Awọn Episteli Johannu

Lesson 361 - Junior

Memory Verse
“Bi awa ba nrin ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ni idapọ pẹlu ara wa, è̩jẹ Jesu Kristi Ọmọ rè̩ ni nwè̩ wa nù kuro ninu è̩ṣẹ gbogbo” (I Johannu 1:7).
Notes

Ọmọ-ẹhin ti Jesu Fẹran

A mọ Johannu Aposteli gẹgẹ bi “ọmọ-ẹhin ti Jesu fẹran” nigbati Jesu wà ni aye. O lo ọpọlọpọ akoko pẹlu Jesu, oun pẹlu Peteru ati Jakọbu gbadun idapo ti o jinlẹ pẹlu Olugbala ju ẹnikẹI ninu awon Apọsteli iyoku lọ.

Nigbati Johannu pari kikọ Ihinrere yi, o wi pe: “Wọnyi li a kọ, ki ẹnyin ki o le gbagbọ pe, Jesu ni iṣe Kristi na, ỌmọỌlọrun; ati ni gbigbàgbọ, ki ẹnyin ki o le ni iye li orukọ rè̩” (Johannu 20:31). Johannu gbagbọ pe Jesu ni ỌmọỌlọrun, Ẹnikeji ninu Mẹtalọkan. O kọ akọsilẹ pe: “Li atetekọṣe li Ọrọ wa, Ọrọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlorun si li Ọrọ na Ọrọ na si di ara, on si mba wa gbé” (Johannu 1:1, 14). Eyi ni Jesu.

Lẹhin ti o ti ba Jesu gbe fun ọdun mẹta ati àbọ, ti o gbọ iṣẹ-iranṣẹ Rè̩, ti o ri awọn iṣẹ-iyanu ti O ṣe, ti o si ri I ti a kan mọ Agbelebu, ati bi O ti tun wà laaye ninu ara, Johannu mọ pe Jesu ni Kristi i ṣe nitootọ. O lò gbogbo akoko ati igba rè̩ lati fi otitọ yi hàn fun awọn ẹlomiran.

Nigbati Johannu di arugbo lẹhin ọpọlọpọọdun ti o lò ni ijolootọ si Ọlọrun ati eniyan. Ọlọrun mí si i lati kọ awọn iwe wọnni ti a pamọ fun wa ninu Bibeli. Ero kanna ti o fihan ninu iwe rè̩ akọkọ li o fi bẹrẹ ekini ninu iwe wọnyi pe Jesu ti wà pẹlu Ọlọrun ni atetekọṣe, ati pe O ti wá si aye lati ba eniyan gbé.

Mimọ Nkan

Johannu sọrọ nipa awọn ohun ti o da a loju. O ju igbàọgbọn lọ ti o lo “mọ” ninu awọn iwe wọnyi. O ni idaniloju gbangba ninu gbogbo ohun ti o sọ. O si fihan wipe Jesu n gbani lọwọè̩ṣẹ O si n pani mọ kuro ninu è̩ṣẹ, O si fẹ ki gbogbo aye ki o mọ otitọ yi.

Johannu sọ idi mẹrin ti o fi kọ iwe wọnyi: lati mu ayọ awọn Onigbagbọ pọ si i; lati kilọ fun wọn lati pa ara wọn mọ kuro ninu è̩ṣẹ; lati kilọ fun wọn nitori awọn eké olukọni; ati lati fi ẹsẹ igbagbọ wọn mulẹ ninu Kristi ati lati fun wọn ni idaniloju iye ainipẹkun, niwọn-igbati wọn ba n rin pẹlu Ọlọrun ninu imọlẹỌrọ Rè̩, eyiti i ṣe Bibeli.

Ẹkun Ayọ

“Ki ayọ nyin ki o le di kikun.” Kò si ayọ tootọ ninu aye yi lai jẹ pe eniyan ni imọ igbala Jesu Kristi Oluwa. Nitori pe Jesu jẹỌmọỌlọrun, O fi agbara fun awọn eniyan Rè̩ lati maa gbé laidẹṣẹ. Oun ni Imọlẹ aye, bi a ba si n rin pẹlu Rè̩ a nilati maa rin ninu Imọlẹ.

“Eyi ni idajọ na pe, imọlẹ wá si aiye, awọn enia si fẹ okunkun ju imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru” (Johannu 3:19). Nigba ti awọn eniyan ba ṣe ohun ti ko tọ wọn a fẹ lati bò o mọlẹ. Ọmọ kekere paapaa ma nmọ igbati oun ba ṣe ohun ti ko tọ, ọpọlọpọ igba li o si maa n gbiyanju lati fi i pamọ fun iya rè̩, tabi ki o purọ nipa rè̩.

Awa ti i ṣe Onigbagbọ nilati gbe igbesi-aye wa tobẹ ti ohun gbogbo ti a ba n ṣe fi le wa si gbangba. Bi a ba fẹ lati ba Jesu rin, a nilati gbe igbesi-aye wa gẹgẹbi Tirè̩. “Ẹniti o ba wipe on ngbé inu rè̩, on na pẹlu si yẹ lati mā rin gẹgẹ bi on ti rìn” (I Johannu 2:6).

Laisi ẹṣẹ

Johannu ṣe alaye idi keji ti o fi kọ awọn episteli rè̩ bayi pe: “Ẹnyin ọmọ mi, iwe nkan wọnyi ni mo kọ si nyin, ki ẹ má ba dẹṣè̩” (I Johannu 2:1).

O ṣoro fun ẹlẹṣẹ lati gba pe eniyan le gba laye yi laidé̩ṣẹ. Ọpọlọpọ alafẹnujẹ Onigbagbọ ni o ti ka ohun ti Johannu kọsilẹ, wọn si ti sọ pe ki i ṣe ohun ti Johannu ni lọkan ni o n sọ. Wọn ni ko ṣe iṣe fun eniyan lati gbe iru igbesi-aye ti Johannu wi. S̩ugbọn Johannu gbé igbesi-aye na; bi ẹnikan ba si le ṣe e, gbogbo eniyan le ṣe e bakanna nipa iranlọwọỌlọrun.

Johannu wi pe: “Bi awa ba nrin ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ni idapọ pẹlu ara wa, è̩jẹ Jesu Kristi Ọmọ rè̩ ni nwẹ wa nù kuro ninu è̩ṣẹ gbogbo” (I Johannu 1:7). A nilati gbà wa là kuro ninu è̩ṣẹ ki a to le rin ninu imọlẹ. Nigbana nigbati a ba nrin ninu imọlẹ, Ẹjẹ Jesu n wẹ wa nù kuro ninu è̩ṣẹ gbogbo -- itumọ eyi ti I ṣe Isọdimimọ. Ẹda è̩ṣẹ, ifẹ lati dé̩ṣẹ eyiti a bi wa bi pẹlu rè̩, ni a wè̩ mọ kuro ninu aye wa.

Awọn ẹlomiran yoo ka ẹsẹ yi: “Bi awa ba wipe awa kò li è̩ṣẹ, awa tan ara wa jẹ, otitọ kò si si ninu wa” (I Johannu 1:8), wọn a si ro pe eyi fun wọṅ ni ẹtọ lati sọ pe olukuluku eniyan ni o n dè̩ṣẹ. S̩ugbọn awọn ti a ko ti itunbi, ti wọn si n rò pe awọn ki I ṣe ẹlẹṣẹ ni a kọẹsẹọrọ yi silẹ fun. Wọn ro pe awọn ti ni iwa rere to lairi igbala. Wọn ro pe awọn yoo lọ si Ọrun lai ronupiwada. Iru awọn eniyan bẹ n tan ara wọn.

Ẹsẹ ti o tẹle e sọ fun wa pe, “Bi awa ba jẹwọè̩ṣẹ wa, olõtọ ati olododo li on lati è̩ṣẹ wa ji wa, ati lati wè̩ wa nu kuro aiṣododo gbogbo” (I Johannu 1:9). Gbogbo wa li o ti dẹṣẹ; o si yẹ ki a gba pe ẹlẹṣẹ li awa i ṣe. Ohun ti o si yẹ ki a ṣe ni wi pe ki a ronupiwada awọn è̩ṣẹ wa. Nigbana Jesu yio dariji wa, a o si ma gbe laidẹṣẹ niwọn-igbati a ba n gbọran si Oluwa lẹnu.

S̩iṣẹgun ẹni Ibi ni

Johannu wi pe oun n kọwe si awọn ọdọmọkunrin nitori pe wọn ti “ṣẹgun ẹni buburu ni” (I Johannu 2:13). Lati jẹ aṣẹgun nipe ki a bori. Ẹni ibi ni ni Satani, nigbati a ba si jẹ Onigbagbọ a ki yoo fara fun idanwo ti o n gbe wà siwaju wa. “Emi ti kọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin li agbara, ti ọrọỌlọrun si duro ninu nyin, ti ẹ si ṣẹgun ẹnibuburu ni” (I Johannu 2:14). Awọn aṣẹgun a maa gbe igbesi-aye ti o bori è̩ṣẹ.

Idi rè̩ ti awọn eniyan kan fi wi pe a ko le gbe laidẹṣẹ ni wi pe wọn fẹran awọn è̩ṣẹ kan wọn ko si fẹ fi wọn silẹ. Bi eniyan ba n fẹ nitootọ lati ma gbe laidé̩ṣẹ, Ọlọrun yoo fun un li agbara.

Fifẹ aiye

“Ẹ maṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aiye, ifẹ ti baba kò si ninu rè̩” (I Johannu 2:15). O le jẹ wi pe ohun na ti eniyan fẹ ki i ṣe ohun buburu, ṣugbọn bi o ba fẹran rè̩ ju bi o ti fẹran Ọlọrun lọ ohun ti kò tọ li o n ṣe. Ọlọrun n fẹ lati wà ni ipo ekinni ninu aye wa; bi a ba si n ro nipa ile, ilẹ, owo, agbara, tabi ọlá, ju bi a ti n ro nipa Jesu lọ ifé̩ Baba kò si ninu wa. Awọ nkan aye yi yoo rekọja, bi a kò ba si ni ifẹỌlọrun ninu ọkàn wa ki yoo ku ohunkohun silẹ fun wa. S̩ugbọn bi awa ba ṣe ifẹ Baba, a o ma “wà” titi lailai.

Awọn Olukọni Eke

Idi kẹta ti Johannu fi kọ iwe wọnyi ni lati kilọ fun awọn eniyan na nipa awọn olukọni èké. Kò i ti pẹ pupọ ti a fi idi ijọỌlọrun kalẹ ti Satani fi dide lọna yi tabi ọna miran, lati ja awọn eniyan l’ole igbagbọ wọn, gẹgẹ bi o ti n ṣe lode oni.

Ọna kan ti Satani n gba ni lati mu ki awọn eniyan ṣiyemeji nipa otitọ nì pe ỌmọỌlọrun ni Jesu I ṣe, pe lati atetekọṣe ni O ti wa pẹlu Ọlọrun, ati pe nipasẹ Rè̩ ni a ti dá aye. S̩ugbọn Johannu gba eyi gbọ, o si wi pe ẹnikẹni ti kò ba gba eyi gbọèké ni, aṣodi-si-Kristi ni. Iwọ ronu nipa gbogbo awọn ti wọn n lọ si ile-isin ti wọn gba pe Jesu jẹ olukọni nla ati woli, ṣugbọn ti wọn gbagbọ pe eniyan bi awa ni Oun I ṣe. Aṣodi-si-Kristi ni iru awọn wọnni i ṣe. Bi o ba ti kọè̩kọ ni ile-è̩kọ pe lati inu ẹranko kekere ni eniyan ti jade wa, ranti pe ohun ti a fi ọgbọn ori eniyan gbekalẹ ni eyi ni, ki i ṣe otitọ. Awọn ti o ni imọ ti aye yi kò dẹkun sibẹ lati ma yi ọrọ wọn pada nipa iṣẹdalẹ aye ati awọn ti n gbe inu rè̩, ṣugbọn ỌrọỌlọrun ki i yipada. Ranti pe, Bibeli sọ nipa Jesu bayi: “Nipasẹ rè̩ li a ti da ohun gbogbo; lẹhin rè̩ a kò si da ohun kan ninu ohun ti a da” (Johannu 1:3).

Ẹmi Otitọ

Jesu wi pe nigbati Oun ba pada lọ si Ọrun Oun yoo ran Olutunu, Ẹmi Otitọ nì. “Nigbati on, ani Ẹmi otitọ ni ba de, yio tọ nyin si ọna otitọ gbogbo” (Johannu 16:13). Johannu sọrọ nipa Ẹmi otitọ ni gẹgẹbi “ifororóyàn lati ọdọẸni Mimọ ni wa;” ati pẹlu “ifororóyan ti ẹnyin ti gbà lọwọ rè̩” eyiti “o n gbe inu nyin: … ti o jẹ otitọ, ti ki si iṣe èké, ani gẹgẹ bi o ti kọ nyin. Ẹ mā gbe inu rè̩” (I Johannu 2:20, 27).

A le ri bi Johannu ti n wasu oriṣi iriri mẹta pataki nigbati o n kọ awọn Episteli rè̩, idariji è̩ṣẹ, ti a n pe ni idalare; iwẹnumọọkàn, ti a n pe ni isọdimimọ; ati ifi agbara Ẹmi Mimọ wọni – “ifororóyàn ti ẹnyin ti gbà lọwọ rè̩, o ngbe inu nyin.”

Apejuwe Johannu nipa Onigbagbọ

“Olufẹ, ọmọỌlọrun li awa iṣe nisisyi, a kò si ti ifihàn bi awa o ti ri: awa mọ pe, nigbati a bá fihan ao dabi rè̩; nitori awa o ri i ani bi on ti ri” (I Johannu 3:2). Bi a ba jẹ “ọmọ” Ọlọrun a nilati fi iwà jọ Baba wa. “Ẹnikẹni ti a ti ipa Ọlọrun bi ki idẹṣẹ” (I Johannu 3:9).

Iyatọ wà larin awọn ọmọỌlọrun ati awọn ọmọ Satani. A maa nṣakiyesi awọn ti wọn n wipe Onigbagbọ li awọn iṣe, o si ma nyanilẹnu nigbamiran pe a kò ri ọna ti wọn fi yatọ si awọn ti aye. “Ninu eyi li awọn ọmọỌlọrun nfarahan, ati awọn ọmọ Eṣu: ẹnikẹni ti kò ba nṣe ododo ki iṣe ti Ọlọrun, ati ẹniti kò fẹran arakunrin rè̩” (I Johannu 3:10).

O ha jẹ ohun pataki fun ọ lati fẹran arakunrin rẹ? ỌrọỌlọrun sọ fun wa pe “ẹnikẹni ti o ba korira arakunrin rè̩ apania ni” (I Johannu 3:15). Kò si si alaironupiwada apania kan ti yio lọ si Ọrun. A ma n fi ifẹ wa si arakunrin wa han nipa iṣe wa. “Ẹnyin ọmọ mi, ẹ maṣe jẹ ki a fi ọrọẹnu tabi ahọn fẹran, bikoṣe ni iṣe ati li otitọ” (I Johannu 3:18).

Bi awa ba n lo igbesi-aye wa gẹgẹ bi Ọlọrun ti fẹ ki a lo o, Oun yoo gbọ adura wa yoo si dahun pẹlu. “Olufẹ, bi ọkàn wa kò ba dà wa lẹbi, njẹ awa ni igboiya niwaju Ọlorun. Ati ohunkohun ti awa ba bẽre, awa nri gbà lọdọ rè̩, nitoriti awa npa ofin rè̩ mọ, awa si nṣe nkan wọnni ti o dara loju rè̩” (I Johannu 3:21, 22). Bi awa ba si n pa ofin Rè̩ mọ, Ẹmi Rè̩ yoo ba ẹmi wa jẹri pe ọmọ Rè̩ li awa iṣe.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Apele wo ni a n pe Johannu Apọsteli?

  2. 2 Kin ni ṣe ti o kọ Ihinrere Johannu?

  3. 3 Kin ni koko ọrọ awọn Episteli Johannu?

  4. 4 Sọ idi mẹta ti Johannu fi kọ awọn Episteli wọnyi.

  5. 5 Eeṣe ti awọn eniyan fi fẹ okunkun ju imọlẹ lọ?

  6. 6 Bawo ni awa Onigbagbọṣe nilati maa rin ninu aye yi?

  7. 7 Kin ni Jesu yoo ṣe fun wa bi a ba jẹwọè̩ṣẹ wa?

  8. 8 Kin ni Johannu sọ nipa awọn ti o fẹran aye?

  9. 9 Kin ni Johannu pe awọn ti kò gbagbọ pe ỌmọỌlọrun ni Jesu I ṣe?

  10. 10 Kin ni ohun ti Johannu sọ nipa fifẹ arakunrin wa?