Efesu 6:1-4

Lesson 356 - Junior

Memory Verse
“Ẹnyin ọmọ, ẹ má gbọ ti awọn õbi nyin ninu Oluwa: nitoripe eyi li o tọ” (Efesu 6:1).
Notes

Igbọran si awọn obi

“Ẹnyin ọmọ, ẹ mā gbọ ti awọn õbi nyin.” Eyi ti jẹ ohun inira fun awọn ọmọde lati ṣe to! Wọn a maa wa ọna lati máṣe ohun ti awọn õbi wọn fẹ nipa ṣiṣe oriṣiriṣi awawi. Ọna ti ara wọn ni wọn sa n fẹ. Ni ọpọlọpọ igba ni wọn maa n ro pe awọn gbọn ju awọn õbi wọn lọ, ati pe awọn õbi w to do ẹni igba atijọ.

S̩ugbọn ỌrọỌlọrun ni: “Ẹnyin ọmọ, ẹ mā gbọ ti awọn õbi nyin ninu Oluwa, nitoripe eyi li o tọ,” “Ninu Oluwa.” Bi awọn õbi rẹ ba fẹ ki o ṣe ohun ti o lodi si eyi ti Jesu n fẹ, o lẹtọ lati kọ fun wọn. S̩ugbọn o gbọdọ gbọ ti awọn õbi ti n ṣe ohun ti o tọ.

“Bọwọ fun baba ati iya rẹ; eyi ti iṣe ofin ikini pẹlu ileri; ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wà pẹ li aiye” (Efesu 6:2, 3).

Awọn Ọmọde ti o Layọ

Ọlọrun mọ ohun ti imu inu eniyan dun, O si n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ layọ. Awọn ọmọde ti ima ṣe ifẹ inu-ara wọn ki i layọ. Awọn wọnni ti a jẹniya nigba ti wọn wà ni ewe, ti wọn si mọ bi a ti igbọran si awọn õbi wọn lẹnu ati bi a ti ihuwa rere si gbogbo eniyan laini ẹmi imọ-ti-ara-ẹni-nikan, a maa layọ ju awọn wọnni ti wọn fẹran lati maa ṣe ohun ti o wu won. N jẹ o ro pe ọmọ ti o n binu nitori ki o le ṣe ohun ti o fẹ le ni ayọ?

Wo bi yoo ti jẹ ohun inira fun awon ẹniti o ni ọmọ olóri kunkun, alaigbọran ati onikanra lọdọ. Sọlomọni wi pe: “Ọlọgbọn ọmọṣe inu-didùn baba rè̩, ṣugbọn aṣiwere ọmọ ni ibanujẹ iya rè̩” (Owe 10:1). Ọlogbọn ọmọ ni ẹniti o gbọran si ỌrọỌlọrun ati ti o n bọwọ fun awon õbi rè̩. Aṣiwere ọmọ ni ẹniti o n ṣaigbọran si Ọlọrun ati eniyan

Ọlọrun n ṣọ ohun gbogbo ti a n ṣe. O n ṣọ awọn ọmọde, O si ti ran angẹli oluṣọ lati dabobo wọn; ṣugbọn bi won ba taku sinu iwa iṣọtẹ wọn, a nilati jẹ wọn niya. Wọn yoo jiya ninu aye yi; bi wọn kò ba si ronupiwada, wọn yoo tun jẹ iya ti o pọju bẹẹ nigba ti wọn ba duro niwaju Onidajọ gbogbo aye.

Awọn obi gbọdọ kọ awọn ọmọde bi a ti ṣe le jẹ olugbọran. A kò bi iwa rere mọ awọn ọmode. Woli Isaiah ni: “Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan” (Isaiah 53:6); Onipsalmu wi pe: “Nwọn ti ṣina lojukanna ti a ti bi wọn” (Orin Dafidi 58:3). A gbọdọ kọ awọn ọmọde lati inu ile lati maa mọọ fun ẹlomiran ati lati mọ bi a ti ipa ofin mọ. Awọn ti o ṣe alainaani aṣẹ awọn obi wọn kò ni le bọwọ fun ofin ilu, tabi ofin Ọlọrun.

Nigba ti Jesu paapaa ẹniti I ṣe ỌmọỌlọrun wa si aye gẹgẹbi eniyan, O n gbọran si awọn obi Rè̩ nipa ti ara lẹnu. O fi apẹẹrẹ bi a ṣe nila ti gbe lelẹ fun wa. Awọn ọmọde miran ro pe awọn ti dagba ju lati gbọ ti awọn obi wọn tabi ki a jẹ wọn niya, nigba ti wọn ba ti to ọmọọdun mejila. Nigba ti Jesu di ọmọọdun mejila a ri I ninu Tẹmpili nibi ti O gbe n fi Bibeli ba awọn Ju ti i ṣe olukọni sọrọ. O sọ fun iya Rè̩ pe Oun kò le ṣaima wà nibi iṣẹ Baba Oun ti n bẹ ni ọrun, eyiti o jẹ ohun pataki. Sibẹsibẹ, O ba Maria ati Josẹfu pada lọ si Nasarẹti, “O si fi ara balẹ fun wọn” (Luku 2:51).

Aṣẹ ti a pa fun awọn obi

Awọn obi yoo jihin fun Ọlọrun lori ọna ti wọn gba tọ awọn ọmọ wọn. A paṣẹ fun awọn naa paapaa lati ọdọỌlorun pe: “Ati ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu: ṣugbọn ẹ mā tọ wọn ninu ẹkọ ati ikilọ Oluwa” (Efesu 6:4). O jẹ ojuṣe awọn obi lati rii pe awọn ọmọ won gbọran; ṣugbọn wọn gbọdọ jẹ oniyọnu, ki wọn si ba ni wi pẹlu ifẹ ninu ọkàn wọn.

Nigba ti Ọlọrun yan Abrahamu lati jẹ baba orilẹ-ede Ju, O ri iwa pataki kan ninu rè̩ ti yoo jẹ iranwọ lati fi ipilẹ orilẹ-ède naa lelẹ. O wi pe: “Nitoriti mo mọọ pe, on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rè̩ ati fun awọn ara ile rè̩ lẹhin rè̩, ki nwọn ki o ma pa ọna OLUWA mọ lati ṣe ododo ati idajọ; ki OLUWA ki o le mu ohun ti o ti sọ fun Abrahamu wá fun u” (Gẹnẹsisi 18:19).

Awọn ọmọ Onigbagbọ yoo jẹ iranlọwọ fun awọn obi wọn lọpọlọpọ bi wọn ba n le ba awon obi wọn kọè̩kọ papọ ninu Bibeli pẹlu ifọwọ s’owọpọ lati gbọran si Ọrọ naa. Awọn ọmọ ati awọn ọmọ-ọmọ Abrahamu ran an lọwọ lati mu ifẹỌlorun ṣẹ nipa gbigbọran si ohun ti o ba sọ ati si awọn aṣẹỌlọrun.

Didara pọ mọ aye

Nigba gbogbo ni awọn ọmode maa n ro pe ohun ti o ṣe pataki julọ ni igba ọdọ wọn ni lati ni è̩kọ ti o yanju, lati dabi awọn ọdọẹlẹgbẹ wọn ti wọn ju mọ n lọ si ile-è̩kọ papọ. Ẹgbẹ jọda aṣọ yoo jẹ ohun gunmọ pẹlu. Ẹgbẹ aye, ere idaraya, ile-ijo, ati ode-apejẹ ma n tan ọpọlọpọọdọ kuro ninu ỌrọỌlọrun. Wọn ni ifẹ ati di olokiki larin awujọ eniyan, ni igba pupọ awon obi wọn ma n gbiyanju lati ṣe iranwọ fun wọn. Ọpọlọpọ iya li o ma n lo aṣọ ti kọ nilari ki wọn ba le ri owo lati fi da aṣọ ti o ba ode mu fun awọn ọmọbinrin wọn. Awọn obi yoo du ara wọn ni ọpọlọpọ nkan ki wọn ba le fun awọn ọmọ wọṅ ni anfaani pupọ ninu aye.

S̩ugbọn kin ni anfaani ti o tobi julọ ninu aye? Bi awọn obi wa kò tilẹ fi ohunkohun silẹ fun wa ninu awon ohun rere aye yi, bi wọn ba fi apẹẹrẹ igbesi-aye Onigbagbọ ati igbẹkele tootọ ati igbagbọ ninu ỌrọỌlọrun lelẹ fun wa, ko si ogún ti o tobi ju eyi lọ. Aye yi pẹlu ọlá ati igberaga rè̩ yoo kọja lọ laipẹ. S̩ugbọn ifẹỌlọrun ninu ọkàn wa yoo wà titi.

Pẹpẹ Adura Agbo-ile

“Agbole ti o ba jọ n gbadura papọ yoo wà papọ,” jẹ gbolohun ti a ma n saba tọka si. A kò le ri idapọ ti o gbadun nibikibi ju ibi pẹpẹ adura agbo-ile ati ajumọ kọè̩kọ papọ ninu Bibeli. Ọlọrun bukun ẹsin agbo-ile nitori ti o jẹ igbọran si ifẹỌlọrun. AṣẹỌlọrun lati ẹnu Mose ni: “Ki ẹnyin ki o si mā fi won (awọn ọrọỌlọrun) kọ awọn ọmọ nyin, ki ẹnyin kā fi won ṣe ọrọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọna, nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide” (Deuteronomi 11:19). S̩ugbọn kikọỌrọỌlọrun ninu ile kò to. A gbọdọ mu awọn ọmọde lọ si Ile-è̩kọỌjọ Isimi ati Ile-isin. Awọn ọmọ kékèké a ma kọè̩kọ pupọ ninu isin awoṅ agba, ibukun Ọlọrun a si maa wà lori wọn.

Nigbati Jọṣua n fun awọṅỌmọ Israẹli li aṣẹ, awọn ọmọ wẹẹrẹ wọn wà nibẹ pẹlu. “Kò kùọrọ kan ninu gbogbo eyiti Mose palaṣẹ, ti Jọṣua kò kà niwaju gbogbo ijọ Isaẹli, ati awon obirin, ati awọn ọmọ wẹrẹ ati awọn alejò ti nrin lārin wọn” (Jọṣua 8:35). Wò bi ayọ wọn ti pọ to nigba ti Ọlọrun tu ibukun Rè̩ sori ẹbọ wọn! “Nitori Ọlọrun ti mu wọn yọ ayọ nla, aya wọn ati awọn ọmọde yọ pẹlu, tobḝ ti a si gbọ ayọ Jerusalẹmu li okere reré” (Nehemiah 12:43).

Jesu n fẹ awọn ọmọde ninu isin Rè̩. O wi pe, “Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere ki o wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú won ni ijọba Ọlorun” (Marku 10:14). Bi awọn ọmọde ba jẹ pataki fun Jesu bayi, ro bi o ti tọ ki wọn ṣe huwa nigba ti wọn ba wà ni ile Ọlọrun. O fẹran wọn O si n fẹ won nibẹ; ṣugbọn wọn gbọdọ fi ọlá ati ọwọ fun ile Rè̩. Wọn gbọdọ dakẹ jẹ ki wọn si duro jẹ lai rin kiri nigba ti ẹnikan ba n ṣiwaju gbogbo ijọ ninu adura. Ọlọrun li o n ba sọrọ, awọn naa nilati gbadura pẹlu.

Li akoko kan awọn alufa buburu n fẹ mu Jesu, nigbati ọpọ ninu awọn eniyan ti kuro ninu Tẹmpili. S̩ugbọn ọpọ awon ọmọde ti wọn fẹran Jesu, wà ninu Tẹmpili, wọn si n kọrin wi pe, “Hosanna fun Ọmọ Dafidi.” Eyi bi awọn alufa ninu, ṣugbọn Jesu wi pe: Ẹnyin kò ti kà a ninu iwe pe, Lati ẹnu awọn ọmọ-agbo ati awọn ọmọ-ọmu ni iwọ ti mu iyin pé?” (Matteu 21:15, 16). Awọn ọmọde wọnyi bu ọlá fun Jesu ju awọn agba ti wọn jẹẹlesin lọ.

Ni igba pupọ ni awon ọmọde Onigbagbọ tootọ ti mu awon obi wọn mọ Jesu. Ọmọde kekere le ri igbala ninu Ile-è̩kọỌjọ Isinmi, ki o si lọ sọ fun awon obi rè̩ nipa ayọ ti o ni ninu ọkàn rè̩. O si ti gbadura fun awon obi rè̩. Ọlọrun ma n gbọ adura ti ọmọde kekere ba gbà pẹlu igbagbọ, A si maa dahun. Ni ọpọlọpọ igba ni awọn ẹlẹṣẹ ma n tẹ eti silẹ lati gbọ Itan Jesu lati ẹnu ọmọde nigbati wọn kò ni ṣuja ohun ti agbalagba n sọ. Wo bi ihuwasi ọmode ti ṣe pataki to! Ati ohun nla ti igbesi-aye ti o n gbe fun Jesu le ṣe!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Kin ni ofin Ọlọrun fun awọn ọmọde?

  2. 2 Kin ni ileri Rè̩ fun igbọran?

  3. 3 Awọn ọmọde wo li o layọ?

  4. 4 Nibo ni a gbe nila ti kọ kọọmọde bi a ti ipa ofin ati aṣẹ mọ?

  5. 5 Bawo ni a ṣe mọ pe Jesu gbọran si awọn obi Rè̩ lẹnu?

  6. 6 Kin ni ofin Ọlọrun fun awọn obi?

  7. 7 Kin ni awọn ohun ti o wà ni ile-è̩kọ ti o le ṣI ọkàn ọmọde kuro lọdọỌlọrun bi oun kò ba ṣọra?

  8. 8 Kin ni ogún wa ti o tobi julọ ninu aye yi?

  9. 9 Kin ni Jesu sọ nipa titẹwọgba awọn ọmọde?

  10. 10 Kin ni awọn ohun ti ọmọde Onigbagbọ le ṣe fun awọn obi wọn?