Lesson 358 - Junior
Memory Verse
“Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mā fi tọkàntọkàn ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa, ki si iṣe fun enia” (Kolosse 3:23).Notes
FifẹỌlọrun
“Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹỌlọrun Oluwa rẹ. Eyi li ekini ati ofin nla” (Matteu 22:37, 38).
Ọpọ eniyan ni o wa ni aye ti wọn ki i ṣe Onigbagbọṣugbọn ti wọn mọ pe o yẹ ki awọn fẹran Ọlọrun. Wọn a maa sọ pe wọn fẹẸ. Olukuluku eniyan ni a bi ifẹ kan mọ ninu ara rè̩ lati sin ohun kan, ati lati fẹẹnikan ti o tobi ju u lọ. Awọn ti kò mọ nipa Ọlọrun tootọ a maa saba bọ oriṣa.
S̩ugbọn ni ọpọlọpọ igba awọn eniyan lẹhin ti wọn ti ṣe gbogbo eto iṣẹ-isin wọn si Ọlọrun, maa n kùna lati fi iṣẹ-isin wọn diwọn igbesi-aye wọn ojoojumọ laarin awon ẹlomiran. Jesu wi pe a nilati fẹran Oluwa Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkàn wa, ati pe eyi li ekinni ati ofin nla. S̩ugbọn ki i ṣe eleyi nikan ni ofin.
FifẹẸnikeji Rẹ
Jesu fi kún ofin kinni yi: “Ekeji si dabi rè̩, Iwọ fẹọmọ-nikeji rẹ bi ara rẹ” (Matteu 22:39). Awọn eniyan le wi pe awọn fẹran Oluwa, o si le ṣoro fun wa lati lè fihan pe bẹẹkọ. S̩ugbọn a le yara mọ bi eniyan ba fẹran ẹnikeji rè̩ tabi bẹẹkọ. Ẹnikeji wa le jẹẹnikẹni ti ohun kan pawapọ pẹlu rè̩. Amofin kan n beere lọwọ Jesu nigbakan pe, “Tani ẹnikeji mi?” Jesu sọ itan Alaanu ara Samaria fun un. Ọkunrin kan ti bọ si ọwọ awọn ọlọṣa wọn si ti ṣá a li ọgbé̩ pupọ. Bi o si ti wà bayi li ẹba ọnà, alufa kan kọja ni ẹgbẹ rè̩. Ẹniti a kasi aṣoju Ọlọrun ni aye. O tọ ki o fi aanu hàn fun ọkunrin ti o gbọgbé̩ yi gẹgẹbi Jesu ti n fẹ. S̩ugbọn alufa yi tobi tobẹẹ gẹ loju ara rè̩ ti ko fi naani lati ṣe iranwọ fun ọkunrin alaini oluranlọwọ yi. Ọmọ Lefi ti o kọja nibẹ lẹhin eyi paapaa jẹẹni ti o ni ìpin ninu isin Tẹmpili. Itọju awọn alaisan ati awọn ti a n pọn loju nilati pẹlu iṣẹ ti o n ṣe. Nitori eyi o tọ fun un lati ran ọkunrin yi lọwọ bi kò tilẹ fẹran rè̩. S̩ugbọn oun pẹlu kọja lọ “niha keji.”
Lẹhin eyi ara Samaria kan de ibè̩, ẹni ti kò tilẹ wi pe ẹlesin kan ni oun bi alufa ati ọmọ Lefi nì ti wi pe awọn jé̩, ṣugbọn o ni ifé̩ ninu ọkàn rè̩ si ọkunrin ti o wà ninu wahala yi, o si ran an lọwọ.
Lẹhin ti Jesu sọ itan yi tan, O bere lọwọ amofin na pe: “Ninu awọn mẹtẹta wọnyi, tani iwọ rò pe iṣe ẹnikeji ẹniti o bọ si ọwọ awọn ọlọṣà?”(Luku 10:36). Ẹnikẹni ni o le dahun ibeere yi. Bẹẹ gẹge, ẹnikẹni ti o n fẹ iranwọ wa ni ẹnikeji wa.
A le pe awọn ara ile wa paapaa ni ẹnikeji wa. O fẹrẹ jẹ pe gbogbo awọn iyá li o n gbọ pe awọn ọmọ wọn a maa huwa ti o dara ni ile ọré̩ wọn ju bi wọn ti n ṣe ni ile wọn lọ. O ṣeeṣe ki awọn ọmọde maa rò pe kò tọ fun wọn lati jẹ oninu rere ati pe ki wọn si maa ronu lati ṣe rere si awọn ọmọ iya wọn l’ọkunrin ati l’obinrin. S̩ugbọn bi ifẹ Jesu ba wà ninu ọkàn wa, a o fẹran gbogbo eniyan.
Ẹmi sọ fun Johannu Apọsteli lati kọwe: “Bi ẹnikẹni ba wipe, emi fẹran Ọlọrun, ti o si korira arakunrin rè̩, eke ni: nitori ẹniti kò fẹran arakunrin rè̩ ti o ri, bawo ni yio ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti on kò ri?” (I Johannu 4:20). Bi a bá kọ lati ma bọwọ fun ara ode; a o si pa awọn ofin rere ti ilẹ wa mọ pẹlu. A sọ fun wa pe: “Nitorina ẹ san ohun ti o tọ fun ẹni gbogbo: owo-ode fun ẹniti owo-ode iṣe tirè̩: owo-bode fun ẹniti owo-bode iṣe tirè̩; è̩ru fun ẹniti è̩ru iṣe tirè̩; ọlá fun ẹniti ọlá iṣe tirè̩: (Romu 13:7). Orilẹ-ède wa, ijọba, ati awọn ilu wa ni awọn ofin ti a ṣe fun anfaani awọn ọmọ-ibilè̩; ki agbájọpọ awọn eniyan ba le maa gbé pọ ni alafia, a nilati pa awọn ofin wọnyi mọ. “Ki olukuluku ọkàn ki o foribalẹ fun awọn alaṣẹ ti o wà ni ipo giga. Nitori kò si aṣẹ kan, bikoṣe lati odọỌlọrun wá: awọn alaṣẹ ti o si wà lati odọỌlọrun li a ti lana rè̩ wá” (Romu 13:1).
Ojuṣe awọn Oṣiṣẹ
Awọn eniyan ti a m ba ṣiṣẹ pọ paapaa jẹ aladugbo wa. A nilati huwa si wọn lọna ti wọn o fi mọ pe ọmọỌlọrun li awa I ṣe. Paulu Apọsteli kọwe si Timoteu pe: “Ki gbogbo awọn ti iṣe ẹrú labẹ iru mā ka awọn oluwa ti o ni wọn yẹ si ọlá gbogbo, ki a ma bā isọrọ odi si orukọỌlọrun ati è̩kọ rè̩. Awọn ti o si ni oluwa onigbagbọ, ki nwọn máṣe gan wọn, nitori arakunrin ni nwọn; ṣugbọn ki nwọn tubọ mā sin wọn, nitori awọn ti iṣe alabapin iṣẹ rere wọn jẹ onigbagbọ ati olufẹ” (I Timoteu 6:1, 2).
A le ṣalai ka ara wa si ẹrú, ṣugbọn bi a ba n ṣiṣẹ fun ẹnikan, a nilati ṣiṣẹ ni kikun fun owo ti a n san fun wa. Nigba miran ẹni ti o gbani siṣẹ le jẹẹni ti kòṣe ba ro ero, eyi a si mu ki o ṣoro lati ba a ṣiṣẹ pọ. Eyi paapa ko da wa lare bi a ba kùna lati ṣiṣẹ wa ni kikun fun owo naa ti a n gba. Peteru kọ akọsilẹ pe: “Ẹnyin ọmọ-ọdọ, ẹ mā tẹriba fun awọn oluwa nyin pẹlu ibẹru gbogbo; ki iṣe fun awọn ẹnirere ati oniwa tutu nikan, ṣugbọn fun awọn onrorò pẹlu. Nitoripe eyi ni itẹwọgba, bi enia ba fi ori ti ibanujẹ, ti o si njiya laitọ, nitori ọkàn rere si Ọlorun” (I Peteru 2:18, 19). A o gba erè ti o tobijù li Ọrun fun awọn nkan ti a jiya nitori rè̩ nihin, ti o si dabi ẹnipe a ko gba erè kan – ki o má tilẹ si wipe, ‘O ṣeun” – ju erè ti a o ri gbà fun awọn nkan ti o ti mu erè wá fun wa li aye.
Jesu wi pe: “Ẹ kiyesi ara ki ẹ máṣe itọrẹānu nyin niwaju enia, ki a ba le ri nyin: bi o ba ri bḝ, ẹnyin kò li ère lodọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun” (Matteu 6:1). Ohunkohun ti a ba ṣe, bi a ba ṣe e fun iyin eniyan, a ti gba èrè wa nihin. Ẹ jẹ ki a ṣiṣẹ fun Jesu, laipariwo, boya ki a ma tilẹ ri wa, ki a ba le ni iṣura ni Ọrun.
Gẹge bi fun Oluwa
Igba pupọ ni o n ṣoro fun ẹniti o n ṣiṣẹ fun ẹlomiran lati mọ pe oun n ṣe e fun Oluwa. Nigba ti Paulu kọwe si awọn ara Efesu, o wi pe: “Ẹ mā gbọ ti awọn oluwa nyin nipa ti ara, pẹlu ibẹru ati iwariri, ni otitọọkàn nyin, bi ẹnipe si Kristi, … ẹ mā fi inurere sin bi si Oluwa, ki si ṣe si enia” (Efesu 6;5-7). Oju Ọlọrun n bẹ lara ohun gbogbo ti a n ṣe. O ri awọn ibi ti o ṣoro ti a nilati là kọja, O si ti ṣeleri pe Oun ki yoo fi wa silẹ bẹẹni Oun ki yoo kọ wa; Oun yoo si fun wa li ere iṣẹ rere wa bi a ba ṣe wọn bi fun Un.
Nigbati Paulu kọwẹ si awọn ara galatia, o wi pe, “Ẹ má si jẹ ki agara da wa ni rere iṣe: nitori awa o ká nigbati akoko ba de, bi a kò ba ṣe ārè̩.” O tun wi pẹlu pe: “Ẹ jẹki a ma ṣõre fun gbogbo enia, ati pāpa fun awon ti iṣe ara ile igbagbọ” (Galatia 6:9, 10).
Awọn ẹlomiran rò pe nitori pe awọn n ṣiṣẹ fun ẹnikan ninu ijọ, kòṣe danindanin fun wọn lati ṣiṣẹ karakara bi o ti yẹ ki wọn ṣe fun ara ode. S̩ugbọn nigba gbogbo ni a gbọdọ fi otitọọkàn, ni ọna ti iṣẹṣiṣe gan. Paulu Apọsteli gba awọn Onigbagbọ niyanju pe: “ẹ máṣe ọlẹ” (Romu 12:11). Bi a ba mọè̩tọ awọn ọrẹ wa fun wọn, wọn yoo jẹọrẹ wa fun ọjọ pipẹ, bẹẹni ibukun Ọlọrun yoo si wa lori aye wa.
Ọlọrun paapaa n ba awọn oga ibiṣẹ sọrọ kan. “Ẹnyin oluwa, ẹ mā fi eyiti o tọ, ti o si dọgba fun awọn ọmọ-ọdọ nyin; ki ẹ si mọ pe ẹnyin pẹlu ni Oluwa kan li ọrun” (Kolosse 4:1). Alaiṣõtọọga yoo jiya iwa aitọ rè̩ ni ọjọ idajọ (Jakọbu 5:1-6).
Ofin Wura
Nigba ti Jesu fun wa ni Ofin Wura, O wi pe: “Nitorina gbogbo ohunkohun ti ẹnyin ba nfẹ ki enia ki o ṣe si nyin, bḝni ki ẹnyin ki o si ṣe si wọn gẹgẹ” (Matteu 7:12). O wi bayi pe “enia,” eyini ni pe gbogbo eniyan -- ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọde – gbogbo orilẹ-ede, awọn eniyan mimọ ati awọn ẹlẹṣẹ.
A sọ fun ni pe gbogbo wahala ti o wà ninu aye ni yoo dopin bi olukuluku eniyan ba pinnu loorọọjọ kan lati tẹle Ofin Wura yi. Ki yoo si ẹmi iwọra lati gba agbara, ki yoo si ṣiṣe awọn ẹlomiran ni iwọsi ki a ba le ri ojurere fun ara wa. Ọlọrọ ki yoo ni talaka lara mọ; awọn ọga-ibiṣẹ ki yoo fi iṣẹ pá awọn oṣiṣẹ lori; oṣiṣẹ yoo ṣe ohun gbogbo ti o tọ fun ọga rè̩, ati jubẹlọ pẹlu bi o ba le ṣe. Awọn arakunrin ati arabinrin ki yoo jà; awọn ọkọ ati aya yoo maa fi ifẹ ati ọwọ ba ara wọn lò. Ki yoo si iyapa ati ikọsilẹ, ki yoo si si awọn ọmọde ti kò ni olutọju. Bawo ni aye iba ti dùn to? Iru aye ti Jesu n fẹ ki a maa gbe inu rè̩ li eyi. Nitorina ni O ṣe fun wa ni iru ofin wọnyi fun igbesi-aye wa.
Questions
AWỌN IBEERE1 Kin ni ofin ikinni ati nla?
2 Ewo ni ekeji ti o si dabi rè̩?
3 So itan Alaanu ara Samaria.
4 Kin ni ṣe ti ara Samaria naa fi jẹ aladugbo rere?
5 Kin ni Ọlọrun pe ẹniti o wi pe oun fẹran Ọlorun ṣugbọn ti kò fẹran aladugbo tabi arakunrin rè̩?
6 Bawo ni a ṣe nilati huwa si awọn ẹniti a n ṣiṣẹ fun?
7 Ka Ofin Wura?
8 S̩e apejuwe bi aye yoo ti ri bi gbogbo eniyan ba tẹle Ofin Wura.