Lesson 357 - Junior
Memory Verse
“Ẹ mā takéte si ohun ti iṣe buburu; ẹ faramọ ohun ti iṣe rere” (Romu 12:9).Notes
Mimọ
Jesu gbadura fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ ati fun gbogbo awọn ti yoo tẹle E. O gbadura pe ki wọn le jẹọkan, ki wọn wà ni iṣọkan pẹlu ara wọn ati pẹlu Ọlọrun. O gbadura pe ki a sọ wọn di mimọ. Isọdimimọ ni wiwà ni mimọ, ki a wẹ wa nu kuro ninu è̩ṣẹ. A fi isọdimimọ we fifa gbọngbo igi tu kuro ninu ilẹ. A fi Igbala we igi ti a ge lulẹ eyiti kukute rè̩ tun le hu ki o si dagba. S̩ugbọn ni akoko Isọdimimọ a fa gbongbo rè̩ tu kuro ninu ile.
Jesu gbadura pe ki awọn ọmọ-ẹhin Oun le jẹ olootọ, ati ki wọn le jẹ olootọ si Ọlọrun, ani ninu aye ti o kun fun idanwo ati ipọnju. (Ka Johannu 17:15-21).
Isọdimimọ ma n fun Onigbagbọ ni agbara si I lati bori è̩ṣẹ. O jẹ “ifẹỌlọrun, ani wiwà ni mimọ nyin” (I Tẹssalonika 4:3). Awọn Onigbagbọ n fẹ gbe igbesi-aye ti o ba ifẹỌlọrun mu, nitori na wọn n fi ara wọn rubọ wọn a si gbadura titi Ọlọrun ma fi sọ wọn di mimọ. Awọn nkan miran wà ti Onigbagbọ nilati ṣe ki o to le jẹ olootọ si Ọlọrun, ki o to le ṣe ifẹ Rè̩, ati ki o to le wulo fun Un. Onigbagbọ nilati ṣiṣẹ ninu isin Rè̩, ki o si sa ipa rè̩ nigbagbogbo lati jọ Oluwa rè̩.
Apẹẹrẹ
Ninu iwe rè̩ si ijọ ti o wà ni Romu, Paulu darukọ awọn ohun ti o le ran wọn lọwọ lati le jẹ Onigbagbọ ti o peye. A le pe awọn ohun naa ni iṣẹ Onigbagbọ. Wọn jẹ apẹẹrẹ fun igbesi-aye Onigbagbọ. Nigba ti eniyan ba ni ifẹỌlọrun ninu ọkàn rè̩ yio ka gbigbe igbesi-aye mimọ si anfaani. Yoo fẹ gbe igbesi-aye ti o wu Ọlọrun, ati ni ṣiṣe bẹẹ oun yoo mọ pe oun wà ni imurasilẹ lati lọ si Ọrun.
Awọn ọmọde miran mọ pe lati ni ipa ninu ṣiṣe awọn are kan, tabi lilọ si ibikan, tabi biba iru awọn ọmọde kan ṣire pọ, ma n saba fi wọn sinu wahala. N jẹ kò ni ṣanfaani lati yẹra kuro ninu awọn ohun wọnni ati lọdọ awọn wọnni ti o n mu wahala dani? Bẹ gẹgẹ ni o ri fun Onigbagbọ: nipa yiyà fun è̩ṣẹ, ni gbigba adura ati ni wiwà fun Ọlọrun, oun yoo ni iranwọ lati le bọ kuro ninu wahla.
Ẹbọ Aye
Paulu n rọ awọn Onigbagbọ lati ya ara wọn si mimọ fun Ọlọrun, ati ki wọn fi ara wọn fun Ọlọrun ni “ẹbọāye”. Ni igba lailai awọn eniyan maa n sin Ọlọrun nipa fifi ẹran ti a pa rubọ, ṣugbọn lọjọ oni Ọlọrun n fẹ ki wiwà wa maa fi ogo ati iyin fun Oun. Woli Isaiah wi pe: “Nitori iboji kò le yin ọ, ikú kò le fiyin fun ọ: … Alāye, alāyè, on ni yio yin ọ, bi mo ti nṣe loni yi” (Isaiah 38;18, 19).
Ẹbọ ni ohun ti a fi rubọ, ti a jọwọ rè̩ lọwọ lọ, ati ti a yda rè̩ fun Ọlọrun. Jijọwọ ara ati igbesi-aye eniyan fun Ọlọrun li “ẹbọāye” jẹ jijọwọ ati yiyda igbesi-aye rè̩ fun Ọlọrun ati ifẹ Rè̩. Ki I ṣe ẹbọāye nìkan ni Ọlọrun n fẹ, ṣugbọn O n fẹ igbesi-aye mimọ, ti o bọ lọwọè̩ṣẹ.
Ipa
Bawo ni o ṣe le wa ni idominira ni è̩ṣẹ titi? “Lati di titun ni iro-inu nyin.” Paulu sọ iru awọn ọrọ bayi ninu adura rè̩ si ijọ Efesu: “Ki a le fi agbara rè̩ mu nyin li okun nipa Ẹmi rè̩ niti ẹni inu; … ki a le fi gbogbo è̩kun Ọlọrun kun nyin” (Efesu 3:16-19). Ni gbigba adura lorowurọṣiwaju lilọ si ile-iwe, ere-ṣiṣe, ati iṣẹ-ṣiṣe, ati nipa kika Bibeli tabi titẹ eti silẹ nigbati a ba n ka a, awọn ọmọde le ni Oluwa pẹlu wọn, Oun yoo le fi han wọn bi wọn ti le ṣe rere ati bi won ṣe le wà fun Un. Kikọ awọn ẹkọ Ile-è̩kọỌjọ Isinmi ati kikọ awọn ẹsẹ akọsori wa sori ma n jẹ ki a di titun ninu ero-inu ati alagbara ninu Oluwa.
Iwa wa si Ẹlomiran
Ọmọ-lẹhin Oluwa jẹ onirẹlẹ, ẹniti o n rò nipa ti ọmọnikeji rè̩ṣ’aaju ti ountikararè̩. Eleyi n han ninu igbesi-aye ti eniyan n gbe lojojumọ. A le fun ọ làye lati mu ọkan ninu eso meji, ninu eyiti ọkan tobi ju ekeji. Satani le sọrọ si ọ leti kẹlẹkẹlẹ pe ki o mu eyiti o tobi ni nitori pe ebi n pa ọ. S̩ugbọn iwọ yoo ranti pe Jesu kò fẹ ki a jẹ onmọ-tara-ẹni-nikan, ati ki a kọkọ maa ro nipa ti ọmọnikeji ẹni, iwọ yoo fi eso ti o tobi ju silẹ fun ẹnikeji. Eyi jẹọna kan ti a le gba fi ifẹ han ati “niti ọlá, ẹ mā fi ẹnikeji nyin ṣ’āju,” lairo nipa ara wa ju bi o ti yẹ.
Rere tabi buburu
“Ẹ mā takete si ohun ti iṣe buburu; ẹ faramọ ohun ti iṣe rere.” Onigbagbọ a maa korira awọn ohun buburu a si takete si wọn. O fẹran awọn ohun rere a si maa faramọ wọn. Li akoko ere, ọmọde ti o ba fẹran Oluwa yoo yẹra fun awọn ohun ti o mu è̩ṣẹ dani. Oun kò gbọdọ daba fifi ibọn-ṣireṣire dẹruba eniyan lati ja a li ole tabi lati pa a. Oun kò gbọdọṣafarawe awọn wọnni ti n mu tabi tabi awọn wọnni ti nkun ète, bi o tilẹ jẹpe iwe kiká lasan ni o fi ṣe taba tabi fifi ẹfun lasan kun ète. Ọmọde Onigbagbọ ki i kan saara si iwa buburu ti o wà ni igbesi-aye awọn wọnni ti o n jale ti wọn si n rẹnijẹ. Satani ni ọna ẹwẹ ti o n fi tan eniyan lati ro pe iwa ibi “kò buru tobẹ,” a si maa tan wọn lati maa fi ọgbọn ẹwẹṣe awọn ohun ti kò dara. Paulu ni, “Ẹ mā pèse ohun ti o tọ niwaju gbogbo enia.” Niti pe awọn miran kò gbe igbesi-aye ti o wu Ọlorun, kò fun wa ni anfaani lati ṣe ohun kan ti ki yoo dun mọỌlọrun ninu.
Rere dipo Buburu
Dipo fifi buburu san buburu, Onigbagbọ a maa fi rere ṣẹgun buburu. A maa ṣoore fun awọn ti o n ṣe e ni ibi. Oun ki yoo ni ẹmi “igbẹsan.” Oun a maa wáàye lati ṣe oore fun awọn wọnni ti o ti huwa aitọ si i. Ninu Iwe Owe a ka nipa ileri ti o wà fun awọn wọnni ti o n ṣoore ati ti o n yọnu si awọn ti o ti ṣe wọn ni ibi. “Bi ebi ba npa ọtá rẹ, fun u li onjẹ: bi ongbẹ ba si ngbẹẹ, fun u li ohun mimu. Nitoriti iwọ o kóẹnyin iná jọ si ori rè̩, Oluwa yio san fun ọ” (Owe 25:21, 22). O ha tọ ki a ṣe rere si awọn ti n fi wa ṣe ẹlẹya? Bẹẹni, o tọ. “Ẹ mā sure awọn ti nṣe inunibini si nyin.”
Idagba
O jẹ iṣẹ-isin ti o tọna si Ọlọrun pe ki a wà fun Un. Ọlọrun ki I beere ju ohun ti awọn eniyan Rè̩ le ṣe lọwọ wọn. Ki i ṣe kiki pe Ọlọrun ni awọn ohun ti O n fẹ lati ọwọ awọn eniyan Rè̩ nikan ṣugbọn bẹẹ gẹgẹ O ni iranwọ fun wọn. Ninu iranlọwọ ti O n fi fun awọn eniyan Rè̩ ni ifẹỌlọrun, ore-ọfẹ, igbagbọ, ireti, agbara, ati suuru. Awa ni wọn wà fun a si le ri wọn gbà nipa adura ati lati inu Bibeli ti i ṣe ỌrọỌlọrun. Eniyan kò le ṣe ohun ti Ọlọrun n fẹ laisi iranwọỌlọrun.
Nigbati eniyan ba kọkọ ri igbala yoo ni awọn ẹbun oore-ọfẹ Onigbagbọ wọnyi lọpọ tabi niwọn diẹ. Ọlọrun n fẹ ki a dagba ninu awọn nkan wọnyi. Ninu II Peteru 1:5-11 a gbà wa niyanju lati dagba ati lati ni kún eyiti a ni, ki a ma ba ja Ọlọrun tilẹ. Peteru tun kọwe pe ki “ẹ mā dagba ninu ore-ọfẹ, ati ninu imọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi” ki a ma baa ṣubu kuro ninu iduro-ṣinṣin ati ijolootọ wa (II Peteru 3:18).
Nigbati ọmọde kò ba dagba soke mọ ati ti kò tẹwọn ju bi o ti wà tẹlẹri, a ma n mọ pe o nidi: ara ẹni bẹẹ ko da ati pe nkan kò rọgbọ; oun yoo kú ayafi bi o ba ri iranlọwọ gbà. Bẹẹ gẹgẹ ni o ri fun Onigbagbọ. Ohun kan ti ṣẹlẹ bi eniyan kò ba dagba mọ. Alaisan ni nipa ti ẹmi, nkan kò si rọgbọ fun un. Iru ipo bayi yoo yọrisi ikú ayafi bi o ba kepe Ọlọrun fun iranwọ.
Onigbagbọ wà fun Oluwa lojojumọ. Jijẹọmọ-lẹhin Oluwa lọjọỌsẹ tabi ki a maa digba ṣe rere kò to rara. Ninu è̩kọ yi a ti kọọpọlọpọ ohun rere ti Onigbagbọ nṣe lati inu iwe Paulu ati Peteru. Ki i ṣe wi pe eniyan n ṣe nkan wọnyi ki o ba le di Onigbagbọ. O n ṣe wọn nitori pe o jẹ Onigbagbọ ni. Ohun ti o wà niwaju rè̩ nigbagbogbo ninu èro rè̩ ni lati wu Ọlọrun ati lati ṣe ifẹ Rè̩. Nigbana ni Oluwa ati gbogbo aye yoo mọ nipa igbesi-aye rè̩ pe Onigbagbọ ni i ṣe.
Questions
AWỌN IBEERE1 Tani o kọ iwe Romu?
2 Tani a si kọọ si?
3 Bawo ni eniyan ṣe le jẹẹbọ aaye fun Ọlọrun?
4 Kin ni o maa n jẹ ki eniyan jẹ olootọ si Ọlọrun?
5 Kin ni eniyan le maa ṣe lojojumọ lati le di alagbara nipa ti ẹmi?
6 Ọna wo ni a fi le mọ pe Onigbagbọ ni ẹniyan i ṣe?
7 Kin ni iṣe si Onigbagbọ si ohun ti i ṣe buburu?
8 Bawo ni Onigbagbọ ti nilati ṣe si awọn ti o ṣe e ni iwọsi?
9 Kin ni isọdimimọ ma n ṣe fun eniyan?
10 Kin ni didagba ninu oore-ọfẹ jẹ?