Lesson 363 - Junior
Memory Verse
“Nitorina ẹ māṣọna; nitori ẹnyin kò mọ wakati ti OLUWA nyin yio de” (Matteu 24:42).Notes
Gẹgẹ bi ole L’oru
“S̩ugbọn ki ẹnyin ki o mọ eyi pe, bāle ile iba mọ wakati na ti olè yio wá, iba ma ṣọna” (Matteu 24:43). A mọ daju pe ole ki sọté̩lẹ nigbati o ba fẹ jale, ṣugbọn bi eniyan ba mọ pe ẹnikan le wá runlè̩ wọ ile oun l’oru ọjọ kan, yoo pe awọn ọlọpa lati farapamọ si itosi lati mu arufin na. A kò le ka iru imurasilẹ bẹẹ si iwa ailọgbọn. Niwọn igbati ole si le wá nigbakugba, a o sé ilẹkun wa a o si wà ni imurasilẹ. O jẹ iwa ọlọgbọn lati murasilẹ de ohun ti a mọ pe o n bọwa ṣẹlẹ.
Jesu wi pe nigbati Oun ba pada wa lati mu Iyawo Rè̩ lọ, Oun yio de gẹgẹ bi ole l’oru. Gbogbo ọrọ ti Jesu sọ jẹ otitọ wọn yoo si ṣẹ. Nitorina bi a ba jẹọlọgbọn a o murasilẹ de akoko ti Jesu yoo pè awọn eniyan Rè̩ kuro ninu aye yi.
O le jẹ ni owurọ nigbati oorun bẹrẹ si iyọ ni ilu wa, awa ti a si ti murasilẹ lati pade Jesu yoo bè̩rè̩ọjọ titun ninu awọn ọrun l’oke. Ni apa ibomiran ninu aye akoko yi yoo jẹ oru, akoko lati lọ sùn. Awọn eniyan na tilẹ ti le wi pe “o d’owurọ o,” lojijini a o si ji wọn sinu ogo bibọ Jesu, wọn o si wi pe, “ẹ kaarọ o” fun awọn mimọ ti won yoo ba pade l’oke. Nibomiran lori ilẹ aye awon eniyan yoo gbe ounjẹọsan kalẹ lati jẹ , awọn ti eti wọn si ti ṣí si ipè Jesu yoo fi ounjẹ wọn silẹ lati jẹ Ase-Alẹ Igbeyawo pẹlu Jesu ninu awọn orun. Lọjọ kan a o gbọ awọn ọrọ wọnyi: “Igbeyawo Ọdọ-Agutan de, aya rè̩ si ti mura tan” (Ifihan 19:7). Wo o bi ọjọ na yoo ti ri! S̩ugbọn a nilati murasilẹ de e.
Wiwa ni Imurasilẹ
Kin ni itumọ imurasilẹ gan an? Awọn ẹlomiran yoo wi pe: “Jesu gbà mi la kuro ninu è̩ṣẹ. Mo mọ pe a dari gbogbo è̩ṣẹ mi jí mi. Mo ranti igbati Jesu wẹọkàn mi ti O si sọ mi di mimọ. Wo iru ogo ti o kun inu aye mi nigbati Jesu fi Ẹmi Mimọ wọ mi!” Iyanu ni awọn iriri wọnyi, bi a ba si tẹsiwaju lati maa ka Bibeli ki a si maa gbadura, ki a si maa gbe igbesi-aye wa gẹgẹbi Bibeli ti kọ wa lẹhin ti a ti ri awọn iriri wọnyi gbà, a o wà ni imurasilẹ nigbati Jesu ba pè.
Iwọ ha tun fẹran gbogbo eniyan gẹgẹbi o ti fẹ wọn nigbati jesu gba ọ là? Njẹ o ranti iyipada ọkàn ti o ni si awọn ti o ti korira tẹlẹri nigbati Jesu wọ inu ọkàn rẹ? N jẹ o ha ranti bi o ti jẹ ifẹọkàn rẹ pe ki awọn ẹlomiran ni iru ayọ igbala ti iwọ ni? O gbadura kikan pe ki awọn ẹlomiran le ri igbala, o si sa gbogbo ipa rẹ lati mu ki wọn ni ifẹ si ohun ti ayeraye. Iwọ ha ni itara yi sibẹ?
Jesu gbadura fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩, “Sọ wọn di mimọ ninu otitọ; otitọ li ọrọ rè̩;” lẹhin na O tun wi pe, “Ki gbogbo wọn ki o le jẹọkan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹọkan ninu mi, ati emi ninu rẹ” (Johannu 17:17, 21). Njẹ o ranti iru alafia ti o ni nigbati Jesu sọọkàn rẹ di mimọ? Iwọ kò fẹ jiyan. Iwọ jẹ igbadun iṣọkan igbagbọ ti o wà ninu isọdimimọ. Njẹ iwọ si tun ni I bi?
Nigbati a fi Ẹmi Mimọ ati ina wọọ, Oluwa sunmọọ tobẹ ti o wu ọ pe ki o rekọja lati aye yi lọ si Ọrun. O dabi ẹnipe iṣisẹ kan ni Njẹ o tun sunmọtosi bẹẹ sibẹ? Jesu wi fun wa pe Olutunu na, ani Ẹmi Mimọ, yio wá lati wá sọ fun wa si i nipa Oun. Yoo sọ fun wa nipa ayọ ti o n duro de wa l’Ọrun. Ẹmi Mimọ wá lati sọ fun wa nipa awọn nkan ti Ibugbe Rè̩.
S̩ugbọn bawo ni o ti ni ifé̩ to loni lati gbọ nipa ile ti Jesu ti lọ pese silẹ fun ọ? O ha n sọ nipa rè̩ to bi o ti n sọ nipa ile ti o n gbe inu rè̩ nihin?
A ha ngbe igbesi-aye wa lojojumọ pẹlu èrò na ninu ọkàn wa pe Iyawo Kristi ni awa iṣe, ati pe a nilati ṣe ara wa yẹ bẹẹ? A ha n ṣọra pe ki o maṣe si ohunkohun ninu aye wa ti ki yoo té̩ Jesu lọrun bi O ba pè wa loni si Igbeyawo na? Eniyan le gbe igbesi-aye ti o dara, ki o ni itara tootọ lati mu ki awọn ẹlomiran maa gbe igbesi-aye wọn gẹgẹ bi Ofin Wura nì ti wi, sibẹ ki o má ni ifẹ Jesu l’ọkàn rè̩ gẹgẹ bi o ti ni I nigbati o ri igbala.
Sisọ Ifẹ Iṣaaju Nù
Nigbati Johannu Apọsteli wa lori Erekuṣu Patmo, a fi iran hàn an nipa iru ipo ti awọn ijọ ti o wa ni Asia wà. Ohun ti Jesu sọ fun un nipa ijọ Efesu niya: “Emi mọ iṣẹ rẹ, ati lālā rẹ, ati ìfarada rẹ, ati bi ara rè̩ kò ti gba awọn ẹni buburu: ati bi iwọ si ti dan awọn ti npè ara wọn ni apọsteli, ti nwọn ki si iṣe bẹẹ wo, ti iwọ si ri pe eleke ni wọn. Ti iwọ si farada iya, ati nitori orukọ mi ti o si fi aiya rán, ti ārè̩ ko si mu ọ. S̩ugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, pe, iwọ ti fi ifẹ rẹ iṣaju silẹ. Nitorina ranti ibiti iwọ gbé ti ṣubu, ki o si ronupiwada, ki o si ṣe iṣẹ iṣaju” (Ifihan 2:2-5).
A ti gba awọn eniyan wọnyi là nitootọ. Jesu wipe, “Ranti … ibiti iwọ gbe ti ṣubu.” Wọn ti ni ifẹỌlọrun ninu ọkàn wọn lẹẹkan ri, ṣugbọn wọn ti fasẹhin. Wọn ti ṣiṣẹ pupọ fun Jesu wọn si n ṣe e sibẹ. Wọn ti ni suru, eyiti o ju ti ọpọlọpọ eniyan ti wọn n pe ara wọn ni Onigbagbọ. Wọn tilẹ fi itara gbigbona dá iwa buburu awọn ẹlomiran lẹbi. Wọn ro pe ohun ti awọn n ṣe nì awọn n ṣe wọn fun Jesu. S̩ugbọn wọn ti sọ ifẹ iṣaju nì nù wọn kò si yẹ lati jẹ Iyawo Kristi.
ỌrọỌlọrun sọ fun wa pe bi a ba ni igbagbọ ti o le ṣi awọn oke nidi, sibẹ bi a ko bá ni ifẹỌlọrun ninu ọkàn wa, a ko jẹ nkankan. A le jọwọ ara wa lati fi ṣe ẹbọ, a le fi gbogbo owo ti a ni ran awọn talaka lọwọ, ṣugbọn eyini ki yoo sọ wa di Iyawo Kristi. A nilati ni ifẹỌlọrun ninu ọkàn wa ki a si pa a mọ sibẹ. “Ju gbogbo rè̩ lọ, ẹ ni ifẹ ti o gbona lārin ara nyin: nitori ifẹ ni mbòọpọlọpọè̩ṣẹ mọlẹ” (I Peteru 4:8).
Awọn Wundia Alaigbọn
Ninu owe awọn wundia marun ti o ṣe ọlọgbọn ati marun alaigbọn a sọ fun wa nipa awọn ẹgbẹẹlẹsin kan, ti olukuluku wọn n reti bibọ Oluwa. Gbogbo wọn ni o ro pe awọn ti murasilẹ, ṣugbọn marun ninu wọn dabi awọn ti o wà ni ijọ Efesu. Wọn ti sọ “ifẹ wọn iṣaju” nù. Awọn na pẹlu n huwa gẹgẹbi awọn marun iyoku ti n huwa. Wọn n ṣe iṣẹ kanna, ṣugbọn ọkàn wọn kò ri bakanna. Nigbakan ri wọn ti ni ifẹỌlọrun, ṣugbọn wọn ti jẹ ki o jò sọnu titi atupa wọn fi ṣofo. Ki i ṣe gbogbo awọn ti o bè̩rẹ gẹgẹ bi Onigbagbọ ni yoo wà ni imurasilẹ nigbati Jesu ba de. “Ẹniti o ba foriti I titi fi de opin, on na ni a o gbala” (Matteu 10:22).
Iyawo Kristi
Bawo ni a ṣe le gbe igbesi-aye wa ti ororo naa ki yoo fi jò danu, ki atupa wa si ṣofo? Ninu Owe 31 a ṣe apejuwe obinrin rere kan, ẹniti o dabi Iyawo Kristi fun wa.
“Aiya ọkọ rè̩ gbẹkẹle e laibẹru” (Owe 31:11). Jesu ni ọkọ na. Njẹ Oun le gbẹkẹle ọ laibẹru? Oun ti lọ nisisiyi. Njẹ o yẹ ki Oun ma ṣiyemeji nitori ihuwàsi rẹ lẹhin ti O ti lọ? Gbogbo iṣẹ wa nilati jẹ pẹlu ero yi ninu ọkàn wa: Njẹ Jesu yoo fẹ ki emi ṣe eyi bi? Bi ẹnikan ninu aye ba n ṣakiyesi iwa mi, yoo ha ri pe Iyawo Kristi ni emi iṣe? Mo ha jẹọkan pẹlu Rè̩ ninu iwa ati igbesi-aye mi niwaju awọn eniyan gẹgẹ bi ọkọ ati aya? “Rere li obirin na yio ma ṣe fun u, ki iṣe buburu li ọjọ aiye rẹ gbogbo”.
Iṣoore
“O fi ọgbọn ya ẹnu rè̩: ati li ahọn rẹ li ofin iṣeun” (Ẹsẹ 26). Wo ọpọlọpọ igba ti awọn eniyan n gbagbé lati ṣoore! “Ifẹ a ma mú suru, a si ma ṣeun” (I Kọrinti 13:4). Oun a maa ṣoore ki iṣe fun kiki awọn ọrẹ rè̩ ati awọn ẹlẹgbẹ rè̩ ti o sunmọọ, ki isi iṣe ni igba kookan. Iṣoore jẹ ofin fun un. Oun a maa ṣore lai ronu nipa rè̩. Gbogbo eniyan ni o kà yẹ lati ṣoore fun, ati awọn ti kò tilẹ fẹran rè̩ pẹlu. O le gbadura fun awọn ti n fi arankan ba a lò. “Ifẹ ki iṣe ilara; ifẹ ki isọrọ igberaga, ki ifè̩.” Eso ti Ẹmi ni ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwa pẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwa tutu, ati ikora-ẹni-nijanu” (Galatia 5:22, 23). IfẹỌlọrun si ni fun wa lati so iru eso bawọnyi lọpọlọpọ. Iru eso wọnyi a maa ti inu kiki ọkàn ti o kún fun ifẹỌlọrun jade wa.
Ririn yẹ
Paulu Apọsteli sọ fun wa: “Ki ẹnyin ki o ma rin bi o ti yẹ fun ipe na ti a fi pe nyin pẹlu irẹlẹ gbogbo ati inu tutu, pẹlu ipamọra, ẹ ma fi ifẹ farada a fun ẹnikeji nyin; ki ẹ si ma lakaka lati pa iṣọkan Ẹmi mọ ni idipọ alafia” (Efesu 4:1-3).
Bi a ba wipe Onigbagbọ niawa iṣe a nilati fihan nipa igbesi-aye wa. Ero ti o gajulọ ninu ọkàn ọmọỌlọrun ni lati wà ni imurasilẹ nigbati Jesu ba de. Oun a maa gbiyanju lati tẹsiwaju lojojumọ ki oun ba le ni gbogbo ọṣọẹmi ti o yẹ. Oun a ma ka ẹsẹ bi iru eyi: “Ẹ ma si ṣe mu Ẹmi MimọỌlọrun binu, ẹniti a fi ṣe edidi nyin dèọjọ idande. Gbogbo iwa kikorò, ati ibinu, ati irunu, ati ariwo, ati ọrọ buburu, ni ki a mu kuro lọdọ nyin” (Efesu 4:30, 31). Oun a ma bẹỌlọrun lati ran an lowọ lati mu aye rẹ ba Ọrọ naa mu. Oun ki ima wo tabi ki o maa sọrọ nipa abuku ti o wà ni igbesi-aye ẹlomiran.
“Maṣe ma wa abuku kiri bi o ti n lọ li aye,
Nigbati o ba tilẹ ri wọn
O dara o si jẹ ohunrere lati mu oju rẹ kuro ninu wọn
Ki o si ma wa ire ti o wa lẹhin wọn.”
“Nitorina bi ayanfẹỌlọrun, ẹni mimọ ati olufẹ, ẹ gbe ọkàn iyọnu wọ, iṣeun, irẹlẹ, inu tutu, ipamọra” (Kolosse 3:12). Iru wọnyi ni iwa Iyawo Kristi.
Iṣẹ Iyawo
“Ati Ẹmi ati iyawo wipe, Mā bọ” (Ifihan 22:17). Iṣẹ Iyawo Kristi ni eyi. Oun a maa ba Ẹmi ṣiṣẹ lati pe awọn ẹlè̩ṣè̩ wa si ironupiwada. Oun a ma mu “onjẹ rè̩ lati ọna jijin rere wa” (Owe 31:14), a si maa fi awọn ohun ti Ọrun bọọkàn rè̩. Oun kò tun ni ifé̩ si ohun ti aye yi ju bi o ti yẹ lati gba ọkan rè̩ kan titi Jesu, Ọkọ Iyawo ọkàn rè̩, yoo fi de.
Questions
AWỌN IBEERE1 Kin ni a mọ nipa akoko ti Jesu yoo de?
2 Kin ni ṣẹlẹ si wa nigbati a ba da wa lare?
3 Kin ni isọdimimọ n ṣe fun wa?
4 Kin ni Jesu wi pe Ẹmi Mimọ yoo sọ fun wa?
5 Njẹ nisisiyi igbagbọ, ireti, ati ifẹ mbẹ, ewo ni o tobi ju?
6 Kin ni Jesu wi pe o kuna ninu ijọ Efesu?
7 Kin ni ọkunrin ọlọgbọn nì sọ nipa iṣoore obinrin oniwa rere nì?
8 Kin ni eso ẹmi?
9 Kin ni iṣẹ Iyawo Kristi?