I Kọrinti 13:1-13

Lesson 355 - Junior

Memory Verse
“Nisisiyi igbagbọ, ireti, ati ifẹ mbẹ, awọn mẹta yi: ṣugbọn eyiti o tobijù ninu wọn ni ifẹ” (I Kọrinti 13:13).
Notes

Ifẹ

“Ifẹ ni Ọlọrun: ẹniti o ba si ngbé inu ifẹ o ngbé inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rè̩.” Awọn eniyan Ọlọrun ni ifẹ Rè̩ ninu ọkàn wọn nitori pe Ọlọrun wà wọn Nigbati awọn eniyan ba ri igbala, a o dari ẹṣẹ wọn ji, Ọlọrun a si fi ifẹ Rè̩ sinu wọn. Nigba ti a ba sọ wọn di mimọ, a wẹọkàn wọn mọ wọn si ni ifẹỌlọrun lọpọlọpọ ninu ọkàn wọn. Awọn ti o ba ri igbala nikan ni o n ni ifẹ Onigbagbọ tootọ, nitori pe awọn Tirè̩ ni Ọlọrun pese rè̩ silẹ fun.

Ifẹ ti Ọlorun ma n dá sinu ọkan awọn eniyan Rè̩ ni a n pe ni ifẹ Onigbagbọ ati ifẹ ará. Ifẹ yi jinlẹ ju fifi owo fun awọn talaka lọ. Ifẹ yi jẹ itara fun anfaani, itura, ati inu didun awọn ẹlomiran. Iṣesi ati ibakẹdun wa si awọn ẹlomiran li o n fi ifẹ han.

Bi ifẹ ti ṣe Pataki to

Fifẹran awọn eniyan Ọlọrun jẹọna kan lati fi han pe Tirẹ ni wa. Jesu wi pe: “Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ pe, ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin” (Johannu 13:35). Ninu iwe ti Peteru kọ a kà a pe, “Ju gbogbo rẹ lọ, ẹ ni ifẹ ti o gbóna larin ara nyin” (I Peteru 4:8). Leke ohun gbogbo! Ifẹ ni a kọkọ darukọ ninu akojọpọ awọn ohun imuyẹ ti o papọ di “eso ti Ẹmi” (Galatia 5:22). A p e Ifẹ ni “ohun ti o tobi julọ ninu aiye.”

Odiwọn

Paulu kọwe si awọn ara Kọrinti nipa ifẹ Onigbagbọ. Apa Iwe Mimọ yi jẹ iwe lori ifẹ. Oun ni odiwọn ti a le fi wọn igbesi-aye wa gẹgẹbi Onigbagbọ. Bi a ti n kọè̩kọ yi, ẹ jẹ ki a gbe igbesi-aye wa le ori ọpa idiwọn yi ki Ọlọrun ba le fi ọna ti a maa fi jẹ Onigbagbọ ti o jafafa si Oluwa ha wa. Ibikibi ti o wu ki wọn maa gbe, ẹnikẹni to wu ki wọn jẹ, bi o ti wu ki wọn kere tabi ki wọn dagba to, gbogbo Onigbagbọ ni o ni awọn ohun amuyẹ wọnyi nitori pe ifẹỌlọrun wà ni igbesi-aye wọn.

Alainifẹ

Paulu ṣe ifiwera laarin ifẹ ati awọn ohun rere miran. Ọpọlọpọ eniyan ni o ni itara lati le sọ ede ẹlomiran; ṣugbọn gbogbo eniyan ni o le gbọ ede ifẹ ti a fihan nipa ẹrin músé̩, ẹmi ibanikẹdun, ati nipa awọn iṣẹ inu rere miran.

Ọpọ eniyan ni o n fẹ olohùn iyọ. Mose mọ wi pe oun ki i ṣe olohùn iyọ. Nigba ti Ọlọrun pe e lati mu awọn Ọmọ Israẹli jade kuro ni Egipti, Mose wi pe, “Emi ki i ṣe ẹni ọrọ isọ … ṣugbọn olohùn wuwo ni mi, ati alahọn wuwo” (Ẹksodu 4:10). S̩ugbọn Ọlọrun sọ fun Mose pe Oun yoo kọọ ni ohun ti yoo wi. O maa ndun mọ ni nigba ti eniyan ba sọrọ pẹlu ohùn-iyọ, ṣugbọn ki i ṣe nini ohùn-iyọ ni o ṣe pataki julọ. Paulu fi ohùn-iyọ ti ko ni ifẹ we iro asan ti “idẹ ti ndún, tabi bi kimbali olohùn goro” (I Kọrinti 13:1).

Paulu ni oun ko jamọ nkankan bi oun ko ba ni ifẹ; ani bi oun ba tilẹ le sọ asọtẹlẹ awọn ohun ti mbọwa ṣe lọjọ iwajụ; bi oun ba tilẹ ni oye gbogbo ohun ijinlẹỌlọrun; bi o ba tilẹ jẹ pe oun ni imọ ati è̩kọ lati inu iwe kika ati lati ọdọ awọn olukọ; ani bi oun tilẹ ni igbagbọ lati fi ṣi oke nidi. S̩ugbọn ifẹỌlọrun ninu ọkàn awọn eniyan Rè̩ tobi ju gbogbo wọnyi lọ.

Awọn ẹlomiran lawọ. Wọn a maa fifun awọn akúṣẹ ati alaini. Awọn miran ṣolootọ tobẹẹ ti wọn le yọọda pe ki a fi wọn rubọ. S̩ugbọn laisi ifẹ ti Ọlọrun, awọn nkan wọnyi kò le mu ère kan ti o niyelori wa. Awọn ẹbun ti Paulu darukọ wọnyi dara nitootọ, ṣugbọn wọn ko to. Eniyan gbọdọ ni ifẹỌlọrun.

Suuru ati Inurere

“Ifẹ a ma mu suru,” IfẹỌlọrun a maa fun eniyan ni suuru. Jobu ni suuru nitori pe o jẹ eniyan Ọlọrun. Nigba ti Jobu padanu awọn ọmọ ati awọn ohun ini rè̩ o wi pe: “Oluwa fifunni Oluwa si gbà lọ, ibukun li orukọ Oluwa” (Jobu 1:21). Nigba ti ipọnju rè̩ pọ si i, o faramọ eyikeyi ti Ọlọrun ṣe. O wi pe: “S̩ugbọn on mọọna ti emi ntọ, nigbati o ba dan mi wò, emi o jade bi wura. Ẹsẹ mi ti tẹle ipasẹ irin rè̩, ọna rè̩ ni mo ti kiyesi, ti nko si yà kuro” (Jobu 23:10, 11). Iwọ ha n mu suuru nigba ti o dabi ẹnipe ohun gbogbo diju? Boya ohun ti o ku ọ ku ni ifẹỌlọrun ninu ọkàn rẹ, lati fun ọ ni suuru, tabi ohun ti o ku fun ọ ni lati dagba ninu suuru ati ifẹỌlọrun.

“Ifẹ … a si ma ṣeun.” A kà a ninu awọn iwe Paulu si awọn ara Efesu pe, “Ẹ māṣore fun ọmọnikeji nyin” (Efesu 4:32). Josẹfu jẹ apẹẹrẹ rere ẹniti o n ṣore paapaa si awọn ti o ti huwa iwọsi si i. Awọn arakunrin Josẹfu korira rè̩, wọn si ta a fun awọn oniṣowo, awọn ẹniti o mu u lọ si Egipti; ṣugbọn li akoko iyan, Josẹfu mu awọn arakunrin rè̩ wà laaye nipa fifun wọn li ounjẹ. O wi fun wọn pe, “Njẹ nisisiyi, ẹ má bè̩ru: emi o bọ nyin, ati awọn ọmọ werẹ nyin.” “O si tu wọn ninu, o si sọrọ rere fun wọn” (Gẹnesisi 50:21). Tani iwọ n ṣore fun? Si kiki awọn ti n ṣe ọ lore nikan?

Nirẹlẹ

IfẹỌlọrun ma njẹ ki eniyan ni itẹlọrun dipo ilara. A sọ funni pe ki ohun ti a ni “ki o to “ wa (Heberu 13:5). A kà a pe, “Iwabi-Ọlọrun pẹlu itẹlọrùn ère nla ni” (I Timoteu 6:6). Awọn onilara a maa kun si ohun rere ti awọn ẹlomiran ni. Ko si ohun rere kan ti a le sọ nipa ilara. A le ri akọsilẹ awọn eniyan ti o kun fun ilara ninu Iwe Mimọ, akọsilẹ kọọkan li o kun fun ibanujẹ. Kaini pa arakunrin rè̩ nitori ilara. Awọn ẹniti o ṣẹsún Daniẹli ti a fi sọọ sinu iho kiniun ṣe e nitori ilara. Awọn olùfisun Kristi yọọda pe ki a kan An mọ agbelebu nitori ilara.

Ifẹ ma n mu ki eniyan rẹ ara rè̩ silẹ dipo ifè̩-sokè. A kọ wa ni iwa irẹlẹ ninu ỌrọỌlọrun. Ka nipa rirẹ ara-ẹni silẹ ninu Iwe Owe 22:4; Jakọbu 4:10; I Peteru-5:5, 6. Ọkan ninu awọn ohun ti Ọlọrun nfẹ lọwọ wa ni pe ki a “rin ni irẹlẹ” pẹlu Rè̩ (Mika 6:8).

Aimọ-ti-ara-ẹni-nikan

“Ifẹ … ki ihuwa aitọ.” Njẹ iwa ti o tọ ni lati maa yọ eniyan lẹnu; tabi lati maa yọṣùti si eniyan nigba ti o ba kọ lati ṣe ohun ti a n fẹ fun wa bi? Awọn ọmọ miran a maa binu lainidi nigba ti nkan kò ba lọ bi wọn ti n fẹ, wọn a maa mu wahala ba awọn ẹlomiran titi nkan ti wọn n fẹ yoo fi to wọn lọwọ. S̩ugbọn iru awọn ọmọ bẹẹ kò ni ifẹỌlọrun ninu ọkàn wọn.

“Ki iwá ohun ti ara rè̩. Ifẹṣe alainimọ-ti-ara-ẹni-nikan tobẹẹ ti ki iwá ohun ti ara rè̩. Wo bi o ṣe yatọ si ẹmi ti aye, eyiti o n mu ki awọn eniyan ma n nnọga si ohun gbogbo, yala wọn ni è̩tọ si i tabi ti ẹlomiran tilẹ ni! Ayọ tootọ ko si ninu gbigbà bikoṣe ninu fifunni. “Ẹ si ma ranti ọrọ Jesu Oluwa, bi ontikararè̩ ti wipe, Ati funni o ni ibukun jù ati gbà lọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 20:35).

Ọkan Titun

“Ifẹ a ki imu u binu.” Wo ogunlọgọ eniyan ti wọn ti gbidanwo lasan lati le kapa ibinu wọn! Nigba ti a ba mu wọn binu, wọn a ti sọrọ wọn a si ti ṣe ohun ti woṅ yio pada kabamọ fun. Inufufu a maa yọrisi ibinu, ikorira ati igbẹsan. Nigba ti eniyan ba binu ki i sọọrọ rere bẹẹni ki ile huwa ti o dara. Kò si ipá ti a le sa lati le kapa ibinu, bikoṣe ki a mu orisun wahala yi – ti i ṣe ọkàn – wa si titọ. IfẹỌlọrun li o ma n fi iranwọ sinu ọkàn ti a ki ifi mu u binu.

“Ifẹ ki igbiro ohun buburu.” Onigbagbọ ki ilana ibi ki isi ṣaṣaro lori ibi. Ki ini ifura si ẹlomiran, lati maa woye fun ibi ni igbesi-aye won. Filippi 4:8 fun wa ni akojọ awọn ohun rere ti o yẹ ki a maa ronu nipa rè̩: awọn ohun ti iṣe ootọ, ti iṣe ọwọ, ti iṣe titọ, ti iṣe mimọ, ti iṣe fifẹ ti o ni ihinrere: “bi iwa-titọ kan ba wà, bi iyin kan ba si wà, ẹ mā gbà nkan wọnyi rò.”

Ni Ifarada

“Ifẹ ki iyè̩ lai.” O ni ifarada. Awọn nkan miran yoo kuna, yoo rekọja, tabi yoo fi àyè fun ohun titun. Igbagbọ, ireti ati ifẹ mbẹ nisisyi -- ṣugbọn li Ọrun kò ni si lilo igbagbọ ati ireti. Ifẹ nikan ni yoo wà titi. Nipa awọn ohun mẹta wonyi Paulu wi pe, “Eyiti o tobiju ninu wọn ni ifẹ.” Igbagbọ ati ireti jẹ ohun ti o ṣe pataki ni igbesi aye Onigbagbọ. Li aisi igbagbọ o ṣoro lati wu Ọlọrun (Heberu 11:6). Igbagbọ ni iṣẹgun ti o ṣẹgun aye (I Johannu 5:4). A sọ fun wa pe ki a “jà gidigidi fun igbagbọ, ti a ti fi le awon enia mimọ lowọ lẹkanṣoṣo” (Juda 3). Ireti jẹ apakan ninu ihamọra Onigbagbọ -- “ireti, igbala fun aṣibori” (I Tẹssalonika 5:8). Ireti ni “idakọro ọkàn, ireti ti o daju ti o si duroṣinṣin” (Heberu 6:19). igbagbọ ni iwa wa si Ọlọrun. Ireti wà fun awa tikarawa. S̩ugbọn ifẹ tobi ju awọn wọnyi lọ. IfẹỌlorun ni ohun ti o n mu ki a fẹran aladugbo wa.

Gẹgẹbi o ti nkọè̩kọ yi gbe igbesi-aye Igbagbọ rẹ le ori ọpa-iwọn, njẹ aye wà fun itẹsiwaju? Ranti pe nṣe ni Onigbagbọ ndagba si i, a si maa pọ si i ninu oore-ọfẹ kọkan ti Onigbagbọ, Peteru wi pe ki a ṣe aisimi gbogbo ati pe ki a fi kun awọn ohun amuyẹ wọnyi: igbagbọ, iwa-rere, imọ, airekọja, suuru, iwabi-Ọlọrun, ifẹọmọnikeji ati ifẹ. Nipa idagba Onigbagbọ a o ni anfaani lati so eso ti ẹmi ati lati sọ “ipe ati yiyan” wa “di dajudaju,” ati lati wà pẹlu jesu ninu ijọba Rè̩ ainipẹkun. S̩ugbọn bi a ba kuna ninu awọn nkan wọnyi a o kuna iye ainipẹkun. (Ka II Peteru 1:5-11).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Kin ni orukọ miran ti a tun le pe ifẹ?

  2. 2 Bawo ni eniyan ṣe le ni ifẹ?

  3. 3 IfẹỌlọrun ti ṣe pataki to?

  4. 4 Kin ni a ṣe le mọẹniti o ni ifẹỌlorun?

  5. 5 Ka ninu I Johannu 4:19 idi rè̩ ti a fi fẹran Oluwa?

  6. 6 Bawo ni awọn eniyan ṣe le mọ pe ọmọlẹhin Jesu ni wa? Jesu kọ wa pe ki o ma ṣe kiki awọn aladugbo wa nikan ni a o fẹran ṣugbọn bẹẹ gẹgẹ ki a tun fẹ awọn tani?

  7. 7 Kin ni ohun ti o ṣẹlẹ bi Onigbagbọ kò ba dagba?

  8. 8 Ninu ẹsẹ ti o kẹhin ninu ori ẹkọ wa a fi yeni pe ifẹ tobi ju awọn ohun meji miran wo ti n bẹ.