Isaiah 7:14; 9:1-7; 11:1-5; 42:1-4; 53:1-12

Lesson 364 - Junior

Memory Verse
“Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa” (Isaiah 9:6).
Notes

Messia ti a S̩eleri

Nigbati a bi Jesu ni Bẹtlẹhẹmu, ọpọlọpọ ileri Ọlorun ni a muṣẹ. Lati igba ọkunrin akọkọ ati obinrin akọkọ, ni ileri Olugbala ti wà. Lẹhin ti Adamu ati Efa dẹṣẹ, Oluwa sọ fun ejo pe: “Emi o si fi ọta sarin iwọ ati obirin na, ati sarin irú-ọmọ rè̩ ati irú-ọmọ rẹ: on o fọọ li ori, iwọ o si pa ni gigisẹ” (Gẹnẹsisi 3:15).

Eyi ni ileri kini nipa Messia (Ẹni Ami-ororo), Olugbala ti yoo gba awọn eniyan la kuro ninu è̩ṣẹ wọn (Matteu 1:21).

p]

Lẹhin eyi, Ọlọrun ṣe ileri kan fun Abrahamu: “Ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye” (Gẹnẹsisi 12:3), eyiti a muṣẹ ninu Jesu Kristi. Bi ọdun ti n gori ọdun a n mú majẹmu Ọlọrun pẹlu Abrahamu wa si iranti awọn Ju. Awọn woli n sọ fun wọn leralera nipa Messia wọn ti n bọwa. Isaiah sọ asọtẹlẹ pupọ nipa wiwa Kristi ju eyikeyi ninu awọn woli lọ.

Woli Kan

Isaiah jẹ woli Juda. O fẹrẹ jẹ pe akoko kanna ti Amọsi ati Hosea n wasu ni Isaiah pẹlu n wasu. O jẹ olootọ woli Oluwa lati igba Ussiah titi di ọjọ Hẹsekiah (Isaiah 1:1). Itan sọ fun wa pe iku ajẹriku ni Isaiah ku nitori awọn ohun ti o wasu nipa Ọlọrun.

Lati sọtẹlẹ ni lati sọ ohun ti n bọwa ṣẹ lọjọ iwaju ṣiwaju akoko rè̩ tabi lati wasu. Ọlọrun n fi awọn ohun ti n bọwa ṣẹlẹ lọjọ iwaju han awọn woli Rè̩, o si misi wọn lati sọ ati lati kọ akọsilẹ awọn ohun wọnni ti Ọlọrun yoo muṣẹ. Ninu Bibeli a ka nipa awọn asọtẹlẹ ati akoko ti ọpọlọpọ ninu wọn yoo ṣẹlẹ.

Ibi Kristi

Ẹ jẹki a ṣe ayẹwo diẹ ninu awọn asọtẹlẹ Isaiah nipa Kristi. Isaiah kọ akọsilẹọrọ Oluwa: “Nitorina, Oluwa tikalarẹ yio fun nyin li ami kan. Kiyesi I, Wundia kan yio loyun, yio si bi ọmọkunrin kan, yio si pe orukọ rè̩ ni Immanuẹli.” Eyi ni yoo jẹ ami pe ọmọ na ni Messia ti a ti ṣeleri. Fun eyi lati ṣẹlẹ yoo jẹ iṣẹ-iyanu nitoripe yoo jẹ ohun abami. Jesu jẹỌmọỌlọrun a si nilati nireti pe ki ibi Rè̩ jẹ iyanu ati iṣẹ-àrà, ki o si yatọ lọna kan si ibi ti ọmọ miran. Njẹ asọtẹlẹ iru eleyi le ṣẹ? Bẹni o ṣẹlẹ. Nipa ibi Jesu a kà a pe angẹli kan sọ fun Maria, wundia, pe oun yio jẹ iya ọmọkunrin kan ẹniti oun yoo pe ni “JESU” (Luku 1:27, 31).

Nigbati akoko to, Maria bi Jesu (Matteu 2:1, 11). “Gbogbo eyi si ṣẹ, ki eyi ti a ti sọ lati ọdọ Oluwa wá li ẹnu woli ki o le ṣẹ” (Matteu 1:22).

Nitoripe ibi Jesu yi jẹ iṣẹ iyanu ti ko ye awọn eniyan, wọn kò fẹ gba a gbọ. S̩ugbọn Bibeli jẹ otitọ, awon ti o fẹ Oluwa gbà ohun ti o sọ gbọ. Jesu jẹỌmọỌlọrun Oun nikan si ni Ẹniti o le mú asọtẹlẹ yi ṣẹ. Jesu ki i ṣe eniyan nikan. ỌmọỌlọrun ni Oun iṣe.

Awọn Orukọ Rẹ

Jẹsu jẹẸni iyanu tobẹẹ ti a fi n pe E ni ọpọlọpọ orukọ, Woli ni ti sọ pe orukọ Rè̩ yoo jẹ Immanuẹli, itumọ eyiti I ṣe “Ọlọrun wà pẹlu wa.” Angẹli naa wipe, “Jesu ni iwọ o pè orukọ rè̩: nitori on ni yio gbà awọn enia rè̩ là kuro ninu è̩ṣẹ wọn” (Matteu 1:21). Jesu tun ni awọn orukọ miran pẹlu. Woli Isaiah wipe: “A o si ma pe orukọ rẹ ni Iyanu, Oludamọran, Ọlorun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia.” Lode oni a ma n saba tọka si Jesu pẹlu ọkan ninu awọn orukọ wọnyi ninu orin ati iwasu. Orukọ kanṣoṣo kò le ṣapejuwe Jesu. Yoo gba lilo pupọ ninu wọn lati sọ nipa titobi Rè̩. Jesu paapaa tilẹ fikun awọn orukọ wọnyi. O wipe: “Emi ni oluṣọ-agutan rere” (Johannu 10:11); “Emi li ọna, ati otitọ, ati iye” (Johannu 14:6); ati “Emi ni ilẹkun” (Johannu 10:9). Boya iwọ na le fikún akọsilẹ ti a ka silẹ nihin. Ẹnikan ti kà orukọ ti o le ni ọgọrun ninu Bibeli ti a fi n pe Jesu.

Ijọba Rè̩

Isaiah sọ asọtẹlẹ nipa Ijọba Jesu ati akoso ijọba Rè̩. Loni ninu ọkàn wa Oun ni I ṣe Ọba ati Alaṣẹ aye wa. Ọjọ na m bọ ti jesu yoo gbà ipo Rè̩ gẹgẹ bi Alaṣẹ lori ohun gbogbo, “ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA” (Ifihan 19:16). Ijọba Kristi ki yio nipẹkun. Oun yoo jọba titi lai (Heberu 1:8; Ifihan 11:15).

Ijọba Rè̩ jẹ ijọba alafia ati ododo. Woli jeremiah sọrọ nipa ijọba Kristi pẹlu. Jeremiah wi pe: “Yio si jẹỌba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na” (Jeremiah 23:5).

Ijọba Kristi yoo yatọ si ti eniyan. “Yio mu idajọ wa si otitọ. Arè̩ ki yio mú u, a ki yio si daiya fò o, titi yio fi gbe idajọ kalẹ li aiye” (Isaiah 42:3, 4). Oun ki yoo ṣe idajọ gẹgẹ bi iri oju, tabi gẹgẹ bi nkan ti dabi ẹnipe o ri, ṣugbọn ijọba Rè̩ yio jẹ ti otitọ ati ododo. “On ki yio si dajọ nipa iri oju rè̩, bḝni ki yio dajọ nipa gbigbọ eti rè̩; ṣugbọn yio fi ododo ṣe idajọ talakà, yio si fi otitọṣe idajọ fun awọn ọlọkàn tùtu aiye” (Isaiah 11:3, 4). Idajọ Rè̩ yio jẹ ododo nitoripe “ẹmi Oluwa yio si bà le e,” yio si fun Un ni “ẹmi ọgbọn ati oye, ẹmi igbimọ ati agbara, ẹmi imọran ati ibè̩ru Oluwa.”

Aanu

A sọ asọtẹlẹ nipa Jesu pe Oun yoo jẹ alaanu. “Iye fifọ ni on ki yio ṣẹ.” Nigbati Jesu wà li aye, O fi aanu han fun awọn ti o wà ninu irora. O wo ọpọlọpọ ti wọn n ṣaisan sàn. O si fi itunu ati iranwọ fun awọn ti o wa A. Lode oni nigbati awọn ti a di ẹru wiwo le lori ti wọn si n jiya ba kepe E ninu adura, O n tu wọn silẹ. Onipsalmu wipe: “Oluwa mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn la” (Orin Dafidi 34:18).

Ijiya Rè̩

Isaiah pẹlu sọtẹlẹ nipa ijiya Olugbala. Ọpọlọpọọdun ṣiwaju kikan Kristi mọ agbelebu, Isaiah sọ awọn ọrọ wọnyi bi ẹnipe o ti ṣẹlẹ: “A ṣa a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ina alafia wa wà lara rè̩, ati nipa ina rè̩ li a fi mu wa lara da.” Nitootọ Jesu ta Ẹjẹ Rè̩ silẹ lati pa ẹṣẹ awọn ti o ba ronupiada ti wọn si gbagbọ ré̩. Jesu ta Ẹjẹ Rè̩ silẹ ki awọn eniyan ba le ri iwosan fun aisan ati arun wọn. Nigbamiran igbesi-aye Jesu ko fi bẹẹ barade. A korira Rè̩ a si gan An. “Awọn Farisi, ti nwọn fẹran owo si gbọ gbogbo nkan wonyi, nwọn si yọ-ṣuti si I” (Luku 16:14). “Awọn ọlọtọ ilu rè̩ korira rè̩, nwọn si ràn ikọ tẹle e wipe, Awa ko fẹ ki ọkunrin yi jọba lori wa” (Luku 19:14). Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ pe: “Bi aiye ba korira nyin, ẹ mọ pe, o ti korira mi ṣaju nyin” (Johannu 15:18).

Fun Wa

A sọ fun Jesu pe ki O fi ilẹ awọn ara Gadara silẹ (Marku 5:17). Wọn hùwa abùkù si I “ẹni ikanu, ti o si mọ ibanujẹ.” Gbogbo nkan wọnyi ni Kristi farada ki awa ba le ni igbala ati iye ainipẹkun. O jiya fun ẹṣẹ wa –“olõtọ fun awọn alaiṣõtọ” (I Peteru 3:18).

“A jẹẹ ni iya, a si pọn ọ loju, ṣugbọn on ko ya ẹnu rè̩.” Jesu ko wijọ bẹni kò si kun wipe Oun n jiya fun awọn ẹlomiran. Awọn ẹlomiran a maa fé̩ pe ki a ba wọn kẹdun, wọn a si maa wijọ nigbati o jẹ pe awọn tikarawọn ni o fa ijiya ati itiju wa sori ara wọn. Jesu ẹniti ko mọẹṣẹ ri ni a sọ di è̩ṣẹ fun wa. A sun Jesu lẹsun eke wọn si gbo O lẹjọ, ṣugbọn Oun ko tilẹ dà ati da ara Rè̩ lare; ọpọlọpọ igba ni ko tilẹ dahun ọrọ kan (Matteu 26:63; 27:14; Luku 23:9).

Jesu tikararẹ ni O yọọda ara Rè̩ fun awọn ẹlomiran. Gbogbo è̩ṣẹ wa li a di le E lori. O jiya fun wa. S̩ugbọn kin ni awa ṣe fun Un? Li akoko ajọyọ Keresimesi yi, nigbati a n fi ẹbun fun awọn ẹlomiran, a ha n fi aye wa ati iyin wa fun Un bi ẹbun? Ọlorun fun wa ni ẹbun ti o tobi julọ nigbati O fi Ọmọ Rè̩ fun wa. Lati ọdọ Rè̩ ni iwọ tile ni iye-ainipẹkun. O le ri igbala. Njẹ o ni i loni? Iwọ pẹlu le ni i, nipa gbigbadura, jijẹwọè̩ṣẹ rẹ, nipa kikọè̩ṣẹ rẹ silẹ, ati nipa gbigba awọn ileri Rè̩ gbọ.

Iku Jesu

Awọn asọtẹlẹ miran wà ti isaiah sọ ti a muṣẹ nigba iku Jesu. “A ti ke e kuro ni ilẹ alāye: nitori irekọja awọn enia mi li a ṣe lù u.” Iku Rè̩ wà “pẹlu awọn enia buburu” – laarin awọn ole meji (Matteu 27:38) – ati “pẹlu ọlọrọ” – ninu iboji Josẹfu (Matteu 27:59, 60).

Jesu Kristi, ỌmọỌlọrun, mu asọtẹlẹṣẹ nigbati a bi I ni Bẹtlẹhẹmu ti Judea. O mu asọtẹlẹṣẹ nigbati O fi Ẹmi Rè̩ lelè̩ ti o si “rùè̩ṣẹọpọlọpọ.” Nisisiyi paapaa, Kristi n mu asọtẹlẹṣẹ sibẹ nitoripe O wà li ọwọọtun Ọlọrun, O si n bẹbè̩ fun wa (Romu 8:34). “Nitorina o si le gba wọn la pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọỌlọrun wá nipasẹ rè̩, nitoriti o mbẹ lāye titi lai lati mā bè̩bè̩ fun wọn” (Heberu 7:25).

Isaiah jẹ eniyan Ọlọrun, ẹniti o sunmọỌlọrun timọtimọ ti o si ṣiṣẹ fun Ọlọrun. O ni anfaani nlánlà lati sọtẹlẹ nipa Kristi, ỌmọỌlọrun. A ti ka a ninu Bibeli pe ọpọlọpọ ninu asọtẹle wọnyi ni a ti muṣẹ. Awọn iyoku yoo si ṣẹ bakanna gẹgẹ bi a ti mu awọn miran ṣẹ. Ẹ jẹ ki a fi adura ati igbọran pese ara wa silẹ fun Ijọba Kristi ki a ba le wà pẹlu Rè̩ nibẹ. Ẹ jẹ ki a ṣe bẹẹ loni nipa sisin Ọmọ-ọwọ Bẹtlẹhẹmu naa.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Tani a n pe ni woli?

  2. 2 Darukọ diẹ ninu awọn woli.

  3. 3 Ewo ni o sọ pupọ nipa Kristi?

  4. 4 Kin niṣe ti ibi Jesu jẹ iṣẹàrà ati iṣẹ-iyanu?

  5. 5 Kin ni orukọ iya Jesu?

  6. 6 Kin ni ṣe ti Jesu jiya ti O si kú?

  7. 7 Asọtẹlẹ Isaiah wo ni a muṣẹ nigba iku Jesu?

  8. 8 Ewo ninu awọn asọtẹlẹ Isaiah nipa Kristi ni a kò iti muṣẹ?