Nahumu 2:3, 4; II Timoteu 3:1-5; II Peteru 3:3, 4; Jakọbu 5:7, 8; Matteu 24:3-28

Lesson 362 - Junior

Memory Verse
“Nitori gẹgẹ bi manamana ti ikọ lati ila-õrun, ti isi mọlẹ de iwọ-õrun; bḝni wiwáỌmọ-enia yio ri pẹlu” (Matteu 24:27).
Notes

Lori Oke Olifi

Lori Oke Olifi yi gan, nibiti Jesu yio gbe goke lọ s’Ọrun, ni Jesu joko lọjọ kan pẹlu awọn ọmọ-ẹhin Rè̩. “Sọ fun wa,” ni wọn wi fun Jesu “ kini yio si ṣe àmi wiwá rẹ, ati ti opin aiye?” Nigbana ni Jesu sọ fun wọn nipa ogun, iyàn ati isẹlẹ gbogbo ti yoo wá sori ilẹ aye ṣiwaju bibọ Rè̩. O sọ nipa awọn èké woli, tabi awọn oniwasu èké ti yoo tan awọn eniyan jẹ, ati nipa è̩ṣẹ buburu ati wahala ti yoo wa sori aye. O wipe “A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de.”

Lẹhin eyi lọjọ kan Jesu tun wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ lẹkan si i lori Oke Olifi, nibiti awọsanma gbe gba A lọ si Ọrun. “Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bḝ gẹgẹ bi ẹ ti ri I ti o nlọ si ọrun,” li ọrọ ti awọn ọkunrin meji alaṣọàla ti o duro leti ọdọ wọn sọ fun wọn (Iṣe Awọn Apọsteli 1:11).

Onigbagbọ ati Alaigbagbọ

Bi o tilẹ jẹ pe ẹgbaa ọdun ti rekọja lẹhin ọjọ iyanu nì, sibẹsibẹ nigbagbogbo ni awọn eniyan ti wà ti wọn n ṣọna, ti wọn n duro, ti wọn si n pongbẹ fun bibọ Jesu. Lode oni, Onigbagbọ tootọ kò tun n wipe, “Sọ fun wa, kini yio si ṣe ami wiwá rẹ?” ṣugbọn oun a ma wo inu Iwe MimọỌlọrun fun awọn ami wọnni, bi o si ti n ṣakiyesi ohun ti n ṣẹlẹ oun yoo mọ daju pe gbogbo ami wọnyi li o ti ṣẹlè̩. Kin ni gbogbo nkan wọnyi n sọ fun wa? Eyi ni pe Jesu le de nigbakugba!

Ẹ maṣe jẹ ki a wa larin awọn ti wọn n ṣẹfẹ ti wọn wipe: “Nibo ni ileri wiwa rè̩ gbé wà? lati igbati awọn baba ti sùn, ohun gbogbo nlọ bi nwọn ti wà ri lati igba ọjọ iwa” (II Peteru 3:4). Ileri na mbẹ ninu ỌrọỌlọrun, a si gbagbọ pe a o wà laaye a o si ri Jesu nigbati o ba n pada bọ.

Nitoripe ohun kan ko i ti ṣẹlẹ kò fihan pe ohun na ki yoo ṣẹlẹ. S̩’aaju Ikun-omi, nigbati Noa kan ọkọ nì, awọn eniyan kò gbagbọ pe ikun-omi yoo de. Wọn n fi Noa ṣẹlẹya gẹgẹ bi wọn ti n fi awọn oniwasu ododo ṣẹsin lode oni. S̩ugbọn lojiji, “omi de, ti o gbá gbogbo wọn lọ” (Matteu 24:39).

“Gẹgẹ bḝni wiwáỌmọ-enia yio ri pẹlu” (Matteu 24:39). Lojiji! Fun awọn ti kò fi oju sọna fun bibọ Rè̩. “Gẹgẹ bi ikẹkun” fun awọn ti kò wà ni imurasilẹ! (Luku 21:35). “Bi ole” fun ẹniti kò di ara rè̩ ni amure (I Tẹssalonika 5:2). “Gẹgẹ bi manamana,” ti nda eniyan niji! (Matteu 24:27). “Larin ọganjọ,” nigbati ohun gbogbo ṣokunkun! (Matteu 25:6).

Ọpọlọpọ “àmi” ni o wà ti o n kọ wa pe bibọ Jesu wa lẹhin ilẹkun. Awọn eniyan Ọlorun ti n gbé lori ilẹ aye ṣaju igba Kristi sọrọ nipa awon ohun ti yoo ṣẹlẹ ni ikẹhin ọjọ. Awọn ami ti Jesu sọtẹlẹ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ -- ogun, isè̩lẹ, idamu – gbogbo wọn li o ti ṣẹlè̩. Ọpọlọpọ awọn ọdọmọde lode oni ni o le ranti igbati wọn dagbere fun ẹgbọn wọn ọkunrin tabi baba wọn ti o lọ si ogun. Gbogbo wa ni o ti gbọ nipa isẹlè̩ ti o si ti ṣiṣẹ iparun lọpọlọpọ ni akoko tiwa yi, ati nipa iyà ati wahala ti ọpọlọpọ eniyan wà ninu rè̩ lori ilẹ aye.

Awọn Arinrin Ajo

Njẹ o ṣakiyesi nigbati o n rin irin-ajo lọ si ilu kan pe bi o ti n sunmọ ilu na ni o n ri ọpọlọpọ apejuwe ti o n fihan pe iwọ fẹrẹ de bẹ? Awọn apejuwe miran n sọ nipa ile-èro tabi ile-ounjẹ ti o wa ni ilu na; awọn apejuwe miran n fi bi ilu na ti jinna to han; bẹni awọn apejuwe miran a maa sọ fun wa akoko ti a le lò ki a to de ilu na.

L’oni a n rin irin-ajo. Olukuluku wa li o n rin irin ajo lọ si Ayeraye, awọn ohun itọka ti o han gbangba si wa li oju ọna Iye na. Laiṣe aniani, Onigbagbọ arinrin-ajo na ni iwe-amunimọna, iwe-aworan-apẹrẹ ilẹ ati ẹrọ amunimọna, bẹẹni a si ma farabalè̩ṣafiyesi iwe-amunimọna rè̩, ani Bibeli. Gẹgẹ bi o si ti n rin ọna aye lọ a maa ri awọn ami oju-ọna. Yio wo inu iwe-amunimọna rè̩. Yio si ri I dajudaju pe ibiti oun de yi wà ninu iwe-amunimana na, bẹni lẹba ọna ami ọna na si wà nibẹ pẹlu. O tẹsiwaju; laipẹ yio tun ri apejuwe miran niaju; nigbati o ba sunmọọ to lati ri I ka, yio si ri I pe apejuwe naa nsọ ohun kan ti o ti ka ninu Bibeli fun un.

Jẹ ki a fi ọkàn wa wọọkọ, ki a si ma wa ọkọ na lọ li opopo ọna ti o lọ si eti ebute. A le ri ọkọ gẹdu nlanlà lọkankan ti a ti to igi gẹdú ti o tobi pupọ sinu wọn ti wọn si n lọ si ile-è̩rọ. Lẹsẹkẹsẹẹsẹọrọ Iwe Mimọ yi yoo wa sinu ọkàn wa pe ni ọjọ imurasilẹ Rè̩, “igi firi li a o si mì titi” (Nahumu 2:3). A n wa ọkọ wa lọ, bẹni lojiji niwaju wa a ri I pe ọpọlọpọọkọ duro loju ọnà, bi a si ti duro a ri I pe ọkọ meji ti kọlu ara wọn. Lẹkan si I a tun ranti pe “iwe-atọna” wa sọ fun wa pe “Ariwo kẹké̩ ni igboro, nwọn o si ma gbún ara wọn ni ọna gbigboro.” A si gbà li ọkàn wa pe eyi ni ọjọ imurasilẹ Rè̩.

A gbọ wi pe awọn ti o wa ọkọ wọnni ti mu ọti lile eyi ti I ṣe “àmi” miran pe eyi jẹ akoko ti o ṣiwaju ipadabọ Jesu si aye. Bẹni ọro-odi nti ẹnu awọn ti afẹ-aye ti sọ di wère, ti o wa ninu ọkọ na jade, eyi pẹlu si tun jẹ ami igbà ikẹhin (II Timoteu 3:1-5).

Awọn Ami Miran

Ẹ jẹ ki a wo yika ki a ṣakiyesi awọn “ami” miran ti a le ri. A ka ninu II Timoteu 3:2, pe “ni ikẹhin ọjọ” awọn ọmọde yoo jẹ aṣaigbọran si obi. Njẹ o ti duro ki o si ronu pe nigbati o ba ṣaigbọran iwọ n ṣe ohun na ti Bibeli sọ pe ọpọlọpọ awọn ọmọde yoi maa ṣe ṣiwaju bibọ Jesu? Laiṣe aniani, o jẹ ohun pataki julọ fun iru awọn ọmọde bẹẹ lati ri igbala kiakia, ki wọn si bẹ awọn obi wọn pe ki wọn dari aigbọran wọn ji wọn, ki wọn si murasilẹ ni kikun de bibọ Oluwa. Iwọ ha jẹ alailọpé̩ si Ọlọrun fun abo Rè̩ lori ẹmi rẹ? Iwọ ha jẹ alailọpé̩ si awọn obi rẹ ati awọn ọrẹ rẹ fun iṣoore wọn si ọ ati fun ọpọlọpọ nkan rere ti o ni laye yi? Bi o ba ri bẹẹ, iwọ na pẹlu awọn eniyan ti wọn n fi idi “amì” miran mulẹ pe igbà ikẹhin li a wa yi.

Ọpọlọpọ eniyan ni wọn ki I tẹriba nidi tabili wọn lati gbadura ati lati dupẹ lowọỌlọrun fun ounjẹ ti O ran si wọn. “Eyi ni ki o mọ, pe ni ikẹhin ọjọ … awọn enia jẹ … alailọpẹ” (II Timoteu 3:2). Awọn Onigbagbọ miran paapaa ki iníọkàn ọpẹ, wọn gbagbe pe “gbogbo ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pipé lati oke li o ti wá, o si n sọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá” (Jakọbu 1:17).

Iwọ ha jẹọdọmọde Onigbagbọ ti n lọ si ile-ẹkọ ti gbgbogbo? Boya iwọ n ri i ti awọn ọmọde ti ko i ti ri igbala n huwa ti kò tọ si ọ ti won si n fi ọṣe ẹlẹya nitoripe iwọ ki iba wọn lọ si ile-ere, ile-ijo, tabi eré bọlù, ati awọn ere idaraya miran gbogbo. Iwọ ki i ṣe aṣerége ninu aṣọ wiwọ bi awọn ẹlẹṣẹ ti n ṣe, bẹni iwọ ki ifi ohun ọṣọ sara tabi ki o kun ete, le tiroo tabi kun atike. A le ta ọ nu nitoripe o yatọ ninu iṣe ati iwọṣọ rẹ. Eyi pẹlu jẹ “ami” miran nitori ỌrọỌlọrun wi pe nikẹhin ọjọ awọn eniyan yoo jẹ “alainifẹ-ohun-rere.” S̩ugbọn ọjọ kan mbọ nigbati Oluwa yoo rẹrin idamu awọn eniyan buburu, awọn ti won ko ronupiwada ẹṣẹ wọn.

Irin ajo yi le dopin laipẹ; gẹgẹbi arinrin-ajo ni si ti ri ọpọlọpọ apejuwe lati fihan pe ilu na ko jinna mọ, bakanna ni Onigbagbọ nri ọpọlọpọ awọn ami ti o n fihàn an pe Ilu Ọlorun ni wà nitorisi.

Eyiti O ṣe Pataki Julọ

Bi iwọ kò ba ti murasilẹ fun bibọ Jesu, maṣe fi ọjọ imurasilẹ dọla rara. Fi gbogbo aya rẹ wa Oluwa; wá ayọ ni ti o n ti ọdọ Rè̩ nikanṣoṣo wá. Nigbana ni iwọ wà li oju ọna ti o nlọ si Ọrun. Nigbati a ba gbàọ la, o nilati wá isọdimimọ ki o si ri I gbà ati ifi Ẹmi Mimọ ati iná wọ ni.

“Awọn ami” bibọ Jesu laipẹ n pọ si i lojojumọ -- nitorina opin ọna ko jinna mọ! O le pẹ ju bi o ti ro lọ. O ha ti murasilẹ?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ibeere wo ni awọn ọmọ-ẹhin beere lọwọ Jesu lori Oke Olifi?

  2. 2 Idahun wo ni Jesu fi fun wọn?

  3. 3 Darukọ alakọsilẹ kan ninu Majẹmu Lailai ti o sọrọ bakanna nipa awọn ami igba ikẹhin.

  4. 4 Kin ni o sọ asọtẹlẹ nipa rè̩?

  5. 5 Bawo ni a ti ṣe mọ pe nkan wọnyi ti ṣẹlẹ?

  6. 6 Kin ni ohun ti o yẹ fun wa lati ṣe ki a ba le wà ni imurasilẹ lati pade Jesu nigbati O ba de?

  7. 7 Kin ni ṣe ti o fi jẹ ohun pataki lti murasilẹ ati lati wa bẹẹ ninuimurasilẹ?

  8. 8 Kin ni awọn ẹlẹgan n wi?

  9. 9 Kin ni ybo ṣẹlẹ si awọn ti o ba kù silẹ?

  10. 10 Kin ni yoo jẹ ere awọn ti wọn murasilẹ?