Lesson 359 - Junior
Memory Verse
“Ẹnikẹni ti o ba pa ẹnu ati ahọn rè̩ mọ, o pa ọkàn rè̩ mọ kuro ninu iyọnu” (Owe 21:23).Notes
Ẹda Ọlọrun
Ọlọrun da eniyan ni aworan ara Rè̩. O fun Adamu ati Efa, ọkunrin ati obinrin akọkọ, ni ọgba daradara kan lati maa gbe inu rè̩. Wọn a maa ba Ọlọrun sọrọ bi O ti n rin ninu ọgba ni itura ọjọ. Dajudaju ayọ wọn nilati pọ nibẹ ki o to di pe wọn gba èké Satani gbọ, ti wọn si dè̩ṣẹ. Wọn ṣaigbọran si Ọlọrun wọn si gbiyanju lati farapamọ kuro niwaju Rè̩. Ẹṣẹ a maa yà eniyan kuro lọdọỌlọrun. Adamu ati Efa ko le gbe ninu ọgba daradara nì mọ, nitoripe wọn ti ṣe ohun ti kò tọ. Ọkan ninu awọn ọmọ wọn ṣe ohun ti kò dara pẹlu, a si jẹniyà fun è̩ṣẹ rè̩. Kaini pa arakunrin rè̩, Abẹli, nitori pe Kaini jowu Abẹli. Lẹhin eyi o purọ fun Ọlọrun o si gbiyanju lati bo è̩ṣẹ rè̩ mọlẹ, ṣugbọn Ọlọrun mọ ohun ti o ṣẹlẹ. Nitori è̩ṣẹ rẹ, Kaini sa kuro niwaju Ọlorun o si fi ile rè̩ silẹ. Igba kan wà ti inu Ọlọrun bajẹ pe Oun da eniyan si aye. Dipo ti eniyan iba fi tẹle Ọlọrun, o kun fun iwa buburu.
Fun Ifẹ Tirẹ
Jesu, ỌmọỌlọrun, wà pẹlu Baba Rè̩ nigba dida aye. A ka a wi pe, “Nipasẹ rè̩ li a ti dá ohun gbogbo, ati fun u” (Kolosse 1:16). A dà ohun gbogbo lati maa fi ọlá ati iyin fun Ọlọrun. Ninu Ifihan a kà nipa orin iyin kan: “Oluwa iwọ li o yẹ lati gba ogo, ati ọlá ati agbara: nitoripe iwọ li o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rè̩ ni nwọn fi wà ti a si da wọn” (Ifihan 4:11). A ti wi bayi pe gbogbo è̩dáỌlọrun ni o nyin In, afi eniyan. “Awọn orun nsọrọ ogo Ọlorun ati ofurufu nfi iṣẹ owọ rè̩ hàn” (Orin Dafidi 19:1).
Ara eniyan gbọdọ jẹ tẹmpili Ọlọrun alaaye, ṣugbọn Ọlọrun kò le gbe ninu awọn miran nitori pe è̩ṣẹ wà nibẹ. Awọn ẹlomiran a maa gba ẹṣẹ wọn làye lati mu wọn lọ sinu ibi. Awọn ẹlomiran a maa fi ọwọ wọn jale, wọn a si maa fi pa ẹlomiran lara. Ẹnu ati ahọn awọn ẹlomiran a maa sọ ohun buburu gbogbo.
Didun inu Ọlọrun ni pe ki a lo ahọn wa fun ogo Rè̩. A kà ninu Orin Dafidi ti o gbẹhin pe, “Jẹ ki ohun gbogbo ti o li ẹmi ki o yin Oluwa. Ẹ fi iyin fun Oluwa” (Orin Dafidi 150:6). A tun ri kà ninu Orin Dafidi miran pe: “Ẹ fi iyin fun Oluwa: nitori ohun rere ni lati ma kọ orin iyin si Ọlọrun wa” (Orin Dafidi 147:1). Awọn eniyan Ọlọrun a maa lo ahọn wọn lati gbadura, lati mu awọn ẹlomiran lọkanle, lati jẹri Jesu ati lati sọ nipa Rè̩ fun awọn ẹlomiran.
Eya ara kekee
Bio tilẹ jẹ pe ahọn eniyan jẹè̩ya kekere ninu ara, ohun buburu ni o si ṣoro lati ṣakoso. Awọn ẹye, awọn ẹranko awon ohun ti n rakò, ati awon eda inu omi ni eniyan ti tù loju. Nigba ti awọn eniyan ba n fẹ lati gun ẹṣin, wọn a fi ijanu si I li ẹnu ki wọn ba le ṣe akoso rè̩. Nipa ijanu yi, ẹṣin a maa ṣe ifẹẹniti o gun un lati lọ s’ọtun tabi s’osi tabi lati duro. “S̩ugbọn ahọn li ẹnikẹni kò le tù loju; ohun buburu alaigbọran ni, o kún fun oró iku ti ipani.” S̩ugbọn Ọlọrun le tù ahọn loju.
Ina
Ahọn jẹẹya kekere ninu ara wa ṣugbọn o le ba ọpọlọpọ nkan jẹ. Ohun ti a ba ti sọ jade kòṣe igbémi mọ. Ẹniti o ba gbọ ohun ti a sọ le ma ranti rè̩ fun ọjọ pipẹ lẹhin ti awa ti gbagbe. “Ina si ni ahọn.” Iná le jẹ ibukun fun eniyan. A n lo o lati fi se ounjẹ, lati fi mu ile gbona nigba otutu, ati lati fi ṣe awon ohun rere bawọnni bi a ba loo daradara. S̩ugbọn ina le ṣe ọpọlọpọ ibi pẹlu. Ani ina kekere paapaa! Bi a ba jowọ rè̩, yoo ràn yoo si maa pọ si i titi yoo yoo fi jo ọpọlọpọ ibugbe ati ọpọlọpọ ile, ọpọẹmi a si ṣòfò. “Iná si ni ahọn.” Ahọn le mu ọpọlọpọ ibukun wá. O si le mu iparun ti ako le fẹnusọ wá, nipa ṣiṣe ofófó diẹ, ti a ko le tunṣe mọ lai. Iwa ilè ko ahọn nijanu ti pa igbesi-aye awọn eniyan lara, o ti ba awọn miran jẹ, o si ti pa awọn miran run.
Sisọ Ibi
Igba miran wà ti awon ẹlomiran maa n mọọmọ sọrọ irira ati ọrọ lile. Wọn a maa kà si ohun ti o yẹ ki awọn ṣe lati “gbẹsan” tabi lati fiya jẹẹlomiran nipa ọrọẹnu wọn. O dabi ẹnipe awọn ẹlomiran ma n fẹ fi iya jẹ awọn ẹlomiran ni iru ọna bayi. Bi idajọ tabi ijiya kan ba tọ, ti Oluwa ni lati mu u wá. “Ẹ máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni … Oluwa wipe, Temi li ẹsan, emi o gbẹsan” (Romu 12:17-19).
Nigbamiran o tọ fun awọn ti o wà nipo aṣẹ -- awọn obi, awọn olukọ, tabi awọn alufa – lati ba awọn ọmọde wi tabi awọn ẹlomiran. Bi o tilẹ jẹ pe o le ma dùn mọẹniti o n baniwi ati ẹniti a n bawi, bi ọrọ na tilẹ dabi ẹnipe o le ni akoko na, Oluwa nfẹ ki a baniwi. A kà a lati iwe Owe pe: “Nàọmọ rẹ nigbati ireti wa” (Owe 19:18), ati pe, “Máṣe fa ọwọ ibawi sẹhin kuro lara ọmọde” (Owe 23:13).
Igbamiran wà ti awọn ẹlomiran ma n sọọrọ eke ati è̩tan. Fun igba diẹ o le dabi ẹni pe wọn n jere nipa ṣiṣe bẹẹ, ṣugbọn ara wọn ni wọn n ṣe ni ibi. A ka ninu Owe pe: “Ini iṣura nipa ahọn eke, o jẹẽmi ti a ntì sihin tì sọhun lọwọ awọn ti nwá ikú kiri” (Owe 21:6). “Irira loju Oluwa li ahọn eke” (Owe 12:22): ati pe, “Ẹlẹri eke ki yio lọ laijiya, ẹniti o si nṣeke yio ṣegbe” (Owe 19:9). “Awọn eke gbogbo” wà larin awọn ti a o sọ sinu adagun ti n fi iná ati sulfuru jó lati ma jó titi lai (Ifihan 21:8).
Aṣisọ ninu ọrọ
Nigbati awọn ẹlomiran ba sọrọ ti ko dara wọn a maa ṣe awawi pe o ṣèsí bọ lẹnu wọn ni. Wọn le sọọrọ ti wọn ko fẹ lati sọ, ṣugbọn nitoripe ọrọ buburu wọnni wà ninu wọn a si jade bẹẹ. Ibinu ati ikorira ninu ọkàn a maa mu ki ahọn ma sọrọ buburu jade. Nigbati è̩ṣẹ ba wà ninu ọkàn gbogbo ara ni yio bajẹ. Ẹṣẹ, gẹgẹ bi iwukara, a maa kó ba gbogbo ara eniyan. “Iwukara kiun ni imú gbogbo iyẹfun wu” (Galatia 5:9). Iru ipo ti ọkàn wà a maa han ninu ọrọ ati iṣe eniyan. “Ju gbogbo ohun ipamọ, pa aiya rẹ mọ; nitoripe lati inu rè̩ wá ni orisun iye” (Owe 4:23). Jesu wi pe: “S̩ugbọn nkan wọnni ti o ti ẹnu jade, inu ọkàn li o ti wá; nwọn a si sọ enia di alaimọ” (Matteu 15:18).
Ninu ọkan
A le ṣalai ri è̩ṣẹ ti o wà ninu ọkàn ṣugbọn a maa hàn ninu ọrọ ti o n ti ẹnu jade. O le mú ibura, èké, ihin èké, ofófó, isọkusọ, ati awọn ọrọ ti kò nilari ati ọrọ buburu. Nigbati eniyan ba ri igbala, awọn è̩ṣẹ ti o wà ninu ọkàn yio kuro. IfẹỌlorun ninu ọkàn eniyan yoo mú ki o maa sọọrọ rere. Orisun kan ko le sun omi tutu ati omiró jade. Wọn o dapọ. Omi tutu naa yoo si di omiró. Bakanna ni kò yẹ ki èpe, ègun ati ire ki o maa jade lati ẹnu kanna wá. Ọrọ buburu wọnni yoo ba ọrọ rere wọnni jẹ. Ọrọ buburu kanṣoṣo ba gbogbo igbesi-aye rere jẹ.
Lẹhin ti eniyan ba ri igbala, Satani yoo gbiyanju lọna pupọ lati mu ki o sọọrọ ti kò tọ. IfẹỌlọrun ninu ọkàn Onigbagbọ yoo ran an lọwọ lati kó ahọn rè̩ nijanu. Oun yoo maa gbadura pupọ yoo si ma pa ara rè̩ mọ ninu Ẹmi dipo ki o maa sọrọ wérewérẹ. Oun yoo ma yẹra fun ọrọ asọju ati sisọrọ laironu. Igba ọrọ sisọ wà bẹni igba idakẹjẹ si wà. (Oniwasu 3:7).
Eredi Kan
Ẹ jẹ ki a pa ahọn wa mọ, ki a si kiyesi ọrọị Onipsalmu ti o wi pe: “Pa ahọn rẹ mọ kuro ninu ibi ati ète rẹ kuro li è̩tan sisọ” (Orin Dafidi 34:13). Dafidi wi pe: “Emi o ma kiyesi ọna mi, ki emi ki o má fi ahọn mi ṣẹ” (Orin Dafidi 39;1), “Emi ti pinnu rè̩ pe, ẹnu mi ki yio ṣẹ” (Orin Dafidi 17:3), ati pe, “Ahọn mi yio si má sọrọ ododo rẹ ati ti iyin rẹ ni gbogbo ọjọ” (Orin Dafidi 35:28). Nipa ṣiṣe eyi ki iṣe pe awa yio pa ara wa mọ kuro ninu iyọnu nikan (Owe 21:23), ṣugbọn a le jẹ ibukun fun awọn ẹlomiran pẹlu.
A ka lati inu Owe pe: “ahọn olõtọ dabi āyọ fadaka: Ete olododo mbọọpọlọpọ enia” (Owe 10:20, 21). Awọn ti o murasilẹ fun bibọ Oluwa li a fi wé iyawo rere ẹniti a sọ nipa rè̩ pe, “Ati li ahọn rè̩ li ofin iṣeun” (Owe 31:26).
Questions
AWỌN IBEERE1 Fun ifẹ inu tali a dá wa?
2 Tẹmpili tani ara wa iṣe?
3 Ọna wo li ahọn gba jọịna?
4 Kin ni ṣe ti orisun kan kò le sun omi tutu ati omiró jade?
5 Bawo ni ibukun ati egun ti ṣe le jade lati ẹnu kanna wá?
6 Kin ni o n mu ki eniyan sọọrọ buburu?
7 Kin ni le ṣakoso ahọn ọmọ-eniyan ki o ma ba ṣisọ?
8 Ọna wo li ahọn gba jẹ ohun buburu alaigbọran ti o kun fun oró?
9 Bawo ni eniyan ṣe le ṣọẹnu rè̩ ki o ma ba sọọrọ buburu?
10 Iru ọrọ wo ni Dafidi pinnu lati maa sọ?