiboṣeti, arọ (Ka II Samuẹli 4:4; 9:5-7).
Nitori ti Ẹlomiran
Paulu fi gbolohùn ọrọ kan kun iwe rè̩ si ọrẹ rè̩ pe ki o tẹwọgba Onesimu gẹgẹbi o ti le tẹwọgba Paulu: njẹ Onesimu jẹ oluwa rè̩ ni igbese ohun kan bi? O ha ti ṣẹ Filemoni bi? Bi o ba ri bẹẹ, Paulu wi pe “Kà a si mi lọrun.” “Emi o san a pada.”
Nigbati ọmọde ba tọỌlọrun wa, ti o si yi pada kuro ninu è̩ṣẹ rè̩ ti o si bẹbẹ fun idariji è̩ṣẹ rè̩, jesu yoo gba ẹjọ rè̩ ro yoo si wi pe, “Baba, gba a gẹgẹ bi emi tikarami. Emi ta Ẹjẹ mi silẹ mo si ku ki a ba le dari ji i.” Ẹlẹṣẹ yi ti ṣẹ si Ọlọrun, ṣugbọn nigbati o ba wa pẹlu ironu pi wada, Ọlọrun yoo dariji nitori ti Jesu.
Pada bọ Sile
Irin ọna jijin pada si Kolosse dopin nigba ti Onesimu pada sọdọ Filemoni. Onesimu dabi ọmọ oninakuna ẹniti o pada pẹlu ārè̩ ati ẹsẹ riro, aṣọ yiya, owo ti tan lapo, ṣugbọn baba oninure ti o ti ri i lati okere fi tayọtayọ dari gbogbo rẹ ji i.
Onesimu mu iwe ti Paulu kọ lati fi ba a bẹbẹ fun aanu ati idariji lọwọ. Awa ti a ti ri igbala lọjọ-oni le bojuwo ẹhin wo ọjọ ti a yi pada sọdọỌlọrun, pẹlu iwe idariji ti a fi Ẹjẹ Jesu iyebiye saami si lọwọ wa. “O si rùè̩ṣẹọpọlọpọ; o si nṣipẹ fun awọn alarekọja” (Isaiah 53:12).
Ri Idariji
Inu Onesimu ti dun to nisisiyi! Ọpẹ rè̩ si Paulu ẹniti o ba a ṣipẹ fun Filemoni ọga rè̩ yoo ti pọ to! Igbese ọpẹ ati ifẹ rè̩ si Paulu ati Filemoni ti pọ to! Bawo ni igbese rè̩ si Jesu yoo ti pọ to fun ọkàn mimọ, akọsilẹ ti o mọ gaara, ati ibè̩rẹ igbesi-aye titun! Igbese wa si Ọlọrun ati si Kristi, Ẹniti o san gbese wa, ti O ru è̩ru è̩ṣẹ wa, ti O si sọ wa di ẹbi Ọlọrun ti pọ to? “Njẹ nitorina ẹnyin ki iṣe alejò ati atipo mọ, ṣugbọn ajumọ jẹọlọtọ pẹlu awọn enia mimọ, ati awọn ara ile Ọlọrun” (Efesu 2:19).
“Jesu san gbogbo,
’Gbese ti mo jẹ;
Ẹṣẹ ti m’abawọn wa,
O fọ mi fun bi sno.”
Questions
AWỌN IBEERE1 Nibo ni Paulu wà nigba ti o kọ iwe yi?
2 Tani a kọọ si? Tani a si fi ran?
3 Aye wo ni Onesimu wà lọdọ Filemoni?
4 Nibo ni yoo jẹ ibujoko rè̩ titun?
5 Kin ni Bibeli kọni nipa atunṣe?
6 Kin ni Paulu sọ ninu iwe rè̩ ti o jẹ ki a mọ pe oun ni ireti pe a o tuoun silẹ kuro ninu tubu?
7 Kin ni Paulu sọ nipa igbese Onesimu?
8 Tani Onesimu jẹ ni’gbese ọpẹ nla?
9 Tani a jẹ ni’gbese ifẹ ati isin atọkàn wá?
10 Bawo ni a ṣe le fi ifẹ wa si Jesu hàn?