Lesson 360 - Junior
Memory Verse
“Fi ibukún fun Oluwa, iwọọkàn mi, má si ṣe gbagbe gbogbo ore rè̩; ẹniti o dari gbogbo è̩ṣẹ rẹ ji; ẹniti o si tan gbogbo àrun rẹ” (Orin Dafidi 103:2, 3).Notes
Apẹrẹ Rere
Jakọbu, ẹniti o kọ Episteli yi, ni imọ nipa igbesi-aye awọn woli Ọlọrun ti o wà ni aye lọpọlọpọọdun ṣiwaju rè̩. Wọn jẹ apoẹẹrẹ fun Jakọbu, ati fun awa naa pẹlu, niti suuru, adura, ati igbagbọ. Boya nigbati Jakọbu gbọ nipa ipọnju Jobu ati ijiya Jeremiah ẹniti wọn sọ sinu ọgbun, o le ṣalai mọ iru ijiya nla ti o wà lọjọ iwaju fun oun paapaa. Awọn Onigbagbọ a maa di alagbara sii nigbati wọn ba ri igboya awọn ẹlomiran. Gbogbo eyi jẹ iranlọwọ fun Jakọbu lati mura silẹ fun ikú ajẹrikú ti yoo kú, laipẹ lehin ti o kọ Episteli yi, gẹgẹ bi iwe itan ti sọ fun wa.
Jijiya fun Kristi
Ade iye kan nduro de awọn eniyan mimọ wọnyi ti igba Majẹmu Lailai ati Titun, ti wọn fi ẹmi wọn lelẹ fun Oluwa. Lode oni paapaa awọn Kristiani n sọẹmi wọn nù fun Kristi. Nitootọ, Jesu wipe: “Ẹnikẹni ti o ba fẹ gbàẹmi rè̩ là, yio sọọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọẹmi rè̩ nù nitori mi, yio ri i” (Matteu 16:25). Kini itumọ eleyi? Itumọ rè̩ ni pe awọn ti wọn tẹle Jesu ti wọn jiya fun Un ti wọn si fi ẹmi wọn lelẹ fun Un, yoo ni iye ainipẹkun lẹhin aye yi. Nigba miran Jesu a pe ẹnikan lati fi ile rè̩ silẹ lati jẹ ajihinrere. Awọn ọmọde ti wọn kò i ti dagba pupọ le fi ara wọn rubọ, bi Jesu ba fa bibọ Rè̩ sẹhin ti Ẹmi Ọlorun si pe wọn ninu ọkàn wọn nigbati wọn dagbà to lati lọ, wọn le lọ si ilẹ ajeji ki wọn si sọn ọna igbala di mimọ fun awọn eniyan. A o kọ ninu Ẹkọ 365 nipa ipe ti o n jade lati iha gbogbo aye wá fun awọn ajihinrere.
Iṣẹ ti a fi OtitọỌkan ṣe
Ni ọdun diẹ sẹhin, Ọlọrun pe ọdọmọkunrin ara ilu Portland kan lati sin In. Oun a maa ṣakiyesi bi anfaani kan yoo ba ṣi silẹ fun oun lati ṣe iṣẹ kekere kan ninu ile Ọlọrun. O kiyesi pe awọn adèna a maa lọ kó iwe orin bi awọn eniyan ti n de inu ile-isin. Bi o si ti n dagba o si di alohun-elo-orin ninu ijọ ati lẹhin eyi o di oṣiṣẹ ati alufa, ati ajihinrere si ilẹ Afrika, o si rin irin-ajo yika gbogbo aye. O farada ọpọlọpọ inira, ṣugbọn o layọ ninu iṣẹ-isin Oluwa rè̩. “Awa a maa kà awọn ti o farada iya si ẹni ibukún” (Jakọbu 5:11). Lẹhin ti o ti sọ itan Jesu fun ọpọlọpọọkàn ti o wà ninu okunkun, Oluwa, Ẹniti n ṣe ohun gbogbo daradara, pe e lọ si Ile ni Ọrun lati wà pẹlu Jesu ati lati maa sin yika Itẹ pẹlu awọn eniyan Ọlọrun ti o ti lọṣaaju. Loni o n gbadun ère awọn olootọ -- o wà pẹlu Jesu titi lai, ati pẹlu awọn wọnni ti akọsilẹ won jẹ iṣiri fun un lati tẹsiwaju. O wà pẹlu Jakọbu ti o kọ akọsilẹ pe, “Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ” (Jakọbu 5:16). Idi rè̩ li eyi ti o fi ṣe aṣeyọri: on a maa ka Bibeli nigba gbogbo a si maa gbadura pupọ. Nigba ti eniyan ba n ka Bibeli, Ọlọrun m ba a sọrọ lati inu Ọrọ Mimọ Rè̩; nigba ti eniyan ba si n gbadura o mba Ọlọrun sọrọ.
Adura Elijah
Jakọbu darukọ Elijah gẹgẹ bi apẹẹrẹẹniti o ri idahun adura rè̩ gbà. Eniyan li oun paapaa i ṣe nipa bi a ti imọ nkan lara ati gẹgẹ bi ifẹ inu rè̩; ṣugbọn wò o bi o ṣe gbadura! Ọlọrun gbọ adura atọkanwa ọkunrin yi, O si dáòjo duro fun ọdun mẹta ati abọ. Iyan nla wá sori Israẹli gẹgẹ bi ìjiya è̩ṣẹ awọn eniyan wọnyi. Lori Oke Karmẹli ni Elijah gbe gbadura ki òjo ki o tun rọ. Igba meje ni Elijah gbadura ki idahun to de. O le jẹ pe Ọlọrun n fẹ lati dá igbagbọ Elijah wò, tabi Ọlọrun n fẹ lati kọ wa pe ki a maa taku ninu adura titi idahun yoo fi de. Elijah nilati gbadura nigba meje, ṣugbọn idahun de – si wò bi òjo ti rọ to!
Aisan
Igba kan ma n wa ni igbesi-aye olukuluku eniyan ti aisan yoo kọlu agọ-ara. Ẹsẹ kẹtala ati ẹkẹrinla ninu ori karun iwe ti Jakọbu jẹ eyiti o rọrun lati yé eniyan tobẹe ti ọmọde paapaa le mọ itumọ wọn. “Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura.” Eyi ni Onigbagbọ maa nṣe; ṣugbọn ẹniti kò ti ri igbala yoo wa õgùn ti yoo lò bi oogùn ẹfọri. “Inu ẹnikẹni ha dùn? jẹ ki o kọrin mimọ.” Eyi gan li ohun ti Onigbagbọ maa n ṣe. Lotitọ oun a maa kọrin nigba ti inu rè̩ kò tilẹ dun, ati “nigbati iṣudẹdẹ ba bolẹ.” Ọkàn rè̩ a maa yin Ọlọrun nigbati nkan kò lọ deede.
“Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rè̩, ki nwọn fi oróro kún u li orukọ Oluwa: adura igbagbọ yio si gbaà alaisan na la, Oluwa yio si gbé e dide.” Awọn àgba ijọ yoo fi oróro kùn un li orukọ Oluwa, Oluwa yoo si gbé e dide. Kò si agbara kan ninu oróro ti o le wo alaisan sàn, bẹẹni àgba ijọ ti o fi oróro sàmi si i lori kò ni agbara kan ninu ara rè̩ tabi ninu ọwọ rè̩ lati wo alaisan naa sàn. Igbagbọ ti o wà ninu ọkàn alaisan ati igbagbọ ti o wà ninu ọkàn awọn alufa naa ti wọn gbadura, pẹlu idapọ mọ igbagbọ ijọ, ni o mu iwosan wa fun alaisan.
Ohun ibanujẹ ni lati ri i pe, awọn ẹlomiran, dipo ti wọn iba pe awọn agba ijọ wọn lati gbadura fun wọn, wọn a tọ oniṣegun lọ lati ṣe ayẹwo, ẹniti i maa gba wọn niyanju pe ki wọn lọ si ile itọju awọn alaisan fun lilà. Awọn ijọ igbalode miran ki iI waasu, tabi kọni, tabi ki wọn ni igbagbọ si iwosan nipa agbara Ọlọrun, nitori eyi awọn ọmọ ijọ ki i pe awọn agba ijọ wọn fun adura, ṣugbọn wọn a pe oniṣegun dipo eyi. “Bayi li Oluwa wi: Egbe ni fun ẹniti o gbẹkẹle enia, ti o fi ẹlẹran ara ṣe apa rè̩” (Jeremiah 17:5).
“Ibukun ni fun awọn enia na ti ẹniti Ọlọrun Oluwa iṣe” (Orin Dafidi 144:15).
“Ibukun ni fun ẹniti o ni Ọlọrun Jakọbu fun iranlọwọ rẹ” (Orin Dafidi 146:5).
“Ẹniti o si gbẹkẹ le Oluwa, ibukun ni fun u” (Owe 16:20).
Wo o bi o ti dara to lati gbẹkẹle Oluwa ki a si jẹ alabukunfun ju lati wà labẹ egun Oluwa! Boya idi rè̩ ti ọpọlọpọ kò fi layọ ni pe wọn gbẹkẹle eniyan fun iwosan ara wọn dipo ki wọn gbẹkẹle Ọlọrun.
A ka a pe, “Oluwa, iwọ ni baba wa; awa ni amọ, iwọ si ni ọmọ; gbogbo wa si ni iṣẹọwọ rẹ” (Isaiah 64:8). “Amọkoko kò ha li agbara liri amọ?” (Romu 9:21). Wo o bi ọran na ti lodi to lati rò pe Ẹniti o da ara ki yoo le tun un ṣe!. Jesu lagbara lati wo gbogbo awọn ti wọn tọỌ wa pẹlu igbagbọ san, gẹge bi O ti ṣe nigbati O wà nihinyi lori ilẹ aye.
Adura ti a ko Dahun
“Kiniṣe ti gbogbo awọn alaisan lode oni ki iri iwosan nigbana?” Eyi le jẹ ibeere awọn ẹlomiran. O le jẹ aini gbagbọ tabi idi miran. Ọlọrun wi fun awon Ọmọ Israẹli pe: “Bi iwọ o ba tẹtisilẹ gidigidi si ohun OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o ba si ṣe eyiti o tọ li oju rè̩, ti iwọ o ba si fetisi ofin rè̩, ti iwọ o ba si pa gbogbo aṣẹ rè̩ mọ, emi ki yio si fi ọkan ninu àrun wọnni ti mo muwa sara awọn ara Egipti si ọ lara: nitori emi li OLUWA ti o mu ọ lara dá” (Ẹksodu 15:26). Nihinyi li a ri idi kan ti o n fa aisan: o le jẹ pe ẹni na kòṣe “eyiti o tọ.” S̩ugbọn Dafidi wi pe: “Fi ibukun fun OLUWA, iwọọkàn mi … ẹniti o dari gbogbo è̩ṣẹ rẹ ji; ẹniti o si tan gbogbo àrun rè̩” (Orin Dafidi 103:1-3). Nitorina, bi eniyan ba dè̩ṣẹ, idariji è̩ṣẹ wa, bẹẹni iwosan fun ara wà pẹlu nipasẹ adura igbagbọ. S̩ugbọn ki I ṣe gbogbo aisan ni ère è̩ṣẹẹniti o n ṣaisan.
Ijẹwọè̩ṣẹ jẹ ohun miran ti Oluwa bere – ki i ṣe fun alufa, ṣugbọn fun “ara nyin.” Bi ẹri-ọkàn eniyan ba n daamu rẹ lori ohun kan, o jẹ ohun pataki julọ fun un lati tọẹniti o ti ṣe aitọ si lọ ki o si jẹwọ fun un. Ẹ ma gbadura fun ara nyin, laipẹ jọjọ gbogbo ohun idiwọ yoo kuro.
Adura Atọkanwa
Iwọ ha jẹ Onigbagbọ ti o n fẹ ohun kan lati ọdọỌlọrun -- ọkàn ti a sọdimimọ? Fifi Ẹmi Mimọ wọni? iwosan fun ara rẹ? Awọn nkan miran ha wà ti o tun n fẹ -- anfaani kan lati ṣiṣẹ fun Oluwa? Anfaani kan lati fi talẹnti rẹ wulo fun Un. O ha n fẹ igbala ọkan ọrẹ kan tabi ẹnikan ti o fẹran? O le ri gbogbo nkan wọnyi bi o ba gbadura! Gbadura! gbadura!
S̩ugbọn, iwọ wi pe, a ko dahun adura mi. Iwọ ha ti gbadura pẹlu igbona ọkan? Adura rẹ ha jẹ atọkanwa pelu ọkàn tootọ, ati itara? Adura rẹ ha gbona bi? tabi wọn tutu? Ọlọrun Elijah ṣi n dahun adura awọn olododo l’ọkunrin, l’obinrin, l’ọmọde tabi l’agba.
“Elijah gbadura l’oke Karmeli,
Awọn Ọrun fetisi ‘gbe rẹ
Emi si mọ daju pe ki ṣ’aṣa
Ki ina ti ọrun bọ silẹ.”
“ỌLỌRUN NF’ỌPỌ ENIYAN F’ADURA!”
Questions
AWỌN IBEERE1 O kere tan, darukọ eniyan marun ninu Majẹmu Lailai ti a dahun adura wọn.
2 Kin ni eniyan nilati ṣe nigbati o ba ni ibanujẹ?
3 Kin ni ẹniti n ṣaisan nilati ṣe?
4 Kin ni abayọrisi adura igbagbọ?
5 Sọ itumọ “gbigbona” ati “eyiti o lagbara.”
6 Adura mẹta wo ni Ọlorun fi idahun rè̩ fun Elijah?
7 Kin ni ṣe ti o fi ṣe pataki fun eniyan lati gbẹkẹle Ọlọrun fun iwosan?
8 Kin ni Bibeli sọ nipa awọn ti wọn n tọ oniṣegun lọ fun iwosan?